2021
Àwọn Lẹ́tà Páùlù
Oṣù Kẹsan 2021


“Àwọn Lẹ́tà Páùlù” Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Titun fún àwọn Ọ̀dọ́ Olùkàwé, 2019

“Àwọn Lẹ́tà Páùlù”

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Frẹ́ndì, , Oṣù Kẹ́san 2021

Àwọn Lẹ́tà Páùlù

1 Kọ́ríntì 1 ati Galátíà 1

Àpọ́stélí Páùlù ṣé ìrànlọ́wọ́ láti darí Ìjọ lẹ́hìn tí Jésù padà lọ sí ọrun. Nígbànáà sẹ́hìn, kò sí tẹlifóònì tàbí íntánẹ́ẹ̀tì. Nítorínáà Páùlù kọ lẹ́tà sí àwọn ọmọ Ìjọ.

Àwòrán
Obìrin nka lẹ́tà

Páùlù kọ̀wé sí àwọn ènìyàn tí ó wà ní ìlú Kọ́ríntì. Ó wí fún wọn kí wọ́n dáríji àwọn ẹlómíràn. Ó wí fún wọn kí wọ́n ní sùúrù. Ó kọ̀wé nípa Jésù.

Àwòrán
ọkùnrin nka lẹ́tà

Páùlù kọ̀wé sí àwọn ènìyàn tí ó wà ní ìlú Galátíà. Ó wí fún wọn kí wọ́n fẹ́ràn ọmọnìkejì wọn. Ó sọ fún wọn bí Ẹ̀mí ṣe rí lára.

Àwòrán
ọmọdé nka ìwé

Àwọn lẹ́tà Páùlù ṣe pàtàkì tí ó fi jẹ́pé wọ́n di ará Bíbélì. O lè kà wọ́n nínú Májẹ̀mú Titun.

Àwòrán
àwọn ọmọdé nwo ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò

Mo lè kẹkọ láti inú àwọn ìkọ́ni Páùlù. Èmi yío fetísílẹ̀ sí ohun tí wòlí àti àwọn àpọ́stélì nkọ́ni lónìí!

Kíkùn Ojú-ewé

Mo fẹ́ràn Bíbélì!

Àwòrán
ọmọ nka Bíbélì pẹ̀lú bàbá

Tẹ̀ àwòrán náà láti ṣe ìgbàsílẹ̀.

Àwọn Ìjúwe láti ọwọ́ Apryl Stott

Tẹ̀