Bí Oyè Àlùfáà ti Nbùkún Ọ̀dọ́
Nípasẹ̀ oyèàlùfáà, a lè ní ìgbéga. Oyèàlùfáà nmú ìmọ́lẹ̀ wá sínú ayé wa.
Mo fìmoore hàn láti wà nihin. Nígbàtí mo kọ́kọ́ ri pé èmi yíò ní ànfàní láti bá yín sọ̀rọ̀ loni, mo ní ìmọ̀lára inúdídùn gidi ṣùgbọ́n ní àkokò kannáà nínú ìrẹ̀lẹ̀ gidi. Mo ti lo ọ̀pọ̀ ìgbà ríronú nípa ohun tí mo lè ṣe àbápín, mo sì nírètí pé Ẹ̀mí nsọ̀rọ̀ síi yín tààrà nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ mi.
Nínú Ìwé Mọ́mọ́nì, Léhì fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ kọ̀ọ̀kan ní ìbùkún kí ó tó kú tí ó rànwọ́nlọ́wọ́ láti rí okun wọn àti agbára ayérayé. Èmi ni ó kéréjùlọ nínú àwọn ọmọ mẹ́jọ, àti pé ní ọdún tó kọjá yí mo ti jẹ́ ọmọkanṣoṣo tó wà nílé fún ìgbà àkọ́kọ́. Àìní àwọn ẹ̀gbọ́n mi nítòsí tàbí níní ẹníkan láti bá sọ̀rọ̀ ti jẹ́ ìṣòro fún mi. Àwọn àṣálẹ́ wà nígbàtí mo ti ní ìmọ̀lára àdáwà gidi. Mo fìmoore hàn fún àwọn òbí mi, tí wọ́n gbìyànjú ipá wọn láti ràn mi lọ́wọ́. Àpẹrẹ èyí kan ni ìgbàtí bàbá mi gbà láti fún mi ní ìbùkún oyèàlùfáà ti ìtùnú nínú ìgbà ìpènijà kan pàtó. Lẹ́hìn ìbùkún rẹ̀, àwọn nkan kò yípadà lọ́gán, ṣùgbọ́n mo ní ìmọ̀lára àláfíà àti ìfẹ́ látọ̀dọ̀ Bàbá Ọ̀run àti látọ̀dọ̀ bàbá mi. Mo nímọ̀lára ìbùkún láti ní bàbá yíyẹ tí ó lè pèsè àwọn ìbùkún oyèàlùfáà nígbàkugbà tí mo bá nílò wọn tí ó sì nrànmílọ́wọ́ láti rí okun mi àti agbára ayérayé, gẹ́gẹ́bí Léhì bí ti ṣe nígbàtí ó bùkún àwọn ọmọ rẹ̀.
Ní àìka àwọn ipò yín sí, ẹ lè ní ààyè sí àwọn ìbùkún oyèàlùfáà nígbàgbogbo. Nípasẹ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí, ọ̀rẹ́, òjíṣẹ́ ìránṣẹ́ arákùnrin, olórí oyèàlùfáà, àti Bàbá Ọ̀run kan tí kò ní mú yín kùnà láéláé, ẹ lè gba àwọn ìbùkún ti oyèàlùfáà. Alàgbà Neil L. Andersen wípé: “Àwọn ìbùkún oyèàlùfáà dájúdájú tóbiju ẹnìkan tí a ní kí ó fún ni ní ẹ̀bùn náà. … Bí a ṣe wà ní yìyẹ, àwọn ìlànà oyèàlùfáà yíò fọrọ̀ sí ayé wa.”1
Ẹ máṣè lọ́ra láti bèèrè fún ìbùkún nígbàtí ẹ bá nílò ìtọ́nisọ́nà síi. Àkokò ìṣòro wa ni a nílò Ẹ̀mí láti rànwálọ́wọ́ jùlọ. Kò sí ẹni tó pé, àti wípé gbogbo wa ni a nní ìrírí líle. Àwọn díẹ̀ lára wa lè jìya pẹ̀lú àníyàn, ìrẹ̀wẹ̀sì, bámbákú, tàbí pẹ̀lú àwọn ìmọ̀ara tí kò tó. Àwọn ìbùkún oyèàlùfáà lè rànwálọ́wọ́ láti borí àwọọn ìpèníjà wọ̀nyí àti láti gba àláfíà bí a ṣe nrìn síwájú ọjọ́ ọ̀la. Mo nírètí pé a o tiraka láti gbé ìgbé ayé yíyẹ ti gbígba àwọn ìbùkún wọ̀nyí.
Ọ̀nà míràn tí oyèàlùfáà fi nbùkún wa ni nípasẹ̀ àwọn ìbùkún ti bàbánlá. Mo ti kọ́ láti yípadà sí ìbùkún bàbánlá nígbàkugbà tí mo bá banujẹ́ tàbi dáwà. Ìbùkún mi ràn mí lọ́wọ́ láti rí agbára mi àti kókó ètò tí Ọlọ́run ní fún mi. Ó ntù mí nínú ó sì nràn mi lọ́wọ́ láti rí kọjá ìrò ti ayé mi. Ó rán mi létí nípa àwọn ẹ̀bùn mi àti àwọn ìbùkún ti èmi ó gbà bí mo bá gbé ní yíyẹ. Bákannáà ó ràn mí lọ́wọ́ láti rántí àti ní ìmọ̀lára àláfíà pé Ọlọ́run yíò pèsè àwọn ìdáhùn àti láti ṣí àwọn ilẹ̀kùn fún mi ní déédé àkokò nígbàtí mo nílò rẹ̀ jùlọ.
Àwọn ìbùkún ti bàbánlá nràn wá lọ́wọ́ láti múrasílẹ̀ láti gbé pẹ̀lú Bàbá wa Ọ̀run. Mo mọ̀ pé àwọn ìbùkún ti bàbánlá nwá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ó sì lè rànwálọ́wọ́ láti yí àwọn àìlera wa padà sí okun. Ìwọ̀nyí kìkí ṣe àwọn ọ̀rọ̀ látọ̀dọ̀ alásọtẹ́lẹ̀; ìwọ̀nyí ni àwọn ìbùkún tí ó sọ ohun tí a nílò láti gbọ́ sí wa. Wọ́n dàbí àṣíá fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa. Nígbàtí a bá fi Ọlọ́run ṣíwájú tí a sì ní ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀, Òun yíò darí wa nínú aginjù ti ara wa.
Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe bùkún Joseph Smith pẹ̀lú oyèàlùfáà kí àwọn ìbùkún ìhìnrere lè jẹ́ ìmúpadàbọ̀sípò, a lè gba àwọn ìbùkún ìhìnrere nínú ayé wa nípasẹ̀ oyèàlùfáà. Lọ́sọ́ọ́sẹ̀ a fún wa ní ànfàní àti ààyè láti jẹ́ oúnjẹ Olúwa. Nípasẹ̀ ìlànà oyèàlùfáà yí, a lè ní Ẹ̀mí láti wà pẹ̀lú wa nígbàgbogbo, èyí tí ó lè wẹ̀ wá nù àti yà wá sí mímọ́. Bí a bá ní ìmọ̀lára ìnílò láti mú ohunkan kúrò nínú ayé wa, ẹ nawọ́ jáde sí olórí olùgbẹ́kẹ̀lé kan tí ó lè ràn yín lọ́wọ́ sí ipá ọ̀nà títọ́. Àwọn olórí yín lè ràn yín lọ́wọ́ láti ní ààyè sí agbára kíkún Ètùtù Jésù Krístì.
Ọpẹ́ sí oyèàlùfáà, bákannáà a lè gba ìbùkún àwọn ìlànà ti tẹ́mpìlì. Látìgbà tí mo ti lè wọnú tẹ́mpìlì, mo ti mu ṣe ìfojúsùn àti ìṣíwájú láti lọ déédé. Nípa mímú àkokò àti ṣíṣe àwọn ìrúbọ tó ṣeéṣe láti súnmọ́ Bàbá mi Ọ̀run nínú ilé mímọ́ Rẹ̀, mo ti di alábùkún pẹ̀lú gbígba ìfihàn àti àwọn ìṣínilétí tí ó ti rànwálọ́wọ́ lotitọ ní gbogbo ayé mi.
Nípasẹ̀ oyèàlùfáà, a lè ní ìgbéga. Oyèàlùfáà nmú ìmọ́lẹ̀ wá sínú ayé wa. Alàgbà Robert D. Hales wípé: “Láìsí agbára oyèàlùfáà, ‘gbogbo ilẹ̀ ayé ni yíò di ìfiṣòfò’ (wo D&C 2:1–3). Kò ní sí ìmọ́lẹ̀, kò sí ìrètí—òkùnkùn nìkan.”2
Ọlọ́run ndárayá fún wa. Ó nfẹ́ kí a pada sọ́dọ̀ Rẹ̀. Ó mọ̀ wá níti-ara. Ó mọ̀ yín.” Ó nífẹ́ wa. Ó nfì ìgbàgbogbo nífura nípa wa àti láti bùkún wa àní nígbàtí a bá nímọ̀lára pè a kò lẹtọ síi. Ó mọ ohun tí a nílò àti ìgbà tí a nílò rẹ̀.
“Ẹ bẽrè, a ó sì fi fún yín; ẹ wá kiri, ẹ̀yin ó sì rí; ẹ kànkùn, a ó sì ṣíi sílẹ̀ fún yín:
“Nítorípé ẹnikẹ́ni tí ó bá bẽrè, nrí gbà; ẹnití ó bá sì wá kiri nrí; ẹnití ó bá sì kànkùn, ni a ò síi sílẹ̀ fún“ (Máttéù 7:7–8).
Tí ẹ kò bá ní ẹ̀rí nípa oyèàlùfáà tẹ́lẹ̀, mo gbà yín níyànjú láti gbàdúrà kí a sì bèèrè láti mọ̀ fúnra yín nípa agbára rẹ̀, lẹ́hìnnáà ka àwọn ìwé-mímọ́ láti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Mo mọ̀ pé tí a bá tiraka láti ní ìrírí agbára oyèàlùfáà Ọlọ́run nínú ayé wa, a ó di alábùkún. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.