Títúmọ̀ Ìrántí Níti Ẹ̀mí
Nígbàtí àwọn ìṣòro araẹni tàbí àwọn ipò tí ó kọjá agbára wa bá ṣòkùnkùn bo ipá ọ̀nà wa, àwọn ìrántí onítumọ̀ tí ẹ̀mí látinú ìwé ìyè dàbí okúta ìtànán tí ó nmú ìmọ́lẹ̀ wá sí ọ̀nà níwájú wa.
Ọdún méjìdínlógún lẹ́hìn ìran Èkíní, Wòlíì Joseph Smith kọ àkọsílẹ̀ gígùn kan nípa ìrírí rẹ̀. Ó dojúkọ àtakò, inúnibíni, ìyọnilẹ́nu, ìdẹ́rùbà, àti ìkọlù kíkorò.1 Síbẹ̀síbẹ̀ ó tẹ̀síwájú tìgboyàtìgboyà láti jẹ́ẹ̀rí nípa Ìran Àkọ́kọ̀ rẹ̀: “Mo ti rí ìmọ́lẹ̀ kan nítòótọ́, àti ní àárín ìmọ́lẹ̀ náà mo rí àwọn Ẹni Nlá méjì, wọ́n sì bá mi sọ̀rọ̀ lódodo; bíótilẹ̀jẹ́pé a korira a sì ṣe inúnibíni sí mi fún wíwí pé mo ti rí ìran kan, síbẹ̀síbẹ̀ o jẹ́ òtítọ́. … Mo mọ̀ ọ́, mo sì mọ̀ pé Ọlọ́run mọ̀ ọ́, àti pé èmi kò sì lè sẹ́ ẹ.”2
Nínú àwọn wákàtí líle rẹ̀, ìrántí Joseph padà dé bíi ogún ọdún sí ìdánilójú ìfẹ́ Ọlọ́run fún òun àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó mú Ìmúpadàbọ̀sípò tí a ti sọtẹ́lẹ̀ wá. Ríronú lórí ìrìnàjò ti ẹ̀mí rẹ̀, Joseph wípé: Èmi kò bá ẹnìkẹ́ni wí fún àìgbà ìwé ìtàn mi gbọ́. Bí èmi kò bá ní ìrírí ohun tí mo ní, èmi kò ní gbà a gbọ́ fúnra mi.”3
Ṣùgbọ́n àwọn ìrírí náà jẹ́ òdodo, òun kò sì lè gbàgbé tàbí sẹ́ wọn láéláé, ó fi jẹ́jẹ́ fi ẹ̀sẹ̀ ẹ̀rí rẹ̀ múlẹ̀ bí ó ti nlọ sí Carthage. “Èmi nlọ bí ọ̀dọ́-àgùtàn sọ́dọ̀ apẹran,” ó wípé, “ṣùgbọ́n èmí rọlẹ̀ bí ìjì òwúrọ̀; mo ní ẹ̀rí-ọkàn láìsí ẹ̀bi sí Ọlọ́run, àti sí gbogbo ènìyàn.”4
Àwọn Ìrírí Onítumọ̀ ti Ẹ̀mí
Ẹ̀kọ́ kan wà fún wa nínú àpẹrẹ Wòlíì Joseph. Lẹgbẹ pẹ̀lú ìdarí tí a gbà látọ́dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́, láti ìgbà sí ìgbà, Ọlọ́run fi tagbára-tagbára àti fúnrarẹ̀ dá ẹnìkọ̀ọ̀kan wa lójú pé Òun mọ̀ wá àti pé Òun sì nbùkún wa nípàtàkì àti ní gbangban. Nígbànáà, nínú àwọn àkokò líle wa, Olùgbàlà nmú àwọn ìrírí wọ̀nyí wá padà sínú wa.
Ẹ ro ìgbé ayé ti ara yín. Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́hìn, mo ti fetísílẹ̀ sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ìrírí ti ẹ̀mí tó jinlẹ̀ látẹnu àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn káàkiri ayé, fi ẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ sí mi kọja ìbèèrèkíbèèrè pé Ọlọ́run mọ̀ Ó sì nifẹ ẹnìkọ̀ọ̀kan wa tí Òun fi nfìyára nifẹ láti fi Ararẹ̀ hàn sí wa. Àwọn ìrírí wọ̀nyí lè wá ní àwọn ìgbà pàtàkì gidi nínú ayé wa tàbí nínú ohun tí ó dàbí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí kò ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọ́n fìgbàgbogbo bá okun títayọ ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ti ẹ̀mí ìfẹ́ Ọlọ́run wá.
Rírántí àwọn ìtumọ̀ ìrírí ti ẹ̀mí wọ̀nyí nmú wa lọ sórí eékún wa, kíkéde bí Wòlíì Joseph ti ṣe: Ohun tí mo gbà láti Ọ̀run. Mo mọ̀ ọ́, mo sì mọ̀ pé Ọlọ́run mọ̀ pé mo mọ̀ ọ́.”5
Àwọn Àpẹrẹ Mẹ́rin
Ẹ ronú lórí àwọn ìrántí ti ẹ̀mí ara yín bí mo ti npín àwọn àpẹrẹ látẹnu àwọn ẹlòmíràn.
Ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́hìn, àgbàlagbà bàbánlá èèkàn kan pẹ̀lú ìkùnà awẹ́ ọkàn méjì bẹ̀bẹ̀ fún Dókítà Russell M. Nelson nígbànà láti dási, bíótilẹ̀jẹ́pé ní ìgbà náà kò sí iṣẹ́ abẹ fún yíyanjú awẹ́ keji tó ti bàjẹ́. Dókítà Nelson gbà níkẹhìn láti ṣe iṣẹ́ abẹ. Nihin ni àwọn ọ̀rọ̀ Ààrẹ Nelson:
“Lẹ́hìn rírọ dídí awẹ́ àkọ́kọ́, a ṣí awẹ́ kejì sílẹ̀. A rí i pé ó wà déédé ṣùgbọ́n ó ti fẹ̀ bàjẹ́ tí kò fi lè ṣíṣẹ́ púpọ̀ bí ó ti yẹ kó ṣe mọ́. Nígbàtí mò nyẹ awẹ́ náà wò, ọ̀rọ̀ kan tẹ̀mọ́ mí lọ́kàn yékéyéké: Dín àyíká orùka náà kù. Mo kéde ọ̀rọ̀ náà sí olùrànlọ́wọ́ mi. ‘Ẹ̀là ara náà yíò tó bí a bá lè fi taratara dín orùka náà kù sí ìwọ̀n déédé.’
Ṣùgbọ́n báwo? … Àwòrán kan hàn sínú mi, ó fi bí a ṣe lè rán ibẹ̀ hàn—láti fi sísún sihin àti títì sínú síbẹ̀. … Mo ṣi rántí èyí àwòrán ọpọlọ—pípé pẹ̀lú àwọn ìlà níbití a gbọ́dọ̀ fi rírán sí. Àtúnṣe náà parí bí yíyàwórán nínú mi. A yẹ awẹ́ náà wò a sí rí iwò tí a ní láti dínkù gan an. Olùrànlọ́wọ́ mi wípé, ‘iṣẹ́ ìyanu ni.’”6 Bàbánlá náà gbé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún.
Dókítà Nelson ti gba ìdarí. Ó sì mọ̀ pé Ọlọ́run mọ̀ pé òun mọ̀ pé òun gba ìdarí.
Kathy àti èmi kọ́kọ́ pàdé Beatrice Magré ní France ní ọgbọ̀n ọdún sẹ́hìn. Láìpẹ́ Beatrice wí fún mi nípa ìrírí kan tí ó nípá ti ẹ̀mí ní ìgbé ayé rẹ̀ láìpẹ́ lẹ́hìn ìrìbọmi bí ọ̀dọ́. Nihin ni àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀:
“Àwọn ọ̀dọ́ ẹ̀ká wa ti rin ìrìnàjò pẹ̀lú àwọn olórí wọn lọ sí òkun Lacanau, wákàtí kan àti ààbọ̀ láti Bordeaux.
“Ṣíwájú ìpadabọ̀ sílé, ọ̀kan lára àwọn olórí pinnu láti lùwẹ̀ ìkẹhìn ó sì wẹ̀ lọ sí ìbi-ìjì pẹ̀lú àwọn dígí rẹ̀. Nígbàtí ó padà jáde, àwọn dígí rẹ̀ ti parẹ́. … Wọ́n ti sọnù sínú òkun.
“Àdánù àwọn dígí rẹ̀ yíò dẹ́kun wíwakọ̀ ara rẹ̀. A ó dúró pẹ́títí jìnnà sí ilé.
“Arábìnrin kan tó kún fún ìgbàgbọ́ ní kí a gbàdúrà.
Mo ráhùn pé àdúrà kó lè ṣe ohunkóhun fún wa, mo sì fi àìnírọ̀rùn darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ láti gbàdúrà ní gbangba bí a ṣe dúró pẹ̀lú àyà wa jíjìn nínú omi ṣíṣú.
Nígbàtí a gbàdúrà tán, mo nawọ́ mi láti bomilu gbogbo ènìyàn. Bí mo ṣe ngbá orí òkun náà, àwọn dígí rẹ̀ dúró nínú ọwọ́ mi. Ìmọ̀lára alágbára wọnú ọkàn mi pé nítòótọ́ Ọlọ́run ngbọ́ Ó sì ndáhùn àdúrà wa.”7
Ogoji ọdún ó lé marun lẹ́hìnnáà, ó rántí rẹ̀ bí ẹnipé ó ṣẹlẹ̀ lana. Beatrice ti di alábùkún, ó sì mọ̀ pé Ọlọ́run mọ̀ pé òun mọ̀ pé òun ti di alábùkúnfún.
Àwọn ìrírí Ààrẹ Nelson àti Arábìnrin Magré yàtọ̀ gidi, síbẹ̀síbẹ̀, síbẹ̀síbẹ̀ fún àwọn méjèèjì, ìrántí ìtumọ̀ àìlègbàgbé ti ẹ̀mí ìfẹ́ Ọlọ̀run kan wọnú ọkàn wọn.
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìtumọ̀ nwá nígbàkugbà nínú kíkọ́ ẹ̀kọ́ nípa ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere tàbí nínú pípín ìhìnrere pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.
Fọ́tò yí ni a yà ní São Paulo, Brazil, ní 2004. Floripes Luzia Damasio ti Èèkàn Ipatinga Brazil jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnléláàdọ́fà. Sísọ̀rọ̀ nípa ìyípadà rẹ̀, Arábìnrin Damasio wí fún mi pé àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere nínú ìletò rẹ̀ ti fi ìbùkún oyèàlùfáà fún ọmọ-ọwọ́ tí ó nṣàìsàn líle tí ara rẹ̀ sì yá ní ìyanilẹ́nu. Ó fẹ́ láti mọ̀ síi. Bí ó ṣe ngbàdúrà nípa ọ̀rọ̀ wọn, ẹ̀rí àìlèsẹ́ ti Ẹ̀mí fẹsẹ rẹ̀ múlẹ̀ sí i pé Joseph Smith ni wòlíì Ọlọ́run. Ní ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́ọ̀rún, ó ṣe ìrìbọmi, àti pé ní ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́ọ̀rún, ó gba ìrónilágbára. Lọ́dọọdún lẹ́hìnnáà, ó wọkọ̀ wákàtí mẹ́rìnlá lọ láti lo ọ̀sẹ̀ kan ní tẹ́mpìlì. Arábìnrin Damasio ti gba ìfẹsẹ̀múlẹ̀ tọ̀run, ó sì mọ̀ pé Ọlọ́run mọ̀ pé ẹ̀rí náà jẹ́ òtítọ́.
Nihin ni ìrántí ti ẹ̀mí láti ibi iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere mi lọ sí France ní àádọ́ta ọdún dín méjì sẹ́hìn.
Nígbàtí mò nṣe ìpínkiri, ojúgbà mi àti èmi fi Ìwé ti Mọ́mọ́nì kan sílẹ̀ pẹ̀lú obìnrin àgbà kan. Pípadà sí yàrá obìnrin náà ní ọ̀sẹ̀ kan lẹ́hìnnáà, ó ṣí ilẹ̀kùn. Ṣíwájú kí a tó sọ ọ̀rọ̀ kankan, mo ní ìmọ̀lára dídára kan agbára ti ẹ̀mí. Ìmọ̀lára líle náà tẹ̀síwájú bí Arábìnrin Alice Audubert ṣe pè wá wọlé tí ó sì wí fún wa pé òun ti ka Ìwé ti Mọ́mọ́nì tí ó sì mọ̀ pé ó jẹ́ òtítọ́. Bí a ṣe kúrò ní yàrá rẹ̀ níjọ náà, mo gbàdúrà, “Bàbá Ọ̀run, jọ̀wọ́ ràn mí lọ́wọ́ kín máṣe gbàgbé ohun tí mo ṣẹ̀ mọ̀ lára.” Èmi kò ṣe láé.
Nínú ohun tó dàbí àkokò lásán, níbi lẹ̀kùn tó dàbí irú ọgộgọrun àwọn ìlẹ̀kùn, mo ti ní ìmọ̀lára agbára ọ̀run. Mo sì ti mọ̀ pé Ọlọ́run mọ̀ pé mo mọ̀ pé fèrèsé ọ̀run ti ṣí.
Ní ọ̀kọ̀ọ̀kan àti àìlèsẹ́
Àwọn àkokò ìtumọ̀ ti ẹ̀mí wọ̀nyí wá ní àwọn ìgbà tó yàtọ̀ àti ní àwọn ọ̀nà tó yàtọ̀, ìkọ̀ọ̀kan fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa.
Ẹ ronú nípa àwọn àpẹrẹ nínú ìwé mímọ́ tó dùnmọ́ni. Àwọn wọnnì tí wọ́n fetísílẹ̀ sí Àpọ́stélì Pétérù ní “ìgúnni nínú [àwọn] ọkàn wọn.”8 Obìnrin Lámánáìtì Abish gba “ìran ọlọ́lá ti bàbá rẹ̀” gbọ́.9 Àti pé ohùn kan wá sínú Énọ́sì.10
Ọ̀rẹ́ mi Clayton Christensen ṣàpèjúwe ìrírí kan nígbà tó fi tàdúràtàdúrà ka Ìwé ti Mọ́mọ́nì ní ọ̀nà yí: “Ẹ̀mí ẹlẹ́wà kan, ìyárí, ìfẹ́ni … yí mi ká ó sì wọnú ẹ̀mí mi lọ, ó yí mi ká nínú ìmọ̀lára ìfẹ́ tí èmi kò lérò pé mo lè ní [àti pé àwọn ìmọ̀lára wọ̀nyí tẹ̀síwájú ní alẹ́ sí alẹ́].”11
Àwọn ìgbà kan wà tí ìmọ̀lára ti ẹ̀mí nwọnú ọkàn wa bí iná. Joseph Smith ṣàlàyé pé ìgbàmíràn à ngba “ìlà àwọn èrò lọ́gán” àti ní ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan “ìṣàn mímọ́ ti òye.”12
Ààrẹ Dallin H. Oaks, ní fífèsì sí ọkùnrin olódodo kan tí ó gbà pé òun kò ní irú ìrírí bẹ́ẹ̀ rí, dámọ̀ràn, “Bóyá a ti dáhùn àwọn àdúrà rẹ lẹ́ẹ̀kan àti lẹ́ẹ̀kan si, ṣùgbọ́n ìwọ ti ní ìrò dídúró lórí àmì gíga tàbí ohùn tó láruwo tí ìwọ kò fi ronú pé ìwọ ti gba ìdáhùn kankan.”13 Olùgbàlà Fúnrarẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ nlá àwọn ènìyàn kan “ti a [bùkún] wọn pẹ̀lú iná àti pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́, [ṣùgbọ́n tí wọn] kò mọ̀ ọ́.”14
Báwo Ni Ẹ Ṣe Ngbọ́ Tirẹ̀
Láìgbọ́ a ti gbọ́ Ààrẹ Russell M. Nelson tó wípé: “Mo pè yín láti ronú jinlẹ̀ àti léraléra nípa kókó íbèèrè yí: Báwo ni ẹ ṣe ngbọ́ Ọ? Bákannáà mo pè yín láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ láti gbọ́ Ọ dáradára si àti léraléra si.”15 Ó ntún ìfipè náà sọ ní òwúrọ̀ yí.
À ngbọ Ọ nìnù àwọn àdúrà wa, nínú ilé wa, nínú ìwé mímọ́, nínú àwọn orin, bí a ti nṣe àbápín oúnjẹ Olúwa ní yíyẹ, bí a ti nkéde ìgbàgbọ́ wa, bí a ti nsin àwọn ẹlòmíràn, àti bí a ti nlọ sí tẹ́mpìlì pẹ̀lú àwọn onígbágbọ́. Àwọn àkokò ìtumọ̀ ti ẹ̀mí nwá bí a ṣe nfi tàdúràtàdúrà fetísí ìpàdé àpapọ gbogbogbò àti bí a ti npa àwọn òfin mọ́ dáradára si. Ẹ̀yin ọmọdé, àwọn ìrírí wọ̀nyí wà fún yín bákannáà. Rántí, Jésù “ti kọ́ni ó sì ṣe iṣẹ́ ìrańṣẹ́ sí àwọn ọmọdé … àti pé [àwọn ọmọdé] ti sọ̀ … àwọn ohun nlá àti ìyanu.”16 Olùwa wípé:
“[Ìmọ̀ yí ni] a fúnni nípasẹ̀ Ẹ̀mí mi sí yín, … bí kò sì ṣe nípa agbára mi ẹ kò lè [ni];
“Nítorínáà, ẹ lè jẹri pé ẹ ti gbọ́ ohun mi, ẹ sì mọ̀ ọ̀rọ̀ mi.”17
A lè “gbọ́ Ọ” nítorí ìbùkún àìláfiwé Ètùtù Olùgbàlà.
Nígbàtí a kò lè yan ìgbà gbigba àwọn àkokò ìtumọ̀ wọ̀nyí, Ààrẹ Henry B. Eyring fúnni ní àmọ̀ràn yí ní ìmúrasílẹ̀ wa: “Lálẹ́yìí, àti lálẹ́ ọ̀la, ẹ lè gbàdúrà kí ẹ jíròrò, ní bíbèèrè àwọn ìbèerè: Ṣé Ọlọ́run rán ọ̀rọ̀ kan tí ó kàn wà fún mi? Ṣé mo rí ọwọ́ Rẹ̀ nínú ayé mi tàbí ayé [ẹbí] mi?”18 Ìgbàgbọ́, ìgbọ́ran, ìrẹ̀lẹ̀, àti èrò òdodo nṣí àwọn fèrèsè ọ̀run.19
Àpèjúwe KAn
Ẹ lẹ̀ ronú nípa àwọn írántí ti ẹ̀mí ní ọ̀nà yí. Pẹ̀lú àdúrà lemọ́lemọ́, ìpinnu kan láti pa àwọn májẹ̀mú mọ́, àti ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, a nwá ọ̀nà wa lọ sínú ìyè. Nígbàtí ìṣòro araẹni, iyèméjì, tàbí àìnírètí ṣúbo ipá ọ̀nà wa, tàbí nígbàtí àwọn ipò ayé bá kọjá agbára wa tí ó ndarí wa lọ kiri nípa ọjọ́-ọla, àwọn ìrántí onítumọ̀ ti Ẹ̀mí látinú ìwé ìyè wa dàbí àwọn òkúta ìtànná tí ó nṣèrànwọ́ láti tànmọ́lẹ̀ síwájú, dídá wa lójú pé Ọlọ́run mọ̀ wá, nifẹ wa, ó sì ti rán Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, láti ràn wá lọ́wọ́ padà sílé. Àti nígbàtí ẹnìkan bá gbé àwọn ìrántí onítumọ̀ ọkùnrin tàbí obìnrin sẹgbẹ tí ó sọnù tàbí dààmú, à nyí wọn padà sọ́dọ̀ Olùgbàlà bí a ti npín ìgbàgbọ́ wa àti àwọn ìrántí pẹ̀lú wọn, ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣàwárí àwọn àkokò iyebíye ti ẹ̀mí wọnnì tí wọ́n ti níṣura sí tẹ́lẹ̀.
Àwọn ìrírí díẹ̀ jẹ́ mímọ́ gidi tí a fi ntọ́ wọn ní ìrántí ti ẹ̀mí wa àti láì ṣe àbápín wọn.20
Àwọn angẹ́lì nsọ̀rọ̀ nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí Mímọ́; nítorí-èyi, wọ́n nsọ àwọn ọ̀rọ̀ Krístì.”21
“Àwọn ángẹ́lì kò [dáwọ́dúró] nínú iṣẹ ìránṣẹ́ ṣíṣe fún àwọn ọmọ ènìyan.
“Nítorí ẹ kíyèsĩ, abẹ́ [Krístì] ní wọ́n wà, láti ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ gẹ́gẹ́bí ó ti … pàṣẹ, àti láti fi ara wọn hàn sí àwọn tí ó ní ìgbàgbọ́ púpọ̀ àti ọ̀kan ti ó dúróṣinṣin nínú gbogbo ìwà-bí-Ọlọ́run.”22
“Olùtùnú náà, èyí tí íṣe Ẹ̀mí Mímọ́, … yíò kọ́ yín ní ohun gbogbo, àti mú ohun gbogbo wá sí ìrántí yín.”23
Ẹ di àwọn ìrántí mímọ́ yín mú. Ẹ gbà wọ́n gbọ́. Ẹ kọ wọ́n sílẹ̀ Ẹ pín wọn pẹ̀lú ẹbí yín. Nigbẹkẹle pé wọ́n wá sọ́dọ̀ yín látọ̀dọ̀ Bàbá Ọ̀run àti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀.24 Ẹ jẹ́ kí wọ́n mú sùùrù wá sí iyèméjì yín àti lílóye sí àwọn ìṣòrò yín.25 Mo ṣèlérí fún yín bí ẹ ti nfi tìfẹ́tìfẹ́ jẹ́wọ́ tí ẹ sì nfi pẹ̀lẹ́pẹ́lẹ́ fi ìṣura fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ onítumọ̀ ti ẹ̀mí nínú ayé yín, púpọ̀ àti púpọ̀ yíò wá sọ́dọ̀ yín. Bàbá Ọ̀run mọ̀ yín ó sì nifẹ yín!
Jésù ni Krístì, ìhìnrere Rẹ̀ ni a ti múpadàbọ̀sípò, àti pé bí a bá ṣe dúróṣinṣin, mo jẹ́ri pé ao´ jẹ́ Tirẹ̀ títí láé, ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.