Ìpìlẹ̀ Rere Kan sí Ìgbà tí ó Nbọ̀
Ní àwọn ọdún tí ó nbọ̀, kí á gba àwọn ìlọsíwájú tí a ṣe si Tẹ́mpìlì Salt Lake láti sún wa kí ó sì mí sí wa.
Ìtàn Tẹ́mpìlì Salt Lake
Ẹ jẹ́ ki a rìn ìrìnàjò padà sí ọ̀sán gbígbóná kan ni ọjọ́ kẹrìnlélógún Oṣù Kéje, 1847 ni bíi agogo méjì ọ̀sán. Títẹ̀lé ìrìnajò nínira ọlọ́jọ́ mọ́kànlélãdọ́fà pẹ̀lú ọmọ ìjọ méjìdínlógóje ti wọn jẹ ikọ̀ àkọ́kọ́ ti o darí sí ìwọ̀ oòrùn, Brigham Young, Ààrẹ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá nígbànáà, tí ó nṣe àìsàn tí o si rẹ̀ pẹ̀lú ibà orí-òkè, wọ Àfonífojì Salt Lake.
Ọjọ́ mejì lẹ́hìn náà, bí ara rẹ ti nya kúrò nínú àìlera náà, Brigham Young ṣaájú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ iyejú Àwọn Àpóstélì Méjìlá ati àwọn míràn ni ìrìnàjò ṣíṣe àwárí. William Clayton kọsílẹ̀, “Bíi ìdámẹ́ta-nínú-mẹ́rin máìlì kan sí àríwá àgọ́ na, a dé ibi ilẹ̀ rírẹwà kan, ti o tẹ́jú tí ó sì fì dáradára si apá ìwọ̀-oòrùn.”1
Bí wọ́n ti nṣe àyẹ̀wò ọ̀gangan ilẹ̀ náà pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ náà, Brigham Young dúró lójijì o si fi ọ̀pá rẹ̀ sọlẹ̀, ó kígbe, “Nihĩn ni Tẹ́mpìlì Ọlọ́run wa yio dúró si,” Ọ̀kan nínú àwọn ojúgbà rẹ ni Alàgbà Wilford Woodruff, tí ó sọ ọ̀rọ̀ yí “lọ nínú [rẹ̀] bíi mọ̀nàmọ́ná,” ó si mú ẹ̀ka kan wá sí ilẹ̀ láti ṣe àmì si ọ̀gangan ibi tí ọ̀pá Ààrẹ Young gún. A yan ogoji éékà fún tẹ́mpìlì náà, wọn sì pinnu pé kí a gbe ìlú nla náà kalẹ̀ “ni pípé ní igun mẹ́rin Àríwá & Gúsù, ila-oòrùn & ìwọ̀-oòrùn” pẹ̀lú tẹ́mpìlì ní àárín.2
Ni Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin ọdún 1851, àwọn ọmọ ìjọ dì ìbò ní ìfohùnsọkan láti ṣe ìmúdúró àbá lati kọ tẹ́mpìlì kan “si orúkọ Oluwa.”3 Ọdún méjì lẹ́hìn náà, ni ọjọ́ kẹrìnla oṣù kejì, 1853,a ya ààyè náà sí mímọ́ láti ọwọ́ Heber C. Kimball ninú ayẹyẹ ìta gbangba kan tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ènìyàn Mímọ́ wà, ilẹ̀ sì di wíwú fún ìpìlẹ̀ Tẹ́mpìlì Salt Lake. Lẹ́hìn oṣù díẹ̀ kan, ni ọjọ́ kẹfà Oṣù Kẹ́rin, àwọn òkúta igun ilé nla ti tẹ̀mpìlì náà di fífi lélẹ̀ ati yíyà sí mímọ́ pẹ̀lú àwọn ayẹyẹ nla tí o ni ìtọ́ni àwọ̀ àti àwọn onílù àti títò lẹ́sẹẹsẹ kan ti àwọn olùdarí ìjọ ṣíwájú láti àgọ́ àtijọ́ si ibi ààyè tẹ́mpìlì, níbi ti a ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ ti a si gba àwọn àdúrà ni ibi ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn òkúta mẹ́rin náà.4
Ní ibi ayẹyẹ ilẹ̀ wíwú náà, Ààrẹ Young rántí pé òhun ti rí ìran kan nígbàtí o kọ́kọ́ fi ẹsẹ̀ tẹ orí ilẹ̀ náà bi wọn ti nṣe àyẹ̀wò àfonífojì ilẹ̀ náà, wípé, “Mo mọ̀ [nígbànáà], gẹ́gẹ́bí mo ṣe mọ̀ bayi, pé èyí ni ilẹ̀ náà ní orí èyíti a o kọ́ tẹ́mpìlì si—ó wà níwájú mi.”5
Ọdún mẹwa lẹ́hìnnáà, Brigham Young fúnni ní òye àsọtẹlẹ ti o tẹle ni ibi ìpàdé apapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹ́wàá 1863: “Èmi fẹ́ ri tẹ́mpìlì [náà] ní kíkọ́ ni ọ̀nà ti yíó dúró la ẹgbẹ̀rún ọdún já. Èyí kìí ṣe tẹ́mpìlì kan ṣoṣo ti a o kọ; àwọn ọgọrun irú wọn wà tí a ó kọ́ ti a o si ya si mímọ́ fun Olúwa. Tẹ́mpìlì yí yíò jẹ́ mímọ̀ bíi tẹ́mpìlì àkọ́kọ́ tí a kọ́ ní orí àwọn òkè láti ọwọ́ Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-Ìkẹhìn. … Mo fẹ́ kí tẹ́mpìlì náà … dúró bí ohun ìyangàn ìrántí ìgbàgbọ́, ìforítì àti aápọn àwọn Ènìyan Mímọ́ Ọlọ́run ni orí àwọn òkè.”6
Ní ṣíṣe àyẹ̀wò ìtàn kékeré yí, ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi nípa ipò aríran Brigham Young—àkọ́kọ́, ní fífi dáni lójú pé, bí ó bá ti ṣeéṣe tóàti, ní lílo àwọn ètò ìkọ́lé ti o wa ni ìgbà ati ibi náà, a o kọ Tẹ́mpìlì Salt Lake ni ọ̀nà tí yio fi ara dà jákèjádò Ẹgbẹ̀rún ọdún àti, èkejì, sísọtẹ́lẹ̀ rẹ nípa dídàgbà àwọn tẹ́mpìlì ní ọjọ́ iwájú ní gbogbo àgbáyé, àní láti tó kíkà ni àwọn ọgọọ́gọ̀rún.
Àtunṣe Tẹ́mpìlì Salt Lake
Bíiti Brigham Young, àwọn wòlíì wa ti òní bojútó Tẹ́mpìlì Salt Lake àti àwọn míràn pẹ̀lú ìtọ́jú nla. Ní ọ̀pọ̀ àwọn ọdún, Àjọ Ààrẹ Ìkínní láti ìgbà dé ìgbà gba Alàkóso Bíṣọ́pù nímọ̀ràn láti ríi dájú pé ìpìlẹ̀ Tẹ́mpìlì Salt Lake múlẹ̀ ṣinṣin. Nígbà tí mo sìn ninú Àjọ Bíṣọ́pù Alàkóso , ní ìbèèrè Àjọ Ààrẹ Ìkínní, a ṣe àyẹ̀wò gbogbo ohun ìní ti Tẹ́mpìlì Salt Lake, pẹ̀lú àyẹ̀wò àwọn ìgbèga àìpẹ̀ jùlọ ní ṣíṣe àwòṣe sẹ́smíkì àti àwọn ìlànà-ìṣẹ́ ilé-kíkọ́.
Nihin ni àwọn ìpín ti a yẹ̀wò tí a pèsè fún Ajọ Aàrẹ Ìkínní ní ìgbà náà: “Nínú ṣíṣé àwòrán àti kíkọ́ Tẹ́mpìlì Salt Lake, ìmọ̀ẹrọ ìkọ́lé, òṣìṣẹ́ ọwọ́, àwọn ohun èlò ìkọ́lé, àwọn ọ̀ṣọ́ àti àwọn ohun-èlò dídára jùlọ tí ó wà ní àrọ́wọ́tó ní àkokò náà ni a lò. Láti ìgbà ìyàsímímọ́ rẹ̀ ní ọdún 1893, tẹ́mpìlì náà ti dúró ṣinṣin ó sì ti jẹ́ wíwò bí àpẹrẹ ìgbàgbọ́ [àti] ìrètí kan àti bí ìmọ́lẹ̀ sí àwọn ènìyàn. Ìtọ́jú nlá ni a nṣe láti ṣiṣẹ́, fọ̀ọ́, àti láti mú tẹ́mpìlì dúró ní ipò rere. Òkúta dídán ìta àti àwọn irin ilẹ̀ inú-ilé àti àwọn òpó wà ní ipò rere. Àwọn àṣàrò àìpẹ́ yi fi ẹsẹ̀ rẹ̀ mulẹ̀ pé ibi tí Brigham Young yàn fún tẹ́mpìlì náà ní àwọn ilẹ̀ rere àti agbára ìbámu tí ó tayọ.”8
Àyẹ̀wò náà parí pé àwọn àtúnṣe àti ìmúdára síi ni a nílò láti ṣe ìsọdọ̀tun àti láti mú tẹ́mpìlì náà bá ìgbà mu, pẹ̀lú ilẹ̀ ìtà àti àwọn agbègbè tí a kò bò, àwọn ohun èlò tí ìgbà wọn ti kọjá, àwọn agbègbè ibi ìrìbọmi. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, gbígbèrò ti ìgbésókẹ̀ sẹ́smíkì tí ó dá dúró tí ó sì jẹ́ fínní-fínníbẹ̀rẹ̀ láti ìpìlẹ̀ tẹ́mpìlì lọ sókè ni a dábàá rẹ̀ bákannáà.
Ìpìlẹ̀ Tẹ́mpìlì Náà
Bí ẹ ti lè rántí, Ààrẹ Brigham Young fúnrarẹ̀ kó ipa níabala títóbi nínú kìkọ̀ ojúlówó ìpìlẹ̀ tẹ́mpìlì náà, èyí tí ó ti ṣiṣẹ́ fún tẹ́mpìlì náà dáradáraláti ìgbà àṣeparí rẹ̀ ní ọdún mẹ́tàdínláàdóje sẹ́hìn. Àròpọ̀ ti ìgbésókẹ̀ sẹ́smíkì titun tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ pèrò fún tẹ́mpìlì yíò lo ìmọ̀ ẹ̀rọ béèsì yíyàsọ́tọ̀, èyí tí a kò rò ní ìgbà kíkọ́ rẹ̀. Èyí ni a rò sí titun jùlọ, ìmọ̀-ẹ̀rọ ti ìgbàlódé jùlọ fún ààbò ilẹ̀-rírì.
Ìmọ̀ ẹ̀ro yí, tí kò tíì pẹ́ ní ti ìdàgbàsókè rẹ, bẹ̀rẹ̀ ní ibi ìpìlẹ̀ tẹ́mpìlì gan an, ní pípèsè ààbò tí ó dára ní ìlòdì sí ìbàjẹ́ láti inú ilẹ̀ rírí. Ní àkójá, ó nfún dídúró tẹ́mpìlì lókun láti dúró gbọingbọin, àní bí ilẹ̀ ayé àti àyíka ṣe nní ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀mímì ti sẹ́smíkì kan.
Àtúnṣe tẹ́mpìlì ti yio gba ìmọ̀ ẹ̀rọ yi sí iṣẹ́ ni a kéde rẹ̀ lati ọwọ Àjọ Ààrẹ Ìkínní ní ọdún tí o kọjá. Ní abẹ́ ìdarí Àjọ Alàkóso Bíṣọ́pù ìkọ́lé bẹ̀rẹ̀ ní oṣù díẹ̀ sẹ́hìn, ni Oṣù kínní Ọdún 2020 A fojú sí píparí rẹ ni bíi ọdún mẹ́rin, pẹ̀lú àfikún tàbí àyọkúrò díẹ̀.
Níní Ìdánilójú Ìpìlẹ Araẹni Tiyín
Bí mo ṣe nro ọdún mẹ́rin tí ó nbọ̀ ti ayé Tẹ́mpìlì Salt Lake tí ó rẹwà, tí ó lọ́lá, tí a gbéga, àti onímisí ìyanu, mo wòye rẹ̀ síi bí ìgbà ìsọdọ̀tun ju ìgbà títìpa lọ! Ni ọ̀nà ti o jọra kan, a lè bi ara wa léèrè, “Báwo ní ìsọdọ̀tun gbogbogbò ti Tẹ́mpìlì Salt Lake yi ṣe lè mísí wa láti fi ara da ìsọdọ̀tun, àtúnkọ, àtúnbi, àtúnṣe, tàbí ìmúpadàbọ̀sípòti ẹ̀mi ti ara wa?”
Ìfi ojú inúwò kan lè fihàn pé àwa náà àti àwọn ẹbí wa lè jẹ ànfàní lára ṣíṣe àwọn àtúnṣe àti iṣẹ́ ìsọdọ̀tun tí a nílò, àní ìgbésókè sẹ́smíkì kan! A lè bẹrẹ̀ irú ìlàna kan náà nipa bíbèrè pé:
Kínni wíwò ìpìlẹ̀ mi ṣe rí?
“Kínni àwọn ohun ti o wà nínú odi ti o nípọn, tí ó dúró déédéé, àwọn òkúta igun ilé ti o lágbára tí wọ́n jẹ́ apákan ìpìlẹ̀ ti ara ẹni mi, lórí èyí ti ẹ̀rí mi sinmi le?”
“Kínni àwọn èròjà ìwà ti ẹ̀mí àti ẹ̀dùn ọkàn mi ti yìó gbà èmi àti ẹbí mi láàyè láti dúró ṣinṣin àti láìyẹsẹ̀, pàápàá láti dojúkọilẹ̀-mímì àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ aláriwo ti sẹ́smíkì ti yíò ṣẹlẹ̀ dájúdájú nínú ìgbé ayé wa?”
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ti o farapẹ ilẹ̀ rírì kan ma nṣòro ní ọ̀pọ̀ ìgbà láti sọtẹ́lẹ̀ wọ́n sì máa nwá ní oríṣiríṣi ipele agbára kíkan—wíwọ ìjàkadì pẹ̀lú àwọn ìbéèrè tàbí iyèméjì, dídojúkọ ìpọ́njú tàbí wàhálà, iṣẹ́ ṣíṣe nípa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ araẹni pẹ̀lú àwọn olùdarí ìjọ, àwọn ọmọ ìjọ, ẹ̀kọ́, tàbí àkóso. Ààbò ti o dára jùlọ tako àwọn wọ̀nyí dúró lórí ìpìlẹ̀ ẹ̀mí ti araẹni wa.
Kínni àwọn òkúta igun ilé ti ẹ̀mí ti ìgbé ayé ara wa àti ti ẹbí wa le jẹ́? Wọ́n lè jẹ́ ìrọ̀rùn, kedere, àti àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ iyebiye ti ìgbé ayé ìhìnrere—àdúrà ẹbí, àṣàrò ìwé mímọ́, pẹ̀lú Ìwé ti Mọ́mọ́nì; lílọ si tẹ́mpìlì; àti kíkọ́ ẹ̀kọ́ ìhìnrere nípasẹ̀ Wá, Tẹ̀lé Mi àti ìpàdé ilé ìrọ̀lẹ́. Àwọn ohun èlò míràn tí ó le ranni lọ́wọ́ láti fún ìpìlẹ ẹ̀mí yín ni okun lè ní Àwọn nkan Ìgbàgbọ́, ìkéde ẹbí, àti “Krístì Alàyè nínú.”
Fún èmi, àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ tí wọ́n wa ninú àwọn ìbèèrè tí a ṣe ìjíròrò wọn bí ara gbígba ìwé ìkaniyẹ fún tẹ́mpìlì ṣiṣẹ́ bi ìpìlẹ̀ tí ó lágbára fún ìpìlẹ̀ ti ẹ̀mí—ni pàtàkì àwọn ìbèèrè mẹ́rin àkọ́kọ́. Mo rí wọn bi òkúta igun ile ti ẹ̀mí.
Àwa, dájúdájú, ti mọ àwọn ìbèèrè wọ̀nyí, bi Ààrẹ Russell M. Nelson ṣe kà wọ́n sí wa ní ọ̀kọ́ọ́kan nínú ìpàdé àpapọ gbogbogbò ti o kọjá.
-
Njẹ́ ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú àti ẹ̀rí kan nípa Ọlọ́run, Bàbá Ayérayé; Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì; àti Ẹ̀mí Mímọ́?
-
Njẹ́ ẹ ní ẹ̀rí ti Ètùtù Jésù Krístì àti ti ojúṣe Rẹ̀ bí Olùgbàlà àti Olùràpadà yín?
-
Njẹ́ ẹ ní ẹ̀rí kan nípa Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì?
-
Njẹ́ ẹ ṣe ìmúdúró Ààrẹ ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn bí wòlíì, aríran, àti olùfihàn àti bí ẹnìkanṣoṣo lórí ilẹ̀ ayé tí a fún láṣẹ láti lo gbogbo kọ́kọ́rọ́ oyèàlùfáà?9
Njẹ́ ẹ ríi bí ẹ ṣe le ronú lórí àwọn ìbèèrè wọ̀nyí bi àwọn ohun èlò oníyelórí nínú ìpìlẹ̀ ara ẹni tiyín láti ràn yin lọ́wọ́ láti kọ́ àti láti fi agbára kún un? Páúlù kọ́ àwọn ara Éfésù nípa ìjọ ti a “kọ́ lórí ìpìlẹ̀ àwọn àpóstélì àti àwọn wòlíì, tí Jésù Krístì tìkararẹ̀ jẹ́ pàtàkì òkúta igun ilé; nínú ẹnití gbogbo ilé na ṣe ọ̀kan papọ̀ tí wọ́n sì dàgbà sókè sí tẹ́mpìlì mímọ́ nínú Olúwa.”10
Ọ̀kan nínú àwọn ayọ̀ nla jùlọ ayé mi ni jíjẹ́ bíbárẹ́ pẹ̀lú àti làti ní ìmísí láti ọwọ àwọn ọmọ ìjọ kákiri àgbáyé, àwọn ti wọn gbé ìgbé ayé àpẹrẹ ìgbágbọ́ nínú Jésù Krístì áti ìhìnrere Rẹ̀. Wọ́n ní àwọn ìpìlẹ̀ araẹni líle ti o jẹ́ ki wọn ó dojúkọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ sẹ́smíkì tí ó ti da ayé wọn láàmú pẹ̀lú òye dídúróṣinṣin, láìka ọgbẹ́ ọkàn àti ìrora sí.
Láti ṣe àfihàn èyí lórí ipele ti araẹni si, mo sọ̀rọ̀ láìpẹ́ yi ní ibi ìsìnkú arẹwà, akíkanjú, ọ̀dọ́ ìyàwó àti ìyá kan (ọ̀rẹ́ ẹbí wa bákannáà). Ó jẹ́ agbábọ̀lù ẹ̀ka kékeré kan nígbàtí ó pàdé ti o si fẹ ọkọ rẹ̀, tí ó jẹ́ akẹkọ àyẹ̀wò eyín. A bùkún wọn pẹ̀lú ọmọbìnrin arẹwà, ọ̀yájú kan. Ó fi ìgboyà ja pẹ̀lú oríṣiríṣi àrùn jẹjẹrẹ fún ọ̀dun ìpèníjà mẹ́fà. Pẹ̀lú ìmọ̀lára ẹ̀dùn ọkàn àti ìrora àfojúrí ìgbà gbogboti o la kọjá, o gbẹ́kẹ̀lé olùfẹ́ni Bàbá Ọ̀run rẹ, wọn a si ma ṣe àtúnsọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ jákèjádò láti ẹnu àwọn àtẹ̀le rẹ̀ lórí ìbákẹ́gbẹ́ ìròhìn fún ọ̀rọ̀ tí í maá ṣáábà sọ pé: “Ọlọ́run wa ninú àwọn apákan ohun gbogbo.”
Lórí ọ̀kan làra àwọn ìfìránṣẹ rẹ lórí ìbákẹ́gbẹ́ ìrohìn, ó kọ pé ẹnìkan bèèrè lọ́wọ́ rẹ, “Báwo ni o ṣe tún ni ìgbàgbọ́ pẹ̀lú gbogbo ìrora ọkàn tí o yi ọ ka?” Ó dáhùn ní ìfimúlẹ̀ ṣinṣin pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Nítorípé ìgbàgbọ̀ ni o mú mi la àwọn àkókò tí ó ṣókùnkùn wọ̀nyí kọjá. Níní ìgbàgbọ́ kò túmọ̀ sí pé aburu kì yio ṣẹlẹ̀. Níní ìgbàgbọ́ gbàmí láyè lati gbàgbọ́ pe ìmọ́lẹ̀ yio wa lẹ́ẹ̀kan si. Àti pé ìmọ́lẹ̀ náà yio mọ́lẹ̀ síi pàápàá nítorítí mo ti la òkùnkùn kọjá. Bi òkùnkùn stí mo la kọja ni àwọn ọdún wọnnì ti pọ̀ tó, mo ti la ìmọ́lẹ̀ ti o ju bẹẹ lọ kọjá Mo ti rí àwọn iṣẹ́ ìyanu. Mo ti ni ìmọ̀lára àwọn ángẹ́lì. Mo ti mọ pé Bàbá mi Ọ̀run ngbé mi. Kò sí ọ̀kankan nínú èyíinì ti a le ti ni ìrírí rẹ̀ ti ìgbésí ayé ba rọrùn. Ọjọ́ ọ̀la ti ayé yi le jẹ́ àìmọ̀, ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ mi ko ri bẹẹ. Bí mo ba yan lati ma ni ìgbàgbọ́ nígbànàa mo yan lati rin nínu òkùnkùn nìkan. Nítorí láìsí ìgbàgbọ́, òkùnkùn nìkan ni o kù.”11
Ẹ̀rí àìmira ìgbàgbọ́ rẹ nínú Olúwa Jésù Krístì—nínu àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ—jẹ́ ìmísí fun àwọn ẹlòmíran. Àní bí ara rẹ tilẹ̀ ṣe àárẹ̀, ó gbé àwọn ẹlòmíràn soke láti lókun si.
Mo ro àìníye àwọn ọmọ ìjọ míràn, àwọn ajagun bíi ti obìnrin yi, àwọn ti wọn nrin lójojúmọ́ nínú ìgbàgbọ́, tí wọn ntiraka láti jẹ́ tòótọ́ àti aláìbẹ̀rù ọmọ ẹ̀hìn ti Olùgbàlà, Jésù Krístì. Wọ́n kọ nípa Krístì. Wọ́n wàásù nípa Krístì. Wọ́n tiraka làti tẹ̀lé àpẹrẹ Rẹ. Bóyá àwọn ọjọ ayé wọn dojúkọ ilẹ́ jẹ́jẹ́ tàbí tí ó nmì, wọ́n mọ̀ pé ìpìlẹ̀ wọn ní agbára kò sì lè yẹ̀.
Wọ̀nyí ni àwọn ọkàn mímọ́ ti wọ́n ní òye kókó ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ orin “Báwo ni Ìpìlẹ̀ kan Ṣe fẹsẹ̀-múlẹ̀ sí, ẹ̀yin Ènìyàn Mímọ́ Olúwa” ẹnití o sá tọ Olùgbàlà fún ààbo.”12 Mo dúpẹ́ kọjá òṣùnwọ̀n láti rìn laarin àwọn ẹni ti wọ́n ti múra ìpìlẹ̀ ti ẹ̀mí sílẹ̀ tí o yẹ fún orúkọ Àwọn Ènìyàn Mímọ́ àti ẹni ti o lágbára láti ṣètò tí o tó láti la àwọn ìrúkèrúdò ayé kọjá.
Èmi ko rò pé a le sọ àsọjù pàtàkì irú ìpìlẹ fífẹsẹ̀múlẹ̀ kan bẹ́ẹ̀ nínú ìgbé ayé ara wa. Àní ni ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ orígãn, wọn kọ àwọn ọmọ alakọbẹrẹ wa bi wọn ti kọrin nípa òtítọ́ gidi yi:
Ọlọgbọ́n ọkùnrin kọ́ ilé rẹ sí orí àpáta,
Àti pé ojo wa ó milẹ̀ tìtìtìtì. …
Òjò náàwá sílẹ̀, àti pe ìkún omiwá sókè,
Ilé náà lóri àpátadúró jẹ́.13
Ìwé Mímọ́ tún ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ yi sọ. Olùgbàlà kọ́ àwọn ènìyàn Àmẹ́ríkà:
“Bí ẹ̀yin bá sì fi ìgbà gbogbo ṣe awọn ohun wọ̀nyí alábùkún-fún ni ẹ̀yin í ṣe nítorítí a ti kọ́ọ yín lé orí àpáta mi.
“Ṣùgbọ́n ẹnìkẹ́ni nínú yín tí ó bá ṣe ju èyí tàbí kí ó dín in kù, òun ni a kò kọ́ lé orí àpáta mi, ṣùgbọ́n a kọ́ọ lé orí ìpìlẹ̀ yanrìn; nígbàtí òjò sì rọ̀, tí ìkún omi sì dé, tí afẹ́fẹ́ sì fẹ́, tí wọn sì bìlù wọn, wọn yíò ṣubú.”14
Ó jẹ ìrètí òdodo àwọn olùdarí Ìjọ pe àwọn ìsọdọ̀tun pàtàkì si Tẹ́mpìlì Salt Lake yio pakún ìmúṣẹ ìfẹ́ ọkan Brigham Young láti rí “tẹ́mpìlì náà ní kíkọ́ ni ọ̀nà ti yíó fi dúró la ẹgbẹ̀rún ọdún já.” Ní àwọn ọdún tí ó nbọ̀, kí á gba àwọn ìlọsíwájú tí a ṣe si Tẹ́mpìlì Salt Lake láyè láti sún wa kí ó sì mí sí wa, bi ẹnikọ̀ọ̀kan àti àwọn ẹbí, pé àwa náà—ní àfiwé—yío “le jẹ́ kíkọ́ ni ọ̀nà ti yíó fi dúró fún ẹgbẹ̀rún ọdún náà.”
A ó ṣe bẹ́ẹ̀ bí a ti nmu ọ̀rọ̀ Páúlù Àpóstélì ṣẹ láti “[kójọ] sókè pamọ́ fún [ara wa] ìpìlẹ̀ rere kan sí ìgbà tí ó nbọ̀, pe ki [àwa] lè gbá ayérayé mú.”15 Àdúrà ọkàn mi ni pe ìpìlẹ̀ ti ẹ̀mí wa yio dúro yio sí dájú, pe ẹ̀rí wa nípa Ètùtù Jésù Krístì àti ojúṣe Rẹ̀ bí Olùgbàla àti Olùràpadà wa yio di òkúta pàtàkì igun ilé fún wa, ẹni tí mo jẹri ní orúkọ Rẹ̀, àní Jésù Krístì, àmín.