“Igi Ìyè,” Fríẹ́ndì, Oṣù Kínní 2024, 26–27.
Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì , Oṣù Kínní 2024
Igi Ìyè
Léhì jẹ́ wòlíì kan. Ọlọ́run wí fun láti kó ẹbí rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ ìlérí. Nígbàtí wọ́n rin ìrìn àjò, ó lá àlá nípa igi ẹlẹ́wà. Igi ìyè ni a pè é.
Igi náà dàgbà nínú àdùn èsò funfun. Léhì nímọ̀lára ìdùnnú nígbàtí ó jẹ ẹ́! Ó nfẹ́ kí ẹbí òun gbìyànjú rẹ̀ bákannáà.
Léhì rí ọ̀pá irin tí ó darí lọ si ìdí igi náà pẹ̀lú. Àwọn ènìyàn di ọ̀pá náà mu láti dé idí igi náà àti láti jẹ èso náà.
Ìgi náà nínú àlá Léhì dàbí ifẹ́ Ọlọ́run. Ọ̀pá náà dàbí àwọn ìwé mímọ́. Nígbàtí a bá ka àwọn ìwé mímọ́, a nsúnmọ́ Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì si.
© 2024 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ní a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹ́ta 2024. Language. 19273 000