Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìdàpọ̀ ní Àṣeyọrí Iṣẹ́ Ọlọ́run
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2020


Ìdàpọ̀ ní Àṣeyọrí Iṣẹ́ Ọlọ́run

Ọ̀nà tí o ṣe jùlọ láti mú agbára ọ̀run wa sí ìmúṣẹ ni láti ṣiṣẹ́ papọ̀, bíbùkún nípa agbára àti àṣẹ oyèàlúfáà.

Ẹ̀yin arábìnrin àti arákùnrin ọ̀wọ́n, ó jẹ́ ayọ̀ kan láti wà pẹ̀lú yín. Níbikíbi tí ẹ ti ngbọ, Mo nawọ́ dídìmọ́ra si ẹ̀yin arábìnrin mi àti ìbọnilọ́wọ́ àtọkànwá si ẹ̀yin arákùnrin mi. A jẹ́ dídàpọ̀ nínú iṣẹ́ Olúwa.

Nígbà tí a bá ronú nípa Àdàmu àti Éfà, èrò wa nígbà gbogbo jẹ́ nípa ìgbé ayé àláfíà àti ẹlẹ́wa wọn nínú Ọgbà Édẹ́nì. Mo ròó pé ojú ọjọ́ wọn dára nígbà gbogbo—kò gbóná kò si tutù jù—àti nínú ọ̀pọ̀, àwọn èso aládùn àti àwọn ewébẹ̀ dàgbà ní àrọwọ́tó kí wọn le jẹ ohunkóhun ti wọn fẹ́ràn. Nígbà ti èyí ti jẹ ayé titun fun wọn, ohun púpọ̀ wà láti wá rí, nítorínáà ojojúmọ́ jẹ́ ohun tí o wuni bí wọ́n ti ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ìgbé ayé ẹranko tí wọn si ṣàwárí àwọn àyíká ẹlẹ́wa wọn. A sí fún wọn ni àwọn òfin láti pa mọ́ wọn si ni oríṣiríṣi ọ̀nà láti pa àwọn ìtọ́sọ́nà náà mọ, èyí ti o fa díẹ̀ nínú àìfọnkànbalẹ̀ àti ẹ̀rù.1 Ṣùgbọ́n bi wọ́n ti ṣe àwọn ìpinnu tí o yi ayé wọn padà láéláé, wọ́n kọ́ láti ṣiṣẹ́ papọ̀ wọn si jẹ́ dídàpọ̀ ní àṣeyọrí èrò tí Ọlọ́run ní fún wọn—àti fún gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀.

Bayi ya àwòrán lọ́kọláya yi kannáà ní ayé ikú. Wọn nílò láti ṣe làálàá fún oúnjẹ wọn, díẹ̀ nínú àwọn ẹranko ka wọn kún oúnjẹ, àwọn ìpèníjà ti o nira wà tí a lè borí nípa bi wọn ṣe dámọ̀ràn tí wọn si gbàdúrà papọ̀ nìkan. Mo wòye pé ìgbà díẹ̀ wà tí wọn ni àwọn èrò tí o yàtọ̀ nípa bi wọ́n ṣe lè dojúkọ àwọn ìpèníjà wọn Síbẹ̀síbẹ̀, nínú Ìṣubú náà, wọ́n ti kọ́ pé ó ṣe pàtàkì láti ṣe ìṣe nínú ìdàpọ̀ àti ìfẹ́. Ní kíkọ́ tí wọn gba láti orísun ti ọ̀run, a kọ́ wọn ni ètò ìgbàlà àti ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ìhìnrere ti Jésù Krístì tí o jẹ́ ki ètò náà ṣeéṣe. Nítorí wọ́n ní òye pé àfojúsùn ti ayé àti ti ayérayé báramu, wọn ri ìtẹ́lọ́rùn àti àṣeyọrí ní kíkọ́ láti ṣiṣẹ́ nínú ìfẹ́ àti òdodo papọ̀.

Àwòrán
Ádámù àti Éfà nkọ́ àwọn ọmọ wọn

Bí a ti bí ọmọ fún wọn, Ádámù àti Éfà kọ́ ẹbí wọn ní ohun tí wọ́n ti kọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ ọ̀run. Wọn kọjú sí ríran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti ni òye àti láti gbá àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ tí yio mú inú wọn dùn ní ayé yi mọ́ra, àti láti múra sílẹ̀ láti padà sí ọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn ọ̀run lẹ́hìn tí wọ́n bá ti ṣe àlékún agbára wọn tí wọ́n sì ti jẹri ìgbọnràn wọn sí Ọlọ́run. Nínú ètò náà, Ádámù àti Éfà kọ́ láti mọ rírì oríṣiríṣi agbára àti láti ti ara wọn lẹ́hìn ní iṣẹ́ ayérayé wọn.2

Bí àwọn ọgọrun àti ẹgbẹ̀rún ọdùn ti wá ti wọn sì lọ, híhàn kedere ìmísí àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin àti ìdásí ìgbáralé di ìbòju pẹ̀lú ìṣìwífúnni àti àìgbọ́raẹniyé. Ní àárín àkokò ti ìbẹ̀rẹ̀ ìyanu ni Ọgbà Édẹ́nì sí àkokò yí, ọ̀ta ni àṣeyọrí nípa ipa rẹ gan nínú àfojúsùn rẹ̀ láti pín àwọn okùnrin àti obìnrin níyà ní ìgbìyànjú rẹ̀ láti ṣẹ́gun ẹ̀mí wa. Lúsíférì mọ̀ pé bi ohun bá ba ìṣọ̀kan tí àwọn ọkùnrin ati obìnrin ní jẹ́, bí ó bá dà wa rú nípa yíyẹ tọ̀run àti àwọn ojúṣe májẹ̀mú, yíò ṣe àṣeyọrí nípa pípa àwọn ẹbí run, tí wọn jẹ́ pàtàki ọ̀kan lára ayérayé.

Sàtánì ru àfiwéra sókè gẹ́gẹ́bí ohun èlò láti dá ìmọ̀lára gígajù tàbi rẹlẹ̀ju sílẹ̀, ní sísápamọ́ sábẹ́ òtítọ́ ayérayé pé ìyàtọ̀ ìmọ̀lára àwọn ọkùnrin àti obìnrin wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run o sì níye tí ó dọ́gba. Ó ti gbìyànjú láti já ìdásí àwọn obìnrin kulẹ̀ nínú ẹbí àti àwùjọ ìbílẹ̀, nítorínáà ó ndín agbára gíga wọn kù fún rere. Àfojúsùn rẹ ni láti ṣe agbára ìtiraka dípò ṣíṣe àjọyọ̀ ìdásí àràọ̀tọ̀ àwọn ọkùnrin àti obìnrin ti wọ́n nbáraṣepọ̀ láti dásí ìṣọ̀kan.

Nítorínáà, ní àwọn ọdún àti ní àyíká ayé, níní òye kíkún ti ọ̀run lọ́kọ̀ọ̀kan àti síbẹ̀ yíyàtọ̀ ìdásí àti ojúṣe àwọn obìnrin àti ọkùnrin farasin púpọ̀. Àwọn obìnrin ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwùjọ di oníbara sí àwọn ọkùnrin ju alabaṣepọ ìfẹ̀gbẹkẹgbẹ, àwọn ìṣe wọn dínkù sí ọ̀nà tóóró. Ìlọsíwájú ti ẹ̀mí lọ sílẹ̀ lati tan lákokò òkùnkùn; lootọ, ìmọ́lẹ̀ ẹ̀mí kékeré le wọ ọkàn àti ẹ̀mí wa ni ìgbésẹ̀ àṣà ìjọba.

Àti pé nígbànáà ìmọ́lẹ̀ ìhìnrere ìmúpadàbọ̀sípò náà hàn “borí dídán ju òòrùn”3 nígbà tí Ọlọ́run Bàbá àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, farahàn sí ọmọdékùrin náà Joseph Smith ní kùtùkùtù ìgbà ìrúwé 1820 ní ilẹ̀-igi tí a yasimímọ́ ni òkè-ìpínlẹ̀ New York . Ìṣẹ̀lẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ ìtújáde ìgbàlódé ìfihàn láti ọ̀run. Ọ̀kan lára àwọn ohun èlò Ìjọ àtilẹ̀ba Krístì ti a múpadàbọ̀sípò ni àṣẹ oyèàlúfà Ọlọ́run. Bí ìtẹ̀síwájú ìmúpadàbọ̀sípò tí ṣi, àwọn ọkùnrin àti obìnrin bẹ̀rẹ̀ láti mọ ní ọ̀tun pàtàkì àti agbára láti ṣiṣẹ́ bíi àwọn alabaṣepọ̀, tí o ni àṣẹ àti ìdarí ni iṣẹ́ mímọ́ láti ọwọ́ Rẹ̀.

Àwòrán
Ìkójọ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́

Ni 1842, nígba tí àwọn obìnrin Ìjọ oniyẹ fẹ dá ẹgbẹ́ oníṣẹ́ ti yio ṣe ìrànwọ́ nínú iṣẹ́ náà, Ààrẹ Joseph Smith ní ìmọ̀lára làti ṣètò wọn “lábẹ́ oyèàlúfà lẹ́hìn ìlànà oyèàlúfáà.”4 Ó wípé, “ Báyìí mo fún yín ní kọ́kọ́rọ́ náà ní orúkọ Ọlọ́run; … èyí ni ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọjọ́ dídára.”5 Àti pé láti ìgbà ti a ti gba kọ́kọ́rọ́ yẹn, ẹ̀kọ́, òṣèlú, àti ànfàní ọrọ̀ ajé fún àwọn obìnrin ti bẹ̀rẹ̀ láti máa gbòòrò káàkiri ayé.6

Ìṣètò Ìjọ titun yí fún àwọn obìnrin, tí a pe ní Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́, kò rí bi ẹgbẹ́ àwọn obìnrin míràn ọjọ́ òní nítorí a dá sílẹ̀ láti ọwọ wòlíì tí ó lo àṣẹ oyèàlúfáà láti fún àwọn obìnrin ní àṣẹ, àwọn ojúṣe mímọ́, àti àwọn ipò olóyè laarin ìjọ, kìí ṣe láìsí ara rẹ̀.7

Láti ọjọ Joseph Smith títi dé ti wa, ìmúpadàbọ̀sípò ohun gbogbo tí o n lọ lọ́wọ́ ti mú ìfòyehàn bá ìṣeéṣe àṣẹ àti agbára oyèàlúfà ni ríran àwọn ọkùnrin àti obìnrin lọ́wọ́ láti ṣe àṣepé àwọn ojúṣe ti ọ̀run wọn. Láìpẹ́ a ti kọ́ pé àwọn obìnrin tí a ya sọ́tọ̀ lábẹ́ ìdarí ẹni tí o ni kọ́kọ́rọ́ oyèàlúfáà pẹ̀lú àṣẹ oyèàlúfà nínú ìpè wọn.8

Ní oṣù kẹwa 2019, Ààrẹ Russell M. Nelson kọ́ni pé àwọn obìnrin tí wọn ti gba ìrónilágbára nínú tẹ́mpìlì ní agbára oyèàlúfà nínú ayé wọn àti ilé wọn bí wọ́n ti n pa àwọn májẹ̀mú mímọ́ wọ̀n nì tí wọn da pẹ̀lú Ọlọ́run mọ́.9 Ó ṣàlàyé pé “àwọn ọ̀run ṣí bẹ́ẹ̀gẹ́gẹ́ sí àwọn obìnrin tí wọ́n ti gba ìrónilágbára ẹ̀bùn pẹ̀lú agbára Ọlọ́run tó nsàn látinú àwọn májẹ̀mú oyèàlùfáà bí wọ́n ṣe wà sí àwọn ọkùnrin tí wọ́n ní oyèàlùfáà.” Ó sì gba gbogbo obìnrin níyànjú láti, “ní ẹ̀tọ́ lórí agbára Olùgbàlà láti ràn ẹbí yín àti àwọn míràn tí ẹ fẹ́ràn.”10

Njẹ kíni ìyẹn túmọ̀ sí fún ẹ̀yin àti èmi? Báwo ni òye àṣẹ oyèàlùfáà àti agbára ṣe yi ayé wa padà? Ọ̀kan nínú àwọn kọ́kọ́rọ́ ni lati ní òye pé nígbà tí àwọn obìnrin àti ọkùnrin bá ṣiṣẹ́ papọ̀ a ní àṣeyọrí púpọ̀ ju ki a dá ṣiṣẹ́ lọ.11 Àwọn ojúṣe wa jẹ́ ìbámu dípò ìdíje. Bíótilẹ̀jẹ́pé a kò fún àwọn obìnrin ní àṣẹ sí ipò oyèàlúfà, bí a ti ṣe àkíyèsí tẹ̀lẹ́, àwọn obìnrin jẹ́ alábùnkúnfún pẹ̀lú agbára oyèàlúfáà bí wọ́n ti n pa àwọn májẹ̀mú wọn mọ, tí wọ́n si n ṣiṣẹ́ pẹlú àṣẹ oyèàlúfáà ní gbà tí a bá yàwọ́n sọ́tọ̀ fún ìpè kan.

Ní ọjọ́ dídára kan oṣù Kẹ́jọ, Mo ní ànfànì láti joko pẹ̀lú Ààrẹ Russell M. Nelson ní ilé Joseph àti Emma Smith tí a túnkọ́ ni Harmony, Pennsylvania, nítòsí ibi tí a ti mú Oyèàlúfáà Áárónì padàsípò ni àwọn ọjọ ìkẹhìn wọ̀nyí. Nínú ìbárasọ̀rọ̀ wa, Ààrẹ Nelson sọ́rọ̀ nípa pàtàkì ojúṣe tí àwọn obìnrin kó ní Ìmúpadàbọ̀sípò.

Ààrẹ Nelson: “Ọ̀kan lára àwọn apákan pàtàkì tí mo rántí nígbatí mó dé ibi Ìmúpadàbọ̀sípò yí ni ojúṣe pàtàkì tí àwọn obìnrin ṣe nínú Ìmúpadàbọ̀sípò.

“Nígbàtí Joseph kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ àyípadà-èdè Ìwé ti Mọ́mọ́nì, tani ó kọ̀wé náà? Ó dára, òun ṣe díẹ̀, ṣùgbọ́n kìí ṣe ọ̀pọ̀. Emma wọlé.

“Àti pé nígbànáà mo ronú nípa Joseph tó wọ inú igi lọ láti gbàdúrà nítòsí ilé wọn ní Palmyra, New York. Níbo ni ó lọ̀? Ó lọ sí Igbó Mímọ́. Kínìdí tó fi lọ síbẹ̀? Nítorí ibẹ̀ nì màmá lọ nígbàtí ó fẹ́ gbàdúrà.

“Àwọn méjì náà ni obìnrin tí wọ́n ní ojúṣe pàtàkì nínú Ìmúpadàbọ̀sípò Oyèàlùfáà àti Ìmúpadàbọ̀sípò Ìjọ. Láìṣiyèméjì, a lè wípé àwọn ìyàwó wa jẹ́ pàtàkì bẹ́ẹ̀ loni bí wọ́n ṣe jẹ́ nígbànáà. Bẹ́ẹ̀ni wọ́n jẹ́.”

Bíiti Emma àti Lucy àti Joseph, a nṣe jùlọ nígbàtí a ba nfẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ arawa ti a si ní ìrẹ́pọ̀ ni ohun tí a fẹ da làti di ọmọ ẹ̀hìn Jésù Krístì ki a si ran àwọn míràn lọ́wọ́ ní ipá ọ̀nà náà.

A kọ́ wa pé “oyèàlúfà bùkún ayé àwọn ọmọ Ọlọ́run ni àwọn ọ̀nà àìlóhùnkà. … Ni àwọn ìpè [Ìjọ], àwọn ìlànà tẹ́mpìlì, àwọn ìbáṣepọ̀ ẹbí, àti ìdákẹ́, iṣẹ́ ìránṣẹ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan, àwọn obìnrin àti ọkùnrin Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-Ìkẹhìn lọ síwájú pẹ̀lú agbára àti àṣẹ oyèàlùfáà. Ìgbáralé àwọn ọkùnrin àti obìnrin ni ṣíṣe àṣepé iṣẹ́ Ọlọ̀run nípa agbára Rẹ̀ jẹ́ kókó ti ìhìnrere Jésù Krístì tí a múpadàbọ̀sípò nípa Wòlíì Joseph Smith.”22

Ìṣọ̀kan jẹ pàtàkì si iṣẹ́ tọ̀run a ní ànfàní àti ìpe láti ṣe, ṣùgbọn kò dédé ṣẹlẹ̀. Ó gba àkokò àti ìtiraka láti dámọ̀ràn papọ̀—láti fetísílẹ̀ sí arawa, ní òye ìwò-àmì àwọn ẹlòmíràn, kí a si ṣe àbápín àwọn ìrírí—ṣùgbọ́n ètò náà jásí àwọn ìpinnu ìmísí síi. Bóyá nílé tàbí ni àwọn ojúṣe Ìjọ wa, ọ̀nà tí o ṣe jùlọ láti mú agbára ọ̀run wa sí ìmúṣẹ niláti ṣiṣẹ́ papọ̀, bíbùkún nípa agbára àti àṣẹ oyèàlúfáà ni yíyàtọ̀ síbẹ̀ àwọn ojúṣe tó báramu.

Kí ni àjọṣepọ̀ náà jọ nínú ayé àwọn obìnrin májẹ̀mú loni? Ẹ jẹ́ ki n ṣe àbápín àpẹrẹ kan.

Àwòrán
Tọkọtaya lórí kẹ̀kẹ́ tándẹ́mù

Alison àti John ní àjọṣepọ̀ àràọ̀tọ̀. Wọ́n wa kẹ̀kẹ́ tándẹ́mù nínú eré ìje kúkurú àti gígùn. Láti fi àṣeyorí ṣetán lori ọkọ̀, àwọn olùwà méjèjì gbọ́dọ̀ wà ní ìbárẹ́. Wọn gbọdọ̀ tẹ̀ si ọ̀nà kan náà ní àkokò tí ó tọ́. Ọ̀kan kò lè borí òmíràn, ṣùgbọ́n wọ̀n gbọdọ̀ bárasọ̀rọ̀ yékéyéké àti kí ẹnìkọ̀ọ̀kan sa ipa ti ọkùnrin tàbí obìnrin. Ọ̀gágun náà, níwájú, ní àkóso lórí ìgbà tí yio dúró tàbí ìgbàtí yíò dìde. Adíná, lẹ́hìn, nílò láti fetísílẹ̀ si ohun tí o nlọ àti láti ṣetàn láti fúnni ní àfíkùn agbára bí wọ́n bá fà sẹ́hìn díẹ̀ tàbí yára síi bí wọ́n bá sún mọ́ àwọn awakẹ̀kẹ́ míràn jù. Wọn gbọ́dọ̀ ti ara wọn lẹ́hìn láti ní ilọsíwájú àti láti ṣe àṣeyọrí ìfojúsùn wọn.

Alison ṣàlàyé: “Fún ìgbà díẹ̀ àkọ́kọ́, ẹni ti o wà ní ipò ọgágun yio wípé ‘Díde’ nígbà tí a bá nílò láti dìde àti ‘Dúró’ nígbà ti a nílò láti dúró wíwakẹ̀kẹ́. Nígbà díẹ̀, ẹni tí o jẹ́ adíná kọ́ láti sọ nígbà ọ̀gágun ba fẹ́ dde tàbi dúró, kò sì sí ọ̀rọ̀ kankan ti a niláti sọ. A kọ́ láti ní ìmísí bi ẹnikọ̀ọ̀kan ti nṣe àti láti kí a lè sọ ìgbà tí ẹnì kan ba ntiraka àti [nígbànáà] tí ẹlòmíràn bá gbìyànjú láti yára sókè. Ó ní ṣiṣe pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé àti ṣíṣiṣẹ́ papọ̀.”13

John àti Alison nísọ̀kan kìí ṣe bí wọ́n ti nwa kẹ̀kẹ́ wọn nìkan, ṣùgbọ́n wọ́n níṣọ̀kan nínú ìgbeyàwó wọn bàkannáà. Ẹnìkọ̀ọ̀kan nfẹ́ ìdùnnú ẹlòmíràn ju ara rẹ̀ lọ; ẹnìkọ̀ọ̀kan nwá rere fún ẹlòmíràn wọ́n si nṣiṣẹ́ láti borí ohun tí kò dára to nínú arákùnrin tàbí arábìnrin fúnrarẹ̀. Wọ́n ndarí níkọ̀ọ̀kan wọ́n si nfúnni síi nígbà tí alábaṣèpọ̀ kan ba ntiraka. Ẹnìkọ̀ọ̀kan mọ rírì àwọn ìdásí àwọn míràn àti láti rí ìdáhùn dídárasi fún àwọn ìpèníjà wọn bi wọ́n ṣe da àwọn ẹ̀bùn ati ohun èlò wọn pọ̀. Wọ́n sopọ̀ nitòótọ́ pẹ̀lú ara wọn nípa ìfẹ́ bi Krístì.

Dídionímísí si pẹ̀lú àwòṣetọ̀run ní ṣíṣe pẹ̀lú iṣẹ́ papọ̀ ní ìṣọ̀kan ṣe kókó loni yí ti àwọn ọ̀rọ̀ “èmi-àkọ́kọ́” to yí wa ká. Àwọn obìnrin ni ìyàtọ alágbára, ẹ̀bùn ti ọ̀run14 a si fún wọn ni àwọn ojúṣe àràọ̀tọ̀, ṣùgbọ́n àwọn yẹn kò sí mọ́—tàbí o ti dínkù—ní pàtàkì ju ẹ̀bùn àwọn ọkùnrin àti àwọn ojúṣe. Gbogbo wọn ni a ṣe tí a sì nílò láti mú ètò ti ọ̀run Bàbá Ọ̀run fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ọmọ Rẹ̀ ṣẹ ní ànfàní dídárajùlọ láti mu agbára ti ọ̀run ọkùnrin tàbi obìnrin ṣẹ.

Loni, “a nílò àwọn obìnrin tí o ní ìgboyà àti ìran Iya wa Éfà”15 láti dàpọ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin ní mímú àwọn ọkàn wa sọ́dọ̀ Krístì.16 Àwọn ọkùnrin nílò láti jẹ́ alábaṣepọ tòótọ́ ju ki a gba ojúṣe tábi “díbọ́n” bíi alabaṣepọ nígbà tí àwọn obìnrin nṣiṣẹ́ ti o pọ̀ jù. Àwọn obìnrin nílò láti “lọ síwájú [láti] gba [ẹ̀tọ́] ohun ti o tọ àti ibi ti o yẹ”17 bí alabaṣepọ ju ríronú pé wọ́n nílò láti ṣe é fúnrawọn tàbí dúró ki a sọ ohun ti a ó ṣe.18

Rírí àwọn ọbìnrin bíi olùkópa pàtàkì kìí ṣe nípa dídá ìdọ́gba sùgbọ́n nípa òye ẹ̀kọ́ òtítọ́. Dípò gbígbé ètò láti mú iyẹ́n wá kalẹ̀, a le ṣiṣẹ́ taratara lati ka àwọn obìnrin si bi Ọlọ́run ti ṣe: gẹ́gẹ́bi alábaṣepọ tòótọ́ nínú iṣẹ́ ìgbàlà àti ìgbéga.

Njẹ́ A Ti Múrasílẹ̀? Njẹ́ a ma tiraka láti borí ìwà nípa àṣà àìdáa kí a si gbá àwọn àwòṣe àtọ̀runwá mọ́raàti ìṣe ti o dá lé orí ìpinlẹ̀ ẹ̀kọ́? Ààrẹ Russell M. Nelson pè wá láti “rìn ni apá sí apá ni iṣẹ́ àtọ̀runwá wa yi … [Láti] ṣe ìrànlọ́wọ́ láti múra ayé sílẹ̀ fún Ìpadàbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Olúwa.”19 Bí a ti ṣe, a o kọ́ láti ka ìdásí ẹnìkọ̀ọ̀kan kún a o si mú àṣeyọrí pẹ̀lú èyí ti a o fi mú ipò mímọ́ wa ṣẹ pọ̀ si. A o ní ayọ̀ púpọ̀ síi tóbẹ́ẹ̀ ju bi a ti ní tẹ́lẹ̀rí lọ.

Njẹ́ ki ẹnìkọ̀ọ̀kan wa yàn láti di ìrẹ́pọ̀ ní ọ̀nà ìmísí Olúwa láti ran iṣẹ́ Rẹ̀ lọ́wọ́ láti tẹ̀síwájú. Ní orúkọ ọmọ Rẹ̀ Olólùfẹ́ wa, Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Wo Gẹ́nẹ́sísì 3:1–18; Mósè 4: 1–19.

  2. Wo Mósè 5:1-12. Àwọn ẹsẹ yi kọ́ nípa àjọṣe òtítọ́ Àdàmú àti Éfà: wọ́n ni ọmọ papọ̀ (ẹsẹ 2); wọ́n ṣiṣẹ́ papọ̀ láti pèsè fún ara wọn àti ẹbí (ẹsẹ 1); wọ́n gbàdúrà (ẹsẹ 4); wọ́n pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ wọ́n si rúbọ papọ̀ (ẹsẹ 5); wọ́n kẹkọ (ẹsẹ 4, 6–11) wọ́n sì kọ́ ìhìnrere Jésù Krístì fún àwọn ọmọ wọn papọ̀ (ẹsẹ 12).

  3. Ìtàn—Josefu Smith 1:16.

  4. Wo Sarah M. Kimball, “Auto-Biography,” Woman’s Exponent, Sept. 1, 1883, 51; wo pẹ̀lú Teachings of Presidents of the Church: Joseph Smith (2007), 451.

  5. Joseph Smith, ni “Nauvoo Relief Society Minute Book,” 40, josephsmithpapers.org.

  6. Wo George Albert Smith, “Ọ̀rọ̀ sí àwọn Ọmọ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́,” Relief Society Magazine, Dec. 1945, 717.

  7. Wo John Taylor, ni Nauvoo àwọn Ìròhìn Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́, Mar. 17, 1842, available at churchhistorianspress.org. Gẹ́gẹ́bi Eliza R. Snow, Joseph Smith pé a ti ko àwọn obìnrin jọ ní àwọn ààyè tí o kọja (wo Eliza R. Snow, “Female Relief Society,” Deseret News, Apr. 22, 1868, 1; and Daughters in My Kingdom: The History and Work of Relief Society [2011], 1–7).

  8. Wo Dallin H. Oaks, “Àwọn Kọkọrọ àti Àṣẹ Oyèàlúfà,” Làìhónà, May 2014, 49–52.

  9. Wo Russell M. Nelson, “Àwọn Ìṣúra ti ẹ̀mí,” Làìhónà, Nov. 2019, 78, 79.

  10. Russell M. Nelson, “Àwọn Ìṣúra ti ẹ̀mí,” 77.

  11. “Ṣùgbọ́n ìhìnrere ìmúpadàbọ̀sípò kọ́ àbá ayérayé pé àwọn ọkọ àti aya jẹ́ àìlédáwá pẹ̀lú ara wọn. Wọn jẹ́ dídọ́gba. Wọ́n jẹ akẹgbẹ” (Bruce R. Hafen, “Crossing Thresholds and Becoming Equal Partners,” Làìhónà, Aug. 2007, 28).

  12. Àwọn Àkórí Ìhìnrere, “Àwọn Ìkọ́ni ti Joseph Smith nípa Oyè-àlùfáà, Tẹ̀mpìlì, àti àwọn Obìnrin,” topics.ChurchofJesusChrist.org.

  13. Ìfìwéṣọwọ́sí Araẹni.

  14. Russell M. Nelson, “Ẹ̀bẹ̀ Kan Sí Ẹ̀yin Arábìnrin Mi,” Liahona, Nov. 2015, 95–97.

  15. Russell M. Nelson, “Ẹ̀bẹ̀ Kan Sí Ẹ̀yin Arábìnrin Mi,” 97.

  16. Wo General Handbook: Serving in The Church of Jesus Christ of Latter-day Saints, 1.4, ChurchofJesusChrist.org.

  17. Russell M. Nelson, “Ẹ̀bẹ̀ Kan Sí Ẹ̀yin Arábìnrin Mi,” 97.

  18. “Ẹ̀yin arabìnrin olùfẹ́, eyikeyi ìpè yín, eyikeyi àwọn ipò yín, a nílò àwọn ìkúnnu yin, àwọn ìmọ̀, àti àwọn ìmísí yín. A nílò yín lati sọ̀rọ̀ sókè àti sọ̀rọ̀ síta ni wọ́ọ̀dù àti àwọn ìgbìmọ́ èèkàn. We need each married sister to speak as ‘a contributing and full partner’ as you unite with your husband in governing your family. O ṣe ìgbéyàwó tàbí o dáwà, ẹ̀yin obìnrin ni àwọn agbára ti o yàtọ̀ àti ìmọ̀ inú pàtàkì ti ẹ gabà gẹ́gẹ́bí àwọn ẹ̀bún láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Àwa arakùnrin ko le ṣe ẹ̀dà ipa àràọ̀tọ̀ yín. …

    “… A nílò okun yín!” (Russell M. Nelson, “Ẹ̀bẹ̀ Kan Sí Ẹ̀yin Arábìnrin Mi,” 97).

  19. Russell M. Nelson, “Ẹ̀bẹ̀ Kan Sí Ẹ̀yin Arábìnrin Mi,” 97.

Tẹ̀