Rírí Ààbò kúrò nínú àwọn Ìjì Ayé
Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀ ni ààbò tí gbogbo wa nílò, láìka àwọn ìjì tí ó nna ìgbé ayé wa.
Sẹ́hìn ní ààrin méjì àwọn àádọ́rũn, ní ìgbà àwọn ọdún mi ní ilé ìwé gíga, mo jẹ́ ara àwọn Ikọ̀ Kẹrin ti Ilé Iṣẹ́ Panápaná ti Santiago ní Chile. Nígbàtí mo nṣiṣẹ́ níbẹ̀, mo gbé ní ibi àgọ́ panápaná bíi ara ọlọ́dẹ òru. Bí ọdún ṣe nparí lọ, a sọ fún mi pé mo nílati wà ní ibi àgọ́ panápaná ní Àìsùn Ọdún Tuntun nítorípé ní ọjọ́ náà ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé ìgbà gbogbo ni pàjáwìrì ma nwáyé. Pẹ̀lú ìyanu, mo fèsì pé. “Lõtọ́?”
Ó dára, mo rántí dídúró pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ mi nígbàtí, ní ààrin òru, àwọn iná ìṣeré bẹ̀rẹ̀ sí yìn ní ìsàlẹ̀ ilú Santiago. A bẹ̀rẹ̀ sí dì mọ́ ara wa pẹ̀lú àwọn èrò dáradára fún ọdún tuntun náà. Ní òjijì, àwọn aago ibi àgọ́ panápaná náà bẹ̀rẹ̀ síi dún, ti ó ntumọ̀ sí pé pàjáwìrì kan wà. A mú àwọn irinṣẹ́ wa a sì fò sí inú ẹ̀rọ panápaná. Ní ọ̀nà wa sí ibi pàjáwìrì náà, bí a ti kọjá àwọn àkójọ àwọn ènìyàn tí wọn nṣe àjọyọ̀ ọdún tuntun, mo wòye pé wọ́n kún fún ìwà kò-kàn-mí àti àìsí àníyàn. Wọ́n ngbafẹ́ wọ́n sì ngbadùn òru ti ìgbà ooru náà. Síbẹ̀ ní ibikan ní itòsí, àwọn ènìyàn tí a nkánjú lọ láti ràn lọ́wọ́ wà nínú ìdààmú nlá.
Ìrírí yi ràn mí lọ́wọ́ láti mọ̀ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbé ayé wa le fi ìgbà míràn lọ déédé, àkókò kan yío wá fún olukúlùkù wa nígbàtí a ó dojúkọ àwọn ìpèníjà àti àwọn ìjì àìròtẹ́lẹ̀ tí yío ti òsúnwọ̀n agbára wa láti fi ara dà. Àwọn ìpèníjà àfojúrí, ti ọpọlọ, ti ẹbí, àti ti iṣẹ́ síṣe; àwọn àjálù ti àdánidá; àti àwọn ọ̀rọ̀ míràn ti ìyè tàbí ikú jẹ́ díẹ̀ lára àwọn àpẹrẹ àwọn ìjì tí a ó dojúkọ ní ayé yi.
Nígbàti àwọn ìjì wọ̀nyí bá dojú kọ wa, a máa nfi ìgbà púpọ̀ ní àwọn ìmọ̀lára àìnírètí àti ẹ̀rù. Ààrẹ Russell M. Nelson sọ pé, “Ìgbàgbọ́ ni òògùn fún ẹ̀rù”—ìgbàgbọ́ nínú Olúwa wa Jésù Krístì (“Ẹ Jẹ́kí Ìgbàgbọ́ Yín Hàn,” Lìàhónà, Oṣù Karũn 2014, 29). Bí mo ti rí àwọn ìjì tí wọ́n ní ipa lórí ìgbé ayé àwọn ènìyàn, mo ti pinnu pé èyíkéyí onírúurú ìjì tí ó le ma nà wá—láìka sí bóyá ọ̀nà àbáyọ wà sí i tàbí bóyá òpin wà ní àrọ́wọ́tó—ibi ààbò kanṣoṣo ni ó wà, ó sì jẹ́ ọ̀kannáà fún gbogbo onirúurú àwọn ìjì. Ibi ìsádi ẹyọ kan tí a pèsè láti ọwọ́ Baba wa Ọ̀run ni Olúwa wa Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀.
Kò sí ẹ̀nikankan ní ara wa tí a yọ kúrò ní dídojúkọ àwọn ìjì wọ̀nyí. Hẹ́lámánì, wòlĩì kan nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì kọ́ni báyi pé: “Ẹ rántí pé ní ori àpáta Olùràpadà wa, ẹnití í ṣe Krístì, Ọmọ Ọlọ́run, ni ẹyin gbọdọ̀ kọ́ ìpìlẹ̀ yin lé; pé nigbati èṣù bá rán ẹ̀fúùfù líle rẹ̀ jáde, bẹ́ẹ̀ni, ọ̀pá rẹ̀ ninu ìjì, bẹ́ẹ̀ni, nigbati gbogbo awọn òkúta yìnyín rẹ̀ ati ìjì líle rẹ̀ bá rọ̀ lé yín, kì yíò le ní agbára ní orí yín lati fà yín sọ̀kalẹ̀ sí inú ọ̀gbun òṣì ati ègbé àìlópin, nitori àpáta èyítí a kọ́ yín lé lórí, èyítí í ṣe ìpìlẹ̀ tí ó dájú, ìpìlẹ̀ èyítí bí àwọn ènìyàn bá kọ́ lé, wọn kì yíò lè ṣubú” (Hẹ́lámánì 5:12).
Alàgbà Robert D. Hales, ẹnití ó ní àwọn ìrírí tirẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìji pípẹ́ títí, sọ pé, “Ìyà jíjẹ jẹ́ ti gbogbo ayé; bí a ti ndojúkọ ìyà jíjẹ jẹ́ ti ẹni kọ̀ọ̀kan. Iyà jíjẹ le gbà wá ní ọ̀kan nínú àwọn ọ̀nà méjì. Ó le jẹ́ ìrírí afúnni ní okun àti asọnidi mímọ́ bí ó bá dàpọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́, tàbí ó le jẹ́ ipá apanirun nínú ìgbé ayé wa bí a kò bá ní ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ètùtù ṣíṣe tí Olúwa” (“Ìbanújẹ́ Rẹ ni A Ó Yípadà sí Ayọ̀,” Ensign, Oṣù Kọkànlá 1983, 66).
Kí a le gbádùn ààbò tí Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀ fi lélẹ̀, a gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀—ìgbàgbọ́ kan tí yío fun wa ní ààyè láti díde tayọ gbogbo àwọn ìrora ti àfinúrò tí o ní òdiwọ̀n, ti ayé. Ó ti ṣe ìlérí pé Òun yío mú àwọn àjàgà wa fúyẹ́ bí a bá wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nínú gbogbo ohun tí a bá nṣe.
“Ẹ wa sí ọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí nṣíṣẹ, tí a sì di ẹrù wúwo lé lórí, èmi yíò sì fi ìsinmi fún yín.
“Ẹ gba àjàgà mi sí ọrùn yín, kí ẹ sì máa kọ́ ẹ̀kọ́ ní ọ̀dọ̀ mi; nítorí onínú tútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ni èmí; ẹ̀yin ó sì rí ìsinmi fún ọkàn yín.
“Nítorí àjàgà mi rọrùn, ẹrù mi sì fúyẹ́ (Matteu 11:28-30; bákannáà wo Mosiah 24:14–15).
A sọ ọ́ pé “sí ẹni náà tí ó ní ìgbàgbọ́, àsọyé kan kò ṣe dandan. Sí ẹni náà láìní ìgbàgbọ́, àsọyé kan kò ṣeéṣe.” (Ọ̀rọ̀ yi ni a ti tọ́ka rẹ̀ sí Thomas Aquinas ṣùgbọ́n ó ṣeéṣe kí ó jẹ́ àkékúrú àwọn ohun tí ó kọ́ni.) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a ní òye tí ó ní òdiwọ̀n nípa àwọn ohun tí ó nṣẹlẹ̀ ní orí ilẹ̀ ayé níhĩn, àti pé ní ìgbà púpọ̀ a kìí ní àwọn ìdáhùn sí ìbéèrè ti kínníṣe. Kinníṣe ti èyí nṣẹlẹ̀? Kinníṣe ti èyí nṣẹlẹ̀ sí mi Kínni ó yẹ kí èmi ó kọ́? Nígbàtí àwọn ìdáhùn bá fò wá ru, nígbànáà ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Olùgbàlà wa sọ sí Wòlíì Joseph Smith ní Ọgbà Ẹwọn Liberty jẹ́ mímúlò pátápátá:
“Ọmọ mi, àláfíà fún ọkàn rẹ; àwọn ìrora rẹ àti àwọn ìpọ́njú yíò jẹ́ fún ìgbà díẹ̀;
“Àti nígbànáà, bí o bá fi ara dà á dáradára, Ọlọ́run yíò gbé ọ ga sókè; ìwọ yíò borí gbogbo ọ̀tá rẹ” (D&C 121:7–8).
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn nítòótọ́ gbàgbọ nínú Jésù Krístì, ìbéèrè tí ó ṣe kókó ni bóyá a gba Òun gbọ́ àti bóyá a gba àwọn ohun tí Ó kọ́ wa gbọ́ àti tí ó sọ fún wa láti ṣe. Bóya ẹnikan le rò pé, “Kínni Jésù Krístì mọ̀ nípa ohun tí ó nṣẹlẹ̀ sí mi? Báwo ni Ó ṣe mọ ohun tí mo nílò láti ní ìdùnnú?” Ní tòótọ́, Olùràpadà àti Alágbàwí wa ni ẹni náà tí wòlíì Isaiah ntọ́ka sí nígbàti ó sọ pé:
“A kórira Rẹ̀ a sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn; ẹni ọ̀pọ̀ ìrora-ọkàn, tí ó sì mọ́ ìbànújẹ́.…
“Dájúdájú ó ti fi ara dà ìbànújẹ́ wa, ó sì ti gbé ìrora-ọkàn wa. …
“Ṣùgbọ́n a ṣá a lọ́gbẹ́ nítorí ìrékọjá wa, a pa á lára nítorí àìṣedédé wa; ìbáwí àlàáfíà wa wà ní ara rẹ̀, àti nípa ìnà rẹ̀ ni a mú wa ní ara dá” (Isaiah 53:3–5).
Àpóstélì Pétérù kọ́ni bákannáà nípa Olùgbàla, wípé, “Ẹnití òun tikara rẹ̀ gbé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa nínú àgọ́ ara tirẹ̀ ní orí igi náà, pé kí àwa, ní kíkú sí àwọn ẹ̀ṣẹ̀, le yè sí òdodo: nípa ìnà ẹni náà tí a mú yín ní ara dá” (1 Pétérù 2:24).
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àkókò ikú ajẹ́rĩkú ti Pétérù ti nsúnmọ́, àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò kún fún ìbẹ̀rù àti iyèméjì; dípò bẹ́ẹ̀, ó kọ́ àwọn Ènìyàn Mímọ́ láti “yọ̀,” àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n wà “nínú ìwúwo ọkàn nípasẹ̀ onírúurú àwọn ìdánwò.” Pétérù gbà wá nímọ̀ràn láti rántí “ìdánwò ìgbàgbọ́ [wa], … bí a tilẹ̀ dán an wò pẹ̀lú iná,” yío darí sí “ìyìn àti ọlá àti ògo ní ìfarahàn ti Jésù Krístì” àti sí “ìgbàlà ti ẹ̀mí [wa]” (1 Peterù 1:6–7, 9).
Pétérù tẹ̀síwájú:
“Olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ máṣe rò ó sí ohun àjèjì nípa ìdánwò gbígbóná èyítí a ó fi dan yín wò, bí ẹnipé àwọn ohun àjèjì ti ṣẹlẹ̀ sí yín:
Ṣùgbọ́n ẹ máa yọ̀, níwọ̀n ìgbàtí ẹ̀yin jẹ́ alábapín nínú àwọn ìjìyà ti Krístì; pé, nígbàtí a ó fi ògo rẹ̀ hàn, inú yín yío dùn bákannáà pẹ̀lú ayọ̀ nlá” (1 Peterù 4:12–13).
Ààrẹ Russell M. Nelson kọ́ni pé “Àwọn Ènìyàn Mímọ́ le ní inú dídùn ní abẹ́ ipò gbogbo. … “Nígbàtí ìfojúsùn ti ìgbé ayé wa bá wà ní orí ètò ìgbàlà ti Ọlọ́run … Àti Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ, a lè ní ìmọ̀lára ayọ̀ láìka ohun tí ó nṣẹlẹ̀—tàbí tí kò ṣẹlẹ̀ sí—nínú ìgbé ayé wa. Ayọ̀ nwá láti ọ̀dọ̀ àti nítorí Rẹ̀. Òun ni orísun gbogbo ayọ̀” (“Ayọ̀ àti Ìforítì ti Ẹ̀mí,” Liahónà, Oṣù Kọkànlá. 2016, 82).
Ní tòótọ́, ó rọrùn láti sọ àwọn ohun wọ̀nyí nigbàtí a kò bá sí nínú ìjì kan jù láti gbé ìgbé ayé kí a sì mú wọn lò ní àkókò ìjì náà. Ṣùgbọ́n bíi arákùnrin yín, mo ní ìrètí pé ẹ le mọ̀lára pé mo fẹ́ nítõtọ́ láti ṣe àbápín pẹ̀lú yín bí ó ti níyelórí tó láti mọ̀ pé Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀ ni ààbò tí gbogbo wa nílò, láìka àwọn ìjì tí ó nna ìgbé ayé wa.
Mo mọ̀ pé gbogbo wa jé ọmọ Ọlọ́run, pé Ó fẹ́ràn wa, àti pé a ko nìkan wà. Mo pè yín láti wá kí ẹ sì ri pé Ó le sọ àwọn ẹrù yín di fífuyẹ́ kí ó sì di ibi ìsádi tí ẹ nwá. Ẹ wá kí ẹ sì ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti rí ibi ìsádi náà tí wọ́n npòngbẹ fún. Ẹ wá kí ẹ sì dúró pẹ̀lú wa nínú ibi ìsádi yi, èyítí yío ràn yín lọ́wọ́ láti fi ara gba àwọn ìjì ayé. Kò sí iyè méjì nínú ọkàn mi pé bí ẹ bá wá, ẹ ó rí, ẹ ó ṣe ìrànlọ́wọ́, ẹ ó sì dúró.
Wòlíì Almà ṣe ìjẹ́rìí yí sí ọmọkùnrin rẹ̀ Hẹ́lámánì: “Èmi mọ̀ pé ẹnìkẹ́ni tí ó bá fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sí inú Ọlọ́run ni a ó tì lẹ́hìn nínú àwọn àdánwò wọn; àti àwọn lãlã wọn, àti àwọn ìpọ́njú wọn, a ó sì gbé e sókè ní ọjọ́ ìkẹhìn” (Alma 36:3).
Olùgbàlà Funrarẹ̀ wípé:
“Ẹ jẹ́kí ọkàn yín ní ìtùnú … ; nítorí gbogbo ẹran ara wà ní ọwọ́ mi; ẹ dúró jẹ́ẹ́ kí ẹ sì mọ̀ pé Èmi ni Ọlọ́run. …
Nítorínáà, ẹ má bẹ̀rù àní títí dé ikú; nítorí nínú ayé yi ayọ̀ yín kò kún, ṣùgbọ́n nínú èmi ayọ yín kún” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 101:16, 36
Orin “Dúró Jẹ́ẹ́, Ọkàn Mi,” tí ó ti fí ọwọ́ tọ́ ọkàn mi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, ní àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú fún ọkàn wa. Àwọn ọ̀rọ̀ náà kà báyi:
Dúró jẹ́ẹ́, ọkàn mi: wákàtí náà nkánjú lọ
Nígbàtí a ó wà pẹ̀lú Olúwa títí láé,
Nígbàtí ìjákulẹ̀, ìbànújẹ́, àti ẹ̀rù bá ti lọ,
A ó gbàgbé ẹ̀dùn ọkàn, ayọ̀ pípé ti ìfẹ́ yío padà sípò.
Dúró jẹ́ẹ́, ọkàn mi: Nígbàtí ìyàtọ̀ àti ẹkún bá ti lọ,
Gbogbo wa ní ààbò àti bíbùkún a ó pàdé ní ìkẹhìn. (Àwọn orin, no. 124)
Bí a ti ndojúkọ àwọn ìjì ayé, mo mọ̀ pé bí a bá ṣe aàpọn wa tí ó dára jùlọ tí a sì gbẹ́kẹ̀lé Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀ bíi ààbò wa, a ó bùkún wa pẹ̀lú ìtura, ìtùnú, okun, ìkóra-ẹni-ní-ìjánu, àti àlàáfíà tí a nwá, pẹ̀lú ìdánilójú nínú ọkàn wa pé ní ìparí àkókò wa ní ayé níhĩn, a ó gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa: “O ṣeun, ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ rere àti olõtọ́: … wọlé sí inu ayọ̀ olúwa rẹ” (Matteu 25:21 Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.