Àwọn Ìwé Mímọ́
2 Nífáì 5


Ori 5

Àwọn ará Nífáì ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ará Lámánì, wọ́n pa òfin Mósè mọ́, wọ́n sì kọ́ tẹ́mpílì kan—Nítorí ti àìgbàgbọ́ wọn, a ké àwọn ará Lámánì kúrò níwájú Olúwa, a fi wọ́n bú, wọ́n sì di pàṣán sí àwọn ará Nífáì. Ní ìwọ̀n ọdún 588 sí 559 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Kíyèsĩ i, ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, kígbe púpọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run mi, nítorí ti ìbínú àwọn arákùnrin mi.

2 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, ìbínú wọn pọ̀síi sí mi, tóbẹ̃ tí wọ́n wá láti mú ẹ̀mí mi lọ.

3 Bẹ̃ni, wọ́n nkùn sí mi, wípé: Arákùnrin àbúrò wa nrò láti jọba lórí wa; a sì ti ní ìdánwò púpọ̀ nítorí rẹ̀; nítorí-èyi, nísisìyí ẹ jẹ́kí á pa á, kí àwa má lè rí ìpọ́njú mọ́ nítorí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀. Nítorí kíyèsĩ i, àwa kì yíò gbà fun láti jẹ́ alákõso wa; nítorí ó jẹ́ ti àwa, tí a jẹ́ arákùnrin àgbà, láti jọba lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí.

4 Nísisìyí èmi kò kọ sórí àwọn àwo wọ̀nyí gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí wọ́n fi kùn sí mi. Sùgbọ́n ó tó mi láti sọ, pé wọ́n nwá láti mú ẹ̀mí mi kúrò.

5 Ó sì ṣe tí Olúwa kìlọ̀ fún mi, wípé kí èmi, Nífáì, kí nlọ kúrò lọ́dọ̀ wọn kí nsì sá lọ sínú ijù, àti gbogbo àwọn tí yíò lọ pẹ̀lú mi.

6 Nítorí-èyi, ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, mú ìdílé mi, àti pẹ̀lú Sórámù àti ìdílé rẹ̀, àti Sãmú, ẹ̀gbọ́n mi àti ìdíle rẹ̀, àti Jákọ́bù àti Jósẹ́fù, àwọn àbúrò mi, àti àwọn arábìnrin mi pẹ̀lú, àti gbogbo àwọn tí yíò lọ pẹ̀lú mi. Gbogbo àwọn tí yíò sì lọ pẹ̀lú mi ni àwọn wọnnì tí wọ́n gbàgbọ́ nínú àwọn ìkìlọ̀ àti àwọn ìfihàn Ọlọ́run; nítorí-èyi, wọ́n fetísílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ mi.

7 A sì kó àwọn àgọ́ wa àti àwọn ohun èyíkéyi tí ó bá lè ṣe fún wa, a sì rin ìrìn-àjò ní ijù fún ìwọ̀n ọjọ́ púpọ̀. Lẹ́hìn tí a sì ti rin ìrìn-àjò fún ìwọ̀n ọjọ́ púpọ̀ a tẹ́ àwọn àgọ́ wa dó.

8 Àwọn ènìyàn mi sì fẹ́ pé kí á pe orúkọ ibẹ̀ ní Nífáì; nítorí-èyi, a pè e ní Nífáì.

9 Gbogbo àwọn wọnnì tí ó wà pẹ̀lú mi sì mu lórí wọn láti pe ara wọn ní àwọn ènìyàn Nífáì.

10 A sì gbìyànjú láti pa àwọn ìdájọ́, àti àwọn ìlànà, àti àwọn òfin Olúwa mọ́ nínú óhun gbogbo, gẹgẹbi òfin Mósè.

11 Olúwa sì wà pẹ̀lú wa; a sì ṣe rere lọ́pọ̀lọpọ; nítorí a fún irúgbìn kalẹ̀, a sì tún kórè ní ọ̀pọ̀. A sì bẹ̀rẹ̀sì tọ́jú ọ̀wọ́ ẹran, àti agbo ẹran, àti àwọn ẹran onirũru gbogbo.

12 Èmi, Nífáì, sì ti mú àwọn ìwé ìrántí nì èyí tí a fín sórí àwọn àwo idẹ wá pẹ̀lú; àti bọ̃lù nì pẹ̀lú, tàbí atọ́nà, èyítí a pèsè fún bàbá mi nípa ọwọ́ Olúwa, gẹ́gẹ́bí èyítí a kọ.

13 Ó sì ṣe tí a bẹ̀rẹ̀sí ṣe rere lọ́pọ̀lọpọ̀, tí a sì ndi púpọ̀ ní ilẹ̀ nã.

14 Èmi, Nífáì, sì mú idà Lábánì, ní àwòṣe rẹ̀ mo sì ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ idà, kí àwọn ènìyàn tí à npè ní àwọn ará Lámánì báyĩ má bã wá bá wa kí wọ́n sì pa wá run ní ọ̀nàkọnà; nítorítí mo mọ́ ìríra wọn sí èmi àti àwọn ọmọ mi àti àwọn wọnnì tí a pè ní àwọn ènìyàn mi.

15 Mo sì kọ́ àwọn ènìyàn mi láti kọ́ àwọn ilé, àti láti ṣiṣẹ́ ní irú igi gbogbo, àti níti irin, àti níti bàbà, àti níti idẹ, àti níti akọ-irin, àti níti wúrà, àti níti fàdákà, àti níti àwọn irin àìpò tútù oníyebíye, èyí tí ó wà ní ọ̀pọ̀ nlá.

16 Èmi, Nífáì, sì kọ́ tẹ́mpìlì kan; mo sì kàn án bĩ irú tẹ́mpìlì ti Sólómọ́nì àfi pé a kò kọ́ ọ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun iyebíye; nítorí a kò lè rí wọn lórí ilẹ̀ nã, nítorí-èyi, a kò lè kọ́ ọ bí tẹ́mpìlì Sólómọ́nì. Ṣùgbọ́n irú kíkàn rẹ̀ jẹ́ bí ti tẹ́mpìlì ti Sólómọ́nì; iṣẹ́ èyí nã sì dára lọ́pọ̀lọpọ̀.

17 Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, mú kí àwọn ènìyàn mi lãpọn, kí wọ́n sì siṣẹ́ pẹ̀lú ọwọ́ wọn.

18 Ó sì ṣe tí wọ́n fẹ́ pé kí èmi jẹ́ ọba wọn. Ṣùgbọ́n èmi, Nífáì, nfẹ́ pé kí wọn má ní ọba; bíótilẹ̀ríbẹ̃, mo ṣe fún wọn gẹ́gẹ́bí èyí tí ó wà ní ipá mi.

19 Sì kíyèsĩ i, àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa ni a ti mú ṣẹ sí àwọn arákùnrin mi, èyí tí ó sọ nípa wọn, pé kí èmi ó jẹ́ alákõso wọn àti olùkọ́ wọn. Nítorí-èyi, èmi ti jẹ́ alákõso wọn àti olùkọ́ wọn, gẹ́gẹ́bí àwọn òfin Olúwa, títí di àkókò tí wọ́n wá láti mú ẹ̀mi mi kúrò.

20 Nítorí-èyi, ọ̀rọ̀ Olúwa ni a mú ṣẹ èyí tí ó wí fún mi, wípé: Níwọ̀n bí wọn kì yíò fetísílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ a ó gé wọn kúrò níwájú Olúwa. Sì kíyèsĩ i, a gé wọn kúrò níwájú rẹ̀.

21 Ó sì ti mú kí ìfibú wá sórí wọn, bẹ̃ni, àní ìfibú kíkan, nítorí ti àìṣedẽdé wọn. Nítorí kíyèsĩ i, wọ́n ti sé ọkàn wọn le síi, tí wọ́n ti di bí òkúta ìbọn; nítorí-èyi, bí wọ́n ṣe funfun, tí wọ́n sì lẹ́wà tí wọ́n sì ládùn lọ́pọ̀lọpọ̀, ki wọn má bã jẹ́ ẹ̀tàn sí àwọn ènìyàn mi Olúwa Ọlọ́run mú kí àwọ̀ ara dúdú wá si órí wọn.

22 Báyĩ í sì ni Olúwa Ọlọ́run wí: èmi yíò mú kí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́gbin sí àwọn ènìyàn rẹ, àfi tí wọ́n bá ronúpìwàdà ní ti àìṣedẽdé wọn.

23 A ó sì fi irú-ọmọ ẹni nã bú tí ó bá dàpọ̀ pẹ̀lú irú-ọmọ wọn; nítorí a ó fi wọ́n bú àní pẹ̀lú ìfibú kannã. Olúwa sì sọ ọ́, a sì ṣe é.

24 Nítorí ti ìfibú wọn èyí tí ó wà lórí wọn wọ́n sì di aláiníṣẹ́lápá ènìyàn, tí ó kún fún ìwà ìkà àti àrékérekè, wọ́n sì wá àwọn ẹranko ìgbẹ́ kiri nínú ijù.

25 Olúwa Ọlọ́run sì wí fún mi: Wọn yíò jẹ́ pàṣán sí irú-ọmọ rẹ, láti rú wọn sókè ní ìrántí mi; níwọ̀n bí wọn kò bá ní rántí mi, kí wọ́n sì fetísílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ mi, wọn yíò fi pàṣán ná wọ́n àní sí ìparun.

26 Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, ya Jákọ́bù àti Jósẹ́fù sí mímọ́, kí wọn lè jẹ́ àwọn àlùfã àti àwọn olùkọ́ lórí ilẹ̀ àwọn ènìyàn mi.

27 Ó sì ṣe tí a gbé ní irú ìgbé ayò.

28 Ọgbọ̀n ọdún sì ti kọjá lọ láti ìgbà tí a ti kúrò ní Jerúsálẹ́mù.

29 Èmi, Nífáì, sì ti pa àwọn ìwé-ìrántí nì mọ́ sórí àwọn àwo mi, èyí tí mo ti ṣe, ti àwọn ènìyàn mi di báyĩ.

30 Ó sì ṣe tí Olúwa Ọlọ́run wí fún mi: Ṣe àwọn àwo míràn; ìwọ yíò sì fín àwọn ohun púpọ̀ sórí wọn èyí tí ó dára lójú mi, fún èrè àwọn ènìyàn rẹ.

31 Nítorí-èyi, èmi, Nífáì, láti ní ígbọ́ran sí àwọn òfin Olúwa, lọ mo sì ṣe àwọn àwo wọ̀nyí orí èyí tí mo ti fín àwọn ohun wọ̀nyí sí.

32 Mo sì fín ohun èyí tí ó jẹ́ wíwù sí Ọlọ́run. Bí inú àwọn ènìyàn mi bá sì dùn sí àwọn ohun Ọlọ́run inú wọn yíò sì dùn sí àwọn ìfín mi èyí tí ó wà lórí àwọn àwo wọ̀nyí.

33 Bí àwọn ènìyàn mi bá sì fẹ́ láti mọ́ apá tí ó pàtàkì jùlọ ní ti ìwé ìtàn àwọn ènìyàn mi wọn kò ní ṣe àìwádí àwọn àwo mi míràn.

34 Ó sì tó mi láti sọ pé ogõjì ọdún ti kọjá lọ, a sì ti ní àwọn ogun àti àwọn ìjà ná pẹ̀lú àwọn arákùnrin wa.