Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Àdúrà Ìgbàgbọ́
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2020


Àdúrà Ìgbàgbọ́

Bí a ṣe ngbàdúrà nínú ìgbàgbọ́, a ó jẹ́ ipa pàtàkì nínú iṣẹ́ Olúwa bí Ó ṣe nmúra ayé sílẹ̀ fún Ìpadàbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Rẹ̀.

Àdúrà Alàgbà Maynes ní ìbẹ̀rẹ̀ abala ìkínní ti ìpàdé àpapọ̀ yí ti ngba ìdáhùn. Ìmísí ti wá sọ́dọ̀ wá nípasẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ oníyanu àti orin aládùn. Ìlérí Ààrẹ Russell M. Nelson pé ìpàdé àpapọ̀ yí yíò jẹ́ onírántí ní ó ti bẹ̀rẹ̀sí wá sí ìmúṣẹ.

Àarẹ Nelson ti ya ọdún yí sọ́tọ̀ bí “àkokò àjọyọ̀ ayẹyẹ igba ọdún látigbà tí Ọlọ́run Bàbá àti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, ti farahàn sí Joseph Smith nínú ìran.” Ààrẹ Nelson pè wá láti ṣe ètò araẹni láti múra arawa sílẹ̀ fún ìpadé àpapọ̀ onítàn yí, èyítí ó sọ pé rírántí yíò jẹ́ “kókó àmì kan nínú ìwé-ìtàn Ìjọ, àti pé ipa yín ṣe pàtàkì.”1

Bíiti èmí, bóyá ẹ ti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ kí ẹ sì bèèrè lọ́wọ́ ara yín, “Ní ọ̀nà wo ni ipa mi fi ṣe pàtàkì?” Bóyá ẹ kàá tí ẹ sì gbàdúrà nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ti Ìmúpadàbọ̀sípò. Bóyá, ju ti àtẹ̀hìnwá lọ, ẹ ka àwọn àkọsílẹ̀ ti àwọn ìgbà ọ̀tọ̀ wọnnì nígbàtí Ọlọ́run Bàbá fi Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀ hàn. Bóyá ẹ ka àwọn àpẹrẹ nígbàtí Olùgbàlà sọ̀rọ̀ sí àwọn ọmọ Bàbá wa Ọ̀run. Èmi mọ̀ pé mo ṣe gbogbo ohun wọnnì àti jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Mo rí àwọn ìtọ́kasí nínú kíka mi sí oyèàlùfáà Ọlọ́run àti ṣíṣí àwọn àkokò. Mo nírẹ̀lẹ̀ bí mo ṣe damọ̀ pé ìmúrasílẹ̀ fún ìpàdé àpapọ̀ yí jẹ́ kókó àmì kan nínú ìwé ìtàn ara mi. Mo ní ìmọ̀lára àwọn ìyípadà nínú ọkàn mi. Mo ní ìmoore titun. Mo ní ìmọ̀lára kíkún pẹ̀lú ayọ̀ ní ìgbìrò pípè láti kópa nínú ayẹyẹ Ìmúpadàbọ̀sípò tó nlọ lọ́wọ́ yí.

Mo ronú ohun tí àwọn ẹlòmíràn lè máa rò, nítorí ìmúrasíllẹ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, aláyọ síi, níní ìgbàgbọ́ si, àti níní ìpinnu síi láti sìn ní ipòkípò ìnílò látọ̀dọ̀ Olúwa.

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó tayọ tí a buyì fún ni ìbẹ̀rẹ̀ ti àṣọtẹ́lẹ̀ àkokò tó kọjá, nínú èyí tí Olúwa ti nmúra Ìjọ Rẹ̀ àti àwọn ènìyàn Rẹ̀ sílẹ̀, àwọn tí wọ́n njẹ́ orúkọ Rẹ̀, láti Gbà A. Bí ara ìmúrasílẹ̀ wa fún bíbọ Rẹ̀, Òun yíò gbé wa sókè kí a lè bá àwọn ìpènijà ẹ̀mí àti ànfàní dọ́gba yàtọ̀ sí eyikeyi tí a rí nínú ìwé-ìtàn ayé yí.

Ní Oṣù Kẹsan 1840, Wòlíì Joseph Smith àti àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ nínú Àjọ Ààrẹ Kínní kéde ìwọ̀nyí: “Iṣẹ́ Olúwa ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn wọ̀nyí, ni ọ̀kan lára títóbi jùlọ àti pé ó fẹ́rẹ̀ kọjá òye ẹlẹ́ran ara. Àwọn ògo rẹ̀ jẹ́ ìjúwe tẹ́lẹ̀rí, àti pé ó jẹ́ iyì tí kò láfiwé. Ó jẹ́ àkórí èyí tí ó fi àwòrán àyà àwọn wòlíì àti àwọn ọkùnrin rere látigbà ìṣẹ̀dá ayé wá sílẹ̀ nínú gbogbo iran àtẹ̀lé dé àkokò yí; àti pé nítòótọ́ ó jẹ́ ìgbà ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àkokò nítòótọ́, nígbàtí gbogbo ohun èyítí ó wà nínú Jésù Krístì, bóyá ní ọ̀run tàbí lórí ilẹ̀ ayé, yíò kórajọ papọ̀ nínú Rẹ̀, àti nígbàtí ohun gbogbo yíò padàbọ̀sípò, bí a ti sọ látẹnu gbogbo àwọn wòlíì mímọ́ látìgbà tí ayé ti bẹ̀rẹ̀; nítorí nínú rẹ̀ ni ìmúṣẹ ológo àwọn ìlérí tí a ṣe fáwọn bàbá yíò ti ṣẹlẹ̀, nígbàtí àwọn ìfihàn agbára ti Ọba Ògo yíò jẹ́ títóbí, ológo, àti ọlọ́la“

Wọ́n tẹ̀síwájú láti wípé: “A nímọ̀lára láti lọ síwájú àti da okun wa pọ̀ fún gbígbéga ti Ìjọba, àti gbígbé kalẹ̀ Oyèàlùfáà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àti ògo wọn. A níláti ṣàṣeyege iṣẹ́ yí ní àwọn ọjọ́ tó gbẹ̀hìn ni ọ̀kan ti ìyára, a ó sì pe ìṣe wa sí okun, iṣẹ́, ẹ̀bùn, àti agbára àwọn Ènìyàn Mímọ́, nítorínáà kí ó lè lọ síwájú pẹ̀lú ògo àti ọlánlá tí a júwe látọwọ́ [Dáníẹ́lì] [wo Dáníẹ́lì 2:34–35, 44–45]; ní àṣẹ̀hìnwá a ó bèèrè ìgbáralé àwọn Ènìyàn Mímọ́, láti ṣàṣeyege àwọn iṣẹ́ ti irú títóbi àti iyì náà.”2

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn kókó ohun tí a ó ṣe àti ìgbàtí a ó ṣeé nínú ṣíṣí Ìmúpadàbọ̀ ni a kò tíì fihàn. Síbẹ̀síbẹ̀ Àjọ Ààrẹ Kínní àní ní àwọn ọjọ́ ìṣaájú wọnnì mọ ìbú àti jíjinlẹ̀ iṣẹ́ Olúwa tí a gbékalẹ̀ níwájú wa. Nihin ni àwọn àpẹrẹ díẹ̀ nípa ohun tí a mọ̀ pé yíò ṣẹlẹ̀:

Látọ̀dọ̀ àwọn Ènìyàn Mímọ́ Rẹ̀, Olúwa yíò fúnni ní ẹ̀bùn ìhìnrere Rẹ̀ “sí gbogbo orílẹ̀-èdè, ìbátan, ahọ́n, àti àwọn ènìyàn.”3 Ẹ̀rọ ìgbàlódé àti àwọn iṣẹ́ ìyanu yíò tẹ̀síwájú láti ṣe apákan—bí yíò ti jẹ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan “apẹja ènìyàn”4 tí wọ́n nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú agbára àti àlékún ìgbàgbọ́.

Àwa bí àwọn ẹ̀nìyàn kan yíò ní ìrẹ́pọ̀ síi ní àárín àlékún ìjà. A ó korajọ nínú okun ẹ̀mí ti àwọn ẹgbẹ́ àti ẹbí tó kún pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ ìhìnrere.

Àní ayé àìnígbàgbọ́ yíò dá Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn mọ̀ wọ́n sì mọ̀ agbára Ọlọ́rin lórí rẹ̀. Àwọn Onígbàgbọ́ àti akọni ọmọẹ̀hìn yíò fi àìbẹ̀rù, tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀, àti gbé orúkọ Krístì lé orí ara wọn ní gbangban ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn.

Báwo, nígbànáà, ni ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ṣe lè kópa nínú iṣẹ́ títóbi àti oníyì yí? Ààrẹ Nelson kọ́ni bí a ó ṣe dàgbà níti agbára ẹ̀mí. Nígbàtí a bá gba ìrònúpìwàdà bí ànfàní aláyọ̀ kan nítorí ìgbàgbọ́ wa tó ndàgbà pé Jésù ni Krístì, nígbàtí a bá lóye tí a sì gbàgbọ́ pé Bàbá Ọ̀run ngbọ́ gbogbo àdúrà wa, nígbàtí a bá tiraka láti gbọ̀ran àti làti gbé ìgbé ayé àwọn òfin, a ó dàgbà nínú agbára wa láti gba ìfihàn lemọ́lemọ́. Ẹ̀mí Mímọ́ lè di ojúgba wa léraléra. Ìmọ̀lára ti ìmọ́lẹ̀ kan lè dúró pẹ̀lú wa àní bí ayé ní àyíká wa ṣe ndúdú si.

Jósẹ́fù Smith ni àpẹrẹ kan bí a ṣe lè dàgbà nínú irú agbára ti ẹ̀mí. Ó fi hàn wá pé àdúrà ìgbàgbọ́ ni kọ́kọ́rọ́ sí ìfihàn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ó gbàdúrà nínú ìgbàgbọ́, ní gbígbàgbọ́ pé Ọlọ́run Bàbá ndáhùn àwọn àdúrà. Ó gbàdúrà nínú ìgbàgbọ́, ní gbígbàgbọ́ pé nípasẹ̀ Jésù Krístì nìkan ni òun lè di òmìnira kúrò nínú ẹ̀bi tí òun ní fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ òun. Ó sì gbàdúrà nínú ìgbàgbọ́, ní gbígbàgbọ́ pé òun nílò láti wá Ìjọ òtítọ́ ti Jésù Krístì láti jèrè ìdáríjì náà.

Nínú gbogbo iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti wòlíì rẹ̀, Jósẹ́fù Smith lo àwọn àdúrà ìgbàgbọ́ láti gba ìfihàn lemọ́lemọ́. Bí a ṣe ndojúkọ àwọn ìpenijà òní àti àwọn wọnnì tí kò tíì dé, àwa bákannáà nílò láti ṣe ìṣe irú àwòṣe kannáà. Ààrẹ Brigham Young wípé, “Èmi kò mọ ọ̀nà míràn fún àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ju fún gbogbo ẹ̀mí láti máa gbàdùrà kí Ọlọ̀run tọ́nisọ́nà kí ó sì darí àwọn ènìyàn rẹ̀.”5

Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí látinú àwọn àdúrà oúnjẹ Olúwa nígbànáà gbọ́dọ̀ jẹ́ ìjúwe ti ojoojúmọ́ ayè wa: “Rántí rẹ̀ nígbàgbogbo.” “Rẹ̀” tọ́kasí sí Jésù Krístì. Àwọn ọ̀rọ̀ tó tẹ̀le, “kí ẹ pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́,” dáàbá ohun tí ó túmọ̀ sí láti rántí Rẹ̀.6 Bí a ṣe nrántí Jésù Krístì nígbàgbogbo, a lè bèèrè nínú àdúrà kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, “Ohun tí Yíò fẹ́ kí a ṣe?”

Irú àdúrà náà, tí a gbà ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krìstì, mú àkokò ìgbẹ̀hìn yí wá. Yíò sì wà ní ọkàn ipa tí ẹnìkọ̀ọkan wa yíò ṣe ní ṣíṣí rẹ̀ léraléra. Mo ti rí, bí ẹ ti ní àwọn àpẹrẹ oníyanu irú àdúrà náà.

Àkọ́kọ́ ni Josẹ́fù Smith. Ó bèèrè ní ìgbàgbọ́ ìwàbiọmọdé ohun tí Olúwa yíò fẹ́ kí òun ṣe. Ìdáhùn rẹ̀ yí ìwé-ìtàn ayé padà.

Sí mi, ẹ̀kọ́ pàtàkì jùlọ nwá látinú ìdáhùn Jósẹ́fù sí ìkọlù Sátánì bí Jósẹ́fù ṣe kúnlẹ̀ láti gbàdúrà.

Mo mọ̀ látinú ìrírí pé Sátánì àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ngbìyànjú láti mú wa rò pé a kò gbọ́dọ̀ gbàdúrà. Nígbàtí Jósẹ́fù Smith lo gbogbo agbára rẹ̀ láti képe Ọlọ́run láti gba òun là kúrò nínú agbára tí ó ngbìyànjú láti de òun, àdúrà rẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ ni ó gbà Bàbá Ọ̀run àti Jésù Krístì farahàn.

Ìtiraka Sátánì láti tú ìbẹ̀rẹ̀ Ìmúpadàbọ̀sípò ká le koko nítorí àdúrà Jósẹ́fù ṣe pàtàkì gidi. Ẹ̀yin àti èmi ní àwọn ipa láti ṣe nínú Ìmúpadàbọ̀sípò tó nlọ lọ́wọ́. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀tá Ìmúpadàbọ̀sípò yíò gbìyànjú láti dáwadúró ní gbígbàdúrà. Ìgbàgbọ́ Jósẹ́fù àti ìpinnu rẹ̀ lè fún wa lókun nínú àbájádé wa. Èyí ni ọ̀kan lára ọ̀pọ̀lọpọ̀ èrèdí tí àdúrà mi fi pẹ̀lú ọpẹ́ sí Bàbá Ọ̀run fún Wòlíì Jósẹ́fù.

Énọ́sì nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì ni àwòṣe míràn fún àdúrà ìgbàgbọ́ mi bí mo ṣe ngbíyànjú láti sa ipa mi nínú Ìmúpadàbọ̀sípò léralérá. Ohunkóhun tí ipa yín yíò jẹ́, ẹ lè mu gẹ́gẹ́bí olùtọ́ni ara yín bákannáà.

Bíiti Jósẹ́fù, Énọ́sì gbàdúrà nínú ìgbàgbọ́. Ó júwe ìrírí rẹ̀ ní ọ̀nà yí:

Ẹ̀mí mi si kébi; mo sì kúnlẹ̀ níwájú Ẹlẹ́da mi, mo sì kígbe pẽ nínú ọ̀pọ̀ àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ tí ó lágbára fún ẹ̀mí ara mi; àti ní gbogbo ọjọ́ ni èmi kígbe pè é; bẹ̃ni, nígbàtí alẹ́ sì lẹ́, èmi sì tún gbé ohùn mi sókè tí ó fi dé àwọn ọ̀run.

Ohùn kan sì tọ̀ mí wá, tí ó wípé: Énọ́sì, a dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́, a ó sì bùkún ọ.

Èmi, Énọ́sì sì mọ̀ wípé Ọlọ́run kò lè purọ́; nítorí-èyi, a ti gbá ẹ̀bi mi lọ.

Mo sì wípé: Olúwa, báwo ni a ṣe ṣe èyĩ?

Ó sì wí fún mi pé: Nítorí ìgbàgbọ́ rẹ nínú Krístì, ẹnití ìwọ kò gbọ́ tàbí rí rí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sì kọjá lọ kí ó tó di pé yíò fi ara rẹ̀ hàn ní ẹran ara; nítorí ìdí èyí, máa lọ, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá.”7

Ẹ̀kọ́ tí ó ti bùkún mi ni àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: Nítorí ìgbàgbọ́ rẹ nínú Krístì, ẹnití ìwọ kò gbọ́ tàbí rí rí.”

Jósẹ́fù ní ìgbàgbọ́ nínú Krístì láti lọ sínú igbó àti láti gbàdúrà fún ìtúsílẹ̀ látinú agbára Sátánì bákannáà. Òun kò tíì rí Bàbá àti Ọmọ rí, ṣùgbọ́n ó gbàdúrà nínú ìgbàgbọ́ pẹ̀lú gbogbo okun ọkàn rẹ̀.

Ìrírí Énọ́sì ti kọ́ mi ní irú ẹ̀kọ́ iyebíye kannáà. Nígbàtí mo bá gbàdúrà pẹ̀lú ìgbàgbọ́, mo ní Olùgbàlà bí alágbàwí mi pẹ̀lú Bàbá àti pé mo lè nímọ̀lára pé àdúrà mi dé ọ̀run. Àwọn ìdáhùn nwá. À ngbà àwọn ìbùkún. Àláfíà wa àti ayọ̀ ní àwọn ìgbà líle.

Mo rántí ìgbàtí, bíi ọmọ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá titun, tí mo kúnlẹ̀ nínú àdúrà pẹ̀lù Alàgbà David B. Haight. Ó wà bí ọjọ́ orí tí mo wà báyìí, pẹ̀lú àwọn ìpènijà tí mò nní ìrírí báyìí fúnra mi. Mo rántí ohùn rẹ̀ bí ó ṣe gbàdúrà. Èmi kò la ojú mi láti wòó, ṣùgbọ́n ó dún bíì pé ó nrẹrin. Ó sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Bàbá Ọ̀run pẹ̀lú ayọ̀ nínú ohùn rẹ̀.

Mo lè gbọ́ ìdùnnú rẹ̀ nínú mi nígbàtí ó wípé, “Ní orúkọ Jésù Krístì.” Ó dún sí mi bí Alàgbà Haight ṣe nímọ̀lára Olùgbàlà tí ó ntẹ́numọ́ ọ̀rọ̀ tí ó ti gbàdúrà sí Bàbá fún ní àkokò náà. Ó sì dá mi lójú pé yíò gbà a pẹ̀lú ẹ̀rín.

Agbára wa láti ṣe ìdásí pàtàkì sí Ìmúpadàbọ̀sípò lemọ́lemọ́ oníyanu yíò mú ìdàgbà nínú ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù Krístì bí Olùgbàlà wa àti Bàbá wa Ọ̀run bí olùfẹ́ni Bàbá wa pọ̀si Bí a ṣe ngbàdúrà nínú ìgbàgbọ́, a ó jẹ́ ipa pàtàkì nínú iṣẹ́ Olúwa bí Ó ṣe nmúra ayé sílẹ̀ fún Ìpadàbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Rẹ̀. Mo gbàdúrà pé kí gbogbo wa lè rí ayọ̀ ní ṣíṣe iṣẹ́ tí Ó pe ẹnìkọ̀ọ̀kan wa sí láti ṣe.

Mo jẹ́ẹ̀rí pé Jésù Krístì wà láàyè. Èyí ni Ìjọ Rẹ̀ àti ìjọbá lórí ilẹ̀ ayé. Jósẹ́fù Smith ni wòlíì Ìmúpadàbọ̀sípò. Ààrẹ Russell M. Nelson ni wòlíì alààyè ti Olúwa lórí ilẹ̀ ayé loni. Ó di gbogbo kọ́kọ́rọ́ oyèàlùfáà ní Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.