Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 46


Ìpín 46

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí ìjọ, ní Kirtland, Ohio, 8 Oṣù Kejì 1831. Ní àkókò tí ìjọ bẹ̀rẹ̀ yìí, ìṣọ̀kan àpẹrẹ fún dídarí àwọn ìsìn Ìjọ kò tíì fìdí múlẹ̀. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àṣà gbígba kìkì àwọn ọmọ ìjọ àti àwọn onítara olùwádĩ wọlé sí àwọn ìpàdé oúnjẹ Olúwa àti àwọn ìpéjọ̀pọ̀ míràn ti Ìjọ ti fẹ́rẹ̀ di gbogbogbòò. Ìfihàn yìí ṣe àlàyé ìfẹ́ Olúwa nípa ṣíṣe àkóso àti ìdarí àwọn ìpàdé àti ìtọ́sọ́nà Rẹ̀ ní orí wíwá àti ṣíṣe ìdámọ̀ àwọn ẹ̀bùn ti Ẹ̀mí.

1–2, Àwọn alàgbà yíò darí àwọn ìpàdé bí Ẹ̀mí Mímọ́ bá ṣe tọ́ wọn sọ́nà; 3–6, Àwọn tí wọn nlépa òtítọ́ ni a kò níláti yọ kúrò nínú àwọn ìsìn oúnjẹ Olúwa; 7–12, Ẹ béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run kí ẹ sì máa lépa àwọn ẹ̀bùn ti Ẹ̀mí; 13–26, Àkọsílẹ̀ díẹ̀ nínú àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí ni a fi fúnni; 27–33, Àwọn aṣíwájú ìjọ ni a fún ní agbára láti ṣe ìdámọ̀ àwọn ẹ̀bùn ti Ẹ̀mí náà.

1 Ẹ fetísílẹ̀, Áà ẹ̀yin ènìyàn ìjọ mi; nítorí lõtọ́ ni mo wí fún yín pé àwọn ohun wọ̀nyí ni a sọ fún yín nítorí èrè yín àti ẹ̀kọ́ kíkọ́.

2 Ṣùgbọ́n bí àwọn ohun tí a ti kọ tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a ti fi ìgbà gbogbo fifún àwọn alagbà ìjọ mi láti ìbẹ̀rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni yíò sì wà títí láé, láti darí gbogbo àwọn ìpàdé bí wọn yío ṣe jẹ́ dídarí ati títọ́sọ́nà nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́.

3 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀ a paá láṣẹ fún yín láti má ṣe lé ẹnikẹ́ni jade kúrò nínú àwọn ìpàdé ti gbogbo ènìyàn láé, èyí tí a ṣe níwájú gbogbo ayé.

4 A paá láṣẹ fún yín bákannáà láti má ṣe lé ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ti ìjọ jade kúrò nínú àwọn ìpàdé oúnjẹ Olúwa yín; ṣùgbọ́n, bí ẹnikẹ́ni bá rékọjá, ẹ má ṣe jẹ́ kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ kópa títí tí òun yíò fi ṣe ìlàjà.

5 Àti lẹ́ẹ̀kansíi mo wí fún yín, ẹ̀yin kì yíò lé ẹnikẹ́ni jade kúrò nínú àwọn ìpàdé oúnjẹ Olúwa yín àwọn tí wọ́n nlépa ìjọba náà pẹ̀lú ìtara—èmi sọ ọ̀rọ̀ yìí nípa àwọn tí wọn kìí ṣe ti ìjọ.

6 Àti lẹ́ẹ̀kansíi mo wí fún yín, nípa àwọn ìpàdé fífi ìdì ẹni múlẹ̀, pe bí ẹnikẹ́ni bá wà tí wọn kìí ṣe ti ìjọ, tí wọ́n sì nlépa ìjọ̀ba náà pẹ̀lú ìtara, ẹ̀yin kì yíò lé wọn jáde.

7 Ṣùgbọ́n a pàṣẹ fún yín nínú ohun gbogbo láti béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, ẹni tí ó nfi fún ni lọ́pọ̀lọpọ̀; àti pé èyí tí Ẹ̀mí bá jẹ́rìí sí fún yín àní bẹ́ẹ̀ni èmi yío fẹ́ kí ẹ̀yin ṣe nínú gbogbo ọkàn mímọ́, ní rírìn déédé níwájú mi, pẹ̀lú rírò nípa òpin ìgbàlà yín, ní ṣíṣe ohun gbogbo pẹ̀lú àdúrà àti ìdúpẹ́, kí a má baà tàn yín jẹ nípasẹ̀ àwọn ẹ̀mí búburú, tàbí àwọn ẹ̀kọ́ ti èṣù, tàbí àwọn òfin ti ènìyàn; nítorí díẹ̀ jẹ́ ti àwọn ènìyàn, àti pé àwọn yókù jẹ́ ti èṣù.

8 Nítorínáà, ẹ kíyèsára bíbẹ́ẹ̀kọ́ a ó tàn yín jẹ; àti pé kí á má baà tàn yín jẹ, ẹ fi ìtara wá àwọn ẹ̀bùn tí ó dára jùlọ, ẹ máa fi ìgba gbogbo ṣe ìrántí ìdí rẹ̀ tí a fi fiwọ́n fúnni;

9 Nítorí lõtọ́ ni mo wí fún yín, a fi wọ́n fúnni fún ànfààní àwọn tí wọ́n fẹ́ràn mi tí wọ́n sì npa gbogbo àwọn òfin mi mọ́, àti ẹni náà tí ó nlépa láti ṣe bẹ́ẹ̀, kí gbogbo wọn lè jùmọ̀ jẹ ànfààní àní àwọn tí wọ́n nwá tàbí tí wọ́n nbéèrè mi, tí wọn kò béèrè fún àmi kan kí wọ́n lè lò ó fún àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn.

10 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, èmi nfẹ́ kí ẹ̀yin ó máa rantí nígbà gbogbo, àti kí ẹ fí ìgbà gbogbo paá mọ́ sí inú yín ohun tí àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí jẹ́, tí a fi fún ìjọ.

11 Nítorí a kò fún gbogbo ènìyàn ní gbogbo àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí; nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀bùn ni ó wà, àti pé olúkúlùkù ènìyàn ní a fún ní ẹ̀bùn kan nípa Ẹ̀mí Ọlọ́run.

12 Sí àwọn kan ni a fi ọ̀kan fún, àti sí àwọn míràn ni a fí òmíràn fún, kí gbogbo wọn lè jùmọ̀ jèrè nípa èyí.

13 Sí àwọn kan ni a fifún nípa Ẹ̀mí Mímọ́ láti mọ pé Jésù Krístì ni Ọmọ Ọlọ́run, àti pé a kàn án mọ́ àgbélèbú fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ aráyé.

14 Sí àwọn míràn ni a fifún láti gbàgbọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ wọn, kí àwọn pẹ̀lú lè ní ìyè ayérayé bí wọ́n bá tẹ̀síwájú láti jẹ́ olõtọ́.

15 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, sí àwọn kan ni a fifún nípa Ẹ̀mí Mímọ́ láti mọ àwọn ìyàtọ̀ àkóso iṣẹ́, bí ó ṣe lè jẹ́ inú dídùn sí Ọlúwa kannáà, gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ inú Olúwa, ní fífi àánú rẹ̀ hàn ní ìbámu pẹ̀lú ipo àwọn ọmọ ènìyàn.

16 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, a fi fúnni nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ fún àwọn díẹ̀ láti mọ onírúurú ọ̀nà àtiṣe iṣẹ́, yálà ó jẹ́ ti Ọlọ́run, kí á lè fi ìṣípayá ti Ẹ̀mí fún olúkúlùkù ènìyàn láti lè jẹ èrè pẹ̀lú rẹ̀.

17 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, àwọn díẹ̀ ni a fifún, nípa Ẹ̀mí Ọlọ́run, ọ̀rọ̀ ti ọgbọ́n náà.

18 Ẹlòmíràn ni a fi ọ̀rọ̀ òye fún, kí á lè kọ́ gbogbo ènìyàn láti gbọ́n àti láti ní òye.

19 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, àwọn kan ni a fi fún láti ní ìgbàgbọ́ lati di wíwòsàn;

20 Àti àwọn míràn ni a fí fún láti ní ìgbàgbọ́ láti ṣe ìwòsàn.

21 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, àwọn kan ni a fi fún láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu;

22 Àti àwọn míràn ni a fifún láti sọ àsọtẹ́lẹ̀;

23 Àti fún àwọn míràn láti lè ṣe ìdámọ̀ àwọn ẹ̀mí.

24 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, a fi fún àwọn kan láti fi èdè fọ̀;

25 Àti fún ẹlòmíràn ni a fi fún láti ṣe ìtúmọ̀ èdè.

26 Gbogbo àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí sì wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, fún ànfààní àwọn ọmọ Ọlọ́run.

27 Àti fún bíṣọ́pù ìjọ, àti fún irú àwọn tí Ọlọ́run yíò yàn àti tí yío fi jẹ oyè láti ṣe ìṣọ́ ní orí ìjọ àti láti jẹ́ àwọn alàgbà fún ìjọ, ni wọ́n níláti jẹ́ kí a fifún wọn láti lè dá gbogbo àwọn ẹ̀bùn wọnnì mọ̀, bí bẹ́ẹ̀kọ́ ẹ̀nikẹ́ni lààrin yín yíò máa jẹ́wọ́ àti síbẹ̀ tí kìí ṣe ti Ọlọ́run.

28 Yíò sì ṣe pé ẹni tí ó bá béèrè nínú Ẹ̀mí yíò rí gbà nínú Ẹ̀mí;

29 Pé a lè fifún àwọn díẹ̀ láti ní gbogbo àwọn ẹ̀bùn wọnnì, kí olórí kan le wà, pé kí olúkúlùkù ọmọ ìjọ ó lè jèrè nípa bẹ́ẹ̀.

30 Ẹnikẹ́ni tí ó bá béèrè nínú Ẹ̀mí béèrè gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ inú Ọlọ́run; nítorínáà a ṣe é fún un àní bí òun ti béèrè.

31 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, mo wí fún yín, a gbọ́dọ̀ ṣe ohun gbogbo ní orúkọ Krístì, ohunkóhun tí ẹ̀yin bá ṣe nínú Ẹ̀mí;

32 Àti pé ẹ̀yin gbọ́dọ̀ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run nínú Ẹ̀mí fún èyíkéyìí ìbùkún tí a bá fi bùkún yín.

33 Àti pé ẹ̀yin gbọ́dọ̀ hu ìwà rere àti mímọ́ ní iwájú mi láìdúró. Àní bẹ́ẹ̀ ni. Amin.