Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 66


Ìpín 66

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Hiram, Ohio, 29 Oṣù Kẹwàá 1831. William E. McLellin ti bẹ Olúwa ní ìkọ̀kọ̀ lati sọọ́ di mímọ̀ nípasẹ̀ Wòlíì ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè márũn, èyítí kò jẹ́ mímọ̀ sí Joseph Smith. Ní bíbéèrè láti ọwọ́ McLellin, Wòlíì béèrè lọ́wọ́ Olúwa ó sì gba ìfihàn yí.”

1–4, Májẹ̀mú àìlópin náà ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere; 5–8, Àwọn alàgbà ni wọn yíò máa wàásù, jẹ́rìí, wọn yíò sì máa sọ àsọyépọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn; 9–13, Ìsìn iṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú òtítọ́ fúnni ní ìdánilójú ogún ìní ìyè ayérayé.

1 Kíyèsíi, báyìí ni Olúwa wí fún ìránṣẹ́ mi William E. McLellin—Ìbùkún ni fún ìwọ, níwọ̀nbí ìwọ ti yípadà kúrò nínú àwọn àìṣedéédé rẹ, tí ìwọ sì ti gba àwọn òtítọ́ mi, ni Olúwa Olùràpadà rẹ, Olùgbàlà aráyé wí, àní ti iye àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ nínú orúkọ mi.

2 Lõtọ́ ni mo wí fún ọ, ìbùkún ni fún ìwọ fún gbígba májẹ̀mú àìlópin tèmi, àní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere mi, tí a rán jáde wá sí àwọn ọmọ ènìyàn, pé kí wọ́n ó lè ní ìyè àti kí a sì mú wọn jẹ́ alábàápín nínú àwọn ògo tí a ó sọ di fífihàn ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn, bí a ṣe kọọ́ láti ọwọ́ àwọn wòlíì àti àwọn àpóstélì ní àwọn ọjọ́ wọnnì.

3 Lõtọ́ ni mo wí fún ọ, ìránṣẹ́ mi William, pé ìwọ mọ́, ṣùgbọ́n kìí ṣe nínú ohun gbogbo; ronúpìwàdà, nítorínáà, nínú àwọn ohun wọnnì ti kò tọ́ ní ojú mi, ni Olúwa wí, nítorí Olúwa yíò fi wọ́n hàn fún ọ.

4 Àti nísisìyí, lõtọ́, èmi, Olúwa, yíò fi hàn fún ọ ohun tí èmi fẹ́ nípa rẹ, tàbí ohun tí ó jẹ́ ìfẹ́ inú mi nípa rẹ.

5 Kíyèsíi, lõtọ́ ni mo wí fún ọ, pé ìfẹ́ inú mi ni pé kí ìwọ ó kéde ìhìnrere mi láti ilẹ̀ dé ilẹ̀, àti láti ìlú nlá dé ìlú nlá, bẹ́ẹ̀ni, ni àwọn agbègbè wọnnì káàkiri ní ibi tí a kò tíì kéde rẹ̀ dé.

6 Máṣe dúró fún ọjọ́ púpọ̀ níhĩn yìí; má sì tíì lọ sí ilẹ̀ Síónì nísisìyí; ṣùgbọ́n níwọ̀nbí ìwọ bá lè fi ránṣẹ́, fi ránṣẹ́; bíbẹ́ẹ̀kọ́, máṣe ronú nípa àwọn ohun ìní rẹ.

7 Lọ sí àwọn ilẹ̀ ìlà oòrùn, jẹ́rìí ní ibi gbogbo, sí olúkúlùkù àwọn ènìyàn àti nínú àwọn sínágọ́gù wọn, ní sísọ àsọyé pẹ̀lú àwọn ènìyàn náà.

8 Jẹ́ kí ìránṣẹ́ mi Samuel H. Smith lọ pẹ̀lú rẹ, má sì ṣe kọ̀ ọ́ sílẹ̀, kí o sì fún un ní àwọn ìtọ́sọ́nà; àti ẹni náà tí ó bá jẹ́ olõtọ́ ní a ó sọ di alágbára níbi gbogbo; àti pé èmi, Olúwa, yíò lọ pẹ̀lú yín.

9 Gbé ọwọ́ rẹ lé aláìsàn, ara wọn yíò sì dá. Máṣe padà títí tí èmi, Olúwa, yíò fi rán ọ. Ní sùúrù nínú ìpọ́njú. Béèrè, ìwọ yíò sì rí gbà; kàn ìlẹ̀kùn, a ó sì ṣí i fún ọ.

10 Máṣe wá ìṣòro. Kọ gbogbo àìṣòdodo sílẹ̀. Máṣe ṣe àgbèrè—ìdẹwò pẹ̀lú èyí ti ìwọ ti ní ìdààmú.

11 Pa àwọn ọ̀rọ wọ̀nyí mọ́, nítorí wọ́n jẹ́ òtítọ́ àti òdodo; ìwọ yíò sì gbé ipò iṣẹ́ rẹ ga, ìwọ yíò sì ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lọ sí Síónì pẹ̀lú àwọn orin ayọ̀ àìlópin ní orí wọn.

12 Tẹ̀ síwájú nínú àwọn nkan wọ̀nyí àní títí dé òpin, ìwọ yíò sì ní adé ìyè ayérayé ní ọwọ́ ọ̀tún Bàbá mi, ẹnití ó kún fún ore ọ̀fẹ́ àti òtítọ́.

13 Lõtọ́, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, Olùràpadà rẹ wí, àní Jésù Krístì. Amin.