“Kínni Olùgbàlà Wa Ti Ṣe fún Wa?,” Fún Òkún àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù karun 2021.
Abala Oyè Àlùfáà
Kínni Olùgbàlà Wa Ti Ṣe fún Wa?
Àwọn àkọsílẹ̀
Kínni Jésù Krístì ti ṣe fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa? Ó ti ṣe ohun gbogbo tí ó ṣe kókó fún ìrìnàjò wa nínú ayé ikú yi já sí ọ̀nà àyànmọ́ tí a ti là sílẹ̀ nínú ètò ti Baba wa Ọrun. Èmi ó sọ̀rọ̀ nípa mẹ́rin nínú àwọn ẹ̀yà patàkì ti ètò náà. …
Àjínde náà nfún wa ní ìgbìrò àti okun láti farada àwọn ìpènijà ayé ikú tí ó dojúkọ ẹnìkọ̀ọkan wa àti àwọn wọnnì tí a fẹ́ràn. Ó nfún wa ní ọ̀nà titun láti wo àwọn àìpé ara, ọpọlọ, tàbí ẹ̀dùn ọkàn tí a ní ní ìgbà ìbí tàbí tí a gbà ní àkókò ayé ikú. Ó nfún wa ní okun láti fi ara da àwọn ìbànújẹ́, àwọn ìjákulẹ̀, àti àwọn ìrẹ̀wẹ̀sì.
Àjínde bákannáà nfún wa ní ìwúrí alágbára kan láti pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ ní àkokò ìgbé ayé ikú wa. …
Olùgbàlà àti Olùrapadà wa fi ara da ìjìyà àìlóye láti di ìrúbọ kan fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ti gbogbo ara ikú tí yíò bá ronúpìwàdà. Ètùtù ìrúbọ yi fúnni ní òpin rere, ọ̀dọ́ àgùtàn mímọ́ láìsí àbàwọ́n, fún òpin ìwọ̀n ti ibi, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ti gbogbo aráyé. …
… Jésù kọ́ wa ní ètò ìgbàlà. Ètò yi wà pẹ̀lú Ìṣẹ̀dá, èrèdí ìgbé ayé, jíjẹ́ dandan àtakò, àti ẹ̀bùn ti ìṣojúẹni. Ó tún kọ́wa ní àwọn òfin àti àwọn májẹ̀mú tí a gbọdọ̀ gbọ́ràn sí àti àwọn ìlànà tí a gbọdọ̀ ní ìrírí láti mú wa padà sí ọ̀dọ̀ àwọn òbí wa Ọrun. …
Olùgbàlà wa ní ìmọ̀lára Ó sì mọ àwọn àdánwò wa, àwọn ìtiraka wa, àwọn ìrora ọkàn wa, àti ìjìyà wa, nítorí Ó fi tìfẹ́tìfẹ́ ní ìrírí gbogbo wọn bíi apákan Ètùtù Rẹ̀. … Gbogbo ẹnití njìyà èyíkeyi àwọn àìpé níláti rántí pé Olùgbàlà wa ní ìrírí irú ìrora bẹ́ẹ̀ bákannáà, àti pé nípasẹ̀ Ètùtù Rẹ̀, Ó nfún ẹ̀nìkọ̀ọ̀kan wa ní okun láti gbé e.