Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ronú Nípa Ìṣerere àti Títóbi Ọlọ́run
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2020


Ronú Nípa Ìwàrere àti Títóbi Ọlọ́run

Mo pè yín láti rántí títóbi Bàbá Ọ̀run àti Jésù Krístì àti ohun tí Wọn ti ṣe fún yín.

Ní gbogbo ìgbà, àní àti nípàtàkì ní àwọn ìgbà ìṣòro, àwọn wòlíì ti gbà wá níyànjú láti rántí títobi Ọlọ́run àti láti ronú nípa ohun tí ó ti ṣe fún wa bí ẹnìkọ̀ọ̀kan, bí àwọn ẹbí, àti bí àwọn ènìyàn kan.2 Ìdarí yí ni a rí jákèjádò gbogbo àwọn ìwé mímọ́ ṣùgbọ́n ó hàn kétékété nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Àkọlé ojú-ewé ṣàlàyé pé ọ̀kan lára àwọn èrò Ìwé ti Mọ́mọ́nì ni “lati fi han àwọn ìyókù ti Ilé Ísráẹ́lì àwọn ohun nlá tí Olúwa ti ṣe fún àwọn bàbá wọn.”3 Ìwé ti Mọ́mọ́nì parí pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀ Mórónì: “Ẹ kíyèsi, èmi yíò rọ̀ yín pé nígbàtí ẹ̀yin bá ka àwọn ohun wọ̀nyí … pé ẹ̀yin ó rántí bí Olúwa ti ní àánú tó sí àwọn ọmọ ènìyàn, … ẹ ó sì jíròrò rẹ̀ nínú ọkàn yín.”4

Lemọ́lemọ́ ẹ̀bẹ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì láti ronú lórí ìwàrere Ọlọ́run nmunilọ́kàn.5 Bàbá wa Ọ̀run nfẹ́ kí a rántí ìṣerere Rẹ̀ àti ti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀, kìí ṣe fún ìtẹ́nilọ́rùn ara Wọn ṣùgbọ́n fún agbára tí irú rírántí bẹ́ẹ̀ ní lórí wa. Nípa Ríronú ìwàrere Wọn, èrò àti lílóye wa ngbòòrò si. Nípa ríronú lórí àánú Wọn, à ndi onírẹ̀lẹ̀ si, aladura, àti dídúróṣinṣin.

Ìrírí dídunni kan pẹ̀lú aláìsàn tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀rí kan fi bí ìmoore fún inúrere àti àánú ṣe lè túnwa ṣe. Ní 1987, mo di ojúlùmọ̀ pẹ̀lú Thomas Nielson, ọkùnrin ọlọ́lá kan ẹni tí ó nílò àtúngbìn ọkàn kan. Ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́ta ni ó sì gbé ní Logan, Utah, ní United States. Títẹ̀lé iṣẹ́ ológun nígbà Ogun Agbáyé Kejì, ó gbé Donna Wilkes níyàwó ní Tẹ́mpìlì Logan Utah. Ó di alágbára kan àti aláṣeyege oníṣẹ́ bíríkì. Ní àwọn ọdún lẹ́hìnnáà ó gbádùn ṣíṣe iṣẹ́ nípàtàkì pẹ̀lú ọmọ-ọmọ rẹ̀ àgbà, Jonathan, nígbà ìsinmi ilé-ìwé. Àwọn méjèèjì mú ìsopò pàtàkì gbèrú, ní apákan nítorípé Tom rí ọ̀pọ̀ ara rẹ̀ nínú Jonathan.

Tom rí dídúró fún olùfúnni ní ọkàn bí ìdaniláàmú. Nípàtàkì kìí ṣe onísùúrù ọkùnrin rárá. Ó ti ṣeṣe fún un ní ìgbà gbogbo láti ṣe àgbékalẹ̀ àwọn àfojúsùn kí ó sì yege nípa iṣẹ́ àṣekára àti ìpinnu gãn . Títiraka pẹ̀lú ọkàn ìjákulẹ̀, pẹ̀lú ìgbé ayé rẹ̀ tó wà ní ìdádúró, Tom nígbàmíràn máa nbèèrè lọ́wọ́ mi ohun tí mò nṣe láti mú ètò náà yá kíákíá. Ní ṣíṣe yẹ̀yẹ́, ó dáàbá àwọn ọ̀nà tí mo lè lépa tí yíò mú olùfúni ní ọkàn wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láìpẹ́.

Ní ọjọ́ aláyọ̀ ṣùgbọ́n ẹlẹ́rù kan, olùfúni ní ọkàn tòótọ́ wá fún Tom. Ìwọn àti irú ẹ̀jẹ̀ náà bá ara mu, olùfúni náà sì jẹ́ ọ̀dọ́, ọmọ ọdún mẹrindinlogun péré ni. Ọkàn tí a fúnni náà jẹ́ ti Jonathan, àyànfẹ́ ọmọ-ọmọ Tom. Ṣaájú ní ọjọ́ náà, Jonathan ti ní ìpalára kíkorò nígbàtí ọkọ̀ nínú èyí tí ó wà jáàmù pẹ̀lú ọkọ̀ ojú irin tí nkọjá lọ.

Nígbàtí mo bẹ Tom àti Donna wò nínú ilé-ìwòsàn, wọ́n ní ìyọnu. Ó ṣòro láti ro ohun tí wọn nlà kọjá, ní mímọ̀ pé ìgbé ayé Tom lè gbòòrò si nípa lílo ọkàn ọmọ-ọmọ wọn. Ní àkọ́kọ́, wọ́n kọ̀ láti rò nípa ọkàn náà tí a fúnni láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí olùkẹ́dùn, ọmọbìnrin wọn àti ọkọ-ọmọ. Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀ Tom àti Donna mọ, pé ọpọlọ ni Jonathan ti kú, wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pé kìí ṣe àwọn àdúrà wọn fún ọkàn fífúnni fún Tom kọ́ ni ó fa ìjàmbá ọkọ̀ Jonathan. Rárá, ọkàn Jonathan jẹ́ ẹ̀bùn tí ó lè bùkún Tom ní ìgbà àìní. Wọ́n damọ̀ pé ohun kan tí ó dára lè wá láti inú ìjànbá yí wọ́n sì pinnu láti tẹ̀síwájú.

Àwọn ìṣe ìtúngbìn náà lọ dáradára. Lẹ́hìnnáà, Tom jẹ́ ọkùnrin ọ̀tọ̀. Ìyípadà náà lọ kọjá ìlera dídára si tàbí àní ìmoore. Ó sọ fún mi pé òun ronú ní òwúrọ̀ kọ̀ọ̀kan lórí Jonathan, lórí ọmọbìnrin àti ọkọ-ọmọ rẹ̀, lórí ẹ̀bùn tí ó ti gbà, àti lórí ohun tí ẹ̀bùn náà gbà. Àní bíótilẹ̀jẹ́pé àbínimọ́ ìwàrere àti akọni rẹ̀ ṣì hàn síbẹ̀, mo ṣe àkíyèsí pé Tom ní ọ̀wọ̀, àròjinlẹ̀, àti inúrere síi.

Tom gbé àfikún ìgbé ayé fún ọdún mẹ́tàlá lẹ́hìn àtúngbìn náà, àwọn ọdún tí òun kìbá ti ní. Ìkéde ikú rẹ̀ làásílẹ̀ pé àwọn ọdún wọ̀nyí fi ààyè gbà a láti fi ọwọ́ kan ayé ẹbí rẹ̀ àti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú ìwàrere àti ìfẹ́. Ó jẹ́ oloore ìkọ̀kọ̀ kan àti àpẹrẹ ìrètí àti ìpinnu.

Bíiti Tom, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ti gba àwọn ẹ̀bùn tí a kò lè pèsè fún ara wa, àwọn ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Bàbá wa Ọ̀run àti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀, pẹ́lú ìràpadà nípasẹ̀ ìrúbọ ètùtù Jésù Krístì.6 A ti gba ìyè nínú ayé yí; a ó gba ìyè ti-ara lẹ́hìnwá, àti ìgbàlà ayérayé àti ìgbéga—bí a bá yàn án—gbogbo rẹ̀ nítorí Bàbá Ọ̀run àti Jésù Krístí.

Gbogbo ìgbà tí a bá lòó, ti a jèrè láti inú rẹ̀, tàbí tí a ronú nípa àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí, a níláti ron nípa ìrúbọ náà, inúrere, àti àánú ti àwọn olùfúnni. Ọ̀wọ̀ fún àwọn olùfúnni ṣe ju mímú wa moore nìkan. Ríronú lórí àwọn ẹ̀bùn Wọn lè, ó sì gbọ́dọ̀, tún wa ṣe.

Ìyínipadà ọlọ́lá kan ni ti Álmà Kékeré. Bí Álmà ṣe “nlọ kiri ní ìtàpá sí Ọlọ́run,”7 ángẹ́lì kan fi ara hàn. Pẹ̀lú “ohun àrá,”8 ángẹ́lì náà bá Álmà wí fún síṣé inúnibíni sí Ìjọ àti “mímú ọkàn àwọn ènìyàn kúró.”9 Ángẹ́lì náà fi èyí kún ìkìlọ̀: “Lọ, ki o sì rántí ìgbèkùn àwọn bàbá rẹ …; àti kí o rántí àwọn ohun nlá tí [Ọlọ́run] ti ṣe fún wọn.”10 Nínú gbogbo ọ̀rọ̀ ìyànjú tí ó ṣeéṣe, èyíinì ni ohun tí ángẹ́lì náà tẹnumọ́.

Álmà ronúpìwàdà ó sì rántí. Ó pada ṣe àbàpín ọ̀rọ̀ ìyànjú àngẹ́lì náà pẹ̀lú ọmọkùnrin rẹ̀ Hẹ̀lámánì. Álmà dámọ̀ràn, “Èmi fẹ́ kí ìwọ kí ó ṣe gẹ́gẹ́bí èmi ti ṣe, ní ti rírántí ìgbèkùn àwọn bàbá wa; nítorítí nwọ́n wà nínú oko-ẹrú, tí kò sì sí ẹnití ó lè kó nwọn yọ bí kò ṣe Ọlọ́run Ábráhámù, … Ísãkì, àti … Jákọ́bù; òun sì kó nwọn yọ kúrò nínú ìpọ́njú nwọn nítõtọ́.”11 Álmà wí jẹ́jẹ́ pé, “Mo fi ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ mi sí inú rẹ̀.”12 Álmà ní ìmọ̀ pé nípa rírántí ìgbàlà kúrò nínú ìgbèkùn ati àtilẹhìn nínú “àwọn àdánwò àti ìdààmú onírurú gbogbo,” a wá mọ Ọlọ́run àti dídájú àwọn ìlérí Rẹ̀.13

Díẹ̀ lára wa ní ìrírí bí eré ìtàgé biiti Álmà, síbẹ̀síbẹ̀ ìyípadà wa lè jinlẹ̀ dọ́gba bákannáà. Olùgbàlà ti jẹjẹ nígbà àtijọ́:

“Èmi ó fi ọkàn titun fún yín pẹ̀lú, ẹ̀mí titun ni èmi ó sì fi sí inú yín: èmi ó sì mú ọkàn ókúta kúrò … èmi ó sì fi ọkàn ẹran fún yín.

“Èmi ó sì fi ẹ̀mí mi sí inú yín. …

“… Ẹ̀yin ó sì máà jẹ́ ẹnìyàn mi, èmi ó sì máa jẹ́ Ọlọ́run yín.”14

Olùgbàlà tí ó jínde wí fún àwọn ará Néfì bí àtúnṣe ṣe nbẹ̀rẹ̀. Ó ṣe ìdámọ̀ ìwò pàtàkì kan nínú ètò Bàbá Ọ̀run nígbàtí ó wípé:

“Bàbá mi sì rán mi kí a lè gbé mi sí orí àgbélèbú; lẹ́hìn tí a bá sì ti gbé mi sókè sí orí àgbélèbú, kí èmi ó lè fa gbogbo ènìyàn wá sí ọ̀dọ̀ mi. …

“Nítorí ìdí èyí ni a fi gbé mi sókè; nítorínáà, ní ìbáqmu sí agbára ti Bàbá ni èmi ó fa gbogbo ènìyàn wá sí ọ̀dọ̀ mi.”15

Kínni ó gbà fún yín láti súnmọ́ Olùgbàlà? Ẹ gbèrò ìjuwọ́sílẹ̀ Jésù Krístì sí ìfẹ́ Bàbá Rẹ̀, ìṣẹ́gun Rẹ̀ lórí ikú, gbígbé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn àṣìṣe wa sí orí Ararẹ̀, gbígba agbára Rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Bàbá láti bẹ̀bẹ̀ fún yín, àti ìràpadà ìgbẹ̀hìn Rẹ̀ fún yín.16 Njẹ́ àwọn ohun wọ̀nyí kò ha tó láti fà yín sí ọ́dọ̀ Rẹ̀? Wọ́n wà fún mi. Jésù Krístì “dúró pẹ̀lú apá ṣíṣí sílẹ̀, ní ríretí àti ní fífẹ́ láti wòsàn, láti dáríjì, láti wẹ̀mọ́, láti fún lókun, lati sọ di mímọ́, àti láti ya [ẹ̀yin àti èmi] sí mímọ́.”17

Àwọn ohun wọ̀nyí gbọ́dọ̀ fún wa ní ọkàn titun kí ó sì ṣíwa létí láti yan láti tẹ̀lé Bàbá Ọ̀run àti Jésù Krístì. Síbẹ̀síbẹ̀ àní àwọn ọkàn titun lè “fà sí láti rìn kiri, … fà sí láti fi Ọlọ́run náà tí [a] fẹ́ràn sílẹ̀.”18 Láti bá ìtẹ́sí yí jà, a nílò láti ronú lójoojúmọ́ lórí àwọn ẹ̀bùn tí a ti gbà àti ohun tí wọ́n gbà. Ọba Benjamin dámọ̀ràn, “èmi fẹ́ kí ẹ̀yin rántí, kí ẹ sì fi títóbi Ọlọ́run, sí ìrántí yín nígbàgbogbo … àti ìwàrere àti ìfaradà rẹ̀ sí yín.”19 Bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a yege fún awọn ìbùkún ọlọ́á tọ̀run.

Ríronú lórí ìṣerere àti àánú Ọlọ́run nrànwá lọ́wọ́ láti ní ìtẹ́wọ́gba síi ní ti ẹ̀mí. Ni ìpadà, àlékún ìfura ti ẹ̀mí nfi ààyè gbà wá láti mọ òtítọ́ àwọn ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí Mímọ́.20 Èyí wà pẹ̀lú ẹ̀rí kan nípa òtítọ́ Ìwé ti Mọ́mọ́nì; ní mímọ̀ pé Jésù ni Krístì, Olùgbàlà àti Olùràpadà ti ara wa, àti títẹ́wọ́gba pé ìhìnrere Rẹ̀ náà ti di ìmúpadàbọ̀sípò ní àwọn ọjọ́-ìkẹhìn wọ̀nyí.21

Nígbàtí a bá rántí títóbi Bàbá wa Ọ̀run àti Jésù Krístì àti ohun tí Wọ́n ti ṣe fún wa, a kò ní mú wọn yẹpẹrẹ, gẹ́gẹ́bí Tom kò ṣe mú ọkàn Jonathan ní yẹpẹrẹ. Ní ọ̀nà aláyọ̀ àti ọ̀wọ́ kan, Tom rántí lójoojúmọ́ ìjámbá tí ó mú ẹ̀mí gígùn síi wá fún un . Nínú ọ̀yàyà ti mímọ̀ pé a lè di gbígbàlà àti gbígbéga, a nílò láti rántí pé ìgbàlà àti ìgbéga nwá lórí iye nlá kan.22 A lè fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ láyọ̀ bí a ṣe nmọ̀ pé láìsí Jésù Krístì, a ti parun, ṣùgbọ́n pẹ̀lú Rẹ̀, a lè gba ẹ̀bùn títóbi jùlọ tí Bàbá Ọ̀run lè fúnni.23 Nítòótọ́, ọ̀wọ̀ yí fúnwa láàyè láti gbádùn ìlérí “ti ìyè ayérayé ní ayé yí” àti nígbẹ̀hìn láti gba “ìyè ayérayé … àní ògo àìkú” nínú ayé tó nbọ̀.24

Nígbàtí a bá ronú nípa ìṣerere Bàbá wa Ọ̀run àti Jésù Krístì, ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú Wọn npọ̀si. Àwọn àdúrà wa nyípadà nítorí a mọ pé Ọlọ́run ni Bàbá wa àwa sì jẹ́ ọmọ Rẹ̀. A kò wá láti yí ìfẹ́ Rẹ̀ padà ṣùgbọ́n láti fi ifẹ́ wa sí ìbámu pẹ̀lú Tirẹ̀ kí a sì gba àwọn ìbùkún tí Ó fẹ́ láti fún wa fúnrawa, ní bíbèèrè fún wọn.25 À npòngbẹ láti di ọlọ́kàn-tútù síi, ẹni mímọ́ síi, olùdúró-ṣinṣin síi, ẹni bíi Krístì síi.26 Àwọn ìyípadà wọ̀nyí nmú wa yege fún àfikún àwọn ìbùkùn ti ọ̀run.

Nípa jíjẹ́wọ́ pé gbogbo ohun rere nwá láti ọ̀dọ̀ Jésù Krístì, a ó bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ wa síi taratara.27 A ó ní ìgboyà nígbàtí a bá dojúkọ àwọn iṣẹ́ àti àwọn ipò tí ó dàbí àìlèṣeéṣe.28 A ó fún ìpinnu wa lókun láti pa àwọn májẹ̀mú tí a dá mọ́ láti tẹ̀lé Olùgbàlà.29 A ó kún fún ìfẹ́ Ọlọ́run, a ó fẹ́ láti ran àwọn wọnnì nínú àìní lọ́wọ́ láì dá wọn lẹ́jọ́, a ó ní ìfẹ́ àwọn ọmọ wa a ó sì tọ́ wọn nínú òdodo, a ó mú ìwẹ̀nùmọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa dúró, a ó sì máa yọ nígbà gbogbo.30 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn èso ọlọ́lá ti rírántí ìwàrere àti ìyọ́nú Ọlọ́run.

Ní ìlòdì, Olùgbàlà kìlọ̀ pé, “Nínú ohunkóhun kọ́ ni ènìyàn ti ṣẹ Ọlọ́run, tàbí sí ẹnikẹ́ni kọ́ ní ìbínú Rẹ̀ gbóná , bíkòṣe àwọn wọnnì tí wọn kò jẹ́wọ́ agbára rẹ̀ nínú ohun gbogbo.”31 Emi kò rò pé Ọlọ́run rírífín nígbàtí a bá gbàgbé Rẹ̀. Ṣùgbọ́n, mo rò pé Òun ní ìjákulẹ̀ tí ó jinlẹ̀ nípa wa. Ó mọ̀ pé a ti sẹ́ ara wa ní ànfàní láti fà súnmọ́ Ọ nípa rírántí Rẹ̀ àti ìṣerere Rẹ̀. Nígbànáà a pàdánù Rẹ̀ láti súnmọ́ wa síi àti àwọn ìbùkún ní pàtó tí ó ṣe ìlérí .32

Mo pè yín láti rántí ọlánlá Bàbá Ọ̀run àti Jésù Krístì lójoojúmọ́ àti ohun tí Wọn ti ṣe fún yín. Ẹ jẹ́ kí ìfiyèsí yín nípa ìwàere Wọn ó so ọkàn rírìnkiri yín mọ́ wọn típẹ́típẹ́.33 Ẹ jíròrò lórí àánú Wọn, ẹ̀yin yíò sì di alábùkún pẹ̀lú àfikún níní ìfura ti ẹ̀mí àti dídà bí Krístì síi. Gbígbèrò nípa ìyọ́nú Wọn yíò ràn yín lọ́wọ́ láti “dúró ninú òtítọ́ dé òpin,” títí tí “a ó fi gbà yín sí ọ̀run” láti “gbé pẹ̀lú Ọlọ́run nínú ipò ìdùnnú àìlópin.”34

Bàbá wa Ọ̀run, ní títọ́ka sí Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀, wípè, “Ẹ Máa Gbọ́ Tirẹ̀!”35 Bí ẹ ṣe nṣiṣẹ́ lórí àwọn ọ̀rọ̀ tì ẹ sì nfi etísílẹ̀ sí I, ẹ rántí, tayọ̀tayọ̀ àti tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, pé Olùgbàlà nifẹ láti mú padàbọ̀sípò ohun tí ẹ̀yin kò lè mú padabọ̀sípò , Ó nifẹ láti ṣe ìwosàn àwọn ọgbẹ́ tí ẹyin kò lè wo sàn, Ó nifẹ láti ṣe àtúnṣe ohun tí ó ti fọ́ kọjá àtúnṣe ,36 Ó nsan ẹ̀san fún àìdára tí a ṣe síi yín,37 Ó sì nifẹ láti ṣe àtúnṣe pátápátá sí àní àwọn ọkàn tí ó ti bàjẹ́.38

Bí mo ṣe ti ronú lórí àwọn ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Bàbá wa Ọ̀run àti láti ọ̀dọ̀ Jésù Krístì, mo ti mọ̀ nípa ìfẹ́ àìlópin Wọn àti àìlóyé àánú Wọn fún gbogbo àwọn ọmọ Bàbá Ọ̀run.39 Ìmọ̀ yí ti yí mi padà, ó sì ti yíi yín padà. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Tẹ̀