“Wòlíì Pétérù,” Fríẹ̀ndì, Oṣù Kéje 2023, 46–47.
Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kéje 2023
Wòlíì Pétérù
Lẹ́hìn tí Jésù Krístì jínde tí ó sì lọ sí ọ̀run, Pétérù di wòlíì.
Pétérù kọ́ àwọn ènìyàn nípa ìrìbọmi àti Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ènìyàn yàn láti ṣe ìrìbọmi!
Ní ọjọ́ kan Pétérù rí ọkùnrin kan ní ìta tẹ́mpìlì. Ọkùnrin náà kò lè rìn. Pétérù wí pé, “Ní orúkọ Jésù Krístì, dìde kí o sì máa rìn.”
Ọkùnrin náà ni a wòsàn nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀! Pétérù kọ́ àwọn ènìyàn ní tẹ́mpìlì nípa Jésù Krístì.
© 2023 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ní a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà-èdè: 6/19. Ìyírọ̀padà ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kéje 2023. Language. 19045 779