Mímú Ìdájọ́ Òdodo Dájú
Láti mú ìdájọ́ òdodo dájú, ìrúbọ ètùtù Olùgbàlà yíò nu abẹ́lẹ̀ àìmọ̀ àti ẹ̀kún ìrora ti ìpalára tí àwọn míràn fà kúrò.
Ìwé ti Mọ́mọ́nì Kọ́ni ní Ẹ̀kọ́ Krístì.
Ní Oṣù Kẹ́ẹ̀wá tó kọjá, Ààrẹ Russell M. Nelson pèwáníjà láti gbèrò bí ìgbé ayé wa yíò ti yàtọ̀ bí “a bá dédé mú ìmọ̀ tí a jèrè látinú Ìwé ti Mọ́mọ́nì kúrò lójijì?”1 Mo ti jíròrò lórí ìbèèrè rẹ̀, bí ó ṣe dámilójú pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ yín ni. Èrò kan tí wá lẹ́ẹ̀kan àti lẹ́ẹ̀kan si—láìsí Ìwé ti Mọ́mọ́nì àti ìlàálẹ̀ nípa ẹ̀kọ́ Krítì àti ìrúbọ ètùtù Rẹ̀, níbo ni èmi ó yí sí fún àláfíà?
Ẹ̀kọ́ Krístì—èyítí ó wà pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ìgbàlà àti àwọn ìlànà ìgbàgbọ́ nínú Krístì, ìrònúpìwàdà, ìrìbọmi, ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, àti fífaradà dé òpin—ni a kọ́ ní onírurú ìgbà nínú gbogbo àwọn ìwé mímọ́ nípa ìmúpadàbọ̀sípò ṣùgbọ́n pẹ̀lú agbára Ìwé ti Mọ́mọ́nì ní pàtàkì.2 Ẹ̀kọ́ nbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Krístì, àti gbogbo ohun èlò rẹ̀ dálórí ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìrúbọ ètùtù Rẹ̀
Bí Ààrẹ Nelson ṣe kọ́ni, “Ìwé ti Mọ́mọ́nì npèsè ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àti níní-ìmọ̀ aláṣẹ jùlọ nípa Ètùtù Jésù Krístì tí a ri níbikíbi.”3 Bí a ti nní ìmọ̀ nípa ẹ̀bùn Olùgbàlà tó ga jùlọ si, ní a ó wá láti mọ̀ ọ si, nínú wa àti ní ọkàn wa,4 òdodo ìdánilójú ti Ààrẹ Nelson pé “àwọn òtítọ́ Ìwé ti Mọ́mọ́nì ní agbára láti wòsàn, tùnínú, múpadàbọ̀sípò, tùnilára, fúnnilókun, pẹ̀tùsíni, àti mú ìyárí bá ẹ̀mí wa.”5
Ètùtù Olùgbàlà Tẹ́ Gbogbo Ìbèèrè fún Ìdáláre Lọ́run
Kókó kan àti ìdásí ìfúnni ní àláfíà Ìwé ti Mọ́mọ́nì sí ìmọ̀ wa nípa Ètùtù Olùgbàlà ni ìkọ́ni rẹ̀ pé ìrúbọ ti-àánú Krístì mú gbogbo ìbèerè fún ìdáláre wá sí ìmúṣẹ. Bí Álmà ti ṣàlàyé: Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ṣe ètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ayé, láti mú ètò ãnú wá sí ayé, láti ṣe ìtánràn ìbèèrè ìdáláre, kí Ọlọ́run lè jẹ́ Ọlọ́run pípé, Ọlọ́run títọ́, àti Ọlọ́run alãnú bákannáà.”6 Ètò àánú ti Bàbá7—ohun tí ìwé mímọ́ pè ní ètò ìdùnnú bákannáà8 tàbí ètò ìgbàlà9—kò lè ṣeéṣe àyàfi tí gbogbo àwọn ìbèèrè ìdálàre bá tẹ́nilọ́rùn.
Ṣùgbọ̀n kíni àwọn “ìbèèrè fún ìdáláre” gan an? Gbèrò ìrírí Álmà fúnrarẹ̀. Rántí pé bí ọ̀dọ́mọkùnrin kan, Álmà lọ kâkiri ní wíwá “láti pa ìjọ run.”10 Lódodo, Álmà wí fún ọmọ rẹ̀ Hẹ́lámánì pé òun gba “ìnilára pẹ̀lú ìrora ọ̀run àpáàdì” nítorí òun ti fi ímúnádóko “pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára àwọn ọmọ [Ọlọ́run]” nípa dídarí “wọn lọ sí ìparun.”11
Álmà ṣàlàyé sí Hẹ́lámánì pé àláfíà dé síi níkẹhìn nígbàtí iyè rẹ̀ “gba ìdìmú” lórí ìkọ́ni bàbá rẹ̀ “ní ṣíṣe pẹ̀lú bíbọ̀ ti … Jésù Krístì … láti ṣètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ aráyé.”12 Álmà onírònúpìwàdà bẹ̀bẹ̀ fún àánú Krístì13 ó sì ní ìmọ̀lára ayọ̀ nígbànáà àti ìrànlọ́wọ́ nígbàtí òun damọ̀ pé Krístì ṣètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ó sì san gbogbo ìdáláre tò fẹ́. Lẹ́ẹ̀kansi, kíni ìdáláre ìbá ti bèèrè lọ́wọ́ Álmà? Bí Álmà fúnrarẹ̀ ti kọ́ni lẹ́hìnnáà, “ohun àìmọ́ kankan kò lè jógún ìjọba Ọlọ́run.”14 Báyìí, ara ìrànlọ́wọ́ tí Álmà ní gbọ́dọ̀ ti jẹ́ ìyẹnàyàfi tí àánú bá bẹ̀bẹ̀, ìdáláre yíò díwọ́ rẹ̀ ní pípadà láti gbé pẹ̀lú Bàbá Ọ̀run.15
Olùgbàlà Nwo àwọn Ìpalára Tí a Kòlè Wòsàn Sàn
Ṣùgbọ́n ayọ̀ ti Álmà dojúkọ ararẹ̀ nìkàn —lórí yíyẹra fún ìjìyà rẹ̀ àti lílè padà sí ọ̀dọ̀ Bàbá rẹ̀ ? A mọ̀ pé Álmà bákannáà nírora nípa àwọn wọnnì ẹnití òun ti darí lọ kúrò nínú òtítọ́.16 Ṣùgbọ́n Álmà kò lè wòsàn ki ó sì mú gbogbo àwọn wọnnì tí ó ti darí lọ padàbọ̀sípò. Òun fúnrarẹ̀ kò lè ní ìdájú pé wọn yíò gba ànfàní dídára kan láti kọ ẹ̀kọ́ Krístì àti láti di alábùkúnfún nípasẹ̀ gbígbé àwọn ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ aláyọ̀ rẹ̀. Òun kò lè mú àwọn wọnnì tí ó lè ti kú kí wọ́n ṣì fọ́ lójú nípasẹ̀ ìkọ́ni irọ́ rẹ̀.
Bí Ààrẹ Boyd K. Packer ti kọ́ nígbàkan: “Èrò tí ó gba Álmà là … ni èyí: Mímúpadàbọ̀sípò ohun tí ko lè padàbọ̀sípò, ìwòsàn ọgbẹ́ tí ẹ kò lè wòsàn, àtúnṣe ohun èyí tí ó bàjẹ́ tí ẹ kò lè túnṣe ni èrò gan an nípa ètùtù Krístì.”17 Òtítọ́ aláyọ nínú èyítí iyè-inú Álmà ti “gba ìdìmú” kìí ṣe pé oun fúnrarẹ̀ lásán lè ṣe ìwẹ̀nùmọ́ ṣùgbọ́n kí àwọn wọnnì tí ó ti palára lè gba ìwòsàn kí ara wọn le.
Ìrúbọ Olùgbàlà Mú Ìdájọ́ Òdodo Dájú
Ọ̀pọ̀ ọdún ṣíwájú kí a tó gba Álmà là nípasẹ̀ ìtún-dánilójú ẹ̀kọ́, tí Ọba Benjamin kọ́ni nípa ìbú ìwonisàn tí a fúnni nípasẹ̀ ìrúbọ ètùtù Olùgbàlà. Ọba Benjamin kéde pé “ ìròhìn ìdùnnú ayọ̀ nlá” ni a fún un “nípasẹ̀ ángẹ́lì kan látọ́dọ́ Ọlọ́run.”18 Ní àárín àwọn ìròhìn ìdùnnú wọnnì ni òtítọ́ pé Krístì yíò jìyà tí yíò sì kú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa àti àṣìṣe láti mudájú pé “ìdájọ́ òdodo kan lè wá sórí àwọn ọmọ Ọlọ́run.”19
Kíni ohun tí “ìdájọ́ òdodo” bèèrè fún gan an? Ní ẹsẹ tó tẹ̀le, Ọba Benjamin ṣàlàyé pé, láti mú ìdájọ́ òdodo dájú, ẹ̀jẹ̀ Olùgbàlà ṣètùtù “fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn wọnnì tí wọ́n ṣubú nípasẹ̀ ìrékọjá Ádámù” àti fún àwọn wọnnì “tí wọ́n ti kú láì mọ ìfẹ́ Ọlọ́run nípa wọn, tàbí tí wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ láìmọ̀.”20 Ìdájọ́ òdodo kan bákannáà nfẹ́, ó kọ́ni, pé “ẹ̀jẹ̀ Krístì ṣe ètùtù fún” àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ọmọdé.21
Àwọn ìwé mímọ́ wọ̀nyí kọ́ ẹ̀kọ́ ológo kan:ìrúbọ̀ ètùtù Olùgbàlà nwòsàn, gẹ́gẹ́bí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́, àwọn wọnnì tí wọ́n dẹ́ṣẹ̀ nínú àìmọ̀—àwọn ẹnití, bí Jákọ́bù ṣe sọ ọ́, “kò sí òfin tí a fúnni.”22 Ìdáhùn fún ẹ̀ṣẹ̀ dálórí ìmọ́lẹ̀ tí a ti fúnni ó sì rọ̀ mọ́ agbára wa láti lo agbára láti yàn wa.23 A mọ̀ ìwòsàn yí àti òtítọ́ ìtuninínú nìkan nítorí Ìwé ti Mọ́mọ́nì àti ìwé mímọ́ Ìmúpadapbọ̀sípò míràn.24
Bẹ́ẹ̀ni, nibi tí a bá ti fúnni ní òfin, níbití a kò ṣaláìmọ ìfẹ́ Ọlọ́run, aó dáhun fun. Bí Ọba Benjamin ti tẹnumọ: ègbé ni fún ẹnití ó mọ̀ wípé ó ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run! Nítorítí ìgbàlà kò sí fún irú ẹni bẹ̃ àfi nípasẹ̀ ìrònúpìwàdà àti ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì Olúwa.”25
Èyí pẹ̀lú ni ìròhìn ìdùnnú ti ẹ̀kọ́ Krístì. Kìí ṣe pé Olùgbàlà wòsàn nìkan ó mú àwọn wọnnì tí wọ́n ṣẹ̀ nínú àìmọ̀ padàbọ̀sípò bákannáà, fún àwọn wọnnì tí wọ́n ṣẹ̀ sí ìmọ́lẹ̀, Olùgbàlà fùnni ní ìwòsàn lórí ipò ìrònúpìwàdà àti ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀.26
Álmà gbọ́dọ̀ “gba ìdìmú” ti àwọn òtítọ́ wọ̀nyí. Njẹ́ Álmà ní ìmọ̀lára ohun tí ó júwe bí “ayọ̀ dídára … nítòótọ́”27 bí ó bá rò pé Krístì gba òun là ṣùgbọ́n fi àpá sára àwọn wọnnì tí òun darí lọ kúrò nínú òtítọ́ láéláé? Dájúdájú bẹ́ẹ̀kọ́. Kí Álmà lè ní ìmọ̀lára àláfíà pípé, àwọn wọnnì tí ó pa lára bákannáà nílò ànfàní láti gba ìmúláradá.
Ṣùgbọ́n báwo ni àwọn yíò ti—tàbí àwọn wọnnì tí a lè palára—gba ìmúláradá? Bíótilẹ̀jẹ́pé a kò ní ìmọ̀ àwọn ìṣe mímọ́ ní kíkún nípasẹ̀ èyí tí ìrúbọ ètùtù Olùgbàlà nwòsàn tí ó sì nmúpadàbọ̀sípò, a kò mọ̀ pé láti mú ìdájọ́ òdodo dájú, Olùgbàlà yíò nu abệbúrọ́ọ̀ṣì àìmọ̀ kúrò àti àwọn ẹ̀gún ìrora ti ìpalára tí àwọn ẹlòmíràn dá fún wa.28 Nípa èyí Ó mu dájú pé gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run yíò gba ànfàní, pẹ̀lú ìran òkùnkùn, láti yàn láti tẹ̀lé E àti láti tẹ́wọ́gba ètò nlá ti ìdùnnú.29
Olùgbàlà Yíò Tún Ohungbogbo Tó Ti Bàjẹ́ Se
Àwọn òtítọ́ wọ̀nyí ni pé a ó mú àláfíà wá fún Álmà. Àti pé àwọn òtítọ́ wọ̀nyí ni ó gbọ́dọ̀ mú àláfíà nlá wá fún wa pẹ̀lú. Bí àwọn ọkùnrin àti obìnrin ẹlẹ́ran-ara, gbogbo wa nṣubú, tàbí nígbàmíràn ṣèṣe, sínú arawa tí yíò fa ìpalára. Bí obikobi ṣe lè jẹ́ẹ̀rí, ìrora tí ó rọ̀mọ́ àwọn àṣìṣe wa kìí ṣe ẹ̀rù ìrọ̀rùn ti ìjìyà ti arawa ṣùgbọ́n ẹ̀rù pé a lè fi òpin sí ayọ̀ àwọn ọmọ wa tàbí níàwọn ọ̀nà míràn kí a dá wọn lẹ́kun ní wíwò àti níní òye òtítọ́. Ìlérí ológo ti ìrúbọ ètùtù Olùgbàlà ni pé bí àwọn àṣìṣe wa bí òbí ṣe laniyan sí, Ó ndi àwọn ọmọ wa mú bí aláìlẹbi ó sì nṣèlérí ìwòsàn fún wọn.31 Àní nígbàtí wọ́n bá sì ṣẹ̀ sí ìmọ́lẹ̀—bí gbogbo wa ti nṣe—ọwọ́ àánú Rẹ̀ nà síta32 àti pé Òun yíò sì rà wọ́n padà tí wọ́n yíò bá wo Ó kí wọ́n sì yè.33
Bíótilẹ̀jẹ́pé Olùgbàlà ní agbára láti tún ohun tí a kò lè ṣe ṣe, Ó pàṣẹ fún wa láti ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti ṣe ìdápadà bí apákan ìrònúpìwàdà wa.34 Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa àti àṣìṣe kìí mú ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run kúrò nìkan ṣùgbọ́n bákannáà àwọn ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Nígbàmíràn àwọn ìtiraka wa láti wòsàn àti láti múpadàbọ̀sípò lè jẹ́ ìrọ̀rùn bí ẹ̀bẹ̀ kan, ṣùgbọ́n ní àwọn ìgbà míràn ìdápadà lè gba ọ̀pọ̀ ọdún ìtiraka ti ìrẹ̀lẹ̀.35 Síbẹ̀síbẹ̀, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa àti àṣìṣe, a kò lè wo àwọn wọnnì tí a ti palára sàn ní kíkún lásán. Ìlérí títóbi, ìfúnnini-àláfíà Ìwé ti Mọ́mọ́nì àti ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere ni pé Olùgbàlà yíò tún gbogbo ohun tí a ti bàjẹ́ ṣe.36 Òun ó sì tún wa ṣe bákannáà bí a bá yípadà sí I nínú ìgbàgbọ́ àti ìrònúpìwàdà ìpalara tí a dá.37 Ó fúnni ní àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí méjèèjì nítorí Ó nifẹ gbogbo wa pẹ̀lú ifẹ́ pípé38 àti pé nítorí pé ó ní ìfọkànsìn sí ìmúdájú òdodo kan tí ó nbu ọlá fún méjèèjì ìdáláre àti àánú . Mo jẹ́rí pé èyí jẹ́ òtítọ́ ní orúkọ ti Olúwa Jésù Krístì, àmín.