Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 73


Ìpín 73

Ìfihàn tí a fi fún Wòlíì Joseph Smith àti Sidney Rigdon, ní Hiram, Ohio, 10 Oṣù Kínní 1832. Láti apákan ìbẹ̀rẹ̀ Oṣù Kejìlá tí ó ṣaájú, Wòlíì náà àti Sidney ti lọ́wọ́ nínú wíwàásù, àti ní ọ̀nà yìí wọ́n ṣe àṣeyọrí púpọ̀ ní ṣíṣe àdínkù àwọn ìmọ̀lára àìníojúrere tí ó ti dìde tako ìjọ (wo àkọlé sí ìpín 71).

1–2, Àwọn alàgbà ni wọn yíò tẹ̀síwájú láti wàásù; 3–6, Joseph Smith àti Sidney Rigdon ni wọn yíò tẹ̀síwájú ní ṣiṣe ìtúmọ̀ Bíbélì títí tí yíò fi parí.

1 Nítorí lõtọ́, báyìí ni Olúwa wí, ó tọ̀nà ní ojú mi pé kí wọ́n ó tẹ̀síwájú ní wíwàásù ìhìnrere, àti ní sísọ ọ̀rọ̀ ìyànjú sí àwọn ìjọ Ọlọ́run ní àwọn agbègbè yíkáàkiri, títí di ìpáde àpéjọpọ̀;

2 Àti nígbànáà, kíyèsíi, a ó sọ ọ́ di mímọ̀ fún wọn, nípa ohùn ìpàdé àpéjọpọ̀, onírúurú àwọn iṣẹ́ ìránṣẹ́ wọn.

3 Nísisìyí, lõtọ́ ni mo wí fún yín ẹ̀yin ìránṣẹ́ mi, Joseph Smith Kékeré, àti Sidney Rigdon, ni Olúwa wí, ó tọ̀nà láti túmọ̀ lẹ́ẹ̀kansíi;

4 Àti pé, níwọ̀nbí ó bá ṣeéṣe, láti wàásù ní àwọn agbègbè yíkáàkiri títí ìpàdé àpéjọpọ̀; àti lẹ́hìn náà ó tọ̀nà kí iṣẹ́ ìtumọ̀ ó tẹ̀síwájú títí tí yíò fi parí.

5 Ẹ sì jẹ́ kí èyí jẹ́ àpẹrẹ kan sí àwọn alàgbà títí tí ìmọ̀ yíò fi tẹ̀ síwájú, àni bí a ṣe kọ ọ́.

6 Nísisìyí èmi kò fi fũn yín ju èyí lọ ní àkókò yìí. Ẹ di àmùrè yín kí ẹ sì ronújinlẹ̀. Àní bẹ́ẹ̀ni. Àmín.