Agbára Ìwé ti Mọ́mọ́nì nínú Ìyípadà
Ìwé ti Mọ́mọ́nì npèsè ohun jíjẹ ti ẹ̀mí, ó njúwe ètò ìṣe kan, ó sì nso wa pọ̀ pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́.
Lẹ́hìn síṣe àgbéyẹ̀wò àbájáde láti inú àyẹ̀wò ara ní àìpẹ́ yi, mo kọ́ pé mo nílò láti ṣe àwọb àtúnṣe sí ìgbé ayé mi. Láti rànmí lọ́wọ́, Dókítà mi júwe ohun-jíjẹ́ àti ètò ìdárayá, èyí, bí mo bá yàn láti tẹ̀lé, yíò yí mi padà sí alára líle síi.
Bí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa bá lọ ṣe àyẹ̀wò ti ẹ̀mí, kínní ohun tí a ó kọ́ nípa ara wa? Àwọn àtúnṣe wo ni oníṣègùn wa ti ẹ̀mí yíò júwe? Fún wa láti di ẹni tí a níláti jẹ́, ó ṣe pàtàkì kí a mọ ohun tí a ó ṣe àti láti ṣe ohun tí a mọ̀.
Jésù Krísti ni Ọ̀gá Oníṣegùn .1 Nípasẹ̀ Ètùtù Rẹ̀, Òun di àwọn ọgbẹ́ wa, gbé àwọn àrùn wa lé orí ara Rẹ̀, Ó sì wo ọkàn ìrobínújẹ́ wa sàn.2 Nípa oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀, àwọn àìlera wa lè di okun.3 Ó pè wá láti tẹ̀lé Òun4 nípa kíkọ́ ẹ̀kọ́ ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀, fífi etí sílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀, àti rírìn nínú ọkàntútú ti Ẹ̀mí Rẹ̀.5 Ó ti ṣèlérí láti rànwá lọ́wọ́6 nínú èto ìgbà ìgbé ayé ti ìyípadà yí, èyí tí ó nyíwapadà tí ó sì nmú ayọ̀ ayérayé wá.7
Olùgbàlà ti fún wa ní Ìwé ti Mọ́mọ́nì bíi ohun èlò alágbára láti ṣe àtilẹhìn nínú ìyípadà. Ìwé ti Mọ́mọ́nì npèsè ohun jíjẹ ti ẹ̀mí, ó njúwe ètò ìṣe kan, ó sì nso wa pọ̀ pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́. Kikọ fún wa,8 ó ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú ní kedere9 ó sì sọ fún wa nípa ìdánimọ̀, èrò, àti àyànmọ́ wa.10 Pẹ̀lú Bìbélì, Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ ẹ̀rí nípa Jésù Krístì11 ó sì kọ́ni bí a ṣe lè mọ òtítọ́ kí a sì dàbí Rẹ̀.
Arákùnrin Saw Polo jẹ́ ẹni ọdún mejìdínlọ́gọ́ta nígbàtí a fi ìhìnrere Jésù Krístì tí a múpadàbọ̀sípò hàn án. Nígbàtí mo pàdé rẹ̀, òun ti nsìn bí ààrẹ ẹ̀ka kan fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, ṣùgbọ́n mo gbọ́ pé òun kò tíì ka Ìwé ti Mọ́mọ́nì rí nítorípé ko tíì sí ní èdè àbínibí rẹ̀ Burmese nígbànáà. Nígbàtí mo bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bí ó ṣe mọ̀ pé ìwé náà jẹ́ òtítọ́ láì tíì kà á, ó fèsì pé òun ti ṣe àṣàrò Àwọn ìtàn Ìwé ti Mọ́mọ́nì ìwé àwòrán lójoojúmọ́ nípa wíwo àwọn ìjúwe, lílo ìwé ìtumọ̀ láti ṣe àyípadà àwọn ọ̀rọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì, àti ṣíṣe àwọn àkọsílẹ̀ ránpẹ́ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ nípa ohun tí ó kọ́. Ó ṣe àlàyé pé, “Gbogbo ìgbà tí mo bá ṣe àṣàrò, èmi ngbàdúrà nípa ohun tí mo kọ́, èmí sì nní ìmọ̀lára àláfíà àti ayọ̀, inú mi nmọ́, ọkàn mi sì nrọ̀. Mo ní ìmọ̀lára Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó njẹ́ ẹ̀rí sí mi pé ó jẹ́ òtítọ́. Mo mọ̀ pé Ìwé Ti Mọ́mọ́nì jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”
Bíi ti Arákùnrin Saw Polo, ìkọ̀ọ̀kan lára wa lè ṣe àṣàrò Ìwé ti Mọ́mọ́nì ní ìbámu sí àwọn ipò wa. Bí a ṣe ní ìfẹ́ láti gbàgbọ́ àti láti jíròrò àwọn ìkọ́ni rẹ̀ nínú ọkàn wa, a lè bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run nínú ìgbàgbọ́ bí àwọn ìkọ́ni náà bá jẹ́ òtítọ́.12 Bí a bá jẹ́ olódodo nínú ìfẹ́ wa láti mọ̀ tí a sì ní èrò inú tòótọ́ láti múṣe, Òun yíò fèsì sí wa nínú ọkàn wa nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. Nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́ ni a ó mọ̀ òtítọ́ ohun gbogbo.13 Nígbàtí a bá gba ẹ̀rí ti ọ̀run nípa Ìwé ti Mọ́mọ́nì, a o mọ̀ bákannáà nípasẹ̀ irú agbára kannáà pé Jésù Krístì ni Olùgbàlà ayé, pé Joseph Smith jẹ́ wòlíì Rẹ̀, àti pé Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ni Ìjọ Rẹ̀ tí a múpadàbọ̀sípò .14
Bí ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó nbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn ṣíṣe ìránṣẹ́ ìhìnrere mi, mo wọ ọkọ̀-òfúrufú to nlọ sí Australia. Nínú ìmọ̀lára ìdánìkanwa gidi, nínú àníyàn, àti àìpé ṣùgbọ́n ní fifi ara sílẹ̀ láti sin, mo nílò ìdánilójú kíákíá pé ohun tí mo gbàgbọ́ nínú rẹ̀ jẹ́ òtítọ́. Mo gbàdúrà mo sì ka àwọn ìwé mímọ́ mi pẹ̀lú ìtara, ṣùgbọ́n bí fífò náà ṣe ntẹ̀síwájú, iyèméjì ara mi npọ̀si àti pé ipò ara mi nburú si. Lẹ́hìn tí mo ti tiraka fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí, oṣìṣẹ́ ọkọ̀-òfúrufú kan rìn wá síwájú ó sì dúró nítòsí ijoko mi. Ó gba Ìwé ti Mọ́mọ́nì tí mò nkà lọ́wọ́ mi. Ó wo ẹ̀hìn rẹ̀ ó wípé, “Èyí jẹ́ ìwé nlá kan!” lẹ́hìnnáà ó fún mi ní ìwé náà padà ó nrìn lọ. Èmi kò tún rí i mọ́ láé.
Nígbàtí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ndún nínú etí mi, mo gbọ́ yékéyéké mò sì ní ìmọ̀lára nínú ọkàn mi pé, “Mo wà nihin, mo sì mọ ibi tí ìwọ wà. Kàn sa ipa rẹ, nítorí èmi ó ṣe ìyókù.” Lórí ọkọ̀ òfúrufú náà níkọjá Òkun Pacific, mo gba ẹrì araẹni nípasẹ̀ àṣàrò mi nípa Ìwé ti Mọ́mọ́nì àti àwọn ìṣílétí Ẹ̀mí Mímọ́ pé Olùgbàlà mi mọ ẹni tí mo jẹ́ àti pé ìhìnrere jẹ́ òtítọ́.
Alàgbà David A. Bednar kọ́ni pé: “Mímọ̀ pé ìhìnrere jẹ́ òtítọ́ ni àkójá ẹ̀rí kan. Fífi lémọ́lemọ́ jẹ́ òtítọ́ sí ìhìnrere ni àkójá ìyípadà.”15 Ìyípadà nfẹ́ kí a jẹ́ “olùṣe ọ̀rọ̀ náà, kí a má sì ṣe jẹ́ olùgbọ́ nìkan.”16 Etò iṣẹ́ síṣe ti Olúwa fún wa—ẹ̀kọ́ ti Krístì—ni à nkọ́ kedere jùlọ nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì.17 Nínú rẹ̀ ni:
-
Àkọ́kọ́, lílo ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì nípa gbígbẹ́kẹ̀lé E, pípa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́, àti mímọ̀ pé Òun yíò rànwálọ́wọ́.18
-
Èkejì, ríronúpìwàdà ojoojúmọ ti àwọn àìṣedéédé wa àti níní ìrírí ayọ̀ àti àláfíà nígbàtí Ó bá dáríjì wá.19 Ìronúpìwàdà nfẹ́ kí a dáríji àwọn ẹlòmíràn20 ó sì nrànwálọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú. Olùgbàlà ti ṣèlèrí láti dáríjì wá léraléra bí a ṣe nronúpìwàdà.21
-
Ẹ̀kẹ́ta, dídá àti pípa àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run mọ́ nípasẹ̀ àwọn ìlànà bí irú ìrìbọmi. Èyí yíò pa wá mọ́ ní ipá ọ̀nà májẹ̀mú tí ó ndarí sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.22
-
Ẹ̀kẹ́rin, gbígba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ̀bùn yí fi ààyè gbà wá sí níní ojúgbà léraléra ti ẹnìkan tí ó nyàwá símìmọ̀, tùwánínú, àti tọ́wasọ́nà.24
-
Ẹkarun, fífaradà dé òpin nípa títẹ̀ síwájú gbọingbọin nígbàtí a nṣe àpèjẹ lojoojúmọ́ lórí ọ̀rọ̀ Krístì.25 Nípa ṣíṣe àpèjẹ láti inú Ìwé ti Mọ́mọ́nì àti dídìmú danindanin sí àwọn ìkọ́ni rẹ̀, a lè borí àwọn àdánwò kí a sì gba ìtọ́nisọ́nà àti ààbò ní gbogbo ọjọ́ ayé wa.23
Nípa fífi lémọ́lemọ́ lo ẹ̀kọ́ Krístì nínú ayé wa, a ó borí ìlọ́ra tí ó ndá ìyípadà dúró àti ẹ̀rù tí ó njá ìṣe kulẹ̀. A ó gba ìfihàn araẹni, nítorí Ẹ̀mí Mímọ́ “yíò fi ohun gbogbo tí ẹ ó ṣe hàn sí yín,”26 àti pé “àwọn ọ̀rọ̀ Krístì yíò sọ ohun gbogbo tí ẹ ó ṣe fún yín.”27
Fún ogún ọdún, Arákùnrin Huang Juncong làkàkà pẹ̀lú otí sìgá, àti tẹ́tẹ́ títa dandan. Nígbàtí a fi Jésù Krístì hàn si i àti ìhìnrere Rẹ̀ tí a múpadàbọ̀sípò , Arákùnrin Huang Juncong nifẹ láti yípadà nítorí ọ̀dọ́ ẹbí rẹ̀. Ìpènijà rẹ̀ tí ó tóbijùlọ ni sìgá mímú. Amu-sìgá gidi fìkan-rànkan, ó ti gbìyànjú láti fisílẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà láìyege. Ní ọjọ́ kan, àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí láti inú Ìwé ti Mọ́mọ́nì wọnú rẹ̀ lọ: “pẹ̀lú ọkàn òdodo, pẹ̀lú èrò òtítọ́.”28 Bí ó tilẹ̀jẹ́pé àwọn ìgbìyànjú àtẹ̀hìnwá kùnà, ó ní ìmọ̀lára pé bóyá òun lè yípadà pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Bàbá Ọ̀run àti Jésù Krístì.
Àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere pa ìgbàgbọ́ wọn pọ̀ mọ́ tirẹ̀ wọ́n sì pèsè ètò ìṣe kan àmúlò ti àwọn dídásí, pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdúrà líle àti ṣíṣe àṣàrò ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Pẹ̀lú ìṣododo àti èrò òtítọ́, Arákùnrin Huang ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìpinnu òtítọ́ ó sì ri pé bí òun ṣe nfojúsun síi lór àwọn ìwà titun t òun nfẹ́ láti gbèrú, irú bí ṣiṣe àṣàrò Ìwé ti Mọ́mọ́nì, ó dín ìfojúsun rẹ̀ kù lórí àwọn ìwá tó fẹ́ fi sílẹ̀.
Rirántí ìrírí rẹ̀ láti ọdún mẹ́ẹ̀dógún sẹ́hìn, ó wípé, “Èmi kò rántí ìgbà tí mo fi sìgá mímu sílẹ gan an, ṣùgbọ́n mo gbìyànjú gidi lójoojúmọ́ láti ṣe àwọn ohun tí mo mọ̀ pé mo nílò láti ṣe láti pe Ẹ̀mí Olúwa wá sínú ayé mi mo sì tẹ̀síwájú láti ṣe wọ́n, èmi kò ní ìfàmọ́ra sí sìgá mímú mọ́ èmi kò sì ṣeé mọ́ láti ìgbà náà.” Nípa lílo àwọn ìkọ́ni Ìwé ti Mọ́mọ́nì, ìgbé ayé Arákùnrin Huang ti yípadà, ó sì ti di ọkọ àti bàbá dídára síi.
Ààrẹ Russell M. Nelson ti ṣèlérí pé: “Bí ẹ ṣe nfi tàdúràtàdúrà ṣe àṣarò Ìwé ti Mọ́mọ́nì lójoojúmọ́, ẹ ó ṣe àwọn ìpinnu dídára si—lójoojúmọ́. Mo ṣe ìlérí pé bí ẹ ṣe njíròrò ohun tí ẹ ṣe àṣàrò rẹ̀, àwọn fèrèsé ọ̀run yíò ṣí sílẹ̀, ẹ ó sì gba àwọn ìdáhùn sí àwọn ìbèèrè ti ara yín àti ìdarí fún ìgbé ayé ti ara yín. Mo ṣe ìlérí pé bí ẹ ṣe nri ara yín sínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì lójoojúmọ́, ẹ ó lè gbára yín dì ní ìlòdì sí àwọn ibi ọjọ́ òní, àní ìgbánimú àrùn ti èérí àti àwọn bánbákú bíbá-ọkànjẹ́ míràn.”29
Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n, Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a ó sì fà súnmọ́ Ọ tí a bá ṣe àṣàrò lórí rẹ̀.30 Bí a ṣe nṣe àyẹ̀wò lórí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, a ó gba ẹ̀rí nípa jíjẹ́ òtítọ́ rẹ̀.30 Bí a ṣe nfi lemọ́lemọ́ gbé ní ìbámu sí àwọn ìkọni rẹ̀, a kò ní ní ìfẹ́ mọ́ láti ṣe ibi.“32 Ọkàn wa, ìwò, àti ìwà-ẹ̀dá wa yíò yípadà láti dà bí Olùgbàlà síi.33 Mo pín ẹ̀rí mi tó dájú pé Jésù ni Krístì, Olùgbàlà, Olùràpadà, àti Ọ̀rẹ́ wa. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.