“Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mọ̀ Pé Mo Gbọ́ Ohùn Olúwa nínú Ayé Mi?” Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Ìkejì (èrèlé) 2021, 29.
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Ìkejì (èrèlé) 2021.
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mọ̀ Pé Mo Gbọ́ Ohùn Olúwa nínú Ayé Mi?
Ààrẹ Russell M. Nelson ti pè wá láti “ronú jinlẹ̀ àti léraléra” nípa bí a ṣe ngbọ́ Jésù Krístì àti láti “gbé àwọn ìgbésè láti gbọ Tirẹ̀ dáradára àti léraléra si” (“‘Báwo Ni Ẹ Ṣe #Ngbọ́Tirẹ̀?’ Ìfipè Pàtàkì Kan,” Ọjọ́ Kẹfàlélógún Oṣù Kejì, 2020, búlọ́ọ̀gì.ChurchofJesusChrist.org).
A lè gbọ́ Tirẹ̀ nípasẹ̀ àwọn ìwé mímọ́ àti ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì. Ṣùgbọ́n kìí ṣe gígbọ́ lásán tàbí kíka àwọn ọ̀rọ̀ ni ó jẹ́ kókó. Olúwa Ṣàlàyè, nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith,:
“Ohùn ti èmi ni èyítí ó sọ [àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí] jáde fún yín; nítorí a fi wọ́n fúnní nípa ẹ̀mí mi síi yín … ;
“Nítorínáà, ẹ̀yin lè jẹ̀ ẹ̀ri pé ẹ ti gbọ́ ohùn mi” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 18:35–36).
Ní àfikún, wíwá láti gbọ́ Tirẹ̀ kìí ṣe ohun kan tí à nṣe ní wéréwéré. Ààrẹ Nelson ti wípé, “O gba ìtiraka ìyára àti lemọ́lemọ́” (“Gbọ́ Tirẹ̀,” Ìpàdé àpapọ̀ Oṣù Kẹ́rin, 2020 [Ẹ́nsáìnì tàbì Làìhónà, Oṣù Karun 2020, 89]).
Bí ẹ ti nṣe àṣàrò, gbàdúrà, jọ́sìn, sìn, àti gbọ́ran sí àwọn òfin Olúwa, Òun yíò bùkún yín pẹ̀lú Ẹ̀mí Rẹ̀ àti pé, yíò yí yín padà, nípasẹ̀ Ètùtù Jésù Krístì. Lẹ́hìnnáà ẹ lè mọ̀ pé ẹ ti gbọ́ ohùn Rẹ̀.
© 2020 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ni a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà èdè ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Ìkejì (ṣẹrẹ) 2021. Yorùbá. 17464 000