“Ìtẹ̀síwájú Ìfihàn,” Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹta 2021, 16.
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́ , Oṣù Kẹta 2021.
Ìtẹ̀síwájú Ìfihàn
Láti inú ọ̀rọ̀ ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò kan ti Oṣù Kẹ́rin 2020.
Wòlíì Joseph Smith gba ìfihàn lẹ́yìn ìfihàn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìfihàn nípasẹ̀ Wòlíì Josèph ni a ti fi pamọ́ fún wa nínú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú.
Ní àfikún, a di alábùkúnfún pẹ̀lú ìfihàn tó ń tẹ̀síwájú sí àwọn wòlíì alààyè tí a “fifun wọ́n jẹ́ aṣojú Olúwa, tí wọ́n sì láṣẹ láti sọ̀rọ̀ fún Un.”1
Ìfihàn araẹni bákannáà wà fún gbogbo àwọn tí wọ́n ńfi ìrẹ̀lẹ̀ wá ìtọ́nisọ́nà láti ọ̀dọ̀ Olúwa. Ó ṣe pàtàkì bíi ti ìfìhàn wòlíì.
Ìfihàn ti ara ẹni dá lórí àwọn òtítọ́ ti ẹ̀mí tí a gbà láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ̀mí Mímọ́ ni olùfihàn àti olùjẹ́ri gbogbo òtítọ́, ní pàtàkì èyí ti Olùgbàlà. Láìsí Ẹ̀mí Mímọ́, a kò lè mọ̀ dájúdájú pé Jésù ni Krístì. Ojúṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ̀ Rẹ ni láti jẹ́ ẹ̀rí nípa Bàbá àti Ọmọ àti àwọn Àkórí Wọn àti ògo Wọn.
Mo mu dá yín lójú pé a lè gba ìtọ́nisọ́nà ti ìfihàn nípasẹ̀ bí ẹnì kọ̀ọkan wa bá ṣe ń fi tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà-àjàrà Olúwa.
Ẹ̀bẹ̀ ìrẹ̀lẹ̀ mi ni pé kí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa yíò wá ìtẹ̀síwájú ìfihàn láti darí ayé wa, kí á sì tẹ̀lé Ẹ̀mí bí a ṣe ń sin Ọlọ́run Baba àti Olùgbàlà wa, Jésù Krístì.
© 2021 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ni a fi pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà-èdè: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè: ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹ́ta 2021. Yoruba. 17466 000