Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ẹ wá sí ọ̀dọ̀ Krístì—Gbígbé bí Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2020


Ẹ wá sí ọ̀dọ̀ Krístì—Gbígbé bí Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn

A le ṣe àwọn ohun tí ó ṣòro kí a sì ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ṣe bákannáà, nítorípé a mọ ẹnití a le gbẹ́kẹ̀lé.

Ẹ ṣeun, Alàgbà Soares, fún ẹ̀rí yín alágbára àti ti wòlíì nípa Ìwé ti Mọ́mọ́ni. Ní àìpẹ́ yi, mo ní ànfàní àrà ọ̀tọ̀ láti mú ojú ewé kan ti ojúlówó Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ní ojú ewé yi gan, fún ìgbà àkọ́kọ́ ní àkókò ìríjú yi, àwọn ọ̀rọ̀ akíkanjú ti Néfì wọ̀nyí ni a kọsílẹ̀: “Èmi yíò lọ èmi ó sì ṣe àwọn ohun tí Olúwa ti pàṣẹ, nítorí èmi mọ̀ pé Olúwa kò fi àwọn àṣẹ kankan fún àwọn ọmọ ènìyàn, bíkòṣe pé òun yíò pèsè ọ̀nà kan fún wọn pé kí àwọn ó le ṣe ohun náà èyí tí òun pàṣẹ fún wọn yọrí.”1

Àwòrán
Ojúlówó ojú ewé àfọwọ́kọ Ìwé ti Mọ́mọ́nì

Bí mo ṣe mú ojú ewé yi lọ́wọ́, mo kún fún ìjìnlẹ̀ ìmoore fún àwọn aápọn Joseph Smith ẹni ọdún mẹ́tàlélógún, ẹnití ó yí ọ̀rọ̀ Ìwé ti Mọ́mọ́nì padà nípa “ẹ̀bùn àti agbára Ọlọ́run.”2 Bákannáà mo ní ìmọ̀lára ìmoore fún àwọn ọ̀rọ̀ Néfì tí ó jẹ́ ọ̀dọ́, ẹnití a sọ fún láti ṣe iṣẹ́ kan tí ó ṣòro púpọ̀ ní gbígba àwọn àwo idẹ láti Lábánì.

Néfì mọ̀ pé bí òun bá tẹ̀síwájú láti dúró ní fífojúsun Olúwa, òun yío yege ní síṣe ìmúṣẹ ohun tí Olúwa pàṣẹ fún un. Ó dúró ní fífojúsun Olùgbàlà jákèjádò ìgbé ayé rẹ̀ àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó jìyà àwọn àdánwò, àwọn ìpèníjà àfojúrí, àti ìwà ọ̀dàlẹ̀ ti díẹ̀ nínú àwọn ẹbí rẹ̀ gan.

Néfì mọ inú ẹnití òun le ní ìgbẹkẹ̀lé.3 Ní kété lẹ́hìn fífi ìyanu kígbe “Áà òtòṣì ènìyàn tí èmi jẹ́! Bẹ́ẹ̀ni, ọkàn mi banújẹ́ nítorí ẹran ara mi,”4 Néfì sọ pé, “Ọlọ́run mi ti jẹ́ alatilẹhin mi; ó ti tọ́ mi la àwọn ìpọ́njú mi já nínú ijù; ó sì ti pa mí mọ́ ní orí àwọn omi ibú nlá.”5

Bíi atẹ̀lé Krístì, àwọn ìpèníjà àti àdánwò kò yọ wá sílẹ̀ nínú ìgbé ayé wa. A máa nbèrè lọ́wọ́ wa nígbà púpọ̀ láti ṣe àwọn ohun tí ó ṣòro tí ó jẹ́ pé bí a bá dá nìkan gbìyànjú rẹ̀, yío jẹ́ bíbonimọ́lẹ̀ ó sì le jẹ́ àìṣeéṣe. Bí a ṣe ngba ìpè Olùgbàla láti “wá sí ọ̀dọ̀ mi,”6 Òun yío pèsè àtìlẹ́hìn, ìtùnú, àti àlàáfíà tí ó ṣe dandan, gẹ́gẹ́bí Ó ti ṣe fún Néfì àti Joseph. Àní nínú àwọn àdánwò wa tí ó jinlẹ̀ jùlọ, a le ní ìmọ̀lára ooru ìgbàmọ́ra ìfẹ́ Rẹ̀ bí a ti gbẹ́kẹ̀lé E tí a sì tẹ́wọ́gba ìfẹ́ Rẹ̀. A le ní ìrírí ayọ̀ tí a fi pamọ́ fún àwọn olõtọ́ ọmọ ẹ̀hìn Rẹ̀, nítorí “Krístì ni ayọ̀.“7

Ní 2014, nígbàtí mo nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní kíkún, ẹbí wa ní ìrírí àyípadà àìròtẹ́lẹ̀ kan ní ti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀. Bí a ṣe nrin ìrìnàjò sọ̀kalẹ̀ ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè ní orí bọ́ọ̀dù-gígùn kan, ọmọkùnrin wa kékeré jùlọ ṣubú ó sì ní ìfarapa híhalẹ̀ mọ́ ìgbé ayé sí ọpọlọ rẹ̀. Bí ipò rẹ̀ ti nbàjẹ́ síi, àwọn elétò ìlera sáré gbé e lọ sí ibi iṣẹ́ abẹ pàjáwìrì.

Ẹbí wa kúnlẹ̀ ní orí ilẹ̀ yàrá ilé ìwòsàn kan tí ó ṣófo, a sì tú ọkàn wa jáde sí Ọlọ́run. Ní ààrin àkókò ìdàrúdàpọ̀ àti ìrora yi, a kún wa pẹ̀lú ìfẹ́ àti àlàáfíà ti Baba wa Ọ̀run.

A kò mọ ohun tí ọjọ́ iwájú mú dání tàbí bóyá a ó tún rí ọmọkùnrin wa ní ààyè lẹ́ẹ̀kansíi. A mọ̀ ní kedere pé ayé rẹ̀ wà ní ọwọ́ Ọlọ́run àti pé àwọn àbájáde, làti ọ̀nà ojú inú ti ayérayé, yío ṣiṣẹ́ fún rere tirẹ̀ àti tiwa. Nípasẹ̀ ẹ̀bùn Ẹ̀mí, a ti múra tán ní kíkún láti gba èyíkéyi àbájáde.

Kò rọrùn rárá! Ìjanbá náà yọrí sí dídúró ní ilé ìwòsàn fún oṣù mẹ́jì nígbàtí a nṣe àkóso àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere ní kíkún tí wọ́n lé ní irinwó. Ọmọkùnrin wa ní ìrírí àìle rántí nkan mọ́ púpọ̀. Yíyá ara rẹ̀ ní àwọn àkókò àkànṣe ìtọ́jú nínú fún ọjọ́ pípẹ́ àti tí ó nira ti àfojúrí, ti ọ̀rọ̀ sísọ, àti ti iṣẹ́ síṣe Àwọn ìpèníjà sì wà síbẹ̀, ṣùgbọ́n bí àkójò ti nlọ a ti rí ìyanu kan.

A ní òye kedere pé kìí ṣe gbogbo àdánwò ti a bá dojúkọ ni yío ní àyọrísí tí a fẹ́. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, bí a ti dúró ní fífojúsun Krístì, a ó ní ìmọ̀lára àlàáfíà a ó sì rí àwọn ìyanu Ọlọ́run, ohunkóhun tí wọ́n le jẹ́, ní àkókò Rẹ̀ àti ní ọ̀nà Rẹ̀.

Àwọn àkókò kan yío wà nígbàtí a kò ní le rí ọ̀nà kankan pé ipò tí a wà yío parí dáradára, àti pé a tilẹ̀ le sọ, bíi Néfì, pé “Ọkàn mi banújẹ́ nítorí ẹran ara mi.”8 Àwọn àkókò kan le wà tí ó jẹ́ pé ìrètí kanṣoṣo tí a ní nínú Jésù Krístì. Irú ìbùkún wo ni ó jẹ́ láti ní ìrètí náà àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Rẹ̀. Krístì ni ẹní náà tí yío fi ìgbà gbogbo pa àwọn ilérí Rẹ̀ mọ́. Ìsinmi Rẹ̀ dánilojú fún gbogbo ẹnití ó wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.9

Àwọn olùdárí wa fi tọkàntọkàn fẹ́ fún ẹni gbogbo láti ní ìmọ̀lára àlàáfíà àti ìtùnú tí ó nwá nípasẹ̀ gbígbẹ́kẹ̀lé àti fífi ojú sun Olùgbàlà Jésù Krístì.

Wòlíì alààyè wa, Ààrẹ Russell M. Nelson, ti nsọ nípa ìran ti Olúwa fún gbogbo ayé àti fún àwọn ọmọ Ìjọ Krístì: “Ọrọ̀ wa sí aráyé jẹ́ rírọrùn àti òtítọ́: a pe gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run ní àwọn ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ti ìkele láti wá sí ọ̀dọ̀ Olùgbàlà wọn, kí wọn ó gba àwọn ìbùkún ti tẹ́mpìlì mímọ́, kí wọn ó ní ayọ̀ tí ó npẹ́ títí, kí wọn ó sì yege fún ìyè ayérayé.”10

Ìpè yí láti “wá sí ọ̀dọ̀ Krístì” ní àwọn ìtúmọ̀sí pàtó fún Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn.11 Bí ọmọ Ijọ ti Olùgbàlà, a ti dá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Rẹ̀ a sì ti di ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin bíbí Rẹ̀ níti ẹ̀mí.12 A ti fúnwa ní ànfàní bákannáà láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Olúwa ní pípe àwọn ẹlòmíràn láti wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

Bí a ti nṣe iṣẹ́ pẹ̀lú Krístì, ìjìnlẹ̀ àwọn àfojúsùn aápọn wa nílati wà ní ààrin àwọn ibùgbé ti ara wa. Àwọn àkókò kan yío wà nígbàtí àwọn mọlẹ́bí àti àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n súnmọni yío dojúkọ àwọn ìpèníjà. Àwọn ohùn ti aráyé, àti bóyá àwọn ìfẹ́ inú ti ara wọn, le mú wọn máa wádi òtítọ́. A nílati ṣe gbogbo ohun tí a bá le ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ ní ìmọ̀lára méjéèjì ìfẹ́ ti Olùgbàla àti ìfẹ́ tiwa. A rán mi létí ẹsẹ ìwé mímọ́ tí ó ti di orin wa ọ̀wọ́n “Ẹ Fẹ́ràn Ara Yín” tí ó kọwa pé, “Nípa èyí ni … àwọn ènìyàn yío mọ̀ … pé ọmọ ẹ̀hìn mi ni ẹ̀yín í ṣe, bí ẹ̀yín bá ní ìfẹ́ ẹnikan sí ẹlòmíràn.”13

Nínú ìfẹ́ wa fún àwọn wọnnì tí wọn nṣe ìwádi òtítọ́, ọ̀ta gbogbo ayọ̀ le gbìyànjú láti mú wa ní ìmọ̀lára pé a dalẹ̀ àwọn wọnnì tí a fẹ́ràn bí àwa fúnra wa bá tẹ̀síwájú láti máa gbé ìgbé ayé ìhìnrere ní kíkún tí a sì nkọ́ni ní àwọn òtítọ́ rẹ̀.

Agbára wa láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti wá sí ọ̀dọ̀ Krístì tábí padà sí ọ̀dọ̀ Krístì yío jẹ́ pípinnu púpọjù nípa àpẹrẹ tí a bá gbé kalẹ̀ nípasẹ̀ ìfọ̀kànsìn ti ara wa láti dúró ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú.

Bí ìfẹ́ inú wa ní tòótọ́ bá jẹ́ láti gba àwọn wọnnì tí a fẹ́ràn sílẹ̀, àwa fúnra wa gbọ́dọ̀ dúró ṣinṣin pẹ̀lú Krístì nípa gbígba Ijọ àti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere Rẹ̀ mọ́ra.

Ní pípadà sí ìtàn Néfì, a mọ̀ pé fífẹ́ Néfì láti ní ìgbẹkẹ̀lé nínú Olluwa wáyé nípa fífẹ́ ti àwọn òbí rẹ̀ láti ní ìgbẹkẹ̀lé nínú Oluwa àti àpẹrẹ wọn ní pípa májẹ́mú mọ́. A ṣe àpẹrẹ èyí ní ọ̀nà tí ó rẹwà nínú ìran ti Léhì nípa igi ìyè. Lẹ́hìn jíjẹ nínú èso dídùn àti aláyọ̀ ti igi náà, Léhì “gbé ojú [rẹ̀] yíká kiri, pé bóyá [òun] le rí ẹbí [rẹ̀].”14 Ó rí Sarià, Sámù, àti Néfì tí wọ́n dúró “bí ẹnipé wọn kò mọ́ ibi tí wọn yíò lọ.”15 Lẹ́hìnnáà Léhì sọ pé, “mo ju ọwọ́ sí wọn; mo sì wí fún wọn bákannáà pẹ̀lú ohùn rara pé kí wọn ó wá sí ọ̀dọ̀ mi, kí wọn ó sì jẹ nínú èso náà.”16 Ẹ jọ̀wọ́ ẹ kíyèsíi pé Léhì kò fi igi ìyè náà sílẹ̀. Ó dúró pẹ̀lú Olúwa nínú ẹ̀mí ó sì pe ẹbí rẹ̀ láti wá sí ibi tí òun wà láti jẹ nínú èso náà.

Ọ̀tá yío tan àwọn kan jẹ láti fi ayọ̀ ìhìnrere sílẹ̀ nípa yíya àwọn ìkọ́ni ti Krístì kúrò ní ara Ijọ Rẹ̀. Òun yío fẹ́ kí a gbàgbọ́ pé a le dúró ṣinṣin ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú fúnra ara wa, nípasẹ̀ ẹ̀sìn síṣe ti ara wa, ní òmìnira sí Ijọ Rẹ̀.

Ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn wọ̀nyí, a mú Ijọ ti Krístì padàbọ̀ sípò kí ó le ba ṣeéṣe láti ran àwọn ọmọ májẹmú ti Krístì lọ́wọ́ dúró sí ipa ọ̀nà majẹmú Rẹ̀.

Nínú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú a kà pé, “Kíyèsíi, èyí ni ẹ̀kọ́ mi—ẹnikẹ́ni tí ó bá ronúpiwàdà tí ó sì wá sí ọ̀dọ̀ mi, òun kannáà ni ìjọ mi.”17

Nípasẹ̀ Ìjọ ti Krístì, a ngba okun nípasẹ̀ àwọn ìrírí wa bíi àwùjọ Àwọn Ènìyàn Mímọ́. A ngbọ́ ohùn Rẹ̀ nípasẹ̀ àwọn wòlíì, àwọn aríran, àti àwọn olùfihàn Rẹ̀. Ní pàtàkì jùlọ, nípasẹ̀ Ijọ Rẹ̀ a pèsè gbogbo àwọn ìbùkún pàtàkì ti Ètùtù Krístì, tí a le rí nípasẹ̀ kíkopa nínú àwọn ìlànà mímọ́ nìkan.

Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn ni Ìjọ Olúwa ní órí ilẹ̀ ayé, tí a mú padàbọ̀ sípò ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn wọ̀nyí fún ànfààní àwọn ọmọ Ọlọ́run.

Mo jẹ́ ẹ̀rí pé bí a ti “wá sí ọ̀dọ̀ Krístì” tí a sì ngbé bíi Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn, a ó bùkún wa pẹ̀lú àfikún ìwọ̀n ìfẹ́ Rẹ̀, ayọ̀ Rẹ̀, àti àlàáfíà Rẹ̀. Bíi ti Néfì, a le ṣe àwọn ohun tí ó ṣòro a sì le ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ṣe bákannáà, nítorípé a mọ ẹnití a le gbẹ́kẹ̀lé.18 Krístì ni ìmọ́lè wa, ìyè wa, àti ìgbàlà wa.19 Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Tẹ̀