Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ó Nlọ Ṣíwájú Wa
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2020


Ó Nlọ Ṣíwájú Wa

Olúwa ndarí Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Rẹ̀ àti Ìjọ Rẹ̀. Ó mọ ọjọ́-ọ̀la ní pípé. Ó pè yín sí iṣẹ́ náà.

Ẹ̀yin àyànfẹ́ arákùnrin àti arábìnrin mi, mo ní ìmoore láti wà pẹ̀lú yin nínú ìpàdé àpapọ̀ ti Ìjọ ti Jésù Krístì tí Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn. Nínú ìfipè rẹ̀ láti ronú lórí ọ̀nà tí Ìmúpadàbọ̀sípò Olúwa nipa Ìjọ Rẹ̀ ní àkokò ìgbẹ̀hìn yí ti bùkún wa àti àwọn olólùfẹ́ wa, Ààrẹ Russell M. Nelson ṣèlérí pé ìrírí wa kò ní jẹ́ oniranti nìkan ṣùgbọ́n àìgbàgbé.

Ìrírí mi ti jẹ́ oniranti, bí ó ṣe dá mi lójú pé tiyín ṣe jẹ́. Bóyá yíò jẹ́ àìlegbàgbé dálórí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa. Ìyẹn ṣe kókó sí mi nítorí ìrírí oniránti ti mímúrasílẹ̀ fún ìpàdé àpapọ̀ yí ti yí mi padà ní ọ̀nà tí èmi fẹ́ kó pẹ́ títí. Ẹ jẹ́ kí nṣàlàyé.

Ìmúrasílẹ̀ mi mú mi lọ sí àkọsílẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ kan nínú Ìmúpadàbọ̀sípò. Mo ti kà nípa rẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà, ṣùgbọ́n ìgbàgbogbo ni ó jẹ́ àkọsílẹ̀ ìpàdé pàtàkì kan tí ó wà pẹ̀lú Joseph Smith sí mi, wòlíì Ìmúpadàbọ̀sípò. Ṣùgbọ́n ní àkokò yí mo rí nínú àkọsílẹ̀ bí Olúwa ṣe ndarí wa, àwa ọmọlẹ́hìn Rẹ̀, nínú Ìjọ Rẹ̀. Mo rí ohun tí ó túmọ̀ sí fún wa alára-ikú láti gba ìdarí látọ̀dọ̀ Olùgbàlà aráyé, aṣẹ̀dá—ẹnití ó mọ ohun gbogbo, tóti kọjá, lọ́wọ́lọ́wọ́, àti ọjọ́-ọ̀la. Ó nkọ́ wa lẹ́sẹ-ẹsẹ ó sì ntọ́wasọ́nà, láìmu nípá.

Ìpàdé tí èmi nṣe àpèjúwe jẹ́ ìgbà pàtàkì nínú Ìmúpadàsípò. Ó jẹ́ ìpàdé Ọjọ́-Ìsinmi kan tí a ṣe ní Ọjọ́ Kẹta Oṣù Kẹrin, 1836, ní Tẹ́mpìlì Kirtland ní Ohio, ọjọ́ keje lẹ́hìn tí a yàásímímọ́. Joseph Smith júwe ìgbà nlá yí nínú ìwé-ìtàn aráyé ní ọ̀nà ìrọ̀rùn kan. Ọ̀pọ̀ lára àkọsílẹ̀ rẹ̀ ní a kọ sínú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú ìpín 110:

Ní ọ̀sán, mo ran àwọn Ààrẹ míràn lọ́wọ́ ní pípín Oúnjẹalẹ́ Olúwa sí Ìjọ, mo gbà á látọwọ́ àwọn Méjìlá, àwọn ẹnití wọ́n ní ànfàní láti ṣiṣẹ́ lórí tábìlì mímọ́ loni yí. Lẹ́hìn ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn yí sí àwọn arákùnrin mi, mo padà sórí pẹpẹ, àwọn ìbòjú ṣí kúrò, mo sì tẹrí arami ba, pẹ̀lú Oliẹer Cowdery, nínú ọ̀wọ̀ àti àdúrà jẹ́jẹ́. Lẹ́hìn dídìde látinú àdúrà, ìran wọ̀nyí ṣí sí àwa méjèèjì.”1

“A mú ìbojú kúrò ní ọkàn wa, àwọn ojú àgbọ́yé wa sì ṣí.

“Àwa rí Olúwa ní dídúró sí orí ibi ìgbáralé ti àga ìwàásù náà; níwájú wa; ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ ní iṣẹ́ ọnà tí ó jẹ́ ti wúrà gidi, ní àwọ̀ tí ó dàbí ámbérì.

“Àwọn ojú rẹ̀ bí ọ̀wọ́ iná; irun orí rẹ̀ funfun bíi ìrì dídì tí kò ní èérí; ìwò ojú rẹ̀ tàn kọjá ìtànṣán oòrùn; àti ohùn rẹ̀ dàbíi ìró omi púpọ̀, àní ohùn ti Jèhófàh, ní wíwí pé:

“Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ikẹhìn; Èmi ni ẹni náà tí ó wà láàyè, èmi i alágbàwí yín pẹ̀lú Bàbá.

“Kíyèsíi, a dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín; ẹ jẹ́ aláìlèrí ní iwájú mi; nítorínáà, ẹ gbé orí yín sókè kí ẹ sì yọ̀.

“Ẹ jẹ́ kí ọkàn àwọn ìránṣẹ́ yín kí ó yọ̀, ẹ sì jẹ́kí ọkàn gbogbo àwọn ènìyàn mi kí ó yọ̀, àwọn tí, pẹ̀lú agbára wọn, wọ́n ti kọ́ ilé yìí ní orúkọ mi.

“Nítorí kíyèsíi, mo ti tẹ́wọ́ gba ilé yìí, orúkọ mi yíò sì wà níbẹ̀; èmi yíò si fi ara mi hàn sí àwọn ènìyàn mi nìnù àánú nìnù ilé yìí.

“Bẹ́ẹ̀ni, èmi yíò fi ara hàn sí àwọn ìránṣẹ́ mi, èmi ó sì bá wọn sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ohùn mi, bí àwọn ènìyàn mi yíò bá pa àwọn òfin mi mọ́, tí wọn kò sì sọ ilé mímọ́ yìí di àìmọ́.

“Bẹ́ẹ̀ni ọkàn ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ní àwọn ọ̀nà mẹ́wàá-mẹ́wàá ni yíò yọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ ní ìyọrísí ti àwọn ìbùkún èyítí a ó tú jáde, àti ẹ̀bùn náà èyìtí a ti bùn àwọn ìránṣẹ́ mi nínú ilé yìí.

“Òkìkí ilé yìí yíò dì tàn sí àwan ilẹ̀ míràn; èyí sì ni ìbẹ̀rẹ̀ ìbùkún èyítí a ó tú jáde sí orí àwọn ènìyàn mi. “Àní bẹ́ẹ̀ni. Àmín.

Lẹ́hìn tí ìran yìí parí, àwọn ọ̀run tún ṣí síwá lẹ́ẹ̀kansi; Mose sì fi ara hàn níwájú wa, ó sì fi àwọn kọ́kọ́rọ́ ti kíkójọ Ísráẹ́lì láti ìpín mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé fún wa, àti ṣíṣaájú àwọn ẹ̀yà mẹ́wàá láti ilẹ̀ àríwá.

“Lẹ́hìn èyí, Elíásì fi ara hàn, ó sì fi ìgbà ìhìnrere ti Abráhámù fúnni, ní wíwí pé nínù wa àti irú ọmọ wa ní gbogbo ìran lẹ́hìn wa ni yíò di ẹni ìbùkún.

“Lẹ́hìn tí ìran yìí ti parí, ìran míràn tí ó tóbi àti tí ó lógo tú jáde sí orí wa; nítorí wòlíì Èlíjàh, ẹnití a mú lọ sí ọ̀run láì tọ́ ikú wò, dúró ní iwájú wa, ó sì wìpè:

“Kíyèsíi, àkókò náà ti dé ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, èyítí a ti sọ láti ẹnu Málákì—ní jijẹri pé òun [Èlíjàh] ni a ó rán, síwájú kí ọjọ́ nlá tí ó sì ní ẹ̀rù ti Olúwa tó dé—

“Láti yí ọkàn àwọn sí àwọn ọmọ, àti ti awọn ọmọ sí àwọn bàbá, bíbẹ́ẹ̀kọ́ kí gbogbo ilẹ̀ má baà di kíkọlù pẹ̀lú ẹ̀gún—

“Nítorínáà, àwọn kọ́kọ́rọ́ ìgbà yí ni a a ti fi sí ọwọ́ yín; àti nípa èyí ni ẹ̀yin yíò lè mọ̀ pé ọjọ́ nlá tí ó sì ní ẹ̀rù ti Olúwa súnmọ́ itòsí, àní ní ẹnu àwọn ilẹ̀kùn.”2

Báyìí, mo ti ka àkọsílẹ̀ náà lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà. Ẹ̀mí Mímọ́ ti fi ẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ sí mi pé àkọsílẹ̀ jẹ́ òtítọ́. Ṣùgbọ́n bí mo ṣe ṣàṣàrò tí mo sì nmúrasílẹ̀ fún ìpàdé àpapọ̀ yí, mo wá láti mọ̀ agbára Olúwa kedere síi láti darí àwọn ọmọlẹ́hìn Rẹ̀ kíníkíní nínú iṣẹ́ Rẹ̀.

Ọdún méje lẹ́hìn tí Mósè fi àwọn kọ́kọ́rọ́ ìkójọ́ Ísráẹ́lì lé Joseph lọ́wọ́ ní Tẹ́mpìlì Kirtland, “Joseph kọ́ látinú àkọlé ojú ewé Ìwé ti Mọ́mọ́nì ìyẹn ni èrò rẹ̀ láti ‘fihàn sí àwọn yóku ti ilé Ísráẹ́lì … kí wọ́n lè mọ̀ àwọn májẹ̀mú Olúwa, pé a kò tà wọ́n nù láéláé.’ Ní 1831, Olúwa sọ fún Joseph pé ìkójọ Ísráẹ́lì yíò bẹ̀rẹ̀ ní Kirtland, ‘Àti látigbànáà ní [Kirtland], ẹnìkẹ́ni tí èmi bá fẹ́ yíò lọ ní àárín gbogbo orílẹ̀-èdè … nítorí a ó gba Isráẹ́lì là, èmi ó sì darí wọn.’”3

Bíótilẹ̀jẹ́pé iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere ni a nílò láti kó Ísráẹ́lì jọ, Olúwa kọ́ àwọn Méjìlá, tí wọ́n di àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere ìṣíwájú, “Ẹ rántí pé ẹ kò níláti lọ sí àwọn orílẹ̀ èdè míràn, títí ẹ ó fi gba ìrónilágbára.”4

Ó dàbí ẹnipé Tẹ́mpìlì Kirtland ṣe pàtàkì nínú ètò ipele-sí-pele Olúwa fún ó kéréju àwọn èrèdí méjì: Àkọ́kọ́, Mósè dúró títí tí tẹ́mpìlì fi parí láti mú àwọn kọ́kọ́rọ́ ti ìkójọ Ísráẹ́lì padàbọ̀sípò. Àti èkéjì, Ààrẹ Joseph Fielding Smith kọ́ni pé “Olúwa pàṣẹ fún àwọn Ènìyàn Mímọ́ láti kọ́ tẹ́mpìlì kan [Tẹ́mpìlì Kirtland] nínú èyítí òun lè fi àwọn kọ́kọ́rọ́ àṣẹ hàn àti ibití àwọn àpọ́stélì ti lè gba ìrónilágbára àti ìmúrasílẹ̀ láti tún ọgbà-àjàrà rẹ̀ ṣe fún ìgbà ìkẹhìn.”5 Bíótilẹ̀jẹ́pé a kò fúnni ní ìrónilágbára tẹ́mpìlì bí a ṣe mọ̀ ọ́ loni ninú Tẹ́mpìlì Kirtland, ní ìmúṣẹ ti àṣọtẹ́lẹ̀, mímúrasílẹ̀ àwọn ìlànà tẹ́mpìlì ni a bẹ̀rẹ̀ láti fihàn níbẹ̀, pẹ̀lú ìtújáde àwọn ìfihàn ti ẹ̀mí èyítí ó di àwọn wọnnì tí a pè sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ mú pẹ̀lú ìrónilágbára ìlérí ti “agbàra láti òkè”6 tí ó darí lọ sí ìkójọ nlá nípasẹ̀ iṣẹ́-ìsìn iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere.

Lẹ́hìn tí a ti fi àwọn kọ́kọ́rọ́ ìkọ́jọ ti Ísráẹ́lì lé Joseph lọ́wọ́, Olúwa mísí Wòlíì láti rán àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn Méjìlá jáde lórí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere.Joseph, Bí mo ṣe ṣàṣàrò, ó hàn kedere sí mi pé Olúwa ti múra ọ̀nà sílẹ̀ kíníkíní fún àwọn Méjìlá láti lọ fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere lokèèrè níbití a ti múra àwọn ènìyàn sílẹ̀ láti gbàgbọ́ àti láti mú wọn dúró. Ní àkokò, ẹgbẹẹgbẹ̀rún yíò, nípasẹ̀ wọn, wá sí Ìjọ ìmúpadàbọ̀sípò Olúwa.

Gẹ́gẹ bí àwọn àkọsílẹ̀ wa, o jẹ́ ìwọ̀n ní àárín ẹgbẹ̀rún àti ọgọ́ọ̀rún marun sí ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ tí wọ́n ṣe ìrìbọmi nígbà iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere méji ti àwọn Méjìlá sí Erékùṣù British. Èyí gbé i`pìlẹ̀ fún iṣẹ́ i`ránṣẹ́ ìhìnrere kalẹ̀ ní Europe. Ní òpin cẹ́ntúrì mọ́kàndínlógún, àwọn bí ẹgbẹ̀rún àádọ́ọ̀rún kan ti kórajọ sí Amẹ́ríkà pẹ̀lú púpọ̀jù lára àwọn wọ̀nyí láti Erékùṣù British àti Scandinavia.7 Olúwa ti mísí Joseph àti àwọn olódodo òjíṣẹ́ ìhìnrere wọnnì tí wọ́n lọ ṣiṣẹ́ láti ṣàṣeyege ìkórè kan tí ó gbọ́dọ̀ ti dàbíì pé, ó kọjá agbára wọn, ní ìgbà náà. Ṣùgbọ́n Olúwa, pẹ̀lú ìmọ̀tẹ́lẹ̀ pípé Rẹ̀ àti mímúrasílẹ̀, mu ṣeéṣe.

Ẹ rántí èdè eléwì ìrọrùn tí ó fẹ́rẹ̀ hàn gbangban látinú ìpín 110 ti Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú:

“Kíyèsíi, àkókò náà ti dé ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, èyítí a ti sọ láti ẹnu Málákì—ní jijẹri pé òun [Èlíjàh] ni a ó rán, síwájú kí ọjọ́ nlá tí ó sì ní ẹ̀rù ti Olúwa tó dé—

“Láti yí ọkàn àwọn sí àwọn ọmọ, àti ti awọn ọmọ sí àwọn bàbá, bíbẹ́ẹ̀kọ́ kí gbogbo ilẹ̀ má baà di kíkọlù pẹ̀lú ẹ̀gún—

“Nítorínáà, àwọn kọ́kọ́rọ́ ìgbà yí ni a a ti fi sí ọwọ́ yín; àti nípa èyí ni ẹ̀yin yíò lè mọ̀ pé ọjọ́ nlá tí ó sì ní ẹ̀rù ti Olúwa súnmọ́ itòsí, àní ní ẹnu àwọn ilẹ̀kùn.”8

Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Olúwa ríi jíjìnà lọ sí ọjọ́-ọ̀la àti bí Òun yíò ti darí wa láti ràn Án lọ́wọ́ ní ṣíṣe àṣeyege àwọn èrò Rẹ̀ ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn.

Nígbàtí mo nsìn ní Olùṣàkóso Bìṣọ́ọ́príkì ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́hìn, mo wà ní bíbojútó ṣíṣe àti ìdàgbàsókè ẹgbẹ́ tí ó dá ohun tí a pè ní ÌwákiriẸbí. Mo fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wí pé mo “ti rí” ìdásílẹ̀ rẹ̀ ju wíwí pé mo “darí” rẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọlọ́gbọ́ ènìyàn fi àwọn iṣẹ́ sílẹ̀ wọ́n sì wá láti kọ́ ohun tí Olúwa fẹ́.

Àjọ Ààrẹ Ìkínní ti gbe àfojúsùn ti dídín ṣíṣé àwọn ìlànà irúkannáà mejì kalẹ̀ kù. Kókó àníyàn wọn ni àìlè mọ̀ bóyá a ti ṣe àwọn ìlàna ẹnìkan tẹ́lẹ̀. Fún ọ̀pọ̀ ọdún—tàbi\ ohun tó dàbí ọ̀pọ̀ ọdún—Àjọ Ààrẹ Ìkínní bi mí léèrè, “Ìgbàwo ni ìwọ ó ṣeé?”

Pẹ̀lú àdúrà, ìtara, àti ìrúbọ araẹni ti àwọn alágbára nlá ènìyàn, iṣẹ́ náà di àṣeyọrí. Ó wá lẹ́sẹẹsẹ. Iṣẹ́ àkọ́kọ́ ni láti ṣe ÌwákiriẸbí lílo-ìbáṣọ̀rẹ́ fún àwọn wọnnì tí ayárabíàṣá kò tù wọn lára. Àwọn ìyípadà díẹ̀ dé, mo sì mọ pé wọn yíò tẹ̀síwájú, nítorí ibikíbi tí a bá ti bẹ̀rẹ̀ láti yanjú wàhálà ìmísí kan, a ṣí ilẹ̀kùn fún ìtẹ̀síwájú ìfihàn si fún àwọn ìgbéniga tí ó ṣe pàtàkì bákannáà ṣùgbọ́n tí a kò tíì rí. Àní ní òní, ÌwákiriẸbí ndi ohun tí Olúwa nílò fún apákan Ìmúpadàbọ̀sípò Rẹ̀—kìí sì ṣe yíyẹra fún ṣíṣe àwọn ìlànà irúkannáà méjì.

Olúwa jẹ́ kí a ṣe àwọn àtúnṣe láti ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti jèrè àwọn ìmọ̀lára mímọnìlára àní àti ìfẹ́ fún àwọn bàbánlá wọn àti láti parí àwọn ìlànà tẹ́mpìlì wọn. Báyìí, bí Olúwa ṣe mọ̀ dájúdájú pé yíò ṣẹlẹ̀, àwọn ọ̀dọ́ ndi olùtọ́ ayárabíàṣá fún àwọn òbí wọn àti àwọn ọmọ wọ́ọ̀dù. Gbogbo ènìyàn ti rì ayọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn yí.

Ẹ̀mí Èlíjàh nyí ọkàn àwọn ọ̀dọ́ àti àgbà, ọmọdé àti òbí, ọmọ-ọmọ àti òbí àgbà padà. Àwọn tẹ́mpìlì lẹ́ẹ̀kansi yíò ṣe ètò àwọn ànfàní ìrìbọmi láìpẹ́ àti àwọn ìlànà mímọ́ míràn. Ìfẹ́ láti sin àwọn bàbánlá wa àti rírẹ́pọ̀ àwọn òbí àti àwọn ọmọ ndàgbà si.

Olúwa ri pé gbogbo rẹ̀ nbọ̀. Ó ti ṣètò rẹ̀, lẹ́sẹẹsẹ, bí Ó ti ṣe pẹ̀lú àwọn ìyípadà míràn nínú Ìjọ Rẹ̀. Ó ti gbé sókè ó sì tì múra àwọn olódodo ènìyàn tí wọ́n yàn láti ṣe àwọn ohun líle bákannáà sílẹ̀. Ó máa nní sùúrù nígbàgbogbo láti ṣerànwọ́ fún wa láti kọ́ ẹ̀kọ́ “ìlà lórí ìlà, ìlànà lórí ìlànà, díẹ̀ nihin àti díẹ̀ lọhun.”9 Ó dúró gbọingbọin ní ṣiṣe àkokò àti títẹ̀lé àwọn ìgbìrò Rẹ̀, síbẹ̀síbẹ̀ Ó nmudájú pé ìrúbọ nígbàkugbà ni tàbí nmú ìbùkún kan tí a kò rí tẹ́lẹ̀ wá.

Mo parí nípa fífi ìmoore mi hàn sí Olúwa—Ẹni tí ó mísí Ààrẹ Nelson láti pè mí láti ṣe ìrúbọ làti múrasìlẹ̀ fún ìpàdé àpapọ̀ yí. Gbogbo wákàtí àti gbogbo àdúrà nígbà ìmúrasílẹ̀ mi mú ìbùkún kan wá.

Mo pe gbogbo ẹnití ó gbọ́ ọ̀rọ̀ yí tàbí ka àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí láti ní ìgbàgbọ́ pé Olúwa ndarí Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Rẹ̀ àti Ìjọ Rẹ̀. Ó Nlọ Ṣíwájú Wa. Ó mọ ọjọ́-ọ̀la ní pípé. Ó pè yín sí iṣẹ́ náà. Ó ndarapọ̀ mọ́ọ yín nínú rẹ̀. Ó ti ṣètò ibìkan fún iṣẹ́ ìsin yín. Àti pé bí ẹ ti nṣe ìrúbọ, ẹ ó ní ìmọ̀lára ayọ̀ bí ẹ ṣe nran àwọn míràn lọ́wọ́ láti dìde láti ṣetán fún bíbọ̀ Rẹ̀.

Mo jẹri sí yín pé Ọlọ́run Bàbá wa wà láàyè. Jésù ni Krístì. Èyí ni Ìjọ Rẹ̀. Ó mọ̀ Ó sì fẹ́ràn yín. Ó fẹ́ràn yín. Ó ti múrà ọ̀nà sílẹ̀ fún yín. Ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín

Tẹ̀