“Ìtàn Ọdún Àjínde,” Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹrin 2021
Oṣooṣù Fríẹ́ndì , Oṣù Kẹ́rin gbe) 2021
Ìtàn Ọdún Àjínde
Jésù nifẹ àwọn Ọ̀rẹ́ Rẹ. Ó fọ ẹsẹ̀ wọn. Lẹ́hìnnáà Ó fún wọn ní oúnjẹ Olúwa. Ó wí fún wọn kí wọ́n rántí Òun. Ó wí fún wọn kí wọ́n fẹ́ràn ara wọn.
Lẹ́hìnnaa, Jésù lọ sí ọgbà kan. Ó gbàdúrà fún gbogbo wa. Ó ní ìmọ̀lara ìrora àwọn àísàn wa. Ó ní ìmọ̀lara ìrora àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.
Àwọn ènìyàn tí wọ́n nbínú gbé Jésù lọ. Wọ́n pa Á lára. Ó kú lórí igi àgbélébu fún wa. Àwọn ọ̀rẹ́ Rẹ gbé ara Rẹ̀ sí ibojì kan.
Ọjọ́ mẹta lẹ́hìnnaa, àwọn ọ̀rẹ́ Rẹ̀ padà wa. Ibojì náà ṣófo! Àwọn angẹ́lì sọ fún wọn pé, “Ó ti jíìnde.” Jésù wà láàyè lẹ́ẹ̀kansi! Nítorí Jésù, gbogbo wa yìó yè lẹ́ẹ̀kan si lẹ́hìn tí a bá kú.
Jésù nifẹ mi. Mo lè jẹ́ kí Ọdún Àjíìde jẹ́ pàtàkì nipa rírántí Rẹ̀.
© 2021 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ni a fipamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ èdè Gẹ̀ẹ́sì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà-èdè: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè ti Ọ̀rọ̀ Fríẹ́ndì, Oṣù Ìkínní 2021. Yoruba 17467 000