Jésù Sọ láti Pín Ìhìnrere náà,” Fríẹ́ndì, Oṣù kẹ́jọ 2021
Jésù Sọ láti Pín Ìhìnrere náà”
Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Titun fún àwọn Ọ̀dọ́ Olùkàwé
Jésù Sọ láti Pín Ìhìnrere náà
Lẹ́hìn ti Jésù kú tí ó sì jìnde, Ó bẹ àwọn tí wọ́n ntẹ̀le E wò. Ó wí fún àwọn Àpóstélì Rẹ láti kọ́ gbogbo ènìyàn láti pa àwọn òfin mọ́ kí wọn ó sì jẹ́ rírìbọmi.
Pétérù ni wòlíì nísisìyí tí yio darí Ìjọ náà ní ilẹ̀ ayé. Jésù ṣèlérí pé Ẹ̀mí Mímọ́ yio wà pẹ̀lú wọn.
Lẹ́hìn kíkọ́ àwọn tí wọ́n ntẹ̀le E, Jésù padà sí ọ̀run
Àwọn Àpóstélì bẹ̀rẹ̀ rírin ìrìnàjò àti kíkọ́ àwọn ènìyàn ní oríṣiríṣi àwọn ilẹ̀.
Èmi náà lè ṣè ìranlọ́wọ́ láti pín ìhìnrere bákanáà. Èmi lè jẹ́ ọ̀rẹ́ rere kan kí nsì dúró fún ohun tí ó tọ́.
© 2021 by Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ètọ́ ni a fi pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀pada-èdè: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè ti Ọ̀rọ̀ Fríẹ́ndì Oṣoòṣù, Oṣù Kẹ́jọ 2021. Yoruba. 17471 000