“Ṣíwájú Kí A Tó Wá sí Ilẹ̀-ayé,” Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì , Oṣù Ìkínní 2022
“Ṣíwájú Kí A Tó Wá sí Ilẹ̀-ayé”
Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì , Oṣù Ìkínní 2022
Ṣíwájú Kí A Tó Wá sí Ilẹ̀-ayé
Ṣíwájú kí a tó bí wa, a gbé ní ọ̀run pẹ̀lú Baba Ọ̀run. Ó kọ́ wa nípa ètò ìdùnnú Rẹ̀.
Baba Ọ̀run wípé a ó wá sí ilẹ̀-ayé láti gba àwọn ara. A ó kẹkọ a ó sì ṣe àṣàyàn. Nígbàmíràn a ó ṣe àwọn àṣìṣe. A ó nílò Olùgbàlà kan.
Olùgbàlà yíò fihàn wá bí a ó ṣe gbé ìgbé-ayé. Àti nígbàtí a bá ṣe àṣàyàn ìṣìṣe, a ó lè ronúpíwàdà.
Jésù wípé, “Èmi nìyí, rán mi.” Baba Ọ̀run yàn Án láti jẹ́ Olùgbàlà wa. Jésù Ṣe ìlérí láti wá sí ilẹ̀-ayé láti gbà wá là.
Mo lè tẹ̀lé Jésù Níjọ́kan mo lè padà kí n sì gbe pẹ̀lú Baba Ọ̀run.
© 2021 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ni a fi pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà-èdè: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Ìkínní 2022. Yoruba. 18295 000