Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìbùkún ti Ìtẹ̀síwájú Ìfihàn sí àwọn Wòlíì àti Ìfihàn Araẹni sí Ìtọ́nisọ́nà Ìgbé Ayé Wa
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2020


Ìbùkún ti Ìtẹ̀síwájú Ìfihàn sí àwọn Wòlíì àti Ìfihàn Araẹni sí Ìtọ́nisọ́nà Ìgbé Ayé Wa

Ìtẹ̀síwájú ìfihàn ni a ti gbà tí a sì ngbà nípasẹ̀ àwọn ọ̀nà tí Olúwa ti gbé kalẹ̀.

Loni èmi yíò sọ̀rọ̀ lórí ìtẹ̀síwájú ìfihàn sí àwọn wòlíì àti ìtẹ̀síwájú ìfihàn araẹni sí ìtọ́nisọ́nà ìgbé ayé wa.

Nígbàmíràn a ngba ìfihàn àní ìgbàtí a kò mọ àwọn èrò Olúwa. Ní kétá ṣíwájú kí a tó pe Alàgbà Jeffrey R. Holland bí Àpọ́stélì ní Oṣù Kẹfa ti 1994, mo ní ìrírí ìfihan ẹlẹ́wà kan pé a ó pè é. Èmi ni aṣojú agbègbè kan èmi kò sì rí èrèdí kankan tí a fi lẹ̀ fún mi ní ìmọ̀ náà. Ṣùgbọ́n a jẹ́ ojúgbà bí ọ̀dọ́ oníṣẹ́ ìrànṣẹ́ ìhìnrere ní England ní ìbẹ̀rẹ̀ 1960 mo sì ní ìfẹ́ nlá fún un. Mo gbèrò ìrírí náà bí àánú ìrọ́nú fún mi. Ní àwọn àìpẹ́ ọdún, ó ti yà mí lẹnu bí Olúwa bá nmúra mi sílẹ̀ láti jẹ́ kékeré nínú àwọn Méjìlá sí ojúgba òjíṣẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere alámì tí ó jẹ́ ojúgbà kékeré sí mi nígbàtí a jẹ́ ojíṣẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere.1 Mo máa nkìlọ̀ fún àwọn ọ̀dọ́ òjìṣẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere láti jẹ́ onínúrere sí ojúgba wọn kékeré nítorí wọn kò mọ rárá ìgbàtí wọ́n lè jẹ́ ojúgbà àgbà.

Mo ní ẹrí daindain pé ímúpadàbọ̀sípò Ìjọ yí ni Olùgbàlà wa, Jésù Krístì ndarí. Ó mọ ẹni tí yíò pè bí Àpọ́stélì Rẹ̀ àti ní ètò láti pè wọ́n. Bákannáà Ó mọ bí yíò ṣe múra Àpọ́stélì Rẹ̀ àgbà sílẹ̀ láti jẹ́ wòlíì àti Ààrẹ Ìjọ.

A di alábùkúnfún ní òwúrọ̀ yí láti gbọ́ olólùfẹ́ wòlíì wa, Ààrẹ Russell M. Nelson, láti fún wa ní ìkéde ìjìnlẹ̀ igba ọdún sí ayé pẹ̀lú ọ̀wọ̀ sí Ìmúpadàbọ̀sípò ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere Jésù Krístì.2 Ìpolongo ìkọ́ni yí látẹnu Ààrẹ Nelson ti mu hàn pé Ìjọ Jésù Krístì ní àtilẹ̀bá rẹ̀, wíwà, àti ìdarí fún ọjọ́-ọ̀la sí ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ti ìtẹ̀síwájú ìfihàn. Ìkéde titun fi ìbánisọ̀rọ̀ Bàbá olùfẹ́ni sí àwọn ọmọ Rẹ̀ hàn.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ ṣíwájú, Ààrẹ Spencer W. Kimball fi ìmọ̀lára tí mo ní loni hàn. Ó wípé“ “Nínú ohun gbogbo, tí …52Cook_1235884_html a gbọ́dọ̀ fìmoore hàn [fún] jùlọ ni pé àwọn ọ̀run ti ṣí sílẹ̀ nítòótọ́ àti ìjọ ìmúpadàbọ̀sípò Jésù Krístì náà ni a pìlẹ̀ lórí òkúta ìfihàn. Ìtẹ̀síwájú ìfihàn nítòótọ́ ni ìgbé-ayé ìhìnrere ti Olúwa alààyè àti Olùgbàlà, Jésù Krístì gan an.“2

Wòlíì Enoch ti rí àwọn ọjọ́ nínú èyí tí à ngbé. Olúwa jẹ́wọ́ ìwà búburú nlá tí yíò wà sí Enoch ó sì sọtẹ́lẹ̀ nípa “ìpọ́njú nlá“tí yíò ṣẹlẹ̀. Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, Olúwa ṣèlérí, “ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi ni èmi ó pamọ́.“4 “Òdodo ni èmi ó rán sílẹ̀ láti ọ̀run; òtítọ́ ni èmí ó sì rán jáde sílẹ̀ ayé, láti jẹ́ ẹ̀rí Ọmọ Bíbí mi Nìkanṣoṣo.“5

Ààrẹ Ezra Taft Benson kọ́ni pẹ̀lú agbára nlá pé Ìwé ti Mọ́mọ́nì, igunòkúta ẹ̀sìn wa, jáde wá láti ilẹ̀ ayé ní ìmúṣẹ ìpòlongo Olúwa sí Enoch. Bàbá àti Ọmọ àti àwọn ángẹ́lì àti àwọn wòlíì farahan Wòlíì Joseph Smith ni “a darí láti ọ̀run láti mú àwọn agbára tó ṣeéṣe sí ìjọba padàbọ̀sípò.“6

Wolíì Joseph Smith gba ìfihàn lẹ́hìn ìfihàn. Àwọn kan ni a ti sọ nínú ìpàdé àpapọ̀ yí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìfihàn nípasẹ̀ Wòlíì Josèph ni a ti fi pamọ́ fún wa nínú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú. Gbogbo àwọn iṣẹ́ òṣùwọn ti Ìjọ ni ọkàn àti ìfẹ́ Olúwa wà fún wa ní àkokò ìkẹhìn yí.7

Ní àfikún sí àwọn ìpìlẹ̀ nlá ìwé mímọ́ wọ̀nyí, a di alábùkúnfún pẹ̀lú ìfihàn tó ntẹ̀síwájú sí àwọn wòlíì alààyè. Àwọn wòlíì ni “àwọn aṣojú yíyàn Olúwa, tí a fún láṣẹ láti sọ́rọ̀ fún Un.“8

Àwọn ìfihàn jẹ́ ohun ìránti pàtàkì, àti àwọn míràn láti mú ìmọ̀ wa nípa pàtàkì àwọn òtítọ́ tọ̀run gbòòrò si àti láti pèsè ìtọ́nisọ́nà fún ọjọ́ wa.9

A fi ìmoore alámì hàn fún ìfihàn sí Ààrẹ Spencer W. Kimball nínawọ́ oyèàlùfáà àti àwọn ìbùkún tẹ́mpìlì sí gbogbo àwọn ọkùnrin ọmọ ìjọ tóyẹ ní Ọjọ́ Kẹjọ Oṣù Kẹfà, 1978.10

Mo ti sìn pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Méjìlá tí wọ́n wà nìsisìyí tí wọ́n sì kópa nígbàtí a gba ìfihàn oníyelórí náà. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn, ní ìbánisọ̀rọ̀ araẹni, fi ẹsẹ̀ alágbára àti ìrẹ́pọ̀ ti ìtọ́nisọ́nà ti èmí Ààrẹ Kimball múlẹ̀ wọ́n sì ní ìrírí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wípé ó jẹ́ ìfihàn alágbára jùlọ tí wọ́n ti gbà ṣíwájú tàbí lẹ́hìn ìgbà náà.11

Àwọn wọnnì lára wa tó nsìn lọ́wọ́lọ́wọ́ nínú Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá ti di alábùkúnfún ní ọjọ́ wa bí àwọn ìfihàn pàtákì ti wá nípasẹ̀ àwọn wòlíì wa làìpẹ́.12 Ààrẹ Russell M. Nelson ni a ti yàn bí aṣojú Olúwa nípàtàkì pẹ̀lú ọ̀wọ̀ sí àwọn ìfihàn láti ran àwọn ẹbí lọ́wọ́ láti kọ́ ilé-ìṣọ́ mímọ́ ti ìgbàgbọ́ nínú ilé wa, kó àwọn olùfọ́nká Ísráẹ́lì jọ ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìbòjú, àti láti bùkún àwọn ọmọ ìjọ tí a ti rólágbára nínú ọ̀ràn ìlànà mímọ́ tẹ́mpìlì.

Nígbàtí a polongo àwọn ìyípadà láti bùkún ilé wa nínú ìpàdé àpapọ gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2018, mo jẹ́ri “wípé nínú yíyẹ ọ̀rọ̀ wò ti Ìgbìmọ̀ Àjọ Ààrẹ Kínní àti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá nínú tẹ́mpìlì, … lẹ́hìn tí olólùfẹ́ wòlíì wa bẹ Olúwa fún ìfihàn … , ìfẹsẹ̀múlẹ̀ alágbára ni gbogbo wa gbà.“13

Ní ìgbà náà, àwọn ìfihàn míràn tó bá àwọn ìlànà mímọ́ tẹ́mpìlì mu ti a ti gbà ṣùgbọ́n láì polongo tàbí ṣe.14 Ìtọ́nisọ́nà yí bẹ̀rẹ̀ pẹ́lú ìfihàn ti wòlíì kọ̀ọ̀kan sí Ààrẹ Russell M. Nelson àti ìrọ̀nú àti ìfẹsẹ̀múlẹ̀ alágbára sí àwọn wọnnì tó nkópa nínú ètò náà. Ààrẹ Nelson nípàtakì fi àwọn arábìnrin tí wọ́n nṣàkóso Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́, àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin, àti Alakọbẹrẹ sínú àwọn ìṣètò. Ìtọ́nisọ́nà ìparí náà, nínú tẹ́mpìlì, sí Àjọ Ààrẹ Kínní àti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá jẹ́ ti ẹ̀mí àti alágbára tó jinlẹ̀. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wa mọ pé a ti gba iyenú, ìfẹ́, àti ohùn Olúwa.15

Mo kéde pẹ̀lú gbogbo ọ̀wọ̀ pé ìtẹ̀síwájú ìfihàn ni a ti gbà tí a sì ngbà nípasẹ̀ àwọn ọ̀nà tí Olúwa ti gbé kalẹ̀. Mo jẹ́ri pé ìkéde titun tí Ààrẹ Nelson fúnni ní òwúrọ̀ yí jẹ́ ìfihàn láti bùkún gbogbo ènìyàn.

A Nawọ́ Ìfipè kan sí Gbogbo Ènìyàn láti Ṣàpèjẹ ní Tábìlì Olúwa.

Bákannáà a kéde ìfẹ́ àtọkànwá wa láti ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn wọnnì tí wọ́n nlàkàkà pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí wọn, tí wọn kò wà déédé, tàbí tí a ti yọ orúkọ wọn kúrò nínú àkọsílẹ̀ Ìjọ. A nifẹ láti ṣe àpèjẹ pẹ̀lú yín, “lórí àwọn ọ̀rọ̀ Krístì,“ ní tábìlì Olúwa, láti kọ́ àwọn ohun tí a gbọ́dọ̀ ṣe.1616 A nílò yín. Ìjọ nílò yín! Ọlọ́run nílò yín. Àdúrà atọkànwá wa ni pé kí ẹ darapọ̀ mọ́ wa ní jíjọ́sìn Olùgbàlà ayé. A mọ̀ pé àwọn kan lára yín ti gba àṣìṣe, àìnínurere, tàbí àwọn ìwà míràn tí kò dàbí ti Krístì. Bákannáà a mọ pé àwọn kan ti ní àwọn ìpènijà sí ìgbàgbọ́ wọn tí a kò lè mọyì, moore, ní ìmọ̀, tàbí ṣe.

Díẹ̀ lára àwọn akíkanjú jùlọ àti onígbàgbọ́ àwọn ọmọ ìjọ̀ ti jìyà ìpènijà kan sí ìgbàgbọ́ wọn fún ìgbà kan. Mo ní ìfẹ́ òtítọ́ àkọsílẹ̀ W. W. Phelps, ẹnití ó kọ Ìjọ sílẹ̀ tí ó sì jẹ́ri ní ìlòdì sí Joseph Smith ní ilé-ẹjọ́ ní Missouri. Lẹ́hìn ríronúpìwàdà, ó kọ̀wé sí Joseph, “Mo mọ ipò mi, o mọ̀ ọ́, Ọlọ́run sì mọ̀ ọ́, mo sì fẹ́ láti nígbàlà tí àwọn ọ̀rẹ́ mi yíò bá rànmílọ́wọ́.“17 Joseph daríjì í, ó mú u padà síṣẹ́, ó sì fi tìfẹ́tìfẹ́ kọwé, “Àwọn ọ̀rẹ́ lakọkọ tún jẹ́ ọ̀rẹ́ lẹ́ẹ̀kansi níkẹhìn.“18

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, láìka ipò yín sí, ẹ jọ̀wọ́ ẹ mọ̀ pé Ìjọ àti àwọn ọmọ̀ ìjọ yíò gbà yín padà!

Ìfihàn Araẹni sí Ìtọ́nisọ́nà àwọn Ìgbé Ayé Wa

Ìfihàn araẹni wà fún gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n nfi ìrẹ̀lẹ̀ wá ìtọ́nisọ́nà látọ̀dọ̀ Olúwa. Ó ṣe pàtàkì bi ti ìfìhàn wòlíì. Ìfihàn araẹni, ti ẹ̀mí látọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ ti jáde nínú míllíọ́nù gbìgbaẹ̀rí tó ṣeéṣe láti ṣe ìrìbomi àti ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ọmọ ìjọ̀ ti Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.

Ìfihàn araẹni ni ìbùkún jíjinlẹ̀ tí a gbà lẹ́hìn ìrìbọmi nígbàtí a gba “ìyàsímímọ́ nípasẹ̀ ìtẹ́wọ́gbà Ẹ̀mí Mímọ́.“19 Mo lè rántí ìfihàn pàtàkì ti ẹ̀mí nígbàtí mo jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún. Aràkùnrin mi iyebíye nwá ìtọ́nisọ́nà látọ̀dọ̀ Olúwa fún bí yíò ti fèsì sí bàbá wa ọ̀wọ́n, ẹnití kò fẹ́ kí arákùnrin mi sìn ninú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere. Mo gbàdúrà pẹ̀lú èrò òdodo pẹ̀lú mo sì gba ìfihàn araẹni ti òtítọ́ ìhìnrere.

Ojúṣe ti Ẹ̀mí Mímọ́.

Ìfihàn ti araẹni ni ó dálé àwọn òtítọ́ ti ẹ̀mí tí a gbà látọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́.20 Ẹ̀mí Mímọ́ ni olùfihàn àti olùjẹ́ri gbogbo òtítọ́, nípàtàkì èyí ti Olùgbàlà. Láìsí Ẹ̀mí Mímọ́, a kò lè mọ̀ pé Jésù ni Krístì dájúdájú. Ojúṣe ìkọ́ni rẹ̀ ni láti jẹ́ ẹ̀rí nípa Bàbá àti Ọmọ àti àwọn Àkórí Wọn àti ògo Wọn.

Ẹ̀mí Mímọ́ lè fún gbogbo ènìyàn lókun ní ọ̀nà alágbára.21 Okun yí kò ní wà léraléra àyàfi tí ẹnìkan bá nṣe ìrìbomi tí ó sì gba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ̀mí Mímọ́ nsìn bí àṣoju ìwẹ̀nùmọ́ bákannáà nínú ètò ìrònúpìwàdà àti ìdáríjì

Ẹ̀mí nbánisọ̀rọ̀ ní àwọn ọ̀nà ìyanu. Olúwa lo ìjúwe ẹlẹ́wà yí:

“Èmi ó wí fún yín nínú yín àti nínú ọkàn yín, nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́, èyí tí yíò wá sórí yín tí yíò gbé nínú ọkàn yín.

Báyìí, kíyèsi, èyí ni ẹ̀mí ìfihàn.“22

Bí ó tilẹ̀jẹ́pé ipa rẹ̀ lè lágbára kọjá àmì, ó nwá kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ bí ohun jẹ́jẹ́, kékeré.23 Àwọn ìwé mímọ́ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àpẹrẹ ti bí Ẹ̀mí ṣe nfún iyenu wa lókun, pẹ̀lú sísọ̀rọ̀ àláfíà sínú wa,24 wíwọ inú wa lọ̀,25 fífi òyé síwa nínú,26 àní àti ohùn kan sìnú wa.27

Àwọn ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ tí ó nmúra wa sílẹ̀ láti gba ìfihàn pẹ̀lú:

  • Gbígbàdúrà fún ìtọ́nisọ́nà ti ẹ̀mí. Tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ àti tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ a nílò láti wákiri kí a sì bèèrè28 àti kí a ní sùúrù àti fífi araẹni sílẹ̀.29

  • Mímúrasílẹ̀ fún ìmísí. Èyí nfẹ́ kí a wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìkọ́ni Olúwa àti ní gbígba àwọn òfin Rẹ̀.

  • Ṣíṣe àbápín oúnjẹ Olúwa ní yíyẹ. Nígbàtí a bá ṣe èyí, a njẹ́ ẹ̀rí a sì ndá májẹ̀mú pé a ó gbé orúkọ Ọmọ Mímọ́ Rẹ̀ lé orí arawa kí a sì rántí Rẹ̀ kí a sì pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́.

Àwọn ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ wọ̀nyí nmúra wa sílẹ̀ láti gbà, mọ̀, àti tẹ̀lé ìṣílétí àti ìtọ́nisọ́nà Ẹ̀mí Mímọ́. Èyí pẹ̀lú “àwọn ohun àláfíà … èyí tí ó nmú ayọ̀ [àti]… ìyè ayérayé wá.“30

Ìmùrasílẹ̀ ti ẹ̀mí wa ngbòòrò sí gidi nígbàtí a bá ṣe àṣàro àwọn ìwé mímọ́ àti àwọn òtítọ́ ìhìnrere léraléra tí a sì njíròrò ìtọ́nisọ́nà tí à nwá nínú wa. Ṣùgbọ́n rántí láti ní sùúrù àti ìgbẹ́kẹ̀lé ní àkokò-dídá Olúwa. Ìtọ́nisọ́nà ni à nfúnni látọwọ ọlọ́gbọ́n jùlọ Olúwa nígbàtí Òun bá mọ̀ọ́mọ̀ yàn láti kọ́ wa.31

Ìfihàn nínú àwọn Ìpè Wa àti Ìfúnni-níṣẹṣe

Ẹ̀mí Mímọ́ bákannáà yíò pèsè ìfihàn nínú àwọn ìpè wa àti ìfúnni-niṣeṣe. Nínú ìrírí mi, ìtọ́nisọ́nà ti ẹ̀mí pàtàkì jùlọ nwá léraléra nígbàtí a bá ngbìyànjú láti bùkún àwọn míràn nínú ìmúṣẹ àwọn ojúṣe wa.

Mo lè rántí bí ọ̀dọ́ bíṣọ́ọ̀pù kan ṣe ngba ipè ìtara kan látọ̀dọ̀ tọkọ-tayà ìgbà díẹ̀ ṣíwájú kí ntó lọ wọ ọkọ̀ òfúrufú fún àdéhùn okùn-òwò kan. Mo bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú Olúwa ṣíwájú kí wọ́n tó dé láti mọ̀ bí èmi ó ti bùkún wọn. A fi hàn mi irú wàhálà àti èsì tí èmi ó fún wọn. Ìtọ́nisọ́nà ti ìfihàn náà gbà mí láàyè láti mú àwọn ojúṣe mímọ́ mi ṣẹ sí ìpè mi bí bíṣọ́ọ̀pù bíótilẹjẹ́pé àkokò kúkurú ni ó wà. Àwọn bíṣọ́ọ̀pù ní gbogbo ayé bákannáà ṣe àbápín irú àwọn ìrírí kannáà pẹ̀lú mi. Bí ààrẹ èèkàn, èmi kò gba ìfihàn pàtàkì nìkan ṣùgbọ́n ìbáwí araẹni bákannáà tó ṣeéṣe láti ṣàṣeyege àwọn èrò Olúwa.

Mo mu dá yín lójú pé a lè gba ìtọ́nisọ́nà ti ìfihàn nípasẹ̀ ẹnìkọ̀ọkan wa bí a ṣe nfi tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà-àjàrà Olúwa. Púpọ̀jù lára ìtọ́nisọ́nà wa nwá látọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. Nígbàmíràn àti fún àwọn èrò kan, ó nwá tààtà látọ̀dọ̀ Olúwa. Mo jẹ́rĩ ti araẹni pé èyí jẹ́ òtítọ́. Ìtọ́nisọ́nà fún Ìjọ, ní gbogbogbò, nwá sọ́dọ̀ Ààrẹ àti wòlíì Ìjọ.

Àwa, bí àwọn Àpọ́stélì òde-òní, ti ní ànfàní ti ṣíṣe iṣẹ́ àti rírin ìrìnàjò pẹ̀lú wòlíì wa lọ́wọ́lọ́wọ́, Ààrẹ Nelson. Mo tun gbólóhùn ọ̀rọ̀ tí Wilford Woodruff sọ nípa Wòlíì Joseph Smith; ó jẹ́ òtítọ́ nákannáà nípa Ààrẹ Nelson. Mo ti rí “àwọn iṣẹ́ Ẹ̀mí Ọlọ́run pẹ̀lú rẹ̀, àti àwọn ìfihàn Jésù Krístì sí i àti ìmúṣẹ àwọn ìfihàn wọnnì.“32

Ẹ̀bẹ̀ ìrẹ̀lẹ̀ mi loni ni pé kí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa wá ìtẹ̀síwájú ìfihàn láti tọ́ wa sọ́nà nínú ayé wa àti láti tẹ̀lé Ẹ̀mí bí a ṣe njọ́sìn Ọlọ́run Bàbá ní orúkọ Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, nípa ẹnití a jẹ́ ẹ̀rí ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ Ráńpẹ́

  1. Ní 1960 nígbàtí a dín ọjọ́ orí fún iṣẹ́ ìsìn iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere fún àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin láti ogún ọdún sí ọdún mọ́kàndínlógún, mo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ogún ọdún tó kẹ́hìn.

  2. Wo “Ìmúpadàbọ̀sípò Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ìhinrere Jésù Krísti: Ìkéde Igba Ọdún Kan Sí Àgbáyé.” in Russell M. Nelson, “Gbọ́ Tirẹ̀,” Làíhónà, May 2020, 91. Ìpolongo yí papọ̀ mọ́ àwọn marun míràn tí a ti gbà ní àkokò yí nípasẹ̀ Àjọ Ààrẹ Kínní àti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlà.

  3. Ìkọ́ni àwọn Ààrẹ Ìjọ: Spencer W. Kimball (2006), 243; bákannáà wo Matthew 16:13–19.

  4. Moses 4:2.

  5. Mósè 7:62. Olúwa tẹ̀síwájú, “And righteousness and truth will I cause to sweep the earth as with a flood, to gather out mine elect from the four quarters of the earth” (Moses 7:62; bákannáà wo Psalm 85:11).

  6. Ezra Taft Benson, “The Gift of Modern Revelation,” Ensign, Nov. 1986, 80.

  7. See Ezra Taft Benson, “The Gift of Modern Revelation,” 80.

  8. Hugh B. Brown, “Joseph Smith among the Prophets” (Sixteenth Annual Joseph Smith Memorial Sermon, Logan Institute of Religion, Dec. 7, 1958), 7.

  9. Wo Hugh B. Brown, “Joseph Smith among the Prophets,” 7. In all cases, the revelations are in harmony with the word of God given to previous prophets.

  10. Wo Official Declaration 2; bákannáà wo 2 Nephi 26:33. The revelation implemented doctrine set forth in the Book of Mormon that “all are alike unto God,” including “black and white, bond and free, male and female” (2 Nephi 26:33). This remarkable revelation was received and confirmed in the sacred upper room of the Salt Lake Temple by the Council of the First Presidency and Quorum of the Twelve Apostles.

  11. Many of the Apostles indicated that the revelation was so powerful and so sacred that any words used to describe it would be insufficient and, in some ways, would diminish the deep and powerful nature of the revelation.

  12. Wo “Ẹbí Náà: Ìkéde Kan Sí Àgbáyé,” Liahona, May 2017, 145. Ìpolongo yí ni Ààrẹ Gordon B. Hinckley kéde ní ìpàdé gbogbogbò Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ tí a ṣe ní Ọjọ́ Kẹtàlélógún Oṣù Kẹsan, 1995, in Salt Lake City, Utah. Bákannáà wo Thomas S. Monson, “Welcome to Conference,” Liahona, Nov. 2012, 4–5. Ààrẹ Monson polongo ọjọ́ orí kékeré si fún iṣẹ́ ìsìn iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere.

  13. Quentin L. Cook, “Deep and Lasting Conversion to Heavenly Father and the Lord Jesus Christ,” Liahona, Nov. 2018, 11.

  14. The revelations related to sacred temple ordinances were implemented in all temples beginning on January 1, 2019. It is important to understand that specific details about temple ordinances are only discussed in the temple. However, principles are taught. Alàgbà David A. Bednar beautifully taught the significance of temple covenants and ordinances and how through them “the power of godliness can flow into our lives” (“Let This House Be Built unto My Name,” Làìhónà May 2020, 86).

  15. This process and the meetings held occurred in the Salt Lake Temple in January, February, March, and April 2018. The final revelation to the First Presidency and the Quorum of the Twelve was on April 26, 2018.

  16. Wo 2 Néfì 32:3.

  17. Àwọn Ènìyàn Mímọ́: Ìtàn Ìjọ Jésù Krístì ní àwọn Ọjọ́ Ìkẹhìn, vol. 1, Òṣùwọ̀n O`títọ́, 1815-1846 (2018), 418.

  18. Àwọn Ènìyàn Mímọ́, 1:418.

  19. 3 Néfì 27:20.

  20. The Holy Ghost is a member of the Godhead (see 1 John 5:7; Doctrine and Covenants 20:28). He has a body of spirit in the form and likeness of man (see Doctrine and Covenants 130:22). His influence can be everywhere. He is unified in purpose with our Heavenly Father and Jesus Christ, our Savior.

  21. Fún òye níní ìmọ̀ ìmọ́lẹ̀ Krístì àti ìyàtọ̀ laarin Ìmọ́lẹ̀ àti Krístì àti Ẹ`mí Mímọ́, wo 2 Nephi 32; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 88:7, 11–13; ”Ìmọ́lẹ̀ Krístì,” Ìtumọ̀ Bíbélì. Bákannáà wo, Boyd K. Packer, “Ìmọ́lẹ̀ Krístì,” Liahona, Apr. 2005, 8–14.

  22. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 8:2-3.

  23. Wo Helaman 5:30; Doctrine and Covenants 85:6.

  24. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 6:3.

  25. Wo Doctrine and Covenants 128:1.

  26. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 11:13.

  27. Wo Enos 1:10.

  28. Wo Matteu 7:7-8.

  29. Wo Mòsíàh 3:19.

  30. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 42:61.

  31. Neal A. Maxwell, Gbogbo Ohun Wọ̀nyí Yíò Fún Ọ Ní Ìrírí (2007), 31.

  32. Wilford Woodruff, ní Ìkọ́ni àwọn Ààrẹ Íjọ: Joseph Smith (2007), 283.