Jinlẹ̀ Nínú Ọkàn Wa
Olúwa ti ngbìyànjú láti ràn wá lọ́wọ́—gbogbo wa—mú ìhìnrere jinlẹ̀ si nínú ọkàn wa.
Ẹ̀yin arábìnrin àti arákùnrin, irú ìgbà ìyanu tí à ngbé nínú rẹ̀. Bí a ti nṣe ayẹyẹ ìbẹ̀rẹ̀ Ìmúpadàbọ̀sípò, ó yẹ bákannáà láti ṣe ayẹyẹ Ìmúpadàbọ̀sípò tí ó nlọ lọ́wọ́ tí a njẹ́ri rẹ̀. Mo yọ̀ pẹ̀lú yín láti má gbé ní àkókò yi.1 Olúwa tẹ̀síwájú láti máa fì ohun gbogbo sípò, nípasẹ̀ àwọn wolíì Rẹ̀, gbogbo ohun tí a nílò láti ràn wá lọ́wọ́ múrasílẹ̀ láti gba Á.2
Ọ̀kan nínú àwọn ohun tí a nílò wọnnì ni kíkọ́ni ní ìpilẹsẹ̀ tuntun fún Àwọn Ọmọdé àti Ọdọ́, Púpọ̀ yín ti ní ìfaramọ́ pẹ̀lú àtẹnumọ́ ti ètò yi lóri síṣe àgbékalẹ̀ ìfojúsùn, àwọn àmì tuntun ti jíjẹ́ ara ẹgbẹ́, àti àwọn ìpádé apapọ̀ ti Fún Agbára Àwọn Ọdọ́. Ṣùgbọ́n a kò gbọdọ̀ jẹ́kí àwọn wọ̀nyí bo ojú wa sí àwọn ìpìnlẹ̀ ẹ̀kọ́ tí a gbé ètò náà lé lórí àti èrò wọn: láti ṣe ìrànwọ́ mú ìhìnrere ti Jésù Krístì jìnlẹ̀ nínú ọkàn àwọn ọmọdé àti ọ̀dọ́ wa.3
Mo gbàgbọ́ pé bí a ti nní òye àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ wọ̀nyí síi, a ó rí èyí pé ó ju ètò kan fún àwọn ọmọ ijọ ẹni ọdún mẹ́jọ sí méjìdínlógún lọ. A ó ri bí Olúwa ti ngbìyànjú láti ràn wá lọ́wọ́—gbogbo wa—mú ìhìnrere jinlẹ̀ si nínú ọkàn wa. Mo gbàdúrà pé Ẹ̀mí Mímọ́ yío ràn wá lọ́wọ́ láti kọ́ ẹ̀kọ́ papọ̀.
Àwọn ìbáṣepọ̀—”Ẹ Wà pẹ̀lú Wọn”4
Ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ àkọ́kọ́ ni àwọn ìbáṣepọ̀. Nítorípé wọ́n jẹ́ apákan àdánidá ti Ìjọ Jésù Krístì , ní ìgbà míràn a ngbàgbé pàtàkì àwọn ìbáṣepọ̀ nínú ìrìnàjò padà wa sọ́dọ̀ Krístì tí ó nlọ lọ́wọ́. A ko retí wa lati wá tàbí láti rin ipa ọ̀nà májẹ̀mú ní ẹnìkanṣoṣo. A nílò ìfẹ́ àti àtìlẹ́hìn láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí, àwọn mọlẹ́bí míràn, àwọn ọ̀rẹ́, àti àwọn olùdarí tí wọ́n nrìn ní ipa ọ̀ná yi bákannáà.
Irú àwọn ìbáṣepọ̀ wọ̀nyí ngba àkókò. Àkókò lati wà papọ̀ Àkókò láti rẹrin, ṣeré, kọ́ ẹ̀kọ́, àti lati sìn papọ̀. Àkókò láti mọ iyì àwọn ohun tí olukúlùkù wa fẹ́ àti àwọn ìpèníjà. Àkókò láti ṣí ọkàn wa payá kí a sì jẹ́ olõtọ pẹ̀lú ara wa bí a ti ntiraka láti dára síi papọ̀. Àwọn ìbáṣepọ̀ wọ̀nyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn kókó èrò pípéjọ bíi àwọn ẹbí, àwọn ìyejú, àwọn kíláàsì, àti gbogbo ìjọ. Wọ́n jẹ́ ìpìlẹ̀ fún ṣíṣe ìṣẹ́ ìránṣẹ́ dáadáa.5
Alàgbà Dale G. Renlund fún wa ní kọ́kọ́rọ́ kan sí mímú àwọn ìbáṣepọ̀ wọ̀nyí dàgbà nígbàtí ó sọ pé: “Láti sin àwọn ẹlòmíràn dáradára a nílati rí wọn … nípasẹ̀ ojú ti Baba Ọrun. Nígbànáà nìkan ni a le bẹ̀rẹ̀ sí ní òye ìkàyẹ òtítọ́ ti ọkàn kan. Nígbànáà nìkan ni a le wòye ìfẹ́ ti Baba Ọrun ní fún gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀.”6
Rírí àwọn ẹlòmíràn bí Ọlọ́run ti ṣe jẹ́ ẹ̀bùn kan. Mo pe olukúlùkù wa láti wá ẹ̀bùn yi. Bí ojú wa ti jẹ́ lílà láti rí,7 a ó le ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ bákannáà láti rí ara wọn bí Ọlọ́run ti ṣe.8 Ààrẹ Henry B. Eyring tẹnumọ́ agbára èyí nígbàtí ó wípé: “Ohun tí yío já mọ́ nkan jùlọ ni ohun tí [àwọn míràn] bá kọ́ ní ara [yín] nípa ẹni tí wọ́n jẹ́ gãn àti ohun tí wọn le dà nítòótọ́. Èrò inú mi ni pé wọn kò le kọ́ ọ púpọ̀ tóbẹ́ẹ̀ láti inú àwọn ìkọ́ni ti ilé ìwé. Wọn yío kọ́ ọ láti inú àwọn ìmọ̀lára ẹni tí ẹ jẹ́, ẹni tí ẹ rò pé wọ́n jẹ́, àti ohun tí ẹ rò pé wọ́n le dà.”9 Ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti nímọ̀ irú ìdánimọ̀ àti èrò ni ọ̀kan lára àwọn ẹ̀bùn títóbijùlọ tí a lè fúnni.10 Wíwo àwọn ẹlòmíràn àti arawa bí Ọlọ́run ṣe nso ọkàn wa “papọ̀ nínú ìrẹ́pọ̀ àti nínú ìfẹ́.“11
Pẹ̀lú àwọn ipá ti ayé tí ó npọ̀sí ṣá tí ó sì nfà wá, a nílò okun tí ó nwá láti inú àwọn ìbáṣepọ̀ fífẹ́ni. Nítorínáà bí a ti ngbèrò àwọn ìṣeré, àwọn ìpàdé, àti àwọn ìpéjọpọ̀ miràn, ẹ jẹ́kí a rántí pé olúborí èrò kan fún àwọn ìpéjọpọ̀ wọ̀nyí ni láti ṣe àwọn ìbáṣepọ̀ ìfẹ́ni tí yío mú ìṣọ̀kan wá fún waàti láti ṣe ìrànwọ́ mú ìhìnrere Jésù Krístì jìnlẹ̀ síi nínú ọkàn wa.11
Ìfihàn, Agbára láti yàn, àti Ìrònúpìwàdà—”So Wọ́n Pọ̀ pẹ̀lú Ọrun”12
Nítòótọ́, kò tó láti kàn jẹ́ síso papọ̀ nikàn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹgbẹ́ àti àwọn àgbékalẹ̀ ni wọ́n wà tí wọ́n ní ìṣọ̀kan ní àyíká oríṣiríṣi àwọn nkan. Ṣùgbọ́n ìṣọ̀kan tí a nwá ni láti jẹ́ ọ̀kan nínú Krístì, láti so ara wa pẹ̀lú Rẹ̀.13 Láti so ọkàn wa pẹ̀lú ọ̀run, a nílò ìrírí ti ẹ̀mí ẹnìkọ̀ọ̀kan, bí Alàgbà Andersen ti ṣẹ̀ sọ̀rọ̀ dáadáa sí wa nípa rẹ̀.15 Àwọn ìrírí wọnnì nwá bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti ngbé àwọn ọ̀rọ̀ àti ìfẹ́ Ọlọ́run lọ sí inú àti ọkàn wa.16
Ìfihàn yí máa nwá sí ọ̀dọ̀ wa nípasẹ̀ àwọn ìwé mímọ́, nípàtàkì Ìwé ti Mọ́mọ́nì: nípasẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ onímisí láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì alààyè àti àwọn olõtọ́ ọmọẹ̀hìn míràn; àti nípasẹ̀ ohùn jẹ́ẹ́jẹ́, kékeré.16 Àwọn ọ̀rọ̀ wọnyí pọ̀ ju aró lórí ojú ewé kan, ìró dídún ní etí wa, tàbí àwọn èrò ní inú wa, tàbí ìmọ̀lára nínú ọkàn wa. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ agbára ti ẹ̀mí.17 Ó jẹ́ òtítọ́ àti ìmọ́lẹ̀.18 Ó jẹ́ bí a ti ngbọ́ Tirẹ̀! Ọ̀rọ̀ náà nbẹ̀rẹ̀ ó sì nmú ìgbàgbọ́ wa nínú Krístì pọ̀ síi àti pé ó nkoná mọ́ ìfẹ́ inú wa nínú wa láti dàbí Olùgbàlà síi—èyí ni, láti ronúpìwàdà kí a sì rin ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú.19
Ní Oṣù Kẹrin tí ó kọjá, Ààrẹ Russell M. Nelson ràn wá lọ́wọ́ láti ní òye kókó ojúṣe ìrònúpìwàdà nínú ìrìnàjò onífihàn yí.21 Ó wípé: “Nígbàtí a bá yàn láti ronúpìwàdà, a yàn láti yípadà! A nfi àyè gba Olùgbàlà láti yí wa padà sí ẹ̀dà dídára jùlọ ti ara wa. … A yàn láti dàbí Jésù Krístì síi!”20 Ìlànà ìyípadà yí, tí a koná mọ́ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ni bí a ṣe sopọ̀ pẹ̀lú ọ̀run.
Ìfipè ti Ààrẹ Nelson lábẹ́ láti ronúpìwàdà ni ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ agbára láti yàn. A gbọ́dọ̀ yàn ìrònúpìwàdà fún arawa. A kò lè fi ipá mú ìhìnrere sínú ọkàn wa. Bí Alàgbà Renlund ti sọ pé, “Àfojúsùn ti Baba wa Ọrun ní síṣe òbí kìí ṣe láti mú àwọn ọmọ Rẹ̀ ṣe ohun tí ó tọ́; ó jẹ́ láti mú àwọn ọmọ Rẹ̀ yàn láti ṣe ohun tí ó tọ́.”21
Nínú àwọn ètò tí a rọpò pẹ̀lú ètò Àwọn Ọmọde àti Àwọn Ọ̀dọ́, ó lé ní ọgọ́rũn márũn oríṣiríṣi àwọn ohun tí a nílò láti párí kí a ba le gba onirúurú àwọn àmì ẹ̀yẹ.22 Lóni, ẹyọkan ni ó wà tí ó ṣe kókó. Ó jẹ́ ìfipè kan láti yàn láti dàbí Olùgbàlà si. À nṣe èyí nípa gbígba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ àti fífàyè gba Krístì láti yí wa padà sínú ẹ̀yà ararwa dídárajùlọ.
Èyí pọ̀ jìnná ju iṣẹ́ ìdárayá kan ní síṣe àgbékalẹ̀ àfojúsùn tàbí ìmú ara ẹni gbèrú síi. Àfojúsùn kàn jẹ́ ohun èlò kan láti sopọ̀ pẹ̀lú ọ̀run nípasẹ̀ ìfihàn, agbára láti yàn, àti ìrònúpìwàdà—láti wá sí ọ̀dọ̀ Krístì kí a sì gba ìhìnrere Rẹ̀ jìnlẹ̀ síi nínú ọkàn wa.
Kíkópa àti Ìrúbọ—”Ẹ Jẹ́kí Wọn ó Ṣíwájú”24
N ìparí, láti mú ìhìnrere ti Jésù Krístì jinlẹ̀ nínú ọkàn wa a nílò láti kópa nínú rẹ̀—láti fi àkókò wa jìn àti àwọn tálẹ́ntì wa sí i, láti ṣe irúbọ fún un.25 Gbogbo wa fẹ́ láti gbé ìgbé ayé tí ó ní ìtumọ̀, èyí sì rí bẹ́ẹ̀ ní pàtàkì fún àwọn ìran tí ndìde. Wọ́n fẹ́ ìdí kan.
Ìhìnrere ti Jésu Krístì ni ìdí tí ó tóbi jùlọ nínú ayé. Ààrẹ Ezra Taft Benson sọ pé: “A pàṣẹ fúnwa láti ọwọ́ Ọlọ́run láti mú ìhìnrere yi lọ sí gbogbo ayé. Èyí ni iṣẹ́ tí ó gbọdọ̀ so wá pọ̀ lóni. Ìhìnrere nìkan ní yío gba ayé là kúrò lọ́wọ wàhálà ti ìparun ara ẹni tirẹ̀. Ìhìnrere nìkan ni yío so àwọn ọkùnrin [ati àwọn obìnrin] ti gbogbo àwọn ẹ̀yà àti àwọn orílẹ̀ èdè pọ̀ nínú àlàáfíà. Ìhìnrere nìkan ni yío mú ayọ̀, ìdùnnú, àti ìgbàlà wá fún ẹbí ẹ̀dá ènìyàn.”26
Alàgbà David A. Bednar ṣèlérí, “Bí a tí nró àwọn ọ̀dọ́ ní agbára nípa pípè wọ́n àti gbígbà wọ́n ní ààyè láti ṣe iṣẹ́, Ìjọ yío tẹ̀síwájú ní àwọn ọ̀nà ìyanu.”27 Ní ìgbà púpọ̀jù ni a kò ti pè kí a sì fún àwọn ọ̀dọ́ ní ààyè láti ṣe ìrúbọ fún iṣẹ́ nlá ti Krístì yí. Alàgbà Neal A. Maxwell wòye pé, “Bí àwọn ọ̀dọ́ [wa] kò bá kópa tó [níbi iṣẹ́ Ọlọ́run], ó ṣeéṣe kí ayé borí wọn.”23
Ètò àwọn ọmọdé àti ọ̀dọ́ náà dá lé orí ríró àwọn ọ̀dọ́ ní agbára. Wọ́n nyan àwọn àfojúsùn tiwọn. Àwọn àjọ ààrẹ ti iyejú àti kíláàsì ní a fi sí ipò wọn dáradára. Ìgbìmọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ní wọ́ọ̀dù, gẹ́gẹ́bi ìgbìmọ̀ wọ́ọ̀dù, dá lórí iṣẹ́ ìgbàlà àti ìgbéga.29 Àwọn ìyejú àti àwọn kíláàsì bẹ̀rẹ̀ àwọn ìpàdé wọn nípa gbígba ìmọ̀ràn nípa bí wọn ó ti ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run ti fifún wọn.30
Ààrẹ Nelson wí fún àwọn ọ̀dọ́ inú Ijọ pé: “Bí ẹ bá yàn láti ṣe bẹ́ẹ̀, bí ẹ bá fẹ́, … ẹ le jẹ́ apákan títóbi ohun títóbi kan, ohun nlá kan, ohun tí ó ní ọlá! … Ẹ wà ní ààrin àwọn tí ó dára jùlọ tí Oluwa ti rán wá sí ayé rí . Ẹ ní agbára láti jáfáfá síi àti kí ẹ gbọ́n síi kí ẹ sì ní ipa lórí ayé ju èyíkéyi ìran àtẹ̀hìnwá lọ!”31 Ní àkókò míràn, Ààrẹ Nelson sọ fún àwọn ọ̀dọ́ pé: “Mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé pátápátá nínú yín. Mo fẹ́ràn yín, bẹ́ẹ̀ sì ni Olúwa náà. A jẹ́ ènìyàn Rẹ̀, a nkópa papọ̀ nínú iṣẹ́ mímọ́ Rẹ̀.”32 Ẹ̀yin ọ̀dọ́, njẹ́ ẹ le ní ìmọ̀lára ìgbẹ́kẹ̀le tí Ààrẹ Nelson ní nínú yín àti bí ẹ ti ṣe pàtàkì sí iṣẹ́ yí tó?
Ẹ̀yin òbí àti àgbà olùdarí, mo pè yín láti rí àwọn ọ̀dọ́ bí Ààrẹ Nelson ti ṣe. Bí àwọn ọ̀dọ́ ti nní ìmọ̀lára ìfẹ́ àti ìgbẹkẹ̀lé yín, bí ẹ ti ngbà wọ́n níyànjú tí ẹ sì nkọ́ wọn bí wọn ó ti darí—àti nígbànáà tí ẹ kúrò ní ọ̀nà wọn—wọn yío yà yín lẹ́nu pẹ̀lú àwọn òye wọn, àwọn agbára wọn, àti ìfọkànsìn wọn sí ìhìnrere.33 Wọn yío ní ìmọ̀lára ayọ̀ ti yíyàn láti kópa nínú àti láti ṣe ìrúbọ fún iṣẹ́ nlá yí. Ìhìnrere yío lọ jinlẹ̀ síi sínú ọkàn wọn, iṣẹ́ náà yío sì tẹ̀síwájú ní àwọn ọ̀nà yíyanilẹ́nu.
Ìlérí àti ẹ̀rí
Mo ṣèlérí pé, bí a ti nfojúsùn sí orí àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ wọ̀nyí—àwọn ìbáṣepọ̀, ìfihàn, agbára láti yàn, ìrònúpìwàdà, àti síṣe ìrúbọ fún iṣẹ́ nlá yi—ìhìnrere Jésù Krístì yío wọlé jinlẹ̀ síi ní gbogbo ọkàn wa. A ó rí I`múpadàbọ̀sípò tó ntẹ̀síwájú sí èrò rẹ̀ gíga jùlọ, ìràpadà Israẹlì àti ìgbékalẹ̀ Síonì,35 níbití Krístì yíò jọba bí Ọba a`wọn Ọba.
Mo jẹ́ri pé Ọlọ́run tẹ̀síwájú lati máa ṣe gbogbo àwọn ohun tí ó ṣe dandan láti pèsè àwọn ènìyàn Rẹ̀ sílẹ̀ fún ọjọ́ náà. Njẹ́ kí a le rí ọwọ́ Rẹ̀ nínú iṣẹ́ ológo yi bí gbogbo wa ti ntiraka láti “wá sí ọ́dọ̀ Krístì, kí a sì di pípé nínú rẹ̀.”34 Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.