2023
Jésù Jí Lásárù Dìde kúrò nínú Òkú
Oṣù Kẹrin 2023


“Jésù Jí Lásárù Dìde kúrò nínú Òkú,” Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹ́rin, 2023, 46–47.

Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹ́rin, 2023

Jésù Jí Lásárù Dìde kúrò nínú Òkú

Àwòrán
Jésù njoko pẹ̀lú Màríà, Mártà, àti Lásárù

Àwọn Ìjúwe láti ọwọ́ Apryl Stott

Màríà àti Mártà ní arákùnrin kan tí orúkọ̀ rẹ̀ njẹ́ Lásárù. Wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ Jésù Krístì.

Àwòrán
Jésù ndìmọ́ Màríà àti Mártà

Lásárù di aláárẹ̀ gidigidi. Láìpẹ́, ó kú. Màríà àti Mártà ní ìbànújẹ́. Nígbàtí Jésù wá, Ó sọkún pẹ̀lú wọn.

Àwòrán
Jésù ndúró ní ibojì Lásárù

Lẹ́hìnnáà Jésù lọ pẹ̀lú wọn sí ibojì Lásárù. Ó wípé, “Lásárù, jáde wá.”

Àwòrán
Jésù nran Lásárù lọ́wọ́ láti jáde síta nínú ibojì

Lásárù dìde ó sì rìn jáde nínú ibojì. Ó wà láàyè lẹ́ẹ̀kansi! Nítorí Jésù, gbogbo wa yìó yè lẹ́ẹ̀kan si bákannáà!

Kíkùn Ojú-ewé

Jésù Krístì Wà Láàyè

Àwòrán
Kíkùn ojú-ewé ti ọmọ kan tí ó ndi àwòrán Jésù mú

Ìjúwe láti ọwọ́ Apryl Stott

Báwo ni ẹ ti nrántí Jésù ní akokò Ọdún Àjínde?

Tẹ̀