“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Àwọn Orúkọ Jésù,” Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kejìlá 2022
“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Àwọn Orúkọ Jésù”
Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kejìlá 2022
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Àwọn Orúkọ Jésù
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn wòlíì kọ́ni nípa Jésù Krístì. Wọ́n wípé a ó bí I láti fi bí a ó ti gbé ìgbé ayé hàn wá. Wọ́n lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orúkọ láti kọ́ni nípa Rẹ̀.
Nígbàmíràn nínú àwọn ìwé-mímọ́ a pe Jésù ní Ìmmánúẹ́lì. Orúkọ náà túmọ̀ sí “Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa.”
Bákannáà Jésù ni a pè ní Mèssíàh. Mèssíàh túmọ̀ sí “ẹni-àmì-òróró.” Jésù kú fún wa kí a lè gbé pẹ̀lú Ọlọ́run lẹ́ẹ̀kansi.
Jésù ni Olùgbàlà wa. Ó gbà wá là kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú wa.
Orúkọ míràn fún Jésù ni Ọmọ Aládé Àláfíà. Nígbàtí ẹ̀rù bá bà wá tàbí a bínú, Ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára àláfíà nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́.
Mo nifẹ Jésù Krístì. Mo lè kọ́ nípa ìgbé ayé àti ìfẹ́ Rẹ̀ nínú àwọn ìwé-mímọ́.
© 2022 láti ọwọ́ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ni a fipamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà-èdè: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kejìlá 2022. Yoruba 18318 779