Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2020


Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀

A níláti wákiri, ní gbogbo ọ̀nà tí a lè, láti gbọ́ ti Jésù Krístì, ẹnití ó nbá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ agbára àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́.

Ẹ̀yin àyànfẹ́ arákùnrin àti arábìnrin mi, bí a ṣe kíi yín káàbọ̀ sí ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò onítàn Oṣù Kẹ́rin 2020 ti Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, fún àwọn èrèdí tí ẹ mọ̀, mo dúró níwájú pẹ́pẹ́ tó ṣófo!

Díẹ̀ ni mo mọ̀, nígbàtí mo ṣèlérí fún yín ní ìpàdé àpapọ gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2019 pé ìpàdé àpapọ gbogbogbò Oṣù Kẹrin yíò jẹ́ “olùrántí” àti “àìlègbàgbé,” pé sísọ̀rọ̀ sí àwọn ènìyàn díẹ̀ bíi mẹwa yíò mú ìpàdé àpàpọ̀ yí ní ìránti àti àìgbàgbé gidi fún mi! Síbẹ̀síbẹ̀ ní ìmọ̀ pé ẹ̀ nkópa nípasẹ̀ ẹ̀rọ àgbéléwò, àti orin aládùn látẹnu akọrin “Ó Dára pẹ̀lú Ọkàn Mi,” mú ìtùnú nlá sí ọkàn mi .

Bí ẹ ti mọ̀, wíwà ní ìpàdé àpapọ gbogbogbò yí ní a ti dẹ́kun gidi bí ara ìtitraka wa láti jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè gbogbogbò rere àti láti ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti dẹ́kun ìtànkiri COVID-19. Ààrùn yí ti ní kókó ipa ní gbogbo àgbáyé. Ó sì ti dá àwọn ìpàdé Ìjọ dúró fún ìgbà díẹ̀, iṣẹ́ ìsìn iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere, àti iṣẹ́ tẹ́mpìlì bákannáà fún i`gbà díẹ̀.

Bíótilẹ̀jẹ́pé ìdènà òní bá àjàkálẹ̀ ààrùn kan mu, àwọn àdánwò ìgbé ayé araẹni nà kọjá rúdurùdu yí. Àwọn àdánwò ọjọ́ ọ̀la lè wá látinú ìjàmbá kan, àjálù àdánidá kan, tàbí ìroraọkàn àìròtẹ́lẹ̀ ti araẹni kan.

Báwo ni a ṣe lè farada irú àdánwò bẹ́ẹ̀? Olúwa ti wí fún wa pé ”Bí a bá múrasílẹ̀ a kò ní bẹ̀rù.”1 Bẹ́ẹ̀ni, a lè ṣe ìpamọ́ ilé-ìṣura oúnjẹ ara wa, omi, àti ìfowópamọ́. Ṣugbọ́n ní pàtàkì bẹ́ẹ̀náà ni ìnílò wa láti kún ilé-ìṣura spiritual arawa pẹ̀lú ìgbàgbọ́, òtítọ́, àti ẹ̀rí.

Ìgbìrò ìkẹhìn wa nínú ayé ni láti múrasílẹ̀ láti pàdé Aṣẹ̀dá wa. À nṣe èyí nípa títiraka lójoojúmọ́ láti dàbí Olùgbàlà wa, Jésù Krístì si.2 A sì nṣe bẹ́ẹ̀ bí a ṣe nronúpìwàdà lojoojúmọ́ tí a sì ngba ìwẹ̀nùmọ́ Rẹ̀, ìwòsàn, àti agbára ìfúnni lókun. Nìgbànáà a lè nímọ̀lára fífaradà àláfíà àti ayọ̀, àní ní àwọn ìgbà líle. Èyí ni ìdí náà gan tí Olúwa fi rọ̀ wá láti dúró níbi mímọ́ kí a má sì “mi ara.”3

Ọdún yi, ṣayẹyẹ àjọ̀dún igba ọdún ti ọ̀kan lárá àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ to ṣe pàtàkì jùlọ nínú ìwe-ìtàn ayé—tí a dárúkọ, wíwá Ọlọ́run Bàbá àti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, sí Joseph Smith. Ní ìgbà ìràn kanṣoṣo náà, Ọlọ́run Bàbá nawọ́ sí Jésù Krístì ó wípé: “Èyí ni Àyànfẹ́ Ọmọ Mi. Gbọ́ ti Rẹ̀!”8

Ìkìlọ náà tí a fún Joseph wà fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa. A níláti wákiri, ní gbogbo ọ̀nà tí a lè, láti gbọ́ ti Jésù Krístì, ẹnití ó nbá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ agbára àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́.

Èrò èyí àti gbogbo ìpàdé àpapọ gbogbogbò ni láti ṣèrànwọ́ fún wa láti gbọ́ ti Rẹ̀. A ti gbàdúrà, a sì pè yín láti gbàdúrà, pé kí Ẹ̀mí Olúwa ó wà pẹ̀lú wa ní irú ọ̀pọ̀ ọrọ̀ tí ẹ lè gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ náà tí Olùgbàlà ní fún yín nípàtàkì—àwọn ọ̀rọ̀ tí yíò mú àláfíà wá sí ọkàn yín. Àwọn Ọ̀rọ̀ tí yíò wo ọkàn yín sàn. Àwọn ọ̀rọ̀ tí yíò tànmọ́lẹ̀ sínú yín. Àwọn ọ̀rọ̀ tí yíò ràn yìn lọ́wọ́ láti mọ ohun láti ṣe bí ẹ ṣe nlọ síwájú àwọn ìgbà ewu àti àdánwò.

A gbàdúrà pé ìpàdé àpapọ̀ yí yíò jẹ́ oniranti àti àìlègbàgbé nítorí ti àwọn ọ̀rọ̀ tí ẹ ó gbọ́, àwọn ìpolongo àràọ̀tọ̀ èyí tí a ó ṣe, àti àwọn ìrírí nínú èyí tí a ó pè yín láti kópa.

Fún àpẹrẹ, ní ìparí abala òwúrọ̀ Ọjọ́ Ísinmi, a ó ṣe àkójọpọ̀ ọ̀wọ̀ ní gbogbo ayé nígbàtí èmi ó darí yín ní Igbe Hòsánnà mímọ́. A gbàdúrà pé èyí yíò jẹ́ ìfihàn ti ẹ̀mí fún yín bí a ṣe nfi ìmoore tó jinlẹ̀ han ní àpapọ̀ gbogbogbò sí Ọlọ́run àti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀ nípa yíyìn Wọ́n ní ọ̀nà tóyàtọ̀ yí.

Fún ìrírí mímọ́ yí, a lo aṣọ ìnujú mímọ́ funfun. Ṣùgbọ́n bí ẹ kò bá ní ọ̀kan, ẹ kàn lè ju ọwọ́ yín. Ní ìparí Igbe Hòsánnà náà, gbogbo ìjọ yíò darapọ̀ mọ́ akọrin ní kíkọ “Ẹ̀mí ti Ọlọ́run.”5

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi, ìpàdé àpapọ̀ yí yíò lọ́lá. Ọdún yí yíò jẹ́ àìrírí bí a ṣe ndojúkọ Olùgbàlà típẹ́típẹ́ àti ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Rẹ̀. Àbájáde pípẹ́ pàtàkì jùlọ ti ìpàdé àpapọ̀ onítàn yí yíò jẹ́ ìyípadà ọkàn wa a ó sì bẹ̀rẹ̀ èrò ìgbé ayé pípẹ́ láti gbọ́ ti Rẹ̀.

Ẹ káàbọ̀ sí ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2020! Mo mọ̀ pé Ọlọ́run, Bàbá wa Ọ̀run, àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, nbojú tó wa. Wọn yíò wà pẹ̀lú wa nínú gbogbo àwọn ìtẹ̀síwájú ti ọjọ́ ológo méjì wọ̀nyí bí a ti nwá láti súnmọ́ Wọn si kí a sì bọ̀wọ̀ fún Wọn. Ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín