Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Pípín Ọ̀rọ̀ Ìmúpadàbọ̀sípò àti Àjíìnde
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2020


Pípín Ọ̀rọ̀ Ìmúpadàbọ̀sípò àti Àjíìde

Ìmúpadàbọ̀sípò wà fún ayé, àti pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípàtàkì jẹ́ ìkánjú loni.

Nínú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò yí a ti sọ̀rọ̀ a sì ti kọrin pẹ̀lú ayọ̀ nípa ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ ọjọ́ pípẹ́ náà “ìmúpadà ohun gbogbo,”1 nípa mímú “ohun gbogbo papọ̀ ní ọ̀kan nínú Krístì,”2 nípa ìmúpadà ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere, oyè àlùfáà, àti Ìjọ Jésù Krístì sí ilẹ̀ ayè, gbogbo èyí tí a mú jáde nínú àkọlé “Ìmúpadàbọ̀sípò náà.”

Ṣùgbọ́n Ìmúpadàbọ̀sípò kìí ṣe fún àwa wọnnì tí à nyọ̀ nínú rẹ̀ loni nìkan. Àwọn ìfihàn ti Ìran Àkọ́kọ́ kò wà fún Jósẹ̀fú Smith nìkan ṣùgbọ́n a fifúnni bí ímọ́lẹ̀ àti òtítọ́ fún ẹnikẹ́ni tí ó bá “ku ọgbọ́n fún.”3 Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ ohun ìní gbogbo ẹ̀dá ènìyàn. Àwọn ìlànà oyè àlùfáà ti ìgbàlà àti ìgbéga ni a pèsè sílẹ̀ fún gbogbo ẹnìkọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú àwọn wọnnì tí wọn kò gbé ní ayé ikú mọ́. Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Èniyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn àti àwọn ìbùkún rẹ̀ ni ó wà fún gbogbo ẹni tí ó fẹ́ wọn. Ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ wà fún gbogbo ènìyàn. Ìmúpadàbọ̀sípò wà fún ayé, àti pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípàtàkì jẹ́ ìkánjú loni.

Nítorí-èyi, báwo ni pàtàkì látí sọ àwọn ohun wọ̀nyí di mímọ̀ sí àwọn olùgbé ayé ṣe tóbi tó, kí wọ́n ó lè mọ̀ pé kò sí ẹran ara tí ó lè gbé níwájú Ọlọ́run, bíkòṣepé ó jẹ́ nípasẹ̀ àṣepé, àti àánú, àti ore ọ̀fẹ́ ti Messia Mímọ́, ẹni tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ gẹ́gẹ́bí ti ẹran ara, tí ó sì tún gbà á nípa agbára ti Ẹ̀mí, kí ó le mú àjínde òkú wá sí ìmúṣẹ.”4

Láti ọjọ́ tí arákùnrin Wòlíì, Samuel Smith, tí kó àwọn ẹ̀dà títẹ̀ titun Ìwé ti Mọ́mọ́nì kún àpò rẹ̀ tí ó sì lọ lórí ẹsẹ̀ rẹ̀ láti pín ìwé mímọ́ titun náà, àwọn Ènìyàn Mímọ́ ti ṣe iṣẹ́ láìdúró “láti sọ àwọn ohun wọ̀nyí di mímọ̀ sí àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé.”

Ní 1920, nígbànáà–Alàgbà David O. McKay ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá, bẹ̀rẹ̀ lílọkiri fún ọdún kan sí àwọn mísọ̀n ti Ìjọ. Ní Oṣù Karun1921, ó ndúró ní ibi itẹ́-òkú kèkeré kan ní Fagali’i, Samoa, níwájú ibojì àwọn ọmọdé mẹta tí wọn ṣe dáadáa, ọmọbìnrin àti ọmọkùnrin méjì ti Thomas àti Sarah Hilton. Àwọn ọmọdé wọ̀nyí—èyí tí ó dàgbà jùlọ jẹ́ ọmọ ọdún méjì—kú nígbàtí Thomas àti Sarah sìn bí ọ̀dọ́ tọkọ̀taya òjíṣẹ́ ìhìnrere ní ìparí 1800.

Ṣíwájú kí ó tó kúrò ní Utah, Alàgbà Mckay ṣèlérí fún Sarah, opó báyìí, pé òun yíò bẹ ibojì àwọn ọmọ rẹ̀ wò ní Samoa bí òun kò ṣe lè dé ibẹ̀ mọ́. Alàgbà McKay kọ̀wé padà si, “Àwọn ọmọdé rẹ̀ mẹ́ta, Arábìnrin Hilton, nínú ìdákẹ́ rọ́rọ́ dídùn jùlọ … tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere rẹ tí ó ní ọlá tí ó bẹ̀rẹ̀ ní bíi ọgbọ̀n ọdún sẹ́hìn.” Lẹ́hìnnáà o fi ẹsẹ kan nínú àrokọ ti ara rẹ̀ kún un:

Nípa ọwọ́ ìfẹ́ni ojú ikú wọn padé.

Nípa ọwọ́ ìfẹ́ni ẹsẹ̀ wọn kékeré wàpọ̀,

Nípa ọwọ́ àjèjì a ṣe àwọn iboji ìrẹ̀lẹ̀ wọn ní ọ̀ṣọ́,

Nípasẹ̀ àwọn àlejò wọ́n gba iyì, àti nípasẹ̀ àwọn àlejò a ṣọ̀fọ̀ wọn.5

Ìtàn yí jẹ́ ṣùgbọ́n ọ̀kan lára àwọn ẹgbẹ̀rún, àwọn ẹgbẹ̀rún lọ́nà àwọn ọgọ́rũn, tí ó sọ̀rọ̀ nípa àkokò, ìṣura, àti àwọn ẹ̀mí tí a ti fi rúbọ ní ààrin igba ọdún tí ó kọjá láti pín ọ̀rọ̀ Ìmúpadàbọ̀sípò. Ìgbìrò wa láti dé gbogbo orílẹ̀-èdè, ìbátan, ahọ́n, àti àwọn ènìyàn kò dínkù loni bí a ṣe jẹ́ẹ̀rí nípasẹ̀ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin, ọ̀dọ́mọbìnrin, àti àwọn tọkọ-tayà ẹgbẹ̀rún méjìdínláàdọ̀rin tí wọ́n nnsìn lọ́wọ́lọ́wọ́ lábẹ́ ìpè iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere; nípasẹ̀ àwọn ọmọ ìjọ lápapọ̀ tí wọ́n nṣe àtúnsọ ìfipè Philip láti wá wòó,6 àti nípasẹ̀ àwọn míllíọ̀nù dọ́llà tí a nná lọ́dọọdún láti mú àwọn ìtiraka yí dùró jákèjádò gbogbo ayé.

Nígbàtí àwọn ìfipè wa kìí ṣe tipátipá, a ní ìrètí pé àwọn ènìyàn yíò rí wọn bí ohun tó pọndandan. Fún èyíinì láti rí bẹ́ẹ̀, mo gbàgbọ́ pé a nílò àwọn ohun mẹ́ta ó keréjù: àkọ́kọ́, ìfẹ́ yín; èkejì, àpẹrẹ yín; àti ẹ̀kẹ́ta, lílo Ìwé ti Mọ́mọ́nì yín.

Àwọn ìfipè wa kò lè jẹ́ ọ̀ràn ìfẹ́-ara ẹni; dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ àfihàn ìfẹ́ àìmọtaraẹni-nìkan.”7 Ìfẹ́ yí, tí a mọ̀ sí ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́, ìfẹ́ àìlbàwọ́n ti Krístì, ni tiwa láti bèèrè. A pè wá, àní pàṣẹ fún wa, láti “gbàdúrà sí Bàbá pẹ̀lú gbogbo okun ọkàn, kí [a] lè kún fún ìfẹ́ yí.”8

Bí àpẹrẹ kan, mo pín ìrírí kan tí Arábìnrin Lanett Ho Ching sọ, tí ó nsìn lọ́wọ́lọ́wọ́ pẹ̀lú ọkọ rẹ̀, Ààrẹ Francis Ho Ching, ẹnití ó nṣe àkòso lórí ibi Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Ìhìnrere Samoa Apia. Arábìnrin Ho Ching wí pé:

“Ní àwọn ọdún sẹ́hìn, ọ̀dọ́ ẹbí wa kó lọ sí ilé kínkinní ní Laie, Hawaii. Ibùgbé ọkọ ti ilé wa ni a yípadà sí yàrá stúdíò níbití ọkùnrin kan tó njẹ́ Jonathan gbé. Jonathan ti jẹ́ aladugbo wa ní ibòmíràn. Ní ìmọ̀ pé kìí ṣe àròbádé pé Olúwa ti kó wa papọ̀, a pinnu láti láwọ́ nípa àwọn ìṣeré àti jíjẹ́ ọmọ ìjọ nínú Ìjọ. Jonathan gbádùn ìbáṣọ̀rẹ́ wa ó sì nifẹ láti lo àkokò pẹ̀lú ẹbí wa. Ó fẹ́ràn kíkọ́ nípa ìhìnrere, ṣùgbọ́n kò nifẹ ní síṣe ìlérí fún Ìjọ.

“Ní àkokò, Jonathan gba orúkọ ìnagijẹ ‘Ọ́nkú Jonathan’ pẹ̀lú àwọn ọmọ wa. Bí ẹbí wa ṣe ndàgbà si, bẹ́ẹ̀ni ìfẹ́ Jonathan nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wa. Awọn ìfipè wa sí àwọn àpèjẹ ìgbà ìsinmi, àwọn ọjọ́-ìbí, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ní ilé-ìwé, àti àwọn ìṣe ìdárayá nínú Ìjọ títí kan ìpàdé ilé ẹbí ìrọ̀lẹ́ àti ìrì bọmi àwọn ọmọ.

“Ní ọjọ́ kan mo gba ìpè fóònù láti ọ̀dọ̀ Jonathan. Ó nílò ìrànlọ́wọ́. Ó njìyà nínú àìsàn ìtọ̀-ṣúgà ó sì ti ní àkóràn líle ní ẹsẹ̀ rẹ̀ tí wọ́n níláti gé. Ẹbí wa àti àwọn ọmọ ìjọ aladugbo wà pẹ̀lú rẹ̀ ní àkokò àdánwò náà. À nṣípò ní ilé-ìwòsàn, ó sì gba àwọn ìbùkún oyè àlùfáà. Nígbàtí Jonathan wà ní ibi àtúnṣe, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn arábìnrin Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́, a ṣe ìtọ́jú yàrá rẹ̀. Àwọn arákùnrin oyè àlùfáà kọ́ òkè dídán kan sí ẹnu ọ̀nà rẹ̀ àti irin dìdìmú ní balùwẹ̀. Nígbàtí Jonathan padà dé ilé, ó ní ìbòmọ́lẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀dùnọkàn.

“Jonathan bẹ̀rẹ̀ sí gba àwọn ẹ̀kọ́ iránṣẹ́ ìhìnrere lẹ́ẹ̀kansi. Ọ̀sẹ̀ tí ó ṣíwájú ti Ọdún Titun, ó pè mí ó sì bèèrè, ‘Kínni ò nṣe ní Alẹ́ Ọdún Titun?’ Mo rán an létí nípa àpèjẹ ọdọọdún wa. Ṣùgbọ́n dípò rẹ̀, ó fèsì, ‘Mo fẹ́ kí o wá sí ibi ìrìbọmi mi! Mo fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ọdún titun yi ní ọ̀nà tí ó tọ́.’ Lẹ́hìn ogun ọdún ti ’wá kí o sì ri,’ ‘wá kí ó ṣèrànwọ́,’ àti ’wá kí o sì dúró,’ ẹ̀mí iyebíye yí ṣetán láti ṣe ìrìbọmi.”

Ní 2018, nígbàtí wọ́n pè wá bí ààrẹ iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere àti ojúgbà ní Samoa, ìlera Jonathan ndínkù si. A bẹ̀ ẹ́ láti dúróṣinṣin de ìpadàbọ̀ wa. Ó dúró fún bí ọdún kan, ṣùgbọ́n Olúwa nmúra rẹ̀ sílẹ̀ láti wá sílé. Ó kú lalaafia ní Ọṣù Kẹrin 2019. Àwọn ọmọbìnrin mi lọ sí ibi ìsìnkú ‘Ọnkú wọn Jonathan’ wọn sì kọ orin kannáà tí a kọ níbi ìrìbọmi rẹ̀.”

Mo ṣe àfihàn ohun kejì tí a nílò fún ṣíṣe àṣeyọrí ní pípín ọ̀rọ̀ ti Ìmúpadàbọ̀sípò pẹ̀lú ìbèèrè yí: kínni ohun tí yíò mú ìfipè yín wuni sí ẹnìkan? Ṣé kìí ṣe ẹ̀yin ni, àpẹrẹ ìgbé ayé yín? Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí wón ti gbọ́ tí wón sì ti gba ọ̀rọ̀ Ìmúpadàbọ̀sípò náà ni wọ́n fì ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ní ònfà nípa ohun tí wọ́n rí nínú ọmọ ìjọ kan tàbí àwọn ọmọ ìjọ ti Ìjọ Jésù Krístì. Ó ti lè jẹ́ ọ̀nà ìṣesí wọn sí àwọn ẹlòmíràn, àwọn ohun tí wọ́n sọ tàbí tí wọn kò sọ, ìdúróṣinṣin tí wọ́n fi hàn ní àwọn ipò ìṣòro, tàbí ìwò ojú wọn lásán.10

Ohunkóhun tí ó lè jẹ́, a kò lè fo òtítọ́ náà dá pé a nílò láti ní òye àti láti gbé ìgbé ayé àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ti ìhìnrere tí a múpadàbọ̀ sípò bí a ṣe lè ṣe dárajùlọ sí fún àwọn ìfipè wa láti wuni. Ó jẹ́ ohun kan tí à nfi ìgbàgbogbo tọ́ka sí loni bíi jíjẹ́ tòótọ́. Bí ìfẹ́ Krístì bá ngbé nínú wa, àwọn ẹlòmíràn yíò mọ̀ pé ìfẹ́ wa fún wọn jẹ́ àìṣẹ̀tàn. Bí ìmọ́lẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ ba njó nínú wa, yíò tún ìmọ́lẹ̀ Krístì ṣe ní àárín wọn.11 Ohun tí ẹ jẹ́ nfi jíjẹ́ tòótọ́ sí ìfipè yín láti wá ní ìrírí ayọ̀ ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere Jésù Krístì.

Ohun kẹ́ta tí a nílò ni lílawọ́ ní lílo ohun èlò ti ìyípadà tí Olúwa ti ṣe fún àkokò ìhìnrere ìgbẹ̀hìn yí, Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ó jẹ́ ẹ̀rí àfojúrí pé ìpè Jósẹ́fù Smith jẹ́ ti wòlíì àti ẹ̀rí àìṣiyèméjì jíjẹ́ ti ọ̀run àti Àjínde Jésù Krístì. Àláyé síṣe rẹ̀ nípa ètò ìràpadà ti Bàbá Ọ̀run kò lẹ́gbẹ́. Nígbàtí ẹ bá pín Ìwé ti Mọ́mọ́nì, ẹ̀ npín Ìmúpadàbọ̀sípò.

Nígbàtí Jason Olsen jẹ́ ọ̀dọ́, a kìlọ̀ fún un léraléra láti ọwọ́ àwọn ọmọ ẹbí àti àwọn ẹlòmíràn ní ìlòdì sí dída Krístíẹ́nì. Ó ní àwọn ọ̀rẹ́ rere méjì, bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹ̀hìn, wọ́n sì máa nsọ̀rọ̀ ẹ̀sìn nígbàkugbà. Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, Shea àti Dave, fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ dojúkọ àwọn àríyànjiyàn tí àwọn ẹlòmíràn ti fún Jason ní ìlòdì sí ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì. Nígbẹ̀hìn, wọ́n fún un ní ẹ̀dà Ìwé ti Mọ́mọ́nì kan, wọ́n sì wípé, “Ìwé yí yíò dáhùn àwọn ìbèèrè rẹ. Jọ̀wọ́ kà á.” Ó fi ìlọ́ra gba ìwé náà ó sì fi sínú àpò-ẹ̀hìn rẹ̀, níbití ó wà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù. Kò fẹ́ fi sílẹ̀ ní ilé níbití ẹbí rẹ̀ ti lè ri, kò sì fẹ́ já Shea àti Dave kulẹ̀ nípa dídá a padà. Nígbẹ̀hìn, ó sinmi sí orí ọ̀nà àbáyọ ti jíjó ìwé náà.

Ní alẹ́ kan, pẹ̀lú ìtanná kan ní ọwọ́ kan àti Ìwé ti Mọ́mọ̀nì ní ọwọ́ míràn, ó ti ṣetán láti tan iná sí ìwé náà nígbàtí ó gbọ́ ohùn kan ní inú rẹ̀ tí ó wí pé, “Máṣe jó ìwé mi.” Ní ìbẹ̀rù, ó dáwọ́dúró. Nígbànáà, ní ríronú pé òun lè ti ro ohùn náà, ó gbìyànjú lẹ́ẹ̀kansíi láti ṣá ìtanná náà. Lẹ́ẹ̀kansi, ohùn náà wá sí inú rẹ̀: “Lọ sí yàrá rẹ kí o sì ka ìwé mi.” Jáson mú ìtanná náà kúrò, ó rìn padà sí yàrá ibùsùn rẹ̀, ó ṣí Ìwé ti Mọ́mọ́nì, ó sì bẹ̀rẹ̀sí kàá. Ó tẹ̀síwájú ní ọjọ́ lẹ́hìn ọjọ́, nígbà púpọ̀ títí di wákàtí kùtùkùtù òwúrọ̀. Bí Jason ṣe dé ìparí tí ó sì gbàdúrà, ó ṣe àkọsílẹ̀ pé, “Mo kún láti adé orí mi dé abẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ mi pẹ̀lú Ẹ̀mí. … Mo ní ìmọ̀lára kíkún fún ìmọ́lẹ̀. … Ó jẹ́ ìrírí aláyọ̀ jùlọ tí mo ti rí rí ní ayé mi.” Ó wá ìrìbọmi, lẹ́hìnnáà ó sì di ìránṣẹ́ ìhìnrere fúnrarẹ̀.

Bóyá ó lọ láì wí pé àní pẹ̀lú ojúlówó ìfẹ́ àti ìṣòtítọ́ púpọ̀, bí kò bá jẹ́ púpọ̀ jùlọ, àwọn ìfipè wa láti pín ọ̀rọ̀ Ìmúpadàbọ̀ sípò ni yíò jẹ́ kíkọ̀. Ṣùgbọ́n ẹ rántí èyí: gbogbo ènìyàn ni ó yẹ fún irú ìfipè náà—“gbogbo wa rí bákannáà sí Ọlọ́run”;13 inú Olúwa dùn sí gbogbo ìtiraka tí à nṣe, bíótiwù kí àyọrísí jẹ́; ìfipè tí ó jẹ́ kíkọ̀sílẹ̀ kìí ṣe èrèdí láti fi òpin sí ìbáraṣe wa; àti pé àìní ìfẹ́ sí ní òní lè yípadà dáradára sí níní ìfẹ́ sí ní àwọn ọjọ́ ọ̀la. Láìkàsí, ìfẹ́ wa dúró gbọingbọin.

Ẹ máṣe jẹ́ kí a gbàgbé Ìmúpadàbọ̀sípò ti jáde wá láti inú ìṣẹ̀lẹ̀ líle àti ìrúbọ. Èyíinì jẹ́ẹ̀kọ́ fún ọjọ́ míràn. A yọ̀ loni nínú àwọn èso Ìmúpadàbọ̀sípò, tí ọ̀kan lára àwọn tí ó tayọ jùlọ jẹ́ agbára láti so pọ̀ lẹ́ẹ̀kansi lórí ilẹ̀ ayé àti ní ọ̀run.13 Bí Ààrẹ Gordon B. Hinckley ti sọ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́hìn, “Tí ohun kankan míràn kò bá jáde látinú gbogbo ìkorò àti ìjìyà àti ìrora ti ìmúpadàbọ̀ sípò ju agbára ìfi èdidi dì ti oyè àlùfáà mímọ́ láti so àwọn ẹbí papọ̀ títí láé, kìbá ti yẹ fún gbogbo ohun tí ó gbà.”14

Ìlérí gígajùlọ ti Ìmúpadàbọ̀sípò ni ìràpadà nípasẹ̀ Jésù Krístì. Àjíìnde Jésù Krístì ni ẹ̀rí pé Òun, ní toọ́tọ́, ní agbára láti rà gbogbo ẹni tí ó bá wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ padà—rà wọ́n padà kúrò nínú ìkorò, àìní-ìdáláre, àbámọ̀, ẹ̀ṣẹ̀, àní àti ikú. Òní ni Ọjọ́ Ìsinmi Ọ̀pẹ; ọ̀sẹ̀ kan láti òní ni Ọdún Àjíìnde . A rántí, à nfi ìgbàgbogbo rántí, ìjìyà àti ikú Krísti láti ṣe ètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, a sì nṣe ayẹyẹ ní àwọn Ọjọ́-ìsinmi oníyanu jùlọ náà, ọjọ́ Olúwa, nínú èyítí Òun jí dìde láti inú òkú. Nítorí Àjíìnde Jésù Krístì, Ìmúpadàbọ̀sípò ní ìtúmọ̀, ìgbé ayé ikú wa ní ìtumọ̀, àti pé ní ìgbẹ̀hìn wíwà láyé wa gan ní ìtumọ̀.

Joseph Smith, wòlíì nlá ti Ìmúpadàbọ̀sípò, fúnni ní olúborí ẹ̀rí fún ìgbà tiwa nípa Krístì tí ó jínde: “Pé ó wà láàyè! Nítorítí a rí I, àní ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.”15 Mo fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ fi ẹ̀rí mi kún ti Jósẹ́fù àti sí ti gbogbo àwọn àpọ́stélì àti àwọn wòlíì ṣaájú rẹ̀ àti gbogbo àwọn àpọ́stélì àti wòlíì tí wọ́n tẹ̀lé e, pé Jésù ti Násárẹ́tì ni Mèsíàh tí a ṣe ìlérí, Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo Ọlọ́run, àti Olùràpadà ti ó jínde ti gbogbo ẹ̀dá ènìyàn.

“A jẹri pé àwọn wọnnì tí yíò fi tàdúrà-tàdúrà ṣàṣàrò ọ̀rọ̀ Ímúpadàbọ̀sípò àti ìṣe nínú ìgbàgbọ́ yíò di alábùkúnfún láti jèrè ẹ̀rí ti arawọn nípa àtọ̀runwá rẹ̀ àti nípa èrò rẹ̀ láti múra ayé sílẹ̀ fún ìlérí Ìpadàbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì ti Olúwa àti Olùgbàlà wa, Jésù Krístì.”15 Àjíìnde Krístì nmú àwọn ìlérí Rẹ̀ dájú. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Tẹ̀