Ṣíṣí Ọ̀run fún Ìrànlọ́wọ́
Ẹ jẹ́ kí a gbé ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù Krístì sí ìṣe!
Ohun àrà kan àti oníyanu abala tí èyí ti jẹ́! E ṣeun, Laudy àti Enzo ọ̀wọ́n. Ẹ ṣojú àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin àti ọ̀dọ́mọkùnrin ọlọ́lá Ìjọ dáadáa.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n, a ti gbọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ nípa Ìmúpadàbọ̀sípò Ìjọ loni—Ìjọ gan an tí Olùgbàlà wa Jésù Krístì gbé kalẹ̀ nígbà iṣẹ́ ìránṣẹ́ ilẹ̀ ayé Rẹ̀. Ìmúpadàbọ̀sípò bẹ̀rẹ̀ ní igbà ọdún sẹ́hìn ní ìgbà-ìrúwé nígbàtí Ọlọ́run Bàbá àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì farahàn sí Josèph Smith kékeré.
Ọdún mẹwa lẹ́hìn ìràn tótayọ yí, Wòlíì Joseph Smith àti àwọn marun míràn ni a pè bí olùdásílẹ̀ ọmọ ìjọ ti ìmúpadàbọ̀sípò Ìjọ Olúwa.
Látinú àkójọ egbé kékeré náà ní Ọjọ́ Kẹfà Oṣù Kẹrin, 1830, ni ìṣètò gbogbogbò ọmọ ìjọ tó ju míllíọ̀nù mẹ́rìdínlógún. Rere tí Ìjọ yí nṣe káàkiri ayé láti ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ nínú ìjìyà àti láti pèsè ìgbéga fún gbogbo ènìyàn ní a mọ̀ káàkiri. Ṣùgbọ́n èrò àtilẹ̀wá rẹ̀ ni láti rán àwọn ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn ọmọ láti tẹ̀lé Olúwa Jésù Krístì, pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́, àti yege fún gbogbo ìbùkún gígajùlọ—ti ìyè ayérayé pẹ̀lú Ọlọ́run àti àwọn olólùfẹ́ wọn.
Bí a ti nṣe àyẹyẹ ìṣẹ̀lẹ̀ tí a gbé kalẹ̀ 1820, ó ṣe pàtàkì láti rántí pé nígbàtí à nbu ọ̀wọ̀ fún Josèph Smith bi wòlíì Ọlọ́run, èyí kìí ṣe ìjọ Joseph Smith, bẹ́ẹ̀ni kìí ṣe ìjọ Mọ́mọ́nì. Èyí ni Ìjọ ti Jésù Krístì. Ó pàṣẹ ohun tí a ó pe Ìjọ Rẹ̀: “Nítorí báyìí ni a ó pe orúkọ ìjọ mi ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn, àní Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.”
Mo ti sọ̀rọ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ nípa nínílò èrò àtúnṣe ní ọ̀nà tí a fi npe orúkọ Ìjọ. Látigbà náà, ọ̀pọ̀ ni a ti ṣe láti ṣe àṣeyege àtúnṣe yí. Mo fi ìmoore hàn sí Ààrẹ M. Russell Ballard àti gbogbo Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá, tí wọ́n ti ṣe ohun púpọ̀ láti darí àwọn ìtiraka wọ̀nyí bákannáà ni àwọn wọnnì tí ó bá àwọn ìlàsílẹ̀ míràn lọ tí èmi ó polongo ní ìrọ̀lẹ́ yí.
Àwọn olórí Ìjọ àti àwọn ẹ̀ká, àwọn ìbámu ibi-iṣẹ́, àti àwọn míllíọ̀nù ọmọ ìjọ —àti àwọn míràn—báyìí nlo orúkọ Ìjọ déédé. Àṣà ibi-iṣẹ́ ìtọ́nisọ́nà Ìjọ ni a ti túnṣe. Kókó ibiwẹ́ẹ̀bù Ìjọ báyìí jẹ́ ChurchofJesusChrist.org. Àwọn Àdírẹ́sì fún ìfìwéránṣé, ibi orúkọ, àti àwọn ẹ̀ka ìbákẹ́gbẹ́ ìròhìn ni a ti ṣe déédé. Àwọn akọrin olólùfẹ́ wa báyìí ni Akọrin Àgọ́ ní Igun-mẹ́rin Tẹ́mpìlì.
A ti lọ sí àwọn ìtiraka àràọ̀tọ̀ wọ̀nyí nítorí ìgbàtí a bá mú orúkọ Olúwa kúrò nínú orúkọ Ìjọ Rẹ̀ , à nmọ̀ọ́mọ̀ mú U kúrò bí oókan ìdojúkọ ìjọ́sìn àti ìgbé ayé wa. Ìgbàtí a bá gba orúkọ Olùgbàlà lé orí arawa ní ìrìbọmi, a gbà láti jẹ́ ẹ̀rí, nípasẹ̀ àwọn èrò, àti ìṣe wa, pé Jésù ni Krístì.
Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, mo ṣèlérí pé tí a ó bá sa ipá wa láti mú orúkọ Ìjọ tòọ́tọ́ padàbọ̀sípò,” Òun yíò ”da agbára àti ìbùkún Rẹ̀ sílẹ̀ lé orí àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, irú èyí tí a kò rírí.” Mo tún ìlérí náà ṣe loni.
Láti rànwálọ́wọ́ láti rántí Rẹ̀ àti láti dá Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn mọ̀ bí Ìjọ Olúwa, inú wa dùn láti fi àmì tí yíò jẹ́ oókan ibi ti Jésù Krítì nínú Ìjọ Rẹ̀.
Àmì yí wà pẹ̀lú orúkọ Ìjọ tó wà nínú igun-òkúta. Jésù Krísti ni olórí igun-òkúta.
Ní oókan àmì náà ni ìjúwe ti ère àwo Thorvaldsen’s Krístọ́s náà. Ó fi olùjíìnde, alààyè Olúwa hàn tó nnawọ́ jáde láti gba gbogbo ẹnití yíò wá sọ́dọ Rẹ̀ mọ́ra.
Lapẹrẹ, Jésù Krístì ndúró lábẹ́ òpó kan. Òpó náà nránwalétí nípa Olùjíìnde Olùgbàlà tó njádé látinú ibojì ní ọjọ́ kẹta tótẹ̀lè Ìkànmọ́-àgbélèbú Rẹ̀.
Àmì yí gbọ́dọ̀ nímọ̀lára mímọni sí ọ̀pọ̀lọpọ̀, bí a ti nfi ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere hàn tipẹ́tipẹ́ pẹ̀lú alààyè, olùjíìnde Krístì.
Báyìí àmì náà ni a ó lò bí ìfihàn rírí kan fún ìwé-kíkà gbangba, ìròhìn, àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ti Ìjọ. Yíò rán gbogbo wa létí pé èyí ni Ìjọ Olùgbàlà àti pé gbogbo ohun tí a nṣe bí ọmọ Ìjọ Rẹ̀ dálórí Jésù Krístì àti ìhinrere Rẹ̀.
Báyìí, arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n, ọ̀la ni Ọjọ́-ìsinmi Ọ̀pẹ, bí Alàgbà Gong ṣe kọ́ni pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n. Nígbànáà a wọnu ọ̀sẹ̀ pàtàkì tí ó mú Ọdún Àjíìnde wá. Bi àwọn àtẹ̀lé Jésù Krístì, tí à ngbé ní ọjọ́ nígbàtí rúdurùdu COVID-19 ti fi ayé sí ìrùkèrúdò, ẹ jẹ́ kí a kan sọ̀rọ̀ nípa Krístì tàbí wàásù Krístì tàbí gba àmì kan tó júwe Krístì.
Ẹ jẹ́ kí a gbé ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù Krístì sí ìṣe!
Bí ẹ ṣe mọ̀, àwọn ọmọ Ìjọ nṣe àkíyèsí àṣẹ ààwẹ̀ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan lóṣù.
Ẹ̀kọ́ ààwẹ̀ jẹ́ ti àtijọ́. Ó ti wà nínú ìṣe nípasẹ̀ àwọn akọni ti-bíbélì látìgbà ìṣíwájú ọjọ́. Moses, David, Ezra, Nehemiah, Esther, Isaiah, Daniel, Joel, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn míràn. Nípasẹ̀ àwọn ohun tí Ísáíàh kọ, Olúwa wípé: ”Àwẹ̀ tí mo ti yàn kọ́ ni èyí? láti tú ọ̀já àìṣòdodo, láti tú erù wíwo, àti láti jẹ́ kí aninilára lọ lọfẹ?”
Àpọ́stélì Páùlù kìlọ̀ fún àwọn Ènìyàn Mímọ́ ní Kọrinti láti ”fi arayín fún àwẹ̀ àti àdúrà.” Olùgbàlà Fúnrarẹ̀ kéde pé àwọn ohun pàtó kò ”ní jáde lọ ṣùgbọ́n nípasẹ̀ àdúrà àti àwẹ̀.”
Mo sọ nínú fídíò ìbákẹ́gbẹ́ ìròhìn láìpẹ́ pé ”bí olùwòsàn àti oníṣẹ́-abẹ, mo ní ọ̀wọ̀ gidi fún àwọn òṣìṣẹ́ ìlera, ṣíyẹ́ntísì, àti àwọn míràn tí wọ́n nṣiṣẹ́ yíká aago láti dẹ́kun ìtànká ti COVID-19.”
Báyìí, bí Ààrẹ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn àti Àpọ́stélì Jésù Krístì, mo mọ̀ pé Ọlọ́run “ní gbogbo agbára, gbogbo ọgbọ́n, àti gbogbo ìmọ̀; ó lóye ohun gbogbo, àti pé ó jẹ́ alaanú Ènìyàn, àní sí ìgbàlà, sí àwọn wọnnì tí yíò ronúpìwàdà àti gbàgbọ́ lórí orúkọ rẹ̀.“
Nítorínáà, ní àwọn ìgbà ìrẹ̀wẹ̀sì jíjinlẹ̀, bí ìgbàtí àìsàn dé ipò rúdurùdu, ohun àdáyébá jùlọ fún wa láti ṣe ni láti képe Bàbá wa Ọ̀run àti Ọmọ Rẹ̀—Ọ̀gá Olùwòsàn—láti fi agbára ìyanu Wọn hàn sí ìbùkún ènìyàn ilẹ̀ ayé.
Ní ọ̀rọ̀ fídíò mi, mo pe gbogbo ènìyàn láti darapọ̀ ní àwẹ̀ lọ́jọ́ Ìsinmi, Oṣù Kẹta Ọjọ́ Mọ́kàndínlọ́gbọ̀n, 2020. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára yín ti rí fídíò wọ́n sì darapọ̀ mọ́ àwẹ̀. Àwọn kàn lè má ni. Báyìí a ṣì nílò ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀run.
Nítorínáà lalẹyi, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, ní ẹ̀mí àwọn ọmọ ti Mòsíàh, tí wọ́n fi arawọn fún ọ̀pọ̀ àwẹ̀ àti àdúrà, àti bí ara ìpàdé àpapọ gbogbogbò Oṣù Kẹrin 2020, mò npè fún àwẹ̀ míràn ní gbogbo ayé. Fún gbogbo àwọn ẹnití ìlera lè fàyègbà, ẹ jẹ́ kí a gbàwẹ̀, gbàdúrà, àti ìrẹ́pọ̀ ìgbàgbọ́ wa lẹ́ẹ̀kansi. Ẹ jẹ́ kí a fi tàdúrà-tàdúrà bẹ̀bẹ̀ fún ìránlọ́wọ́ látinú rúdurùdu gbogbo ayé yí.
Mo pe gbogbo ènìyàn, pẹ̀lú àwọn wọnnì tí kìí ṣe ìgbàgbọ́ wa, láti gbàwẹ̀ àti gbàdúrà ní Jímọ̀h Rere, Ọjọ́ Kẹwa Oṣù Kẹrin, kí rúdurùdu lọ́wọ́lọ́wọ́ lè nídarí, kí àwọn olùtọ́jú ní ààbò, kí ìṣúná owó wa gba okun, àti kí ìgbé ayé padàsí dáadáa.
Báwo ní a ó ṣe gbàwẹ̀? Oúnjẹ ẹ̀ẹ̀méjì tàbí ìgbà wákàtí mẹ́rìnlélógún jẹ́ ìṣe. Ṣùgbọ́n ẹ gbọ́dọ̀ pinnu ohun tí yíò ṣe ètùtù kan fún yín, bí ẹ ti nrántí ìrúbọ̀ alágbára jùlọ tí Olùgbàlà ṣe fún yín. Ẹ jẹ́ kí a parapọ̀ nínú ẹ̀bẹ̀ fún ìwòsàn káàkiri àgbáyé.
Jímọ́h Rere yíò jẹ́ ọjọ́ pípé náà láti ní Bábá wa Ọrùn àti Ọmọ Rẹ̀ láti gbọ́ ti wa!
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n. mo fi ìjìnlẹ̀ ìfẹ́ mi hàn fún yín, lẹgbẹ pẹ̀lú ẹ̀rí mi nípa àtọ̀rùnwá iṣẹ́ nínú èyí tí a gbà. Èyí ni Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Ó dúró ní orí tí ó sì ndarí gbogbo ohun tí à nṣe. Mo mọ̀ pé Òun yíò dáhùn sí àwọn ẹ̀bẹ̀ ènìyàn Rẹ̀. Ní mo jẹ́ ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.