2021
Jésù Ṣe Ìrìbọmi
Oṣù Kejì (Èrèlé) 2021


“Jésù Ṣe Ìrìbọmi,” Fríẹ́ndì, Oṣù Ìkejì (Èrèlé) 2021

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Frẹ́ndì, Oṣù Ìkejì (Èrèlé) 2021

Jésù Ṣe Ìrìbọmi

Jòhánù Onírìbọmi nkọ́nì

Àwọn Ìjúwe láti ọwọ́ Apryl Stott

Jòhánù Onírìbọmi jẹ́ wòlíì nlá kan. Ó kọ́ àwọn ènìyàn láti ronúpìwàdà kí wọ́n sì ṣe ìrìbọmi wọn.

Jòhánù Onírìbọmi nkọ́nì

Ní ọjọ́ kan Jòhánù nṣe ìrìbọmi fún àwọn ènìyàn nínú Odò Jọ́dánì. Jésù wá ó sì ni kí Jòhanù ṣe ìrìbọmi fún Òun. Jòhánù mọ̀ pé Jésù kò ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan. Nítorínáà kínìdí tí Jésù fi fẹ́ ṣe ìrìbọmi?

Jésù Krístì

Jésù wípé Òun nílò láti gbọ́ran sí gbogbo àwọn òfin. Ṣíṣe ìrìbọmi jẹ́ òfin kan.

Jòhánù Onírìbọmi nṣe ìrìbọmi fún Jésù

Lẹ́hìn tí Jòhánù ṣe ìrìbọmi fún Jésù, ẹyẹ-àdàbà kan wá láti fihàn pé Ẹ̀mí Mímọ́ wà níbẹ̀. Ohùn Bàbá Ọ̀rún wá láti ọ̀run, ó wípé, “Èyí ni àyànfẹ́ Ọmọ mi, ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi” (Máttéù 3:17).

Bàbá àti ọmọbìnrin ní ìrìbọmi.

A lè gbọ́ran sí àwọn òfin kí a sì yàn láti ṣe ìrìbọmi, bíiti Jésù. Lẹ́hìnáà a le gba ìfẹsẹ̀múlẹ̀ àti ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ pẹ̀lú.

Kíkùn Ojú-ewé

Èmí Dúpẹ́ fún Ara Mi

kíkùn ojú-ewé