“Wọ́n jẹ́ Tèmi Èmi sì Mọ̀ Wọ́n,” Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Ìkínní 2022.
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ Oṣù Ìkínní 2022.
“Wọ́n Jẹ́ Tèmi Èmi Sì Mọ̀ Wọ́n”
Ṣé ẹ ti ní ìmọ̀lára àìjẹ́-pàtàkì rí? Ẹ lè ti ní ìmọ̀lára ọ̀nà yí nígbàtí ẹ ti ronú nípa bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn níbẹ̀ ṣe wà nínú ayé tàbí wo bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìràwọ̀ ṣe wà ní ojú-ọ̀run. Ṣe ẹ ti ròó wò rí bí Ọlọ́run bá mọ̀ ẹni tí ẹ jẹ́ dájúdájú àti bí ìgbé ayé yín ṣe dàbí? Bí o bá rí bẹ́ẹ̀, nígbànáà Mósè ní ọ̀rọ̀ kan fún un yín.
Nínú ìran kan, Ọlọ́run fi gbogbo àmì Ilẹ̀-ayé han Mósè àti gbogbo àwọn ẹni tí yíò gbé níbẹ̀. Wọ́n wà bí “àìníye bíi iyanrìn ní etí òkun” (Mósè 1:28). Nígbànáà Ọlọ́run wí fún Mósè pé Òun ti dá “àwọn ayé láìníye” (Mósè 1:33)—pé àwọn ìṣẹ̀dá Rẹ̀ nà kọjá ilẹ̀-ayé yí.
Àfàìmọ̀ tí Mósè bá ní ìmọ̀lára ìbòmọ́lẹ̀ nígbàtí ó rí gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí. Bóyá ó ròó pé: Níbo ní mo ti ní ìbámu ní àárín ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìṣẹ̀dá bẹ́ẹ̀? Báwo sì ni Ọlọ́run ṣe lè pa ipa-ọ̀nà púpọ̀ bẹ́ẹ̀ mọ́?
Ìdáhùn Ọlọ́run rọrùn: “Ohun gbogbo ni kíkà fún mi.” Báwo? “Wọ́n jẹ́ tèmi èmi sì mọ̀ wọ́n” (Mósè 1:35). Ọlọ́run mọ ẹni tí Mósè íṣe, àní bí Òun ti mọ gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀, bákannáà bíi gbogbo àwọn ìṣẹ̀dá Rẹ̀. Gbogbo wọn jẹ́ Tirẹ̀—àwọn ìràwọ̀, iyanrìn, àti nípàtàkì àwọn ọmọ Rẹ̀ ní orí ilẹ̀-ayé. Wọ́n jẹ́ gbogbo èrèdí tí Òun fi dá ilẹ̀-ayé. Ìgbàlà ayérayé wọn ni iṣẹ́ Ọlọ́run pàtàkì jùlọ.
“Èyí ni iṣẹ́ mi àti ògo mi—láti mú àìkú àti ìyè ayérayé ènìyàn wá sí ìmúṣẹ” (Mósè 1:39).
Gẹ́gẹ́ bí Mósè ṣe kọ́ ibití òun ti bá ètò Ọlọ́run mu, ẹ̀yin náà lè ní ìdánilójú pé Ọlọ́run mọ̀ yín! Ríràn yín lọ́wọ́ láti padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni iṣẹ́ àti ògo Rẹ̀. Kínìdí? Nítorí ẹ jẹ́ Tirẹ̀. Kò sì sí ohunkankan tí ó ṣe àìjẹ́-pàtàkì nípa ìyẹn!
© 2021 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ni a fi pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà-èdè: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kejìlá 2021. Yoruba. 18295 000