“Néfì Rí Jésù Ọmọ-ọwọ́,” Fríẹ́ndì, Oṣù Kejìlá 2024, 26–27.
Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì , Oṣù Kejìlá 2024
Néfì Rí Jésù Ọmọ-ọwọ́
Baba Néfì, Léhì, rí ìran kan nípa Jésù Krístì. Néfì nfẹ́ láti rí ìràn yí bákannáà. Ó gbàdúrà ó sì bèèrè láti rí ohun tí baba rẹ̀ rí.
Ẹ̀mí Mímọ́ fi irú ìran kannáà hàn Néfì. Néfì rí ọ̀dọ́mọbìrin kan tí a npè ní Màríà. Ẹ̀mí Mímọ́ wípé òun yíò jẹ́ ìyá Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run.
Néfì rí Jésù ọmọ-ọwọ́ pẹ̀lú Màríà. Ẹ̀mí Mímọ́ wípé Jésù yíò wá sí ilẹ̀-ayé láti ran àwọn ọmọ Baba Ọ̀run lọ́wọ́.
Néfì rí ìgbésí ayé Jésù Krístì. Ó rí I tí ó nsìn tí Ó sì nkọ́ àwọn ènìyàn. Néfì kọ́ àwọn ohun púpọ̀ nípa Olùgbàlà. Ẹ lè kọ́ nípa Rẹ̀ bákannáà nípa kìka àwọn ìwé-mímọ́.
© 2024 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ní a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kejìlá 2024. Yoruba. 19350 779