2021
Àwọn Ìrìnàjò Iṣẹ́-ìránṣẹ́ Páùlù
Oṣù Kẹ́wàá (Ọ̀wàwà) 2021


“Àwọn Ìrìnàjò Iṣẹ́-ìránṣẹ́ Páùlù,” Fríẹ̀ndì, Oṣù Kẹ́wàá 2021

“Àwọn Ìrìnàjò Iṣẹ́-ìránṣẹ́ Páùlù”

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ̀ndì, Oṣù Kẹ́wàá 2021

Àwọn Ìrìnàjò Iṣẹ́-ìránṣẹ́ Páùlù

Fílíppì 4

Àpóstélì Páùlù rin ìrìnàjò lọ si àwọn ilẹ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti kọ́ àwọn ènìyàn nípa Jésù. Kò sí àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tàbí ọkọ̀ òfúrufú nígbà náà, nítorínáà o rìn lọ́pọ̀lọpọ̀! Nígbàmíràn ó rìn ìrìnàjò pẹ̀lú ọkọ̀ ojú-omi.

Àwòrán
Páùlù nkọ́ àwọn ènìyàn ní òpópónà ìlú-nlá kan

Páùlù kọ́ àwọn ènìyàn nínú àwọn ìjọ àti ilé. Ó kọ́ àwọn ènìyàn ní orí òkè àpáta àti òpópónà àwọn ìlú-nla.

Àwòrán
Páùlù nwo ẹyẹ láti ẹ̀hìn àwọn ẹ̀wọ̀n túbú.

Ọ̀pọ̀ ènìyàn kò fẹ́ràn ohun tí Páùlù kọni. Nígbàmíràn a ti rán Páùlù lọ sí túbú. Nígbàmíràn Páùlù ṣàìsàn.

Àwòrán
Páùlù nrìn ní ọ̀nà kan

Ṣùgbọ́n nínú gbogbo àwọn ohun líle wọ̀nyí, Páùlù ní ìgbàgbọ́. Ó wípé, “Mo lè ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ Krístì.” Ó mọ̀ wípé Jésù yio ràn òun lọ́wọ́ láti ní agbára.

Àwòrán
àwọn òbí nran ọmọbìnrin kan lọ́wọ́ láti wa kẹ̀kẹ́

Jésù Krístì lè ràn mí lọ́wọ́ láti ní agbára bákanáà. Ó nifẹ mi, àti pé mo nifẹ Rẹ̀!

Ojú-ewé Kíkùn

Jésù Lè Ràn Mí Lọ́wọ́ Láti Se Àwọn Ohun Líle

Àwòrán
ọmọ ngbàdúrà nígbàtí ìjì nlọ níta

Tẹ̀ àwòrán náà láti ṣe ìgbàsílẹ̀.

Àwọn Ìjúwe láti ọwọ́ Apryl Stott

Tẹ̀