Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Lọ Síwájú nínú Ìgbàgbọ́
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2020


Lọ Síwájú nínú Ìgbàgbọ́

Mo bùkún yín pẹ̀lú àláfíà àti àlékún ìgbàgbọ́ nínú Olúwa.

Ẹyin àyànfẹ́ arábìnrin àti arákùnrin mi, bí a ti wá sí òpin ìpàdé àpapọ̀ onítàn yí, a fi ìmoore wa hàn sí Olúwa. Orin náà ti jẹ́ ọlọ́lá àti pé àwọn ọ̀rọ̀ náà jẹ́ onimisi.

Nínú ìpàdé àpapọ̀ yí, a ti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì ìrírí. Ní àjọ̀dún igba ọdún yí, a ti fi ìpolongo kan hàn sí àgbáyé ní kíkéde òdodo Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ rẹ̀.

A ṣàjọ̀dún Ìmúpadàbọ̀sípò pẹ̀lú Igbe Hòsánnà.

A ṣí àmì titun tó nfi ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù Krítì hàn àti fún ìwò ìdámọ̀ ti ìwífúnni gbangba Ìjọ àti àwọn ohun èlò.

A ti pè fún ọjọ́ àwẹ̀ àti àdúrà gbogbo ayé, kí rúdurùdu lọ́wọ́lọ́wọ́ lè dáwọ́dúró, ki ààbò wà lórí àwọn olùtọ́jú, kí ọrọ ajé gba okun, àti kí ìgbé ayé wà nibamu. A ó gba àwẹ̀ ní Jímọ̀h Rere, Ọjọ́ Kẹwa Oṣù Kẹrin. Irú Jímọ̀h nlá tí èyí yíò jẹ́!

Ọjọ́-ìsinmi tó mbọ̀ ni Ọjọ́-ìsinmi Ọdún Àjíìnde, nígbàtí a ó ṣayẹyẹ Ètùtù àti Àjíìnde Olúwa wa Jésù Krístì. Nítorí Ètùtù Rẹ̀, ẹ̀bùn àjíìnde Rẹ̀ yíò wá sọ́dọ̀ gbogbo ẹni tí ó ti gbé ayé rí. Ẹ̀bùn ìyè ayèrayé Rẹ̀ yíò wá sọ́dọ̀ gbogbo ẹnití ó yege nípa òtítọ́ sí àwọn ìlànà àti májẹ̀mú tí a ṣe nínú tẹ́mpìlì mímọ́ Rẹ̀.

Àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìmísí ti ìpàdé àpapọ gbogbogbò Oṣù Kẹrin yí —àti ọ̀sẹ̀ mímọ́ tí aó bẹ̀rẹ̀ báyìí—ni a le kópọ̀ nípa ọ̀rọ̀ àṣẹ tọ̀run méjì: “Gbọ́ Tirẹ̀.“1 A gbàdúrà kí ìdojúkọ yín sí Bàbá Ọ̀run, ẹnití ó sọ̀rọ̀ wọnnì, àti lórí Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, yíò dúró pẹ́ nínú ìrántí yín nípa gbogbo ohun tó ti ṣẹlẹ̀. A gbàdúrà pé ẹ ó bẹ̀rẹ̀ lọ́tun nítòótọ́ láti gbọ́, fetísílẹ̀ sí, àti gbọ́ ọ̀rọ̀ Olùgbàlà.2 Mo ṣèlérí pé dídínkù ẹ̀rù àti púpọ̀si ìgbàgbọ́ yíò tẹ̀le.

Ẹ ṣe fún ìfẹ́ yín láti mú ilé yín jẹ́ ibi mímọ́ ìgbàgbọ́ tòótọ́, níbití Ẹ̀mí Olúwa lè gbé. Ohun èlò àṣàrò ìhìnrere wa, Wá, Tẹ̀lé Mi, yíò tẹ̀síwájú lati bùkún ìgbé aye yín. Ìtiraka yín léreléra nínú ìsapá yí—àní nínú àkokò wọnnì nígbàtí ẹ lè nímọ̀lára pé ẹ kò ṣàṣeyọrí nípàtàkì—yíò yí ìgbé ayé yín padà, ti ẹbí yín, àti ayé. A ó gba okun àní bí a ṣe ndi akọni ọmọlẹ́hìn Olúwa si, dídúró sókè àti sísọ̀rọ̀ fún Un, níbikíbi tí a wà.

Báyìí, ẹ jẹ́ kí a sọ̀rọ̀ nípa àwọn tẹ́mpìlì. A ní àwọn tẹ́mpìlì méjìdínlâdọ́san káàkiri ayé. Àwọn míràn wà ní onírurú ìpò ìṣètò àti kíkọ́. Nígbàtí a bá polongo àwọn ètò láti kọ́ tẹ́mpìlì titun, ó di ara íwé-ìtàn mímọ́ wa.

Ó lè dàbí ìṣòdì láti ìpolongo àwọn tẹ́mpìlì titun nígbàtí gbogbo àwọn tẹ́mpìlì wa wà ní títì fún ìgbà díẹ̀.

Ju ọgọ́ọ̀rún ọdún sẹ́hìn, Ààrẹ Wilford Woodruff tirì àwọn ipò bíi tiwa loni, bí a ṣe kọ́sílẹ̀ nínú àdúrà ìyàsímímọ́ Tẹ́mpìlì Salt Lake, tí a fúnni ní 1893. Àwọn kan lára yín lè ti rí àwọn àyọsọ látinú àdúrà ọlọ́lá yí lórí ìbákẹ́gbẹ́ ìròhìn láìpẹ́.

Ẹ gbọ́ àwọn ẹ̀bẹ̀ wọ̀nyí látẹnu wòlíì nlá Ọlọ́run: “Nígbàtí ènìyàn Rẹ kò ní ànfàní wíwọ inú ilé mímọ́ yí … tí wọ́n ní ìnilára àti ìdàmú, tí àwọn ìṣòro yí wọn ká tí wọ́n ó sì yí ojú … wọn síwájú ilé Rẹ mímọ́ yí tí wọn ó bèèrè lọ́wọ́ Rẹ fún ìdándè, fún ìránlọ́wọ́, fún agbára Rẹ láti na jáde ní ìtìlẹhìn wọn, a bẹ̀ Ọ́, láti wolẹ̀ látinú ibùgbé mímọ́ Rẹ ní àánú … kí ó gbọ́ ìgbe wọn. Tàbí nígbàtí awọn ọmọ ènìyàn Rẹ, ní àwọn ọdún tó mbọ̀, yíò níyapa, nípa èròkèrò, láti ibí yí, … tí wọn yíò kígbe sí Ọ látinú ìjìnlẹ̀ ìpọ́njú wọn àti ìkorò láti nawọ́ ìrànlọ́wọ́ àti ìdándè sí wọn, a fìrẹ̀lẹ̀ bẹ̀ Ọ́ láti … fetísí ìgbe wọn, àti láti fi àwọn ìbùkún nínú èyí tí wọ́n bèèrè fún wọn.“3

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ní àwọn ìgbà ìrẹ̀wẹ̀sì wa nígbàtí àwọn tẹ́mpìlì wà ní títì, ẹ ṣì lè fa agbára májẹ̀mú tẹ́mpìlì àti ìrónilágbára wá sórí yín bí ẹ ṣe mbọ̀wọ̀ fún àwọn májẹ̀mú yín. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ lo àkokò yí nígbàtí tẹ́mpìlì wà ní títì láti tẹ̀síwájú láti gbé ìgbé ayé yíyẹ-tẹ́mpìlì, tàbí láti di yíyẹ fún tẹ́mpìlì.

Ẹ sọ̀rọ̀ nípa tẹ́mpìlì pẹ̀lú ẹbí yín àti àwọn ọ̀rẹ́. Nítorí Jésù Krístì wà ní oókan ohungbogbo tí à nṣe nínú tẹ́mpìlì, bí ẹ ṣe nronú si nípa tẹ́mpìlì ẹ ó máa ronu si nípa Rẹ̀. Ẹ ṣe àṣàrò kí a sì gbàdúrà láti kekọ si nípa agbára àti ìmọ̀ pẹ̀lú èyí tí ẹ ti gba ìrónilágbára—tàbí èyí tí ẹ ó gba ìronilágbára síbẹ̀.

Loni inú wa dùn láti kéde àwọn ètò láti kọ́ àwọn tẹ́mpìli mẹ́jọ̀ titun ní àwọn ibí wọ̀nyí: Bahía Blanca, Argentina; Tallahassee, Florida; Lubumbashi, Democratic Republic of the Congo; Pittsburgh, Pennsylvania; Benin City, Nigeria; Syracuse, Utah; Dubai, United Arab Emirates; àti Shanghai, People’s Republic ti China.

Ní gbogbo ibi mẹ́jọ, ni àwọn olùkọ́lé yíò ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ ìbílẹ̀ kí tẹ́mpìlì lè wà ní ìbámu pẹ̀lú kí ó sì jẹ́ àlékún sí ìletò kọ̀ọ̀kan.

Ètò fún tẹ́mpìlì kan ní Dubai wá ní ìdáhùn sí ìfipè ọlọ́á wọn, èyí tí a jẹ́wọ́ pẹ̀lú ìmoore.

Àwọn ọ̀rọ̀ ìṣíwájú fún ètò ti Shanghai ṣe pàtàkì gidi. Fún ọgún ọdún ó lé, àwọn ọmọ-ìjọ yíyẹ-tẹ́mpìlì ní People’s Republic ti China lọ sí tẹ́mpìlì Hong Kong China. Ṣùgbọ́n ní Oṣù Kéje 2019, a ti tẹ́mpìlì fún ìṣètò-pípẹ́ àti àtúnṣe tí a nílò-púpọ̀.

Ní Shangai, ìwọn-déédé ibi ìpàdé onírurú-èrò kan yíò pèsè ọ̀nà kan fún àwọn ọmọ ìjọ Chinese láti tẹ̀síwájú nínú àwọn ìlànà ti tẹ́mpìlì—ní People’s Republic ti China—fún wọn àti àwọn bàbánlá wọn.4

Ní gbogbo orílẹ̀-èdè, Ìjọ yí nkọ́ àwọn ọmọ-ìjọ rẹ̀ làti bọ̀wọ̀, gbọ́ran, àti mímú òfin dúró.5 A nkọ́ pàtàkì ẹbí, níti jíjẹ́ òbí rere àti àwọn oníìlú alápẹrẹ. Nítorí a bọ̀wọ̀ fún àwọn òfin àti àṣẹ ní People’s Republic ti China, Ìjọ kìí rán àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere tó nkààkiri lọ síbẹ̀; tàbí a ó ṣe báyìí.

Àtọ̀húnrìnwá àti gbogbo ìjọ ní Chinese yíò tẹ̀síwájú láti pàdé lọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Ipò ìmòfin Ìjọ yíò dúró láìyípadà. Ní ìbẹ̀rẹ̀ abala ilé lílò, wíwọlé yíò jẹ́ nípa ìfúnniláyè nìkan. Ilé Olúwa ní Shanghai ko jẹ́ ibùdó fún àwọn àlárìnkiri láti àwọn orílẹ̀-èdè míràn.

Àwọn tẹ́mpìlì titun mẹ́jọ wọ̀nyí yíò bùkún ìgbé ayé àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìbòjú ikú. Àwọn tẹ́mpìlì jẹ́ ara ìdádé Ìmúpadàbọ̀sípò ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere Jésù Krístì. Nínú ìwàrere àti inúrere Ọlọ́run, Ó nmú àwọn ìbùkún tẹ́mpìlì súnmọ́ àwọn ọmọ Rẹ̀ si níbi gbogbo.

Bí ìmúpadàbọ̀sípò ṣe ntẹ̀síwájú, mo mọ̀ pé Ọlọ́run yíò tẹ̀síwájú láti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun pàtàkì àti nlá tí ó jẹ mọ́ Ìjọba Rẹ̀ nihin lórí ilẹ̀ ayé hàn.6 Ìjọba náà ni Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n, mo fi ìfẹ́ mi hàn fún yín. Ní ìgbà ìnira àti àìnírétí yí, àti pípa àṣẹ tí a fún mi, èmi fẹ́ láti gbé ìbùkún ti àpọ́stélì lè yín lórí.

Mo bùkún yín pẹ̀lú àláfíà àti àlékún ìgbàgbọ́ nínú Olúwa.7

Mo Bùkún yín pẹ̀lú ìfẹ́ láti ronúpìwàdà àti láti dàbí Rẹ̀ díẹ̀ si ní ojoojúmọ́.8

Mo bùkún yín lati mọ̀ pé Wòlíì Joseph Smith ni wòlíì Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ rẹ̀.

Tí ààrùn bá wà ní àárín yín tàbí àwọn olólùfẹ́ yín, mo fi ìbùkún ìwòsàn kan, tó wà pẹ̀lú ìfẹ́ Olúwa sílẹ̀.

Mo bùkún yín bẹ́ẹ̀, àfikún ìfihàn ìfẹ́ mi fún ẹnìkọ̀ọ̀kan yín, ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.