Ori 32
Àwọn angẹ́lì sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí Mímọ́—Àwọn ènìyàn gbọdọ̀ gbàdúrà kí wọ́n sì rí ìmọ̀ gbà fún àwọn tìkarãwọn láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa.
1 Àti nísisìyí, kíyèsĩ i, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, mo ṣèbí ẹ̀yin wádĩ díẹ̀ ní ọkàn yín nípa ohun èyí tí ẹ̀yin yíò ṣe lẹ́hìn tí ẹ̀yin bá ti wọlé nípasẹ̀ ọ̀nà nã. Ṣùgbọ́n, kíyèsĩ, ẽṣe tí ẹ̀yin fi nwádĩ àwọn ohun wọ̀nyí ní ọkàn yín?
2 Ẹ̀yin kò ha rántí pé mo wí fún yín pé lẹ́hìn tí ẹ̀yin bá ti gba Ẹ̀mí Mímọ́ ẹ̀yin lè sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ahọ́n àwọn angẹ́lì? Àti nísisìyí, báwo ni ẹ̀yin ṣe lè sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ahọ́n àwọn angẹ́lì bíkòṣe tí ó jẹ́ nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́?
3 Àwọn angẹ́lì nsọ̀rọ̀ nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí Mímọ́; nítorí-èyi, wọ́n nsọ àwọn ọ̀rọ̀ Krístì. Nítorí-èyi, mo wí fún yín, ẹ ṣe àpéjẹ lórí àwọn ọ̀rọ̀ Krístì; nítorí kíyèsĩ i, àwọn ọ̀rọ̀ Krístì yíò sọ fún yín gbogbo àwọn ohun èyí tí ó yẹ kí ẹ ṣe.
4 Nítorí-èyi, nísisìyí lẹ́hìn tí mo ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, bí òye wọn kò bá yé e yín yíò jẹ́ nítorí pé ẹ̀yin kò bèrè, bẹ̃ni ẹ̀yin kò kànkùn; nítorí-èyi, a kò mú yín wá sínú ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ kò lè ṣe aiparun nínú òkùnkùn.
5 Nítorí kíyèsĩ i, mo tun wí fún yín pé bí ẹ̀yin yíò bá wọlé nípasẹ̀ ọ̀nà nã, kí ẹ sì gba Ẹ̀mí Mímọ́, òun yíò fi gbogbo àwọn ohun hàn sí yin èyí tí ó yẹ kí ẹ sẹ.
6 Kíyèsĩ i, èyí ni ẹ̀kọ́ Krístì, kì yíò sì sí ẹ̀kọ́ sí i tí a ó fi fún ni títí di lẹ́hìn tí òun yíò fi ara rẹ̀ hàn sí yín nínú ara. Nígbàtí òun yíò sì fi ara rẹ̀ hàn sí yín nínú ara, àwọn ohun èyí tí òun yíò sọ fún yín ni ẹ̀yin yíò ṣọ́ láti ṣe.
7 Àti nísisìyí èmi, Nífáì, kò lè sọ̀rọ̀ sí i; Ẹ̀mí dá ọ̀rọ̀ sísọ mi dúró, a sì fi mí sílẹ̀ láti ṣọ̀fọ̀ nítorí ti àìgbàgbọ́, àti ìwà búburú, àti àìmọ̀, àti ọrùn líle àwọn ènìyàn; nítorí wọn kì yíò wádĩ ìmọ̀, tàbí kí ìmọ̀ nlá yé wọn, nígbàtí a fi fún wọn ní kerekere, àní ní kerekere bí ọ̀rọ̀ ṣe lè wà.
8 Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, mo wòye pé ẹ̀yin nwádĩ síbẹ̀síbẹ̀ ní ọkàn yín; ó sì mú mi kẹ́dùn pé èmi gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ nípa ohun yí. Nítorí bí ẹ̀yin bá fetísílẹ̀ sí Ẹ̀mí èyí tí nkọ́ ènìyàn láti gbàdúrà, ẹ̀yin yíò mọ̀ pé ẹ̀yin gbọdọ̀ gbàdúrà; nítorí ẹ̀mí ibi kì í kọ́ ènìyàn láti gbàdúrà, ṣùgbọ́n ó nkọ́ ọ pé òun kò gbọdọ̀ gbadura.
9 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, mo wí fún yín pé ẹ̀yin gbọdọ̀ gbàdúrà nígbà-gbogbo, kí ẹ má sì ṣe ṣãrẹ̀; pé ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ ṣe ohunkóhun sí Olúwa àfi níṣãjú bí ẹ̀yin yíò bá gbàdúrà sí Baba ní orúkọ Krístì, kí òun kí ó lè ya ìṣe yín sí mímọ́ sí yín, kí ìṣe yín lè wà fún àlãfíà ọkàn yín.