“Làìhónà,” Frẹ́ndì, Oṣù Kejì. 2024, 26–27.
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Frẹ́ndì, , Oṣù Kejì 2024
Lìáhónà
Olúwa wí fún Léhì láti lọ sí ilẹ̀ ìlérí pẹ̀lú ẹbí rẹ̀. Ṣùgbọ́n kò dá wọn lójú bí wọn ó ti dé bẹ̀.
Olúwa fún Léhì ní ohun èlò pàtàkì. Ó dàbí bọ́ọ̀lù. Ó júwe ọ̀nà tí wọn níláti lọ. Wọ́n pè é ní àfọ̀nàhàn.
Nígbàtí wọ́n bá pa àwọn òfin mọ́, àfọ̀nàhàn nṣiṣẹ́. Ó darí wọn sí ibi oúnjẹ àti ààbò. Ṣùgbọ́n nígbàtí wọ́n jiyàn tí wọ́n sì ṣe àìgbọ́ran, ó dáwọ́ ṣíṣe iṣẹ́ dúró.
Ẹbí Léhì tẹ̀lé afọ̀nàhàn kí wọ́n lè dé ilẹ̀ ìlérí. Nígbàtí a bá yan ohun tótọ́, Baba Ọ̀run yíò tọ́wasọ́nà bákannáà.
© 2023 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ní a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kejì 20234 Language. 19276 779