Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ẹ Jẹ́ Kí Ilé Yí Di Kíkọ́ Sí Orúkọ Mi
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2020


Ẹ Jẹ́ Kí Ilé Yí Di Kíkọ́ Sí Orúkọ Mi

(Ẹkọ àti Àwọn Májẹmú 124:40)

Àwọn májẹ̀mú tí a gbà àti àwọn ìlànà tí a ṣe nínú àwọn tẹ́mpìlì ṣe pàtàkì sí ìyàsímímọ́ ọkàn wa àti fún ìgbéga ìgbẹ̀hìn ti àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Ọlọ́run.

Nínú igbó mímọ́ ní igba ọdún sẹ́hìn, Joseph Smith kékeré rí ó sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, Bàbá Ayérayé, àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì. Látọ̀dọ̀ wọn, Joseph kọ́ nípa ìwàẹ̀dá òtítọ́ ti Olórí-ọ̀run àti ìfihàn tó nlọ lọ́wọ́ bí ìran tótayọ yí ṣe mú “àkokò ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn ìgba” ọjọ́ ìkẹhìn wá.“1

Ó fẹ́rẹ̀ tó ọdún mẹ́ta lẹ́hìnnáà, ní ìdáhùn sí àdúrà àtọkànwá ní ìrọ̀lẹ́ Ọjọ́ Kọkanlelogun Oṣù Kẹsan, 1823, yàrá ibùsùn Joseph kún fún ìmọ́lẹ̀ títí tí o “fi mọ́lẹ̀ ju ọ̀sángangan lọ.”2 Ẹni-nlá kan farahàn ní ẹ̀gbẹ́ ibùsùn rẹ̀, ó pe ọ̀dọ́mọkùnrin náà ní orúkọ ó sì kéde “ó jẹ́ olùránṣẹ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run … àti pé orúkọ rẹ̀ ni Mórónì.”3 Ó pàṣẹ fún Josẹ́fù nípa bíbọ̀ wá ti Ìwé Mọ́mọ́nì.

Àti pé lẹ́hìnáà Mórónì ṣe àyọsọ látinú iwé Málákì nínú Májẹ̀mú Láéláé, pẹ̀lú ìyípada díẹ̀ nínú èdè tí a lò nínú Ẹ̀dà ti Ọba Jákọ́bù:

“Kíyèsĩ, èmi yíò fi Oyèàlùfáà hàn síi yín, láti ọwọ́ wòlíì Èlíjàh, kí ọjọ́ Olúwa nã èyítí íṣe nlá tí ó sì ní ẹ̀rù tó dé. …

“Òun ó sì gbin àwọn ìlérí tí a ṣe sí àwọn bàbá sínú ọkàn àwọn ọmọ, ọkàn àwọn ọmọ yíò sì yí padà sí àwọn bàbá wọn. Tí kò bá rí bẹ́ẹ̀, gbogbo ilẹ̀ ayé yíò ṣòfò pátápátá ní bíbọ̀ rẹ̀.”4

Nípàtàkì, àṣẹ Mórónì sí Jósẹ́fù Smith nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ Èlíjàh mú tẹ́mpìlì àti ìwé-ìtàn ẹbí wá ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn ó sì jẹ́ kókó ohun èlò nìnú mímúpadàbòsípò “gbogbo àwọn ohun, èyí tí Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ látẹnu gbogbo àwọn wòlíì mímọ́ látìgbà tí ayé ti bẹ̀rẹ̀.”5

Mo gbàdúrà fún àtìlẹhìn ti Ẹ̀mí Mímọ́ bí a ṣe nkọ́ ẹ̀kọ́ papọ̀ nípa àwọn májẹ̀mú, ìlànà, àti àwọn ìbùkùn tí ó wà fún wa nínú àwọn tẹ́mpìlì Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.

Ìpadàbọ̀ Èlíjàh

Mo bẹ̀rẹ̀ nípa bíbèère ìbèèrè ìpinlẹ̀ kan: Kínìdí tí ìpadàbọ̀ Èlíjàh fi ṣe pàtàkì?

“A kọ́ látinú ìfihàn ọjọ́-ìkẹhìn pé Èlíjàh di agbára èdidì ti Oyèálùfáà Mẹlkisédékì mú”6 ó sì “jẹ́ wòlíì tó gbẹ̀hìn láti ṣe bẹ́ẹ̀ ṣíwájú ìgbà ti Jésù Krístì.”7

Wòlíì Josẹ́fù Smith ṣàlàyè, “Ẹ̀mí, agbára, àti ìpè Èlíjàh ni, pé ẹ ní agbára láti di kọ́kọ́rọ́ … ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Oyèàlùfáà Mẹlkisédékì … ; àti láti … gba … gbogbo àwọn ìlànà tó wà pẹ̀lú ìjọba Ọlọ́run, àní sí yíyí ọkàn àwọn bàbá sí àwọn ọmọ, àti ọkàn àwọn ọmọ sí àwọn bàbá, àní àwọn wọnnì ẹnití ó wà lọ́run.”7

Àṣẹ mímọ́ èdidì yí ṣeéṣe kí “ohunkóhun tí ẹ bá dì lórí ilẹ̀ ayé lè di dídì ní ọ̀run: àti ohunkóhun tí ẹ bá tú sílẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé yíò di títú sílẹ̀ ní ọ̀run.”8

Jósẹ́fù fihàn síwájú si, “Báwo ni Ọlọ́run yíò ṣe wá sí ìgbàlà ìran yí? Òun yíò rán wòlíì Èlíjàh. … Èlíjàh yíò fi àwọn májẹ̀mú láti ṣe èdidì ọkàn àwọn bàbá sí àwọn ọmọ hàn, àti àwọn ọmọ sí bàbá.”9

Èlíjàh farahàn pẹ̀lú Mósè lórí òkè ìyípòpadà ó sì gbé àṣẹ lé Pétérù, Jákọ́bù, àti Jòhánnù lórí.10 Èlíjàh bákannáà farahàn pẹ̀lú Mósè àti Elias ní Ọjọ́ Kẹta Oṣù Kẹrin, 1836, ní Tẹ́mpìlì Kirtland ó sì fi àwọn kọ́kọ́rọ́ oyèàlùfáà irú kannáà sórí Jósẹ́fù Smith àti Oliver Cowdery.11

Ìmúpadàbọ̀sípò ti àṣẹ èdidì látọwọ́ Èlíjàh ní 1836 ṣe pàtàkì láti múra ayé sílẹ̀ fún ìpadàbọ̀ ẹ̀ẹ̀kẹjì Olùgbàlà ó sì fi ọ̀pọ̀ nlá àti ìfẹ́ àgbáyé nínù ìwákiri ìwé-ìtàn ẹbí hàn.

Yíyípadà, Yíyípo, àti àwọn Ọkàn Yíyàsímímọ́

Ọ̀rọ̀ náà ọkàn ni a lò ju ìgbà ẹgbẹ̀rún nínú àwọn iṣẹ́ òṣùwọn. Ọ̀rọ̀ jẹ́jẹ́ yí ṣùgbọ́n pàtàkì nígbàkugbà fi àwọn ìmọ̀lára inú hàn nípa ẹnìkọ̀ọ̀kan. Ọkàn wa—àròpọ̀ àpapọ̀ ti àwọn ìfẹ́ wa, àwọn ìdùnmọ́ni, àwọn èrò, ìgbìrò, àti àwọn ìwà—túmọ̀ ẹni tí a jẹ́ àti pinnu ohun tí a ó dà. Àkójá iṣẹ́ Olúwa nyípadà, nyípo, àti yíyàsímímọ́ àwọn ọkàn símímọ́ nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú ìhìnrere àti àwọn ìlànà oyèàlùfáà.

A kìí kọ́ tàbí wọnú àwọn tẹ́mpìlì mímọ́ nìkan láti ní ìrántí ẹnìkọ̀ọ̀kan tàbí ìrírí ẹbí. Ṣùgbọ́n, àwọn májẹ̀mú tí a gbà àti àwọn ìlànà tí a ṣe nínú àwọn tẹ́mpìlì ṣe pàtàkì sí ìyàsímímọ́ ọkàn wa àti fún ìgbéga ìgbẹ̀hìn ti àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Ọlọ́run.

Gbígbin àwọn ìlérí tí a ṣe sí àwọn bàbá sínú ọkàn àwọn ọmọ—àní Ábráhámù, Ísáákì, àti Jákọ̀bù—yíyí ọkàn àwọn ọmọ padà sí àwọn bàbá ti arawọn, dídarí ìwákiri ìwé-ìtàn ẹbí, àti ṣíṣe ìrọ́pò àwọn ìlànà tẹ́mpìlì jẹ́ àwọn iṣẹ́ tí ó nbùkún àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìbòjú. Bí a ṣe nfi taratara ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ mímọ́ yí, à ngbọ́ran sí àwọn òfin láti nifẹ kí a sì sin Ọlọ́run àti àwọn aladugbo wa.12 Àti pé irú iṣẹ́ ìsìn àìnímọtaraẹni-nìkan náà nrànwálọ́wọ́ nítòótọ́ láti “Gbọ́ Ọ!”13 kí ẹ sì wá sọ́dọ̀ Olùgbàlà.14

Àwọn májẹ̀mú mímọ́ jùlọ àti àwọn ìlànà oyeàlùfáà ni à ngbà nínú tẹ́mpìlì Ọlọ́run nìkan—Ilé Olúwa. Gbogbo ohun tí à nkọ́ àti gbogbo ohun tí à nṣe nínú tẹ́mpìlì ntẹnumọ́ àtọ̀runwá Jésù Krístì àti ojúṣe Rẹ̀ nínú ètò nlá ti ìdùnnú Bàbá Ọ̀run.

Láti Inú Jáde Síta

Ààrẹ Ezra Taft Benson ṣàpèjúwe àwòṣe pàtàkì kan tí Olùràpadà gbà ní mímú “àìkú àti ìyè ayérayé wá sí ìmúṣẹ.”15 Ó wípé, “Olúwa nṣiṣẹ́ láti inú jáde síta. Ayé nṣiṣẹ́ láti ìta wá sí inú. Ayé yíò mú àwọn ènìyàn jáde látinú ẹrẹ̀. Krístì nmú ẹrẹ̀ jáde látinú àwọn ènìyàn. Lẹ́hìnnáà wọ́n nmú arawọn jáde nínú ẹrẹ̀. Ayé yíò mọ ènìyàn nípa yíyí àyíká wọn padà. Krístì nyí ènìyàn padà, tí yíò wá yí àyíká padà lẹ́hìnnáà. Ayé yíò tún ìwà ènìyàn ṣe, ṣùgbọ́n Krístì lè yí ìwàẹ̀dá ènìyàn padà.”16

Àwọn májẹ̀mú àti ìlànà oyèàlùfáà ṣe kókó ní ètò ti àtúnbí ẹ̀mí àti ìyípòpadà tó nlọ lọ́wọ́; láti inú jáde síta. Àwọn májẹ̀mú tí a nbuọlá fún daindain, tí a rántí nígbàgbogbo, tí a sì kọ “pẹ̀lú Ẹ̀mí Ọlọ́run alààyè … nínú tábìlì ẹran ara ti ọkàn”17 pèsè èrò àti ìdánilójú àwọn ìbùkún nínú ayé ikú àti fún àìlópin. Àwọn ìlànà tí a gbà ní yíyẹ tí a sì rántí lemọ́lemọ́ nṣí àwọn ọ̀nà tọ̀run nípasẹ̀ èyí tí agbára ìwàọ̀run lè ṣàn sínú ayé wa.

A kò wá sí tẹ́mpìlì láti sápamọ́ kúrò tàbí sálọ kúrò nínú àwọn ibi ayé. Ṣùgbọ́n, a wá sí tẹ́mpìlì láti ṣẹ́gun ayé ibi. Bí a ṣe npe “agbára ìwàọ̀run”18 nípasẹ̀ gbígba àwọn ìlànà oyèàlùfáà àti ṣíṣe àti dídá àwọn májẹ̀mú mímọ́, a di alábùkún pẹ̀lú okun tó kọjá ti arawa19 láti borí àwọn àdánwò àti ìpènijà aye ikú àti láti ṣe àti láti di rere.

Òkìkí ti Ilé Yí Yíò Tànká

Tẹ́mpìlì àkọ́kọ́ ti àkokò yí ni a kọ́ ní Kirtland, Ohio tí a sì yàsímímọ́ ní Ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n Oṣù Kẹta, 1836.

Nínú ìfihàn kan sí Wòlíì Joseph Smith ọ̀sẹ̀ kan lẹ́hìn ìyàsímímọ́, Olúwa kéde,

“Ẹ jẹ́ kí ọkàn gbogbo àwọn ènìyàn mi yọ̀, ẹnití ó ní, pẹ̀lú okun wọn, kọ́ ilé yí sí orúkọ mi.

“Bẹ́ẹ̀ni ọkàn àwọn ẹgbẹẹgbẹrún àti mẹ́wẹ̀ẹ̀wá ẹgbẹẹgbẹ̀rún yíò yọ̀ nínú àbájádé àwọn ìbùkún èyí ni a ó tú jáde, àti ìrónilágbára náà pẹ̀lú èyí tí a ti ró àwọn ìránṣẹ́ mi lágbára nínú ilé yí.

“Òkìkí ti Ilé yí yíò tànká sí àwọn ilẹ̀ òkèèrè; àti pé èyí ni ìbẹ̀rẹ̀ ìbùkún èyí tí yíò dà jáde sórí àwọn ènìyàn mi.”20

Jọ̀wọ́ kíyèsí àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ ọkàn ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti mẹ́wẹ̀ẹ̀wá ẹgbẹẹgbẹ̀rún yíò yọ gidigidi, àti pé òkìkí ilé yí yíò tànká sí àwọn ilẹ̀ òkèèrè. Ìwọ̀nyí jẹ́ àwọn ìkéde ìyanilẹ́nu ní Oṣù Kẹrin ti 1836, nígbàtí Ìjọ ní àwọn ọmọ ìjọ tí kò pọ̀ rárá àti tẹ́mpìlì kan.

Loni ní 2020, a ní àwọn tẹ́mpìlì méjìdínláàdóje tó nṣiṣẹ. Mọ́kàndínláàdọ̀ta àfikún àwọn tẹ́mpìlì wa lábẹ́ kíkọ́ tàbi tí wọn ti polongo. Àwọn ilé Olúwa ni a nkọ́ lọ́wọ́ ní “àwọn orí òkun”21 àti ní àwọn orílẹ̀ èdè àti àwọn ibi tí a kàsí tẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ bí èyí tí kò tọ́sí tẹ́mpìlì kan.

Ayẹyẹ ìrónilágbára lọ́wọ́lọ́wọ́ ni a gbé kalẹ̀ ní èdè méjìdínláàdọ́rún tí yíò sì wà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àfikún èdè bí a ṣe nkọ́ àwọn tẹ́mpìlì láti bùkún àwọn ọmọ Ọlọ́run síi. Ní àwọn ọdún mẹẹdogun tó mbọ̀, oye àwọn èdè nínú èyí tí àwọn ìlànà tẹ́mpìlì yíò wà a ti lè ọ̀nà méjì.

Ní ọdún yí a ó fọ́ ilẹ̀ a ó sì bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ tẹ́mpìlì méjìdínlógún. Ní ìlòdì, ó gba àádọ́jọ ọdún láti kọ́ àwọn tẹ́mpìlì méjìdínlógún, láti ìdásílẹ̀ Ìjọ ní 1830 sí ìyàsímímọ́ Tẹ́mpìlì Tokyo Japan nìpasẹ̀ Ààrẹ Spencer W. Kimball ní 1980.

Àwòrán
Àwọn tẹ́mpìlì mẹ́fà

Gbèrò yíyára sí iṣẹ́ tẹ́mpìlì tí ó ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀ ní ìgbà-ayé Ààrẹ Russell M. Nelson. Nígbàtí a bí Ààrẹ Nelson ní Ọjọ́ Kẹsan Oṣù Kẹsan, 1924, Ìjọ ní àwọn tẹ́mpìlì mẹ́fà tó nṣiṣẹ́.

Àwòrán
Àwọn tẹ́mpìlì mẹ́rìndínlọ́gbọ́n

Nígbàtí a yan an bí Àpọ́stélì ní Ọjọ́ Keje Oṣù Kẹrin, 1984, ọgọ́ta ọdún lẹ́hìnnáà, tẹ́mpìlì mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ní ó nṣiṣẹ́, àlékún ogún tẹ́mpìlì ní ọgọ́ta ọdún.

Àwòrán
Àwọn tẹ́mpìlì mọ́kàndínlọ́gọ́jọ̀

Nígbàtí a ṣe ìmúdúró Ààrẹ Nelson bí Ààrẹ Ìjọ, àwọn tẹ́mpìlì mọ́kàndínlọ́gọ́fà ni ó nṣiṣẹ́, àlékún àwọn tẹ́mpìlì mẹ́tàlélógóje ní ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n nínú èyí tí ó fi sìn gẹ́gẹ́bí ọmọ ẹgbẹ́ ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá.

Àwòrán
Àwọn tẹ́mpìlì tó nṣiṣẹ́ àti àwọn tí a polongo

Látìgbà tí ó ti di Ààrẹ Ìjọ ní Ọjọ́ Kẹrìnlá Oṣù Kínní, 2018, Ààrẹ Nelson ti kéde àwọn tẹ́mpìlì titun marundinlogoji.

Ìwọn ọgọ́rúndínmẹ́rin àwọn tẹ́mpìlì tó wà ni a ti yàsímímọ́ nígbà ayé Ààrẹ Nelson; mẹ́rinlélọ́gọ́rin ni a ti yàsímímọ́ látìgbà tí a ti yàásọ́tọ̀ bí Àpọ́stélì.

Ẹ Dojúkọ Àwọn Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jùlọ Nígbàgbogbo

Bí àwọn ọmọ Ìjọ ìmúpadàbọ̀sípò Olúwa, a dúró ní gbogbo ìyanu ní ìgbà tó nsáré sí iṣẹ́ Rẹ̀ ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn. Àti pé àwọn tẹ́mpìlì ṣì mbọ̀ si.

Brigham Young sàsọtẹ́lẹ̀, “Láti ṣe àṣeyege iṣẹ́ yí kò níláti jẹ́ tẹ́mpìlì kan nìkan ṣùgbọ́n ẹgbẹẹgbẹ̀rún wọn, ẹgbẹẹgbèrún àti mẹ́wẹ̀ẹ̀wá ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọkùnrin àti obìnrin yíò lọ sínú àwọn tẹ́mpìlì wọ̀nnì àti láti ṣiṣẹ́ fún àwọn ènìyàn tí wọ́n ti gbé pípẹ́ sẹ́hìn bí Olúwa yíò ti fihàn.”22

Níní òye, ìkéde tẹ́mpìlì titun kọ̀ọ̀kan ni orísun ayọ̀ nlá àti ìdí láti fún Olúwa lọ́pẹ́. Bákannáà, kókó ìdojúkọ wa gbọ́dọ̀ jẹ́ lórí àwọn májẹ̀mú àti ìlànà tí ó lè yí ọkàn wa padà kí ó sì mú ìfọkànsìn wa jinlẹ̀ sí Olùgbàlà láì jẹ́ lórí ibìkan tàbí ẹwà ilé náà.

Àwọn ojúṣe ìpìnlẹ̀ tí ó dá lé orí wa bí àwọn ọmọ Ìjọ ìmúpadàbọ̀sípò Olúwa ni (1) láti “Gbọ́ Ọ!”23 kí a sì jẹ́ kí ọkàn wa yípadà nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú àti ìlànà, àti (2) láti mú ojúṣe yíyàn tọ̀run náà ṣẹ tayọ̀tayọ̀ láti fi àwọn ìbùkún tẹ́mpìlì fun gbogbo ẹbí ènìyàn lẹgbẹ méjèèjì ìbòjú. Pẹ̀lú ìdarí Olúwa àti ìrànlọ́wọ́, nítòótọ́ a ó mú àwọn ojúṣe wọ̀nyí wà sí ìmúṣẹ.

Gbígbé Síónì Ga

Wòlíì Joseph Smith kéde:

“Gbígbé ga Síónì ni èrò tí ó tì dùnmọ́ àwọn ènìyàn Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà; ó jẹ́ àkórí lórí èyí tí àwọn wòlíì, àlùfáà àti ọba ti gbé pẹ̀lú adùn pàtó; wọ́n ti fojúsọ́nà pẹ̀lú ìrò aláyọ̀ di ọjọ́ nínú èyí tí a ngbé; wọ́n sì fínná pẹ̀lú àwọn ìrò tọ̀run àti aláyọ̀ tí wọ́n ti kọrin tí wọ́n sì kọsílẹ̀ àti sísọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ wa; ṣùgbọ́n wọ́n kú láìní ìràn; … ó kù fún wa láti ri, kópa nínú kí a sì ṣèrànwọ́ láti yí ògo Ọjọ́-ìkẹhìn síwájú;“

“Oyèàlùfáà tọ̀run yíò darapọ̀ mọ́ ti ayé, láti mú àwọn èrò nl´a wọnnì wá; … iṣẹ́ kan tí Ọlọ́run àti àwọn ángẹ́lì ti gbèrò pẹ̀lú adùn fún àwọn ìran tó kọ́já; tí ó fínná mọ́ ẹ̀mí àwọn bàbánlá àtijọ́ àti àwọn wòlíì; iṣẹ́ kan tí ó ní àyànmọ́ láti mú ìparun bá àwọn agbára òkùnkùn, àtúnṣe ilẹ̀ ayé, ògo Ọlọ́run, àti ìgbàlà ẹbí ènìyàn.“

Mo jẹ́ẹ̀rí tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé Bàbá àti Ọmọ farahàn sí Joseph Smith, àti pé Èlíjàh mú àṣẹ èdidì padàbọ̀wásípò. Àwọn májẹ̀mú mímọ́ tẹ́mpìlì àti àwọn ìlànà lè fún wa lókun kí ó sì ya ọkàn wa sí mímọ́ bí a ṣe “Ngbọ́ Tirẹ̀!”25 àti tí a sì gba agbára ìwàọ̀run nínú ayé wa. Mo sì jẹ́ẹ̀rí pé iṣẹ́ ọjọ́-ìkẹhìn yí yíò pa àwọn agbára òkùnkùn run yíò sì mú ìgbàlà ẹbí àwọn ènìyàn wá. Nípa àwọn òtítọ́ wọ̀nyí ni mo jẹ́ẹ̀rí ni orúkọ mímọ́ Olúwa Jésù Krístì, àmín.

Tẹ̀