“Báwo Ni Ẹ Ṣe Ngbọ́ Tirẹ̀?”, Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹta 2022.
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́ Oṣù Kẹta 2022.
Báwo Ni Ẹ Ṣe Ngbọ́ Tirẹ̀
Ní àfíkún pẹ̀lú ìdarí àlàáfíà tí a gbà láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́, láti ìgbà dé ìgbà, Ọlọ́run fi pẹ̀lú agbára àti níti araẹni gan dá ẹnìkọ̀ọ̀kan wa lójú pé Òun mọ̀ wá Òun sì fẹ́ràn wa. Nígbànáà, nínú àwọn àkokò ìṣòro wa, Olùgbàlà nmú àwọn ìrírí wọ̀nyí padà wá sí inú iyè wa.
Ẹ ro nípa ìgbé ayé ti ara yín. Àwọn ìrírí wọ̀nyí le wá ní àwọn ìgbà pàtàkì gidi nínú ayé wa tàbí nínú ohun tí ó le dàbí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí kò mú ìròhìn wá. Àwọn àkokò onítumọ̀ ti ẹ̀mí wọ̀nyí nwá ní àwọn ìgbà tí ó yàtọ̀ àti ní àwọn ọ̀nà tí ó yàtọ̀, ní ìkọ̀ọ̀kan fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa.
Joseph Smith ṣe àlàyé pé ìgbàmíràn à ngba “ìlà àwọn èrò lójijì” àti ní ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ìṣàn àìléèrí ti òye.1
Ààrẹ Dallin H. Oaks, ní fífèsì sí ọkùnrin olódodo kan tí ó gbà pé òun kò tíì ní irú ìrírí bẹ́ẹ̀ rí, dámọ̀ràn, “Bóyá a ti dáhùn àwọn àdúrà rẹ lẹ́ẹ̀kan àti lẹ́ẹ̀kan si, ṣùgbọ́n ìwọ ti mú àwọn ìrètí rẹ dúró lórí àmì gíga kan tàbí ohùn kan tí ó ní ariwo tóbẹ́ẹ̀ tí ìwọ kò fi ronú pé ìwọ ti gba ìdáhùn kankan.”2
Láìpẹ́ a ti gbọ́ Ààrẹ Russell M. Nelson tí ó wípé: “Mo pè yín láti ronú jinlẹ̀ àti léraléra nípa kókó íbèèrè yí: Báwo ni ẹ ṣe ngbọ́ Tirẹ̀? Bákannáà mo pè yín láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ láti gbọ́ Tirẹ̀ dáradára síi àti léraléra síi.”3
© 2022 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ni a fi pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà-èdè: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè ti Ọrọ̀ Oṣooṣù Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹta 2022. Yoruba. 18296 779