“Jósẹ́fù Múrasílẹ̀ fún àwọn Àkókò Líle,” Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì Oṣù Kẹta 2022
“Jósẹ́fù Múrasílẹ̀ fún àwọn Àkókò Líle”
Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì , Oṣù Kẹta 2022
Jósẹ́fù Múrasílẹ̀ fún àwọn Àkókò Líle
Jósẹ́fù jẹ́ wòlíì kan. Ó gbé ní Égíptì. Ní òru ọjọ́ kan Fáráò, ọba Égíptì, lá àlá àjèjì kan. Ó bi Jósẹ́fù léèrè ohun tí àlá rẹ̀ túmọ̀ sí.
Ọlọ́run ran Jósẹ́fù lọ́wọ́ láti ní òye àlá náà. Fún ọdún méje, àwọn ènìyàn yío ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ Lẹ́hìnnáà fún ọdún méje, àwọn ènìyàn kì yío ní tó. Jósẹ́fù sọ fún Fáráò.
Jósẹ́fù sọ pé kí wọn ó kó oúnjẹ pamọ́ nísisìyí. Nígbànáà wọn ó le gbáradì fún àwọn àkókò líle. Fáráò fi Jósẹ́fù sí ìdí oúnjẹ kíkó pamọ́. Jósẹ́fù ṣiṣẹ́ kára.
Nígbàtí ọdún méje ìyàn dé, àwọn ènìyàn náà ní anító oúnjẹ láti jẹ. Àní wọ́n ní ànító láti pín pẹ̀lú àwọ́n ẹlòmíràn.
Mo le múrasílẹ̀ nísisìyí. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, mo le la àwọn àkókò líle kọjá!
© 2022 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ni a fi pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà-èdè: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹta 2022. Yoruba 18296 779