Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Bí Oyè Àlùfáà ti Nbùkún Ọ̀dọ́
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2020


Bí Oyè Àlùfáà ti Nbùkún Ọ̀dọ́

A fún wa ní ànfàní láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ bí ti àwọn ángẹ́lì, lati wàásù ìhìnrere ní gbogbo àwọn ìpínlẹ̀ ayé, àti láti ran àwọn ọkàn lọ́wọ́ láti wá sí ọ̀dọ̀ Krístì.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, mo kún fún ìmoore nítòótọ́ láti bá yín sọ̀rọ̀ ní ìrọ̀lẹ́ pàtàkì yi nípa ẹ̀bùn mímọ́ ti oyè àlùfáà àti agbára yíyanilẹ́nu tí ó ní lati bùkún àwọn ọ̀dọ́ ní àkókò ìríjú yi. Mo gbàdúrà pé láìka àwọn àìpé mi sí, Ẹ̀mí yío ràn mí lọ́wọ́ ní kíkọ́ni ní òtítọ́.

Àjọ Ààrẹ Ìkínní ti rán àwọn tí wọ́n di Oyè Àlùfáà Áárọ́nì mú létí pé “ẹ ngbé ní ọjọ́ àwọn ànfààní àti àwọn ìpèníjà nlá— ọjọ́ nínú èyítí a ti mú oyè àlùfáà padàbọ̀ sípò. Ẹ ní àṣẹ láti ṣe ìpínfúnni àwọn ìlànà ti Oyè Àlùfáà Áárọ́nì. Bí ẹ ti nlo àṣẹ náà pẹ̀lú àdúrà àti pẹ̀lú ìkàyẹ, ẹ ó bùkún ìgbé ayé àwọn wọnnì ní àyíka yín lọ́pọ̀lọpọ̀.”1 Bi ọ̀dọ́mọkùnrin nínú Ìjọ, a rán wa létí bákannáà pé a jẹ́ “àyànfẹ́ [àwọn ọmọkùnrin] ti Ọlọ́run, àti pé Ó ní iṣẹ́ kan fún [wa] láti ṣe”2 àwa sì nṣe àtìlẹhìn nínú iṣẹ́ Rẹ̀ “láti mú àìkú àti ìyè ayérayé ti ènìyàn wá sí ìmúṣẹ” (Mósè 1:39

Oyè àlùfáà ni àṣẹ láti ṣe ìpínfúnni àwọn ìlànà àti àwọn májẹ̀mú ti ìhìnrere Olùgbàlà sí àwọn wọnnì tí wọn bá yẹ láti gbà wọ́n. Nípasẹ̀ àwọn ìlànà oyè àlùfáà àti àwọn májẹ̀mú mímọ́ wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìbùkún ti Ètùtù Olùgbàlà fi nwá, èyítí ó nràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àṣeyọrí ìpín àtọ̀runwá wa.

Joseph Smith jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin ẹnití Ọlọ́run pè láti mú ìhìnrere ti Jésù Krístì padàbọ̀ sípò àti pé, fún ìdí náà, a fún un ní oyè àlùfáà, èyítí ó lò láti bùkún gbogbo aráyé. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 135 tọ́ka sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn ìbùkún tí Joseph ti fi fún àwọn ọ̀dọ́ ti ìgbà ìríjú yi. A kà pé: “Joseph Smith … ti ṣe púpọ̀, bíkòṣe Jésù nìkanṣoṣo, fún ìgbàlà àwọn ènìyàn ní ayé yi, ju èyíkeyi ẹnikẹ́ni míràn tí ó ti gbé rí nínú rẹ̀. … Òun ti mú Ìwé ti Mọ́mọ́nì jáde wá … ; ó ti rán ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere ayérayé … sí àwọn igun mẹ́rẹ̀rin ilẹ̀ ayé; ó ti mú àwọn ìfihàn àti àwọn òfin èyítí ó wà nínú ìwé Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mu [náà] jáde wá …; ó kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹgbẹgbẹ̀rún àwọn Ẹni Mímọ́ ti Ọjọ́ Ìkẹhìn jọ, … ó sì fi òkìkí àti orúkọ kan sílẹ̀ tí kò ṣeé pa” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 135:3

Láti sìn dáradára bí Joseph ti ṣe, a gbọ́dọ̀ yege pẹ̀lú ìkàyẹ láti lo agbára oyè àlùfáà ti Oluwa. Nígbàtí wọ́n nyí ọ̀rọ̀ Ìwé ti Mọ́mọ́nì padà, Joseph àti Oliver Cowdery fẹ́ láti jẹ́ rírìbọmi, ṣùgbọ́n wọ́n ṣe aláìní àṣẹ tí ó dára. Ní ọjọ́ kẹ̃dógún Oṣù Karũn, 1829, wọ́n kúnlẹ̀ nínú àdúrà a sì bẹ̀ wọ́n wò láti ipasẹ̀ Jòhánnù Onítẹ̀bọmi, ẹnití ó fún wọn ní àwọn kọ́kọ́rọ́ àti àṣẹ ti Oyè Àlùfáà Áárónì, tí ó wípé, “Ní orí yín ẹ̀yin ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ mi, ní orúkọ Messíà mo fi Oyè Àlùfáà ti Áárónì fún yín, èyí tí ó ní kọ́kọ́rọ́ ti iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn ángẹ́lì, àti ti ìhìnrere ìrònúpìwàdà, àti ti ìrìbọmi nípa rírì bọmi fún ìmúkúrò àwọn ẹ̀ṣẹ̀” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 13:1).

A fún wa ní ànfàní láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ bí ti àwọn ángẹ́lì, lati wàásù ìhìnrere ní gbogbo àwọn ìpínlẹ̀ ayé, àti láti ran àwọn ọkàn lọ́wọ́ láti wá sí ọ̀dọ̀ Krístì. Iṣẹ́ ìsìn yi fi wa sí inú àjùmọ̀ṣe iṣẹ́ pẹ̀lú Jòhánnù Onítẹ̀bọmi, Moroni, Joseph Smith, Ààrẹ Russell M. Nelson, àti àwọn aláápọn ìránṣẹ́ Olúwa miràn.

Iṣẹ́ ìsìn wa nínú àti pẹ̀lú oyè àlùfáà Rẹ̀ nmú àwọn wọnnì tí wọ́n ní ìfọkànsìn sí títẹ̀lé àti gbígbé ìgbé ayé àwọn ẹ̀kọ́ ti Olúwa ní pípé wà papọ̀, èyítí mo mọ̀ fúnra ara mi pé ó le ṣòro bí a ti nkojú àwọn ìpèníjà ti ọ̀dọ́. Ṣùgbọ́n dídàpọ̀ pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ ìránṣẹ́ Olúwa wọ̀nyí ní síṣe àṣeyọrí iṣẹ́ Rẹ̀ yío ṣe ìrànwọ́ láti fúnwa ní okun dojúkọ àwọn àdánwò àti àwọn ẹ̀tàn ti ọ̀tá. Ẹ le jẹ́ ìmísí kan ti ìmọ́lẹ̀ sí gbogbo àwọn wọnnì tí wọn kò dá ara wọn lójú. Ìmọ́lẹ̀ tí ó wà nínú yín yío tàn tó bẹ́ẹ̀ tí olukúlùkù ẹnití a bá ní í ṣe pẹ̀lú yío di alábùkún fún nípa pé wọ́n kàn wà nínú àjọ yín. Ó le nira nígbà míràn láti jẹ́wọ́ wíwà níbẹ̀ àwọn ojúgbà wa ní ti ẹ̀mí, ṣùgbọ́n mo dúpẹ́ láti mọ̀ pé mo jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ iyejú olóyè àlùfáà onígbàgbọ́ kan, àwọn ẹnití mo le bá ṣiṣẹ́ pọ̀ láti súnmọ́ Krístì síi.

Pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹbí wa, Ẹ̀mí Mímọ́ ni ọ̀kan lára àwọn ojúgbà wa tí ó jẹ́ olõtọ́ àti tí ó ṣe é gbaralé jùlọ. Ṣùgbọ́n láti le pe ìbákẹgbẹ́ Rẹ̀ ìgbà gbogbo, a gbọ́dọ̀ fi ara wa sí inú àwọn ipò àti àwọn ibi tí Òun yío fẹ́ láti wà. Èyí le bẹ̀rẹ̀ nínú ibùgbé tiwa bi a ṣe nṣiṣẹ́ láti mú wọn jẹ́ ibi mímọ́ nípa kíkópa nínú síṣe àṣàrò ìwé mímọ́ àti àdúrà ojojúmọ́ bí ẹbí kan àti, ní pàtàkì jù, bí a ti nṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́ tí a sì ngbàdúrà fúnra wa.

Enzo àti arábìnrin rẹ̀
Enzo àti ẹbí rẹ̀

Sẹ́hìn ní ọdún yi, a fúnmi ní ànfàní ìdùnnú àti síbẹ̀ onitẹríba kan láti ran arábìnrin mi kékeré lọ́wọ́, Oceane, láti tẹ̀síwájú ní ipa ọ̀nà majẹ̀mú nípa gbígba ìpè láti jẹ́ rírìbọmi kí ó sì mú ọ̀kan ṣẹ lára àwọn ilàsílẹ̀ tí a bééré láti wọ ìjọba sẹ̀lẹ́stíà. Ó sún ìrìbọmi rẹ̀ síwájú ní oṣù kan, títí a fi yàn mí bí àlùfáà, láti fún mi ní ànfàní làti ṣe ìlànà náà, nígbàtí àwọn arábìnrin wa miràn bákannáà ní ànfàní láti ṣiṣẹ́ ní abẹ́ ìyànṣẹ́fúnni ti oyè àlùfáà tí wọ́n sì dúró bi ẹlẹ́rìí. Bí a ti dúró ní dojúkojú ní àwọn ẹ̀gbẹ́ ibi ìrìbọmi, tí a nmura láti wọ inú omi náà, mo rí ìdùnnú rẹ̀, bí ó ti bá tèmi mu. Mo sì ní ìmọ̀lára ìdarapọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ní ríríi pé ó nṣe ìpinnu tí ó dára Ànfàní yi láti lo oyè àlùfáà gba pé kí nkíyèsára síi kí nsì dín àìbìkítà kù nínú ìgbé ayé ìhìnrere mi. Kí nle ba múra, mo lọ sí tẹ́mpìlì ní ojojúmọ́ ní ọ̀sẹ̀ náà, pẹ̀lú àtilẹ́hìn ìyá, ìyá àgbà, àti arábìnrin mi, láti ṣe àwọn ìrìbọmi fún àwọn òkú.

Ìrírí yi kọ́mi ní ohun púpọ̀ nípa oyè àlùfáà àti bí mo ti le lò ó ní yíyẹ. Mo mọ̀ pé gbogbo àwọn olóyè àlùfáà le ní irú ìmọ̀lára àwọn ohun kannáà tí èmi ní bí a bá tẹ̀lé àpẹrẹ Néfì láti “lọ kí a sì ṣe.” (wo 1 Nefì 3:7). A kò le jókòó ní àìníṣẹ́ kí a sì máa retí Olúwa láti lò wá nínú iṣẹ́ nlá Rẹ̀ A kò gbọdọ̀ dúró fún àwọn wọnnì tí wọ́n nílò àtìlẹ́hìn wa láti wá wa jáde; ojúṣe wa ni bíi olóyè àlùfáà láti fi hàn kí a sì dúró bíi Ẹlẹ́rí Olọ́run. Bí a bá nṣe àwọn ìpinnu tí ó ndí wa lọ́wọ́ nínú ìtẹ̀síwájú ti ayérayé, a gbọ́dọ̀ yípadà nísisìyí. Satanì yío gba ìyànjú rẹ̀ tí ó le jùlọ láti fi wá sí ipò ara ti wíwá àwọn ìrọ̀rùn ìtura. Ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé bí a bá ṣe aápọn, tí a wá àwọn tí wọn yío tìwá lẹ́hìn, tí a sì nronúpìwàdà ní ojojúmọ́, àwọn ìbùkún àyọrísí rẹ̀ yío pọ̀ púpọ̀, ìgbé ayé wa yío sì yípadà títí láe bí a ti ntẹ̀síwájú ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú.

Mo mọ̀ pé èyí ni Ijọ òtítọ́ ti Jésù Krístì, ẹnití í ṣe Olùgbàlà wa Òun sì ti fi àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè àlùfáà fún àwọn Àpóstélì Rẹ̀,àwọn ẹnití wọ́n nlò ó láti tọ́ wa, pàápàá ní àwọn ọjọ́ ìpèníjà wọ̀nyí, àti láti pèsè ayé sílẹ̀ fún ìpadàbọ̀ Rẹ̀.

Mo jẹri pé Joseph Smith jẹ́ wòlíì ti Ìmúpadàbọ̀ sípò àti pé Ààrẹ Russell M. Nelson ni wòlíì alààyè wa loni. Mo pe gbogbo wa láti ṣe àṣàrò lóri ìgbé ayé àwọn ẹni nla olóyè àlùfáà wọ̀nyí kí a sì wá láti mú ara wa gbèrú síi ní ojojúmọ́ kí a le ṣetán láti pàdé Ẹlẹ́da wa. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ Ráńpẹ́

  1. Ajọ Ààrẹ Ìkínní, nínú Fulfilling My Duty to God booklet, 2010), 5.

  2. “Akòrí iyejú Oyè Àlùfáà ti Áárónì, nínú Ìwé Ìléwọ́ Gbogbogbò: Sísìn nínú Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn, 10.1.2. ChurchofJesusChrist.org.