“Ìwé-orin Dáfídì Kọ́ni Nípa Jésù Krístì,” Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹ́jọ 2022
“Ìwé-orin Dáfídì Kọ́ni Nípa Jésù Krístì”
Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹ́jọ 2022
Ìwé-orin Dáfídì Kọ́ni Nípa Jésù Krístì
Àwọn Ìwé-orin Dáfídì jẹ́ àwọn orin mímọ́. Àwọn ènìyàn inú Bíbélì kọ àwọn ìwé-orin làti yin Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára àwọn ìwé-orin Dáfídì kọ́ni nípa Jésù Krístì. Nihin ni àwọn ohun tí díẹ̀ lára àwọn ìwé-orin Dáfídì látinú Bíbélì kọ́ni.
Mo fẹ́ràn Olúwa. Òun ni àpàta àti okun mi. Èmi yíò gbẹ́kẹ̀lé E. Èmi yíò yìn Ín.
Olúwa Ni Olùṣọ́-àgùntàn Mi. Ó ndarí mi lọ síbi àwọn ọdán aláwọ̀-ewé. Ó ndarí mi lọ síbi omi jẹ́jẹ́. Èmi kò ní bẹ̀rù.
Olúwa Ni Ìmọ́lẹ̀ Mi Èmi kì yíò bẹ̀rù. Èmi ó ní ìgboyà. Òun yíò mú ọkàn mi le.
Mo fẹ́ràn Jésù Krístì, Óun sì fẹ́ràn mi. Èmi lè yìn Ín nígbàtí mò nkọ́ tí mo sì nkọrin nípa Rẹ̀.
© 2022 láti ọwọ́ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ni a fipamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà-èdè: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè ti Ọ̀rọ̀ Fríẹ́ndì Oṣoòṣù, Oṣù Kẹ́jọ 2022. Yoruba. 18316 779