Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìmúṣẹ nípa Àsọtẹ́lẹ̀
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2020


Ìmúṣẹ níti Ìsọtẹ́lẹ̀

Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí a ti múṣẹ nípasẹ̀ Ìmúpadàbọ̀sípò ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere ti Jésù Krístìjẹ́ púpọ̀.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, mo níyìn láti sọ̀rọ̀ ní ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò oniranti yí tí à nṣayẹyẹ Ìran Kíní Joseph Smith ti Ọlọ́run Bàbá àti ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, nínú ohun tí ó jẹ́, láìsí ìbèère, Igbó Mímọ́ kan. Ìran náà jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ọlánlá kan sí Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere àti gbogbo ohun tó ṣí, látinú Ìwé ti Mọ́mọ́nì sí ìpadàbọ̀ àṣẹ oyèàlùfáà àti àwọn kọ́kọ́rọ́, ìṣètò Ìjọ òtítọ́ Olúwa, àwọn tẹ́mpìlì Ọlọ́run, àti àwọn wòlíì àti àwọn àpóstélì tí wọ́n ndarí iṣẹ́ náà ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn wọ̀nyí.

Nípa àwòṣe tọ̀run, àwọn wòlíì nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́, sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ìmúpadàbọ̀sípò àti ohun tí ó máa ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ wa, àkokò ìkẹhìn àti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn ìgbà. Ọ̀rọ̀ náà kan “fíná mọ́ àwọn ẹ̀mí” ti àwọn aríran ìṣíwájú.1 Nínú àwọn ìran ti ìgbà, wọ́n sọ-tẹ́lẹ̀, lá àlá, rò tẹ́lẹ̀, àti sàsọtẹ́lẹ̀ ọjọ́ ọ̀la ìjọba Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé, ohun tí Ísáíàh pè ní “ìṣẹ́ ìyanu àti àrà kan.”2

Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí a ti múṣẹ nípasẹ̀ Ìmúpadàbọ̀sípò ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere ti Jésù Krístì, pẹ̀lú Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, jẹ́ púpọ̀. Loni, bákannáà, èmi ó sàmì sí ìba díẹ̀ lára àwọn àyànfẹ́ mi. Ìwọ̀nyí ni a kọ́ mi látọwọ́ àwọn olùkọ́ ọ̀wọ́n Alakọbẹrẹ mi àti ní eékún ìyá mi ángẹ́lì.

Àwòrán
Dáníẹ̀lì nínú ihò Kìnìhún

Daniel, ẹni tí ó lé àwọn kìnìún kúrò nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Olúwa Jésù Krístì àti ẹ̀bẹ̀ àwọn ángẹ́lì oníṣẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run, ni ẹnìkan tó rí ọjọ́ wa nínú ìran. Rírọ́ àlá fún Ọba Babiloni Nebuchadnezzar, Daniel sọtẹ́lẹ̀ pé Ìjọ Olúwa yíò dìde ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn bí òkúta kékeré “tí a gé jáde látinú òkè láìsí ọwọ́.”3 “Láìsí ọwọ́,” túmọ̀sí nípasẹ̀ ìlàjà tọ̀run, Ìjọ Olúwa yíò pọ̀ si ní títóbi títí yíò fi kún gbogbo ilẹ̀ ayé “láì [ní] ìbàjẹ́ … [ṣùgbọ́n láti] dúró láéláé.”4

Àwòrán
Dáníẹ̀lì rọ́ àlá

Ó jẹ́ ẹ̀rí tó jinlẹ̀ pé àwọn ọ̀rọ̀ Dáníẹ̀lì ti wá sí ìmúṣẹ bí àwọn ọmọ Ìjọ, láti gbogbo ayé, ṣe nwo tí wọ́n sì nfetísílẹ̀ sí ìpàdé àpapọ̀ loni.

Olùfọ̀kànsìn Àpọ́stélì Pétérù júwe “àwọn ìgbà ìdápadà ohun gbogbo … Látigbà tí ayé ti bẹ̀rẹ̀.”5 Àpọ́stélì Páùlù kọ pé ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn ìgbà, Ọlọ́run yíò “kó … ohun gbogbo jọ ní ọ̀kan nínú Krístì,”6 “Jésù Krístì fúnrarẹ̀ jẹ́ pàtàkì òkúta igunlé.”7 Mo ní ìmọ̀lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọnnì gan an nígbàtí mo kópa nínú ìyàsímímọ́ Tẹ́mpìlì Rome Italy. Gbogbo àwọn wòlíì àti àpọ́stélì wà níbẹ̀ tí wọ́n njẹ́ ẹ̀rí Jésù Krístì, Olùràpàdà ayé, bi ti Pètèrù àti Páùlù. Ìjọ jẹ́ àpẹrẹ alààyè kan ti ìmúpadà, àwọn arákùnrin àti arábìnrin, àti àwọn ọmọ ìjọ jẹ́ ẹlẹ́ẹ̀rí àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ tọ̀run wọnnì tipẹ́tipẹ́ sẹ́hìn.

Àwòrán
Àwọn Wòlíì àti Àpọ́stélì ní Tẹ́mpìlì Rome Italy

Joseph ti Egypt sọtẹ́lẹ̀ pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn: “aríran kan ni Olúwa mi yíò gbé dìde, ẹnití yíò jẹ́ aríran tí a yàn fún àwọn irú ọmọ láti ara mi.”8 “Nítorí òun yíò ṣe iṣẹ́ [Olúwa].”9 Joseph Smith, wòlíì Ìmúpadàbọ̀sípò, jẹ́ àríran náà.

Jòhánnù Olùfihàn sọtẹ̀lẹ́ nípa ángẹ́lì Olódùmarè tí o mú àwọn ohun èlò pàtàkí wá papọ̀ nípa Ìmúpadàbọ̀sípò pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Mo sì rí ángẹ́lì míràn tó nfò ní agbedeméjì ọ̀run, tí ó ní ìhìnrere àìnípẹ̀kun láti wàásù fún àwọn tí ó ngbé ni ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀, àti ẹ̀yà, àti èdè, àti ènìyàn.”10 Mórónì ni ángẹ́lì náà. Ó rí ọjọ́ wa bí a ṣe kọ sínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ní wíwá léraléra, ó múra Joseph Smith sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀, pẹ̀lú àyípadà-èdè Ìwé ti Mọ́mọ́nì: Ẹ̀rí míràn ti Jésù Krístì.

Àwòrán
Mórónì nfarahàn sí Joseph Smith

Àwọn wòlíì míràn sọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ wa. Malachi sọ nípa Elijah níti yíyí “ọkàn bàbá padà sí àwọn ọmọ, àti ọkàn ọmọ padà sí bàbá wọn.”11 Èlíjàh ti wá, àti ní àbájáde, loni, a ní àwọn tẹ́mpìlì méjìdínláadọ́san káàkiri ilẹ̀ ayé. Tẹ́mpìlì kọ̀ọ̀kan kún fún àwọn ọmọ ìjọ yíyẹ tí wọ̀n ndá májẹ̀mú mímọ́ tí wọ́n sì ngba ìbùkún àwọn ìlànà ní ìtìlẹhìn arawọn àti àwọn okú bàbánlá wọn. Iṣẹ́ mímọ́ yí júwe Málákì bí “gbùngbun sí ètò Aṣẹ̀dá fún àyànmọ́ ayérayé ti àwọn ọmọ Rẹ̀.”12

À ngbé ní ìgbà àsọtẹ́lẹ̀ náà; a jẹ́ ènìyàn tí wọ́n fún láṣẹ pẹ̀lú mímúwá Ìpadàbọ̀ Jésù Krístì Ẹ̀ẹ̀kejì; a níláti kó àwọn ọmọ Ọlọ́run jọ, àwọn wọnnì tí wọn yíò gbọ́ àti gba àwọn òtítọ́ náà, àwọn májẹ̀mú àti ìhìnrere àìlópin mọ́ra. Ààrẹ Nelson pèé ní “ìpènijàtítóbi jùlọ náà, èrò títóbi jùlọ náà, àti iṣẹ́ títóbi jùlọ lórí ilẹ̀ ayé [náà] loni.”13 Nípa iṣẹ́ ìyanu náà ni mo jẹ ẹ̀rí mi.

Àwòrán
Ìyàsímímọ́ Tẹ́mpìlì Durban Gúsù Áfríkà

Nípasẹ̀ Ìfúnni-níṣẹ́ṣe mi látọ̀dọ̀ Ààrẹ Russell M. Nelson, ní Oṣù Kejì ọdún yí mo ya Tẹ́mpìlì Durban South Africa sí mímọ́. O jẹ́ ọjọ́ kan tí èmi ó rántí ní gbogbo ayé mi. Mo wà pẹ̀lú àwọn ọmọ ìjọ tí wọ́n wá fún ìhìnrere bí Jeremíàh ti sọtẹ́lẹ ní ọjọ́ pipẹ́ sẹ́hìn—“ọ̀kan lára ìlú, àti méjì lára ẹbí.”14 Ẹ̀kọ́ Jésù Krístì mú gbogbo wa nirepọ̀—yíká ayé—bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Ọlọ́run, bí àwọn arákùnrin àti arábìnrin nínú ìhìnrere. Láìka bí a ṣe rí tàbí ẹ̀wù sí, a jẹ́ ènìyàn kan pẹ̀lú Bàbá ní Ọ̀run ẹnití ètò rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ ni òun sì wà fún ẹbí Rẹ̀ láti ní ìrẹ́pọ̀ nípa dídá àti pípa àwọn májẹ̀mú mímọ́ tẹ́mpìlì.

Sí ìkójọ kékeré àwọn olùdìmú oyèàlùfáà nínú ilé-ìkàwé ní Kirtland, Ohio, ní 1834, Wòlíì Joseph sọtẹ́lẹ̀, “Àwọn Oyèàlùfáà díẹ̀ ni ẹ rí nihin lalẹyi, ṣùgbọ́n Ìjọ yí yíò kún Àríwá àti Gúsù America—yíò kún gbogbo ayé.”15

Ni àwọn ọdún àìpẹ́ yi mo ti rin ìrìnàjò káàkiri ayé láti pàdé àwọn ọmọ Ìjọ. Àwọn arákùnrin mi nínú Iyejú àwọn Àpọstélì ti ní irú ìfúnni-níṣẹṣe kannáà. Síbẹ̀, ẹnití ó lè ní ìbámu pẹ̀lú iṣẹ́ wòlíì wa ọ̀wọ́n, Ààrẹ Nelson, ẹnití ìrìnàjò rẹ̀ ní ọdùn méjì àkọ́kọ́ bí Ààrẹ Ìjọ ti mú u lọ pàdé pẹ̀lú àwọn Ènìyàn Mímọ́ ní orílẹ̀-èdè méjìlélọ́gbọ̀n àti àwọn ààlà U.S.”16 láti jẹ́ ẹ̀rí Krístì alààyè.

Mo rántí ìgbàtí mo gba ìpè iṣẹ́ ìránṣẹ ìhìnrere mi bí ọ̀dọ́mọkùnrin kan. Mo fẹ́ Germany, bí i ti bàbá mi, aràkùnrin mi, àti ọkọ-arábìnrin mi, Láìdúró kí ẹnikẹ́ni délé, mo yára lọ síbi àpótí-ìwé mo sì ṣi ìpè náà. Mo kà pé a pè mí sí Àkórí Míṣọ̀n ìpínlẹ̀ Ìlà-oòrùn ní Ìlú New York. Ó jẹ́ ìjákulẹ̀, nítorínáà mo wọlé mo sì ṣí ìwé mímọ́ mi fún ìtùnú. Mo bẹ̀rẹ̀ sí ka Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú: “Ẹ kíyèsi, kí ẹ̀yin sì wòó, èmi ní àwọn ènìyàn pùpọ̀ ní ihin yìí, ní àwọn agbègbè yíká káàkiri; àti pé àwọn ilẹ̀kùn àìtàsé ni a ó ṣi sílẹ̀ ní àwọn agbègbè yíká káàkiri ìlà-oòrún.”17 Àṣọtẹ́lẹ̀ náà, tí a fún Wòlíì Joseph Smith ní 1833, ni ìfihàn sí mi. Mo mọ̀ nígbànáà pé mo ti gba ípè sí ibi iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere tí Olúwa fẹ́ kí nti sìn gan. Mo kọ́ Ìmúpadàbọ̀sípò àti ìbẹ̀rẹ̀ ìyára nígbàtí Bábá ní Ọ̀run sọ fún Josèh Smith tí ó wípé, “Èyí ni Àyànfẹ́ Ọmọ Mi. Gbọ́ Ọ!”18

Nípasẹ̀ pàtàkì nlá fún gbogbo Ìjọ ni àsọtẹ́lẹ̀ Ìsàíàh, ju ọgọ́ọ̀rún ọdún méje ṣíwájú ìbí Jésù Krístì : “Ó sì ṣe ní ọjọ́ ìkẹhìn, a ó fi òkè ilé Olúwa kalẹ̀ lórí àwọn òkè nlá, … gbogbo orílẹ̀ èdè ni yíò sì wọ inú rẹ̀ lọ.”19

Nínú mi loni, mo wòye àwọn míllíọ̀nù ọmọ ìjọ àti ọ̀rẹ́ tí wọ́n sopọ̀ mọ́ àwọn ìtẹ̀síwájú wọ̀nyí nípa ẹ̀rọ nípasẹ̀ amóhùnmáwòrán, ayélujára, tàbí ohun míràn. A joko bi pé a wà papọ̀ “ní orí òkè.”20 Brigham Young ẹnití ó sọ àwọn ọ̀rọ̀ ti wólíì náà “Èyí ni ibi náà.”21 Àwọn Ènìyàn Mímọ́, àwọn kan lára wọn jẹ́ olùlànà bàbánlá, ṣiṣẹ́ láti gbé Síónì kalẹ̀ ní àwọn Òkè Òkúta “nípasẹ̀ ifẹ́ àti ìnúdídùn òun ẹnití ó pàṣẹ àwọn orìlẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé.”22

Àwòrán
Tẹ́mpìlì Salt Lake nígbà àwọn Ìṣeré ní 2002

Mo dúró loni lórí ilẹ̀ mímọ́ tí ó ti mú àwọn míllíọ́nù àlejò wá. Ní 2002, Ilù Salt Lake gbàlejò àwọn Eré Òlímpìkì Ìgbà-òtútù. Akọrin Àgọ́ kọrin ní ìbẹ̀rẹ̀ ayẹyẹ ṣíṣí, Ìjọ sì kọrin ìfìmọ̀ṣọ̀kan àti ètò fún àwọn àjèjì àti olùkópa láti ọ̀pọ̀lọpọ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè. Èmi yíò máa rántí wíwo Tẹ́mpìlì ní ìsàlẹ̀ ti ìfúnkiri ìròhìn alaalẹ́ nígbàgbogbo.

Àwòrán
Àwọn olórí Ìjọ àti NAACP

Rékọjá àwọn ọdún, àwọn ààrẹ ti United States, àwọn ọba, àwọn adájọ́, àwọn olórí òjíṣẹ́, àwọn oníṣẹ ọba, àti óṣìṣẹ́ ìjọba láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀ ti wá sí Ìlú Salt Lake wọ́n sì pàdé pẹ̀lú àwọn olórí wa. Ààrẹ Nelson gbàlejò àwọn olórí Ẹgbẹ́ Orílẹ̀-èdè fún Ìlọsíwájú Aláwọ̀ Ènìyàn, ìṣètò kan tó nfẹsẹ̀ ẹ̀tọ́ kannáà múlẹ̀ láìsí ìyàsọ́tọ̀ lórí ẹ̀yà. Mo rántí dídúró ní ìgunpa-sí-ìgunpá pẹ̀lú àwọn olórí wọ̀nyí bí Ààrẹ Nelson ṣe darapọ̀ mọ́ wọn ní pípè fún ọ̀làjú gígajùlọ àti ìbàmu ẹ̀yà nínú ayé.23

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti wá sí Igun-mẹ́rin Tẹ́mpìlì wọ́n sì pàdé ní ìgbìmọ̀ pẹ̀lú àwọn olóri Ìjọ. Fún àpẹrẹ, ọdún tó kọjá yí, láti sọ díẹ̀, a gba Ìpàdé Àpapọ̀ ìkejìdínláàdọ́rin Ẹgbẹ́ Ọ̀làjú ti United States wọlé, àkójọpọ̀ gbogbo ayé, àti àkọ́kọ́ ti àwọn irú rẹ̀ níta Ilú New York. A ti pàdé Ìgbìmọ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ẹ̀sìn Vietnam, òjíṣẹ́ ọba láti Cuba, Philippines, Argentina, Romania, Sudan, Qatar, àti Saudi Arabia. Bákannáà a kí akọ̀wé gbogbogbò ti Ẹgbẹ́ Àgbáyé Mùsùlùmí káàbọ̀.

Ohun tí mò njúwe ni ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Ísáíàh pé ní ọjọ́ ìkẹhìn, àwọn orílẹ̀-èdè yíò ṣàn lọ sí “òkè ilé Olúwa.”24 Tẹ́mpìlì nlá Salt Lake dùrò ní gbùngbun ọlánlá àti ògo.

Àwòrán
Ìsọdọ̀tun Tẹ́mpìlì Salt Lake

Kìí ṣe ilẹ̀ tí a rí ni ó nfa ènìyàn wá, bíótilẹ̀jẹ́pé àgbékalẹ̀ wa lọ́lá; ó jẹ́ àkojá ẹ̀sìn mímọ́ tó hàn nínú ẹ̀mí, ìdàgbà, ìwàrere, àti oinúrere Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn àti àwọn ènìyàn rẹ̀; ìfẹ́ wa bí Ọlọ́run ṣe nifẹ àti ìfarasìn wa sí èrò gígajùlọ, ohun tí Joseph Smith pè ní, “èrò ti Krístì.”25

A kò mọ ìgbàtí Olùgbàlà yíò dé, ṣùgbọ́n èyí ni a mọ̀. A gbọ́dọ̀ múrasílẹ̀ ní ọkàn àti inú wa, ní yíyẹ láti gbà Á, àti ọ̀wọ̀ láti jẹ́ apákan ti gbogbo ohun tí a ti sọtẹ́lẹ̀ tipẹ́tipẹ́ sẹ́hìn.

Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Ààrẹ Russell M. Nelson ni wòlíì Olúwa ní ilẹ̀ ayé, àti ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ni àwọn Àpọ́stélì tí Ọlọ́run pè, tí a mú dúró bí àwọn wòlíì, aríran, àti olùfihàn. Àti sí, àwọn arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, Ìmúpadàbọ̀sípò ntẹ̀síwájú.

Mo parí pẹ̀lú àsọtẹ̀lẹ̀ Joseph Smith, àwọn ọ̀rọ̀ tí mo jẹ́ ẹ̀rí jẹ́ òtítọ́: “Kò sí ọwọ́ àìmọ́ tí ó lè dá iṣẹ́ dúró ní lilọsíwájú; inúnibíni lè jà, àgbájọ enìyànkénìyàn lè papọ̀, àwọn ọmọ-ogun lè kórajọ, olùṣátá lè borúkọjẹ́, ṣùgbọ́n òtítọ́ Ọlọ́run yíò lọ síwájú tìgboyàtìgboyà, tọlátọlá, ìgbáraléaraẹni, títí tí a fi wọnú gbogbo agbègbè, bẹ gbogbo ibi gíga wò, gbá gbogbo orílẹ̀-èdè, àti dún ní gbogbo ètí, títí tí gbogbo èrò Ọlọ́run a fi di mímúṣẹ, àti tí Jèhófàh Nlá yíò wípé iṣẹ́ ti parí.”26 Mo jẹ́ ẹ̀rí pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Joseph Smith wọ̀nyí nwá sí ìmúṣẹ.

Mo ṣèlérí pé bí ẹ ṣe ntẹ̀lé àmọ̀ràn ìmísí wòlíì wa ọ̀wọ́n, Ààrẹ Russell M. Nelson, àwọn olùdámọ̀ràn, àwọn Àpọ́stélì, àti àwọn olórí Ìjọ míràn, àti bí ẹ ṣe ngbọ́ ti àwọn wòlíì àtijọ́ tì wọn sọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ wa, ẹ ó gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, ìjìnlẹ̀ nínú ọkàn àti ẹ̀mí yín, pẹ̀lú ẹ̀mí àti iṣẹ́ Ìmúpadàbọ̀sípò. Mo ṣe ìlérí pè ẹ ó rí ọwọ́ Ọlọ́run nínú ayé yín, gbọ́ àwọn ìṣíniletí Rẹ̀, ati ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Rẹ̀. Ní orúkọ Jésù Krístì, pẹ̀lú ìmoore fún Ìmúpadabọ̀sípò ìhìnrere Rẹ̀ àti Ìjọ Rẹ̀, nínú ẹ̀rí ti ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ Rẹ̀, àmín.

Tẹ̀