2022
Ìsàíàh Kọ́ni Nípa Jésù Krístì
Oṣù Kẹsan 2022


“Ìsàíàh Kọ́ni nípa Jésù Krístì,” Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì , Oṣù Kẹsan 2022

“Ìsàíàh Kọ́ni Nípa Jésù Krístì”

Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Frẹ́ndì, , Oṣù Kẹ́san 2022

Ìsàíàh Kọ́ni nípa Jésù Krístì

Àwòrán
Ìsàìáh nkọ̀wé

Àwọn Ìjúwe láti ọwọ́ Apryl Stott

Ìsáíáh jẹ́ wòlíì kan. Ó gbé ṣíwájú kí a tó bí Jésù Krístì. Ṣùgbọ́n ó mọ̀ pé Jésù yíò wá.

Àwòrán
Ìsàíàh nsọ̀rọ̀

Ìsàíàh wípé a ó bí Jésù bí Ọmọ Ọlọ́run. Jésù yíò ṣèrànwọ́ yíò sì wo àwọn ẹlòmíràn sàn.

Àwòrán
Jósẹ́fù, Màríà, àti Jésù ọmọ-ọwọ́

Ìsàíàh wí bákannáà pé Jésù yíò wá sí ilẹ̀-ayé. Òun ni a ó pè ní Ọmọ Aládé Àlááfíà. Òun yíò fi ayé Rẹ̀ fún wa nítorí Òun ní ìfẹ́ wa lọ́pọ̀lọpọ̀.

Àwòrán
Jésù Krístì tí ó jínde

Àwọn ohun tí Ísáíàh kọ́ni ṣẹlẹ̀ gan. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lẹ́hìnnáà, Jésù wá sí ilẹ̀ ayé. Ó fi ọ̀nà hàn wá. Ó kú ó sì yè lẹ́ẹ̀kansi. Ó wà láàyè ní òní!

Àwòrán
Ìyá nkàwé sí àwọn ọmọ nípa Jésù Krístì

Èmi lè kọ́ ẹ̀kọ́ nípa Jésù Krístì. Nígbàtí mo rántí ohun tí Ó ti ṣe fún mi, mo lè ní ìmọ̀lára àlááfíà àti ìrètí!

Kíkùn Ojú-ewé

Èmi lè kọ́ ẹ̀kọ́ nípa Jésù Krístì

Àwòrán
Jésù Krístì ní ìkúnlẹ̀ láti bá obìnrin kan sọ̀rọ̀

Tẹ̀ àwòrán náà láti ṣe ìgbàsílẹ̀.

Ìjúwe láti ọwọ́ Apryl Stott

Kíni ìtàn tí o fẹ́ràn jùlọ nípa Jésù?

Tẹ̀