2021
Orúkọ Ìjọ Rẹ̀
Oṣù Kẹ́wàá (Ọ̀wàwà) 2021


“Orúkọ Ìjọ Rẹ̀,” Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹ́wàá 2021.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ , Oṣù Kẹ́wàá (ọ̀wàwà) 2021.

Orúkọ Ìjọ Rẹ̀

Ìtumọ̀ wà lẹ́hìn orúkọ tí Jésù Krístì fún Ìjọ Rẹ̀.

Àwòrán
Jésù Krístì bí Olùṣọ́-àgùntàn Rere.

ìjọ mi

Ìjọ—ẹgbẹ́ àwọn ènìyàn kan tí wọ́n gba ohun kannáà gbọ́ tí wọ́n sì njọ́sìn papọ̀. Ìjọ yí jẹ́ ti Jésù Krístì. Ó bẹ̀rẹ̀ rẹ̀. Ó ndarí rẹ̀. Ó jẹ́ Tirẹ̀.

ni à pè ni

Jésù Krístì ti sọ fún wa ohun tí Ó fẹ́ kí àwọn ènìyàn pe Ìjọ Rẹ̀. Nítorínáà ìyẹn ni kí á pè é—àti pé ohun ni ó yẹ kí á fi inúrere ní kí àwọn míràn pè é. Orúkọ yí wá láti ọ̀dọ̀ Jésù Krístì.

àwọn ọjọ́-Ìkẹhìn

Àwọn Ọjọ́-ìkẹhìn—àwọn ọjọ́ tí à ngbé nínú rẹ̀; àkókò ṣíwájú Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Jésù Krístì. Jésù Krístì ti mú Ìjọ Rẹ padà wa si ilẹ̀-ayé fún àkókò ìkẹhìn yí. Yio ṣè ìrànlọ́wọ́ láti múra àgbáyé sílẹ̀ fún Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Rẹ̀.

Ìjọ ti Jésù Krístì

(Wo “Ìjọ mi.”) Èyí ni apá kínní orúkọ tí Olùgbàlà fún Ìjọ Rẹ̀. Ó pé é ní “Ìjọ Náà” nítorí Ó ṣètò rẹ. Ó sì ti fi orúkọ Rẹ̀ sí orí rẹ.

Ọjọ́-ìkẹhìn

(Wo “àwọn ọjọ́-ìkẹhìn.”) Èyí ni apá tí ó tẹ̀le ní orúkọ Ìjọ. Ó fihàn jẹ́jẹ́ pé èyí ni Ìjọ tí Ó mú padà wá ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, kìí ṣe èyí tí Ó bẹ̀rẹ̀ ní àwọn àkókò ìṣíwájú.

Àwọn Ènìyàn Mímọ́

Àwọn Ènìyàn Mímọ́—ọ̀rọ kan tí ó túmọ̀ sí “àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ mímọ́.” Èyí ni apá tí ó kẹ́hìn ní orúkọ Ìjọ. Ó nsọ nípa àwọn ọmọ Ìjọ. Jésù Krístì lè sọ wá di aláìlábàwọ́n àti mímọ́. Ó sì fún wa ní Ẹ̀mí Mímọ́ láti fún wa ní okun bí a ti ngbìyànjú láti ṣe ohun tí Ó ti pa láṣẹ. Bí a bá gbàgbọ́ nínú Rẹ̀ tí a sì ntiraka, Òun nsọ wá di mímọ́. Òun nsọ wa di Ènìyàn Mímọ́.

Tẹ̀