“Jésù Krístì Fún Wa ní Oúnjẹ Olúwa,” Fríẹ́ndì, Osù kẹfà 2021
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì , Osù kẹfà 2021
Jésù Krístì Fún Wa ní Oúnjẹ Olúwa
Jésù mọ̀ wípé àkókò Òun ní ílẹ̀ ayé tí fẹ́rẹ̀ parí. Ó kó àwọn Àpóstélì Rẹ̀ jọ fún Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. Ó fún wọn ní oúnjẹ Olúwa ó sì ní kí wọ́n má a rántí Òun nígbàgbogbo.
Jésù lọ sí inú ọgbà láti gbàdúrà. A pa Á lara fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn ohun ìbànújẹ́ nínú ayé gbogbo ènìyàn. Lẹ́hìnnáà Ó kú lórí àgbelèbú a sì sín sínú ibojì.
Ní òwúrọ̀ Ọjọ́ ìsinmi lẹ́hìn tí Jésù kú, àwọn obìnrin kan wá sí ibojì. Wọ́n ti yí òkúta tí ó wà lẹ́nu ọ̀nà kúrò, inú ibojì sì ṣófo! Níbo ni Jésù wà?
Ó wà láàyè lẹ́ẹ̀kansi! Màríà Magalénì rí Jésù. Ó bẹ àwọn Àpóstélì Rẹ̀ wò kí wọ́n le gbáradì láti kọ́ ìhìnrere lẹ́hìn tí Ó bá ti padà lọ sí Ọ̀run.
Nígbàtí mo bá jẹ oúnjẹ Olúwa, mo nrántí Jésù. Mo rántí pé Ó wà láàyè Ó sì kú Ó sì jíǹde fún mi!
© 2021 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ni a fipamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà-èdè: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù kẹfà 2021. Yoruba. 17470 000