Ètò Nlá
Àwa tí a mọ ètò Ọlọ́run tí a sì ti dá májẹ̀mú láti kópa ní ojúṣe kedere láti kọ́ àwọn òtítọ́ wọ̀nyí.
Àní ní àárín àwọn àdánwò tóyàtọ̀ àti ìpènijà, a di alábùkúnfún nítòótọ́. Ìpàdé àpapọ gbogbogbò yí ti fún wa ní ìtújáde ọrọ̀ àti ayọ̀ Ìmúpadàbọ̀sípò ti ìhìnrere Jésù Krístì. A ti láyọ̀ nínú ìran Bàbá àti Ọmọ tí ó bẹ̀rẹ̀ Ìmúpadàbọ̀sípò. A ti ràn wa létí bíbọ̀ ìyanu Ìwé ti Mọ́mọ́nì, èyítí oókan èrò rẹ̀ jẹ́ láti jẹ́ ẹ̀rí Jésù Krístì àti ẹ̀kọ́ Rẹ̀. A ti di ọ̀tun pẹ̀lú òdodo aláyọ̀ ti ìfihàn—sí àwọn wòlíì àti sí wa níti-ara. A ti gbọ́ iyebíye àwọn ẹ̀rí ti Ètùtù àìlópin Jésù Krístì àti àjíìnde Rẹ̀ níti-ọ̀rọ̀. A ti kọ́ wa ní àwọn òtítọ́ míràn nípa ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere Rẹ̀ tí a fihan Joseph Smith lẹ́hìn tí Ọlọ́run Bàbá kéde sí wòlíì titun tí a pè: ”Èyí ni Àyànfẹ́ Ọmọ Mi. Gbọ́ Tirẹ̀!”” (Ìtàn—Josefu Smith 1:17).
A ti tẹnumọ nínú ìmọ̀ wa nípa ìmúpadàbọ̀sípò oyèàlùfáà àti àwọn kọ́kọ́rọ́ rẹ̀. A ti di ọ̀tun nínú ìpinnu wa láti ní ìmúpadàbọ̀sípò Ìjọ Olúwa tí a mọ̀ nípa orúkọ rẹ̀ tótọ́, Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. A si ti pè wá láti darapọ̀ ní àwẹ̀ àti àdúrà láti dín àbájade ọjọ́ ọ̀la kù nípa ìbàjẹ́ rúdurùdu àgbáyé. Ní òwúrọ̀ yí a ní ìmísí látọwọ wòlíì alààyè Olúwa tó ngbé ìkéde onítàn ti Ìmúpadàbọ̀sípò kalẹ̀. A tẹnumọ ìkéde rẹ̀ pé ”àwọn wọnnì tí yíò fi tàdúrà-tàdúrà ṣàṣàrò ọ̀rọ̀ Ímúpadàbọ̀sípò àti tí yíò ṣe ìṣe nínú ìgbàgbọ́ yíò di alábùkúnfún láti jèrè ẹ̀rí ti arawọn nípa àtọ̀runwá rẹ̀ àti nípa èrò rẹ̀ láti múra ayé sílẹ̀ fún ìlérí Ìpadàbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì ti Olúwa àti Olùgbàlà wa, Jésù Krístì.”
Ètò Náà
Gbogbo èyí ni apákan ètò tọ̀run èyítí èrò rẹ̀ ni láti jẹ́ kí àwọn ọmọ Ọlọ́run ní ìgbéga àti láti dàbí Rẹ̀. Tí a tọ́ka sí nínú ìwé-mímọ́ bí ”ètò ìdùnnú nlá,” ”ètò ìràpadà,” àti ”ètò ìgbàlà náà” (Álmà 42:8,11, 5ètò náà—tí a fihàn nínú Ìmúpadàbọ̀sípò—bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìgbìmọ̀ kan ní ọ̀run. Bí àwọn ẹ̀mí a fẹ́ láti ṣàṣeyege ìyè ayérayé tí a gbádùn nípasẹ̀ àwọn òbí wa ọ̀run. Ní àmì náà a ti lọsíwájú bí a ṣe lè ṣe láìsí ìrírí ara ikú nínú ẹran ara. Láti pèsè ìrírí náà, Ọlọ́run Bàbá ṣètò láti dá ayé yí. Nínú ìṣètò ara ikú, a ó gba ìdọ̀tí nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ bí a ṣe dojúkọ àtakò tóṣeéṣe fún ìdàgbà ti ẹ̀mí arawa. Bákannáà a ó di ọmọlẹ́hìn sí ikú ti ara. Láti gba arawa lọ́wọ́ ikú àti ẹ̀ṣẹ̀, ètò Bàbá wa Ọ̀run yíò pèsè Olùgbàlà kan. Àjíìnde Rẹ̀ yíò ra gbogbo ènìyàn padà lọ́wọ́ ikú, àti pé ìrúbọ ètùtù Rẹ̀ yíò san oye tóṣeéṣe fún gbogbo ènìyàn láti gba ìwẹ̀nùmọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ lórí ipò tí a júwe láti gbé ìdàgbà wa sókè. Ètùtù Jésù Krístì yí ni oókan ètò Bàbá.
Nínú Ìgbìmọ̀ ní Ọ̀run, gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀mí Ọlọ́run ni a fihàn sí ètò Bàbá, pẹ̀lú àyọrísí ara ikú àti àwọn àdánwò rẹ̀, àwọn ìrànwọ́ tọ̀run rẹ̀, àti àyànmọ́ ológo. A rí òpin láti ìbẹ̀rẹ̀. Gbogbo ọ̀pọ̀ àwọn ara-ikú tí a ti bí lórí ilẹ̀ ayé yan ètò Bàbá wọ́n sì ja fún un nínú ìdíje tọ̀run tí ó tẹ̀le. Ọ̀pọ̀ nìnu wa dá májẹ̀mú pẹ̀lú Baba nípa ohun ti àwa ó ṣe láyé ikú. Ní àwọn ọ̀nà tí a kò tíì fihàn, àwọn ìṣe wa nínú ayé ẹ̀mí ti fún àwọn ipò wa nínú ara ikú lókun.
Ayé Ikú àti Ayé Ẹ̀mí
Báyìí èmi ó ṣe àkópọ̀ àwọn kókó ohun èlò ètò Bàbá bí wọ́n ṣe bá wa jà nínú ìrìnàjò ara ikú wa àti nínú ayé ẹ̀mí tí ó tẹ̀le.
Èrò ayé ikú àti ìdàgbà ìkọjá ayé ikú tí ó lè tẹ̀lé e fún irú ọmọ Ọlọ́run láti dà bí Òun ṣe wà. Èyí ni ìfẹ́ Bàbá Ọ̀run fún gbogbo ọmọ Rẹ̀. Láti ṣàṣeyege àyànmọ́ aláyọ̀ yí, àwọn àṣẹ ayérayé gbà pé a gbọ́dọ̀ di àwọn ènìyàn yíyàsímímọ́ nípasẹ̀ Ètùtù Jésù Krístì kí a lè gbé níwájú Bàbá àti Ọmọ kí a sì gbádùn àwọn ìbùkún ìgbéga. Bí Ìwé ti Mọ́mọ́nì ti kọ́ni, Ó pé “gbogbo ènìyàn láti wá sọ́dọ̀ rẹ̀ kí wọ́n sì pín ninu inúrere rẹ̀; kò sì kọ ẹnìkẹ́ni tí ó wá sọ́dọ̀ rẹ̀, dúdú àti funfun, inú ìdè àti òmìnira, akọ àti abo; ó sì nrántí àwọn abọ̀rìṣà; gbogbo wọn sì dàbí ọ̀kan sí Ọlọ́run”(2 Néfì 26:33; bákannáà wo Álmà 5:49).
Ètò tọ̀run fún wa láti di ohun tí a yàn láti dà nfẹ́ kí a ṣe àwọn àṣàyàn láti kọ àtakò ibi tí ó ndán àwọn ayé ikú wò láti ṣe ìṣe ní ìlòdì sí àwọn òfin Ọlọ́run àti ètò Rẹ̀. Bákannáà ó nfẹ́ kí a jẹ́ ọmọẹ̀hìn sí àwọn àtakò ayé ikú míràn, látinú irú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíràn tàbí látinú àwọn àlébù obí. Nígbàmíràn ìdàgbà tí a nílò di ṣíṣé dáradára nípa jíjìyà àti ìpọ́njú ju nípa ìtùnú àti ọ̀wọ̀ lọ. Kò sì sí àtàkò ayé ikú yí tí ó lè ṣàṣayege èrò ayérayé rẹ̀ bí ìfọwọ́sí ìrànlọ́wọ́ tọ̀run wa kúrò ní gbogbo àbájáde líle ti ayé ikú.
Ètò yí fi àyànmọ́ wa ní ayé àìlópin hàn, èrò àti àwọn ipò ìrìnàjò wa nínú ayé ikú, àti àwọn ìrànlọ́wọ́ tọ̀run tí a ó gbà. Àwọn òfin Ọlọ́runkìlọ̀ fún wa ní ìlòdì sí ṣíṣìnà lọ sínú ewu àwọn ipò. Àwọn ìkọ́ni ti ìmísí àwọn olórí ntọ́wasọ́nà ipá wa ó sì nfún wa ní ìdánilójú tí ó ngbé ìrìnàjò ayérayé wa ga.
Ètò Ọlọ́run fún wa ní àwọn ìdánilójú nlá mẹ́rin láti rànwálọ́wọ́ ní ìrìnàjò wa nínú ayé ikú. Gbogbo ohun ní a fún wa nípasẹ̀ Ètùtù Jésù Krístì, oókan ti ètò náà. Àkọ́kọ́ dá wa lójú pé nípasẹ̀ ìjìyà Rẹ̀ fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa nípa èyí tí a ronúpìwàdà, a lè gba ìwẹ̀nùmọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọnnì. Nígbànáà ni ìdájọ́ òpin àánú kò “ní rántí wọn mọ́“ (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 58:42).
Ìkejì, bí ara Ètùtù Olùgbàlà wa, Ó gbé gbogbo àwọn àìlera ayé ikú míràn lé orí ararẹ̀. Èyí fàyè gbà wá láti pè É láti fún wa lókun láti gba àwọn àjàgà àìlèkọ̀ ti ayé ikú, araẹni àti gbogbogbò, bí irú ogun àti àjàkálẹ̀ ààrùn. Ìwé ti Mọ́mọ́nì pèsè ìjúwe ti ìwé mímọ́ tó hàn jùlọ nípa agbára pàtàkì ti Ètùtù yí. Olùgbàlà gbé “àwọn ìrora àti àìsàn [àti àwọn àìlera] ti àwọn ènìyàn rẹ̀ lé orí Rẹ̀. … Òun yíò sì gbé gbogbo àìlera wọn lé ara rẹ̀, kí inú rẹ̀ lè kún fún ãnú, nípa ti ara, kí òun kí ó lè mọ̀ nípa ti ara bí òun yíò ṣe ran àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ́wọ́ nínú gbogbo àìlera wọn” (Alma 7:11–12).
Ìkẹ́ta, Olùgbàlà, nípasẹ̀ Ètùtù àìlópin Rẹ̀, pa lílópin ti ikú rẹ́ ó sì fún wa ní ìdánilójú aláyọ̀ pé gbogbo wa yíò jínde. Ìwé ti Mọ́mọ́nì kọ́ni, “Ìmúpadàbọ̀sípò yí yíò wá fún gbogbo ènìyàn, gbogbo ẹni tí ó dàgbà àti ọmọdé, gbogbo ẹnití ó wà ní ìdè tàbí ní òmìnira, gbogbo ọkùnrin àti obìnrin, gbogbo ènìyàn búburú àti olódodo; àti pàápàá ẹyọ irun orí wọn kan kò ní sọnù; ṣùgbọ́n gbogbo ohun ní a mùpadàbọ̀sípò ní pípé rẹ̀.“ (Alma 11:44).
À nṣàjọ̀dún òdodo Àjínde ní àkokò Ọdún Àjínde yí. Èyí fún wa ní ìgbìrò àti okun láti farada àwọn ìpènijà ayé ikú tí ó dojúkọ ẹnìkọ̀ọkan wa àti àwọn wọnnì tí a nifẹ, àwọn ohun bí àìpé ti ara, ọpọlọ, tàbí ẹ̀dùn ọkàn tí a gbà ní ìbí tàbí ìrírí nígbà ayé ikú wa. Nítorí Àjínde, a mọ̀ pé àwọn aìpé ayé ikú wọ̀nyí wa fún ìgbà ránpẹ́!
Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere nmudáwálójú pé Àjínde lè pẹ̀lú ànfàní láti wà pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹbí wa—ọkọ, ìyàwó, àwọn ọmọ, àti àwọn òbí. Èyí ni ìgbàni-níyànjú alágbára fún wa láti mú àwọn ojúṣe ẹbí ṣẹ nínú ayé ikú. Ó rànwálọ́wọ́ láti gbé papọ̀ nínú ìfẹ́ ní ìgbìrò aláyọ̀ ìrẹ́pọ̀ àti ìbáṣepọ̀ ni èyí tó mbọ̀.
Ìkẹ́rin àti ìkẹhìn, ìfihàn òde òní kọ́ wa pé ìlọsíwájú kò parí pẹ̀lú òpin ayé ikú. Díẹ̀ ni a fihàn nípa ìdánilójú pàtàkì yí. A sọ fún wa pé ayé yí ni àkókò láti múrasílẹ̀ láti pàdé Ọlọ́run àti pé a kò gbọ́dọ̀ sún ọjọ́ ìrònúpìwàdà wa síwájú (wo Alma 34:32–33 síbẹ̀, a kọ́ pé nínú ayé ẹ̀mí ìhìnrere ni a wàásù àní sí “ìkà ati aláìgbọràn tí wọ́n kọ òtítọ́ sílẹ̀“ (Doctrine and Covenants 138:29) ati pé awọn wọnnì tí wọ́n nkọ́ni nronúpìwàdà síwájú Ìdájọ́ Ìkẹhìn (wo ẹsẹ 31–34, 57–59).
Nihin ni àwọn ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ kan nípa ètò Bàbá wa Ọ̀run.
Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì nfùn wa ní ìrò tóyàtọ̀ lórí ẹ̀kọ́ ìwàmímọ́, ìgbeyàwó, àti ọmọ bíbí. Ó nkọ́ni pé ìgbeyàwó ṣeéṣe fún àṣeyọrí èrò ti ètò Ọlọ́run, láti pèsè àgbékalẹ̀ yíyàn tọ̀run fún ìbí ayé ikú, àti láti múra àwọn ọmọ ẹbí sílẹ̀ fún ìyè ayérayé. ”Ìgbeyàwó ni Ọlọ́run yàn fún ènìyàn,” Olúwa wípé, “kí ayé lè dáhùn òpin ìṣẹ̀dá rẹ̀” (Doctrine and Covenants 49:15). Nínú èyí, ètò Rẹ̀, bẹ́ẹ̀ni, lòdì sí àwọn agbára ayé líle nínú àṣẹ àti àṣà.
Agbára láti dá ayé ikú ni agbára gíga jùlọ tí Ọlọ́run ti fún àwọn ọmọ Rẹ̀. Ìlò rẹ̀ ni a pàṣẹ nínú òfin kínní sí Ádámù àti Éfà, ṣùgbọ́n òfin míràn pàtàkì ni a fúnni láti dẹ́kun ìlòkulò rẹ̀. Níta ìsopọ̀ ìgbeyàwó, gbogbo lílò agbára obí dé ipò kan tàbí òmíràn jẹ́ ìdójútì ẹlẹ́ṣẹ̀ àti ìtàbùkù ìwà àtọ̀runwá jùlọ ti àwọn ọkùnrin àti obìnrin. Ìtẹnumọ́ tí ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere gbé lé orí àṣẹ ìwàmímọ́ jẹ́ nítorí ti èrò àwọn agbára obí ní ṣíṣe àṣeyege ètò Ọlọ́run.
Kíló kan?
Ní ìgbà àjọ̀dún igba ọdún ti Ìran Àkọ́kọ́, èyí tí ó mú Ìmúpadàbọ̀sípò wá, a mọ̀ ètò Olúwa a sì gba ìyànjú ní sẹ́ntúrì méjì nípa àwọn ìbùkún rẹ̀ nípasẹ̀ ìmúpadàbọ̀sípò Ìjọ Rẹ̀. Nínu ọdún yí 2020, a ní ohun olókìkí tí à npè ní ìran 20/20 fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìkọjá.
Bí a ṣe nwo ọjọ́ ọ̀la, bákannáà, ìran wa dínkù ní dídájú. A mọ̀ pé sẹ́ntúrì méjì lẹ́hìn Ìmúpadàbọ̀sípò, ayé ẹ̀mí báyìí pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrírí òṣìṣẹ́ ayé ikú láti ṣàṣeyege wíwàásù tí ó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀. Bákannáà a mọ̀ báyìí pé a ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tẹ̀mpìlì si láti ṣe àwọn ìlànà ayé àìlópin fún àwọn wọnnì tí wọ́n ronúpìwàdà tí wọ́n si gba ìhìnrere Olúwa mọ́ra ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìbòjú ti ikú. Gbogbo èyí mú ètò Bàbá wa Ọ̀run tẹ̀síwájúsí. Ìfẹ́ Ọlọ́run tóbi gidi, àyàfi fún díẹ̀ tí wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ di àwọn ọmọ ègbé, Ó ti pèsè àyànmọ́ ògo fún gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀ (wo Doctrine and Covenants 76:43).
A mọ̀ pé Olùgbàlà yíò padà wá àti pé mìllẹ́níùmù ti ìjọba àláfià yíò wà láti yí apákan ètò ayé ikú Ọlọ́run pọ̀. Bákannáà a mọ̀ pé àwọn àjíìnde ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ yíò wà, ti olódodo àti aláìṣòdodo, pẹ̀lú ìdájọ́ ìkẹhìn ti ẹnìkankan nígbàgbogbo títẹ̀lé àjínde ọkùnrin àti obìnrin.
A ó gba ìdájọ́ gẹ́gẹ́bí àwọn ìṣe wa, àwọn ìfẹ́ ti ọkàn wa, àti irú ènìyàn tì a ti dà. Ìdájọ́ yí yíò jẹ́ kí gbogbo ọmọ Ọlọ́run tẹ̀síwájú sí ìjọba ògo fún èyí tí ìgbọ́ran wọn ti mú wọn yege àti ibi tí wọn yíò tí nítùnú. Adájọ́ ti gbogbo èyí ni Olùgbàlà wa, Jésù Krístì (wo John 5:22; 2 Nephi 9:41). Agbára tójùlọ Rẹ̀ fun Un ní ìmọ̀ gbogbo àwọn ìṣe wa àti ìfẹ́, àwọn tí wọ́n kò ronúpìwàdà àti àwọn tí wọn kò yípadà àti àwọn tí wọ́n ronúpìwàdà àti àwọn olódodo. Nítorínáà, lẹ́hìn ìdájọ́ Rẹ̀ gbogbo wa ní a ó jẹ́wọ́ “pé àwọn ìdájọ́ Rẹ̀ jẹ́ òdodo“ (Mosiah 16:1).
Ní ìparí, mo ṣe àbápín ìdánilójú tí ó wá sọ́dọ̀ mi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ lẹ́tà àti nípasẹ̀ àtúnyẹ̀wò ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbèèrè láti padà sí Ìjọ lẹ́hìn orúkọ mímúkúrò tàbí ìyípadà-kúrò-nínú-ìgbàgbọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ìjọ wa kò ní ìmọ̀ ètò ìgbàlà yí, èyí tí ó dáhùn àwọn ìbèèrè púpọ̀jùlọ nípa ẹ̀kọ́ àti àwọn ìṣètò ìmísí ti ìmúpadabọ̀sípò Ìjọ. Àwa tí a mọ ètò Ọlọ́run tí a sì dá májẹ̀mú láti kópa ní ojúṣe kedere láti kọ́ àwọn òtítọ́ wọ̀nyí àti láti ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti gbé wọn síwájú fún àwọn míràn àti nínú àwọn ipò arawa nínú ayé ikú. Mo jẹ́ ẹ̀rí nípa Jésù Krístì, Olugbàlà àti Olùràpadà wa, ẹnití o mú gbogbo ohun ṣeéṣe, ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.