“Ìsàíàh Kọ́ni nípa Jésù Krístì,” Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì , Oṣù Kẹsan 2022
“Ìsàíàh Kọ́ni Nípa Jésù Krístì”
Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Frẹ́ndì, , Oṣù Kẹ́san 2022
Ìsàíàh Kọ́ni nípa Jésù Krístì
Ìsáíáh jẹ́ wòlíì kan. Ó gbé ṣíwájú kí a tó bí Jésù Krístì. Ṣùgbọ́n ó mọ̀ pé Jésù yíò wá.
Ìsàíàh wípé a ó bí Jésù bí Ọmọ Ọlọ́run. Jésù yíò ṣèrànwọ́ yíò sì wo àwọn ẹlòmíràn sàn.
Ìsàíàh wí bákannáà pé Jésù yíò wá sí ilẹ̀-ayé. Òun ni a ó pè ní Ọmọ Aládé Àlááfíà. Òun yíò fi ayé Rẹ̀ fún wa nítorí Òun ní ìfẹ́ wa lọ́pọ̀lọpọ̀.
Àwọn ohun tí Ísáíàh kọ́ni ṣẹlẹ̀ gan. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lẹ́hìnnáà, Jésù wá sí ilẹ̀ ayé. Ó fi ọ̀nà hàn wá. Ó kú ó sì yè lẹ́ẹ̀kansi. Ó wà láàyè ní òní!
Èmi lè kọ́ ẹ̀kọ́ nípa Jésù Krístì. Nígbàtí mo rántí ohun tí Ó ti ṣe fún mi, mo lè ní ìmọ̀lára àlááfíà àti ìrètí!
© 2022 láti ọwọ́ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ni a fipamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹ́san 2022. Yoruba. 18299 779