Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
(Igbe Hòsánnà)
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2020


Igbe Hòsánnà

Báyìí, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, bí a ṣe nṣe ayẹyẹ Ìran Àkọ́kọ́ Joseph Smith ti Bàbá àti Ọmọ, a nímọ̀lára pé yíò bamu tí a bá lè yayọ̀ papọ̀ nípa kíkópa nínú Igbe Hòsánnà.

Igbe mímọ́ yí ni a kọ́kọ́ fúnni ní àkokò yí ní ìyàsímímọ́ Tẹ́mpìlì Kirtland ní Ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n Oṣù Kẹta, 1836. A nfúnni báyìí ní ìyàsímímọ́ tẹ́mpìlì kọ̀ọ̀kan. Ó jẹ́ oríyìn sí Bàbá àti Ọmọ, ní àmì ìwà àwọn ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn nígbàtí Olùgbàlà ṣe ìwọlé ìṣẹ́gun Rẹ̀ sí Jérúsálẹ́mù. Bákannáà ó tun ìrírí Joseph sọ ní ọjọ́ náà nínú Igbó Mìmọ́—lórúkọ, pé Bàbá àti Ọmọ jẹ́ awọn Ológo Ènìyàn méjì tí a njọ́sìn tí a sì nyìn.

Báyìí èmi ó júwe bí a ṣe nfúnni ní Igbe Hòsánnà. Bí mo ti ṣe, mo pe àwọn ẹlẹgbẹ́ mi nínú ìwé ìròhìn láti ṣe àkíyèsí mímọ́ yí pẹ̀lú iyì àti ọ̀wọ̀ gidi.

Ẹnìkọ̀ọ̀kan tó nkópa mú ìnujú mímọ́ funfun kan, dìímú ní igun kan, jùú nígbàtí a ó sọ ní àpapọ̀, “Hòsánnà, Hòsánnà, Hòsánnà sí Ọlọ́run àti Ọ̀dọ́-àgùtàn,“ léraléra nígbà mẹ́ta, “Àmín, Àmín, àti Àmín“ yíò tẹ̀le. Bí ẹ kò bá ní ìnujú funfun, ẹ kàn lè ju ọwọ́ yín.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, mo pè yín báyìí láti dùró àti láti kópa nínú Igbe Hòsánnà, títẹ̀lé èyí tí a ó kọ orin ìyìn Hòsánnà a ó sì kọ ”1 Ẹ̀mí Ọlọ́run.

Lórí àmì kan látọwọ́ olùdarí, jọ̀wọ́ darapọ̀ ní kíkọrin “Ẹ̀mí ti Ọlọ́run.“

Ẹ ké hosanna, sí Ọlọ́run àti Ọdọ́-àgùtàn náà

Hòsánnà, Hòsánnà, Hòsánnà sí Ọlọ́run àti Ọ̀dọ́-àgùtàn.

Hòsánnà, Hòsánnà, Hòsánnà sí Ọlọ́run àti Ọ̀dọ́-àgùtàn.

Àmín, Àmín, àti Àmín.

Àkọsílẹ̀ Ránpẹ́

  1. Àwọn orin,no. 166.